ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g99 8/8 ojú ìwé 31
  • “Gbogbo Èèyàn Kọ́ Ló Ń Jẹ Nínú Àǹfààní Náà”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Gbogbo Èèyàn Kọ́ Ló Ń Jẹ Nínú Àǹfààní Náà”
  • Jí!—1999
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìyàtọ̀ Tó Wà Láàárín Ọlọ́rọ̀ àti Tálákà Ń Pọ̀ Sí I
    Jí!—2000
  • Ipò Òṣì ‘Ọ̀ràn Ìṣòro Tí A Kò Fiyè Sí’
    Jí!—1997
  • Àwọn Tí Òṣì Dì Nígbèkùn
    Jí!—1998
  • Ìwọra—Kí Ló Ń Ṣe fún Wa?
    Jí!—1997
Àwọn Míì
Jí!—1999
g99 8/8 ojú ìwé 31

“Gbogbo Èèyàn Kọ́ Ló Ń Jẹ Nínú Àǹfààní Náà”

ÌRÒYÌN 1998 ti Ẹ̀ka Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Tí Ń Rí sí Ọ̀ràn Ìdàgbàsókè Ènìyàn, ìròyìn ọdọọdún tí Ẹ̀ka Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Tí Ń Rí sí Ọ̀ràn Ìdàgbàsókè, tàbí UNDP ṣe, dá lórí ìlò yàlàyàlà táráyé ń lo àwọn ohun àmúṣọrọ̀. Ó sọ pé jákèjádò ayé, owó tí a ń ná lórí àwọn ohun àmúṣọrọ̀ ti fi ìlọ́po mẹ́fà pọ̀ ju iye tí a ná ní ọdún 1950 lọ, ó sì ti fi ìlọ́po méjì pọ̀ ju ti ọdún 1975 lọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìlò yàlàyàlà yìí ń lọ lọ́wọ́, ọ̀gá àgbà ẹ̀ka UNDP, James Gustave Speth, sọ pé: “Gbogbo èèyàn kọ́ ló ń jẹ nínú àǹfààní náà.”

Kó lè yée yín: Ẹja tí àwọn ènìyàn ìpín ogún tó lọ́rọ̀ jù lọ lára àwọn olùgbé ayé ń jẹ fi ìlọ́po méje pọ̀ ju èyí tí àwọn ènìyàn ìpín ogún tó kúṣẹ̀ẹ́ jù lọ ń jẹ. Bákan náà ni ẹran tí àwọn ìpín ogún tó lọ́rọ̀ jù lọ ń jẹ fi ìlọ́po mọ́kànlá pọ̀, agbára mànàmáná tí wọ́n ń lò fi ìlọ́po mẹ́tàdínlógún pọ̀, ìkànnì tẹlifóònù tí wọ́n ní fi ìlọ́po mọ́kàndínláàádọ́ta pọ̀, bébà tí wọ́n ń lò fi ìlọ́po mẹ́tàdínlọ́gọ́rin pọ̀, ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tí wọ́n ní sì fi ìlọ́po mọ́kàndínláàádọ́jọ pọ̀ ju èyí tí àwọn ènìyàn ìpín ogún tó kúṣẹ̀ẹ́ jù lọ lágbàáyé ní.

Ilé iṣẹ́ rédíò àjọ UN sọ̀rọ̀ lórí àwárí yìí pé kí àwọn ohun àlùmọ́nì ilẹ̀ má bàa máa dín kù, àwọn orílẹ̀-èdè onílé iṣẹ́ ẹ̀rọ ńláńlá ní láti yíwọ́ bí wọ́n ṣe ń lò wọ́n padà. Nígbà kan náà, àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n lọ́rọ̀ gan-an ní láti pín lára ọrọ̀ wọn fún àwọn orílẹ̀-èdè tó kúṣẹ̀ẹ́ lágbàáyé kí àwọn náà lè jàǹfààní sí i lára àwọn ohun àlùmọ́nì ilẹ̀ ayé. Báwo ni ọrọ̀ tí wọ́n máa pín fún wọn yóò ṣe pọ̀ tó?

Ọ̀gbẹ́ni Speth fojú díwọ̀n pé bí àwọn orílẹ̀-èdè onílé iṣẹ́ ẹ̀rọ ńláńlá bá lè sọ iye tí wọ́n fi ń ṣèrànlọ́wọ́ fún ìdàgbàsókè ní lọ́wọ́lọ́wọ́ di ìlọ́po méjì—láti àádọ́ta bílíọ̀nù dọ́là sí ọgọ́rùn-ún bílíọ̀nù dọ́là lọ́dún—gbogbo àwọn òtòṣì ayé yóò lè jàǹfààní oúnjẹ, ìlera, ẹ̀kọ́, àti ilé. Bẹ́ẹ̀, àádọ́ta bílíọ̀nù dọ́là lè dà bí owó ńlá. Àmọ́, Ọ̀gbẹ́ni Speth rán wa létí pé: “Iye yẹn ni Yúróòpù ń ná lórí sìgá lọ́dọọdún, ìdajì iye tí Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà sì ń ná lórí ọtí líle lónìí yìí nìyẹn.”

Nígbà náà, ó ṣe kedere pé, sísapá takuntakun láti túbọ̀ pín àwọn ọrọ̀ àlùmọ́nì inú ilẹ̀ pílánẹ́ẹ̀tì yìí lọ́gbọọgba yóò ṣèrànwọ́ ńlá láti fòpin sí ipò òṣì tí ń hanni léèmọ̀. Kí ni a ó fi ṣe èyí? Ọkùnrin kan tó ń bá àjọ UN ṣiṣẹ́ sọ pé: “Ní paríparí rẹ̀, ohun tí a nílò ni pé kí ọkàn, èrò inú, àti ìfẹ́ inú àwọn ènìyàn yí padà.” Ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn ló gbà pẹ̀lú rẹ̀, àmọ́ wọ́n tún ronú pé bó ti wù kí àwọn àjọ tí ń bójú tó ètò ìlú lónìí ní èrò rere lọ́kàn tó, wọn ò lè ṣe irú ìyípadà bẹ́ẹ̀, ká má tilẹ̀ wá sọ ti mímú àwọn ìwà bí ìwọra kúrò.

Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ní ti àwọn tí ọ̀ràn ọjọ́ ọ̀la ìdílé aráyé àti pílánẹ́ẹ̀tì wa ń jẹ lọ́kàn, ìrètí ṣì wà. Ó dùn mọ́ni nínú láti mọ̀ pé Ẹlẹ́dàá ilẹ̀ ayé ti ṣèlérí láti wá nǹkan gidi ṣe sí àwọn ìṣòro aráyé. Onísáàmù sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Dájúdájú, ilẹ̀ ayé yóò máa mú èso rẹ̀ wá; Ọlọ́run, tí í ṣe Ọlọ́run wa, yóò bù kún wa. Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọkà yóò wá wà lórí ilẹ̀; àkúnwọ́sílẹ̀ yóò wà ní orí àwọn òkè ńlá.” (Sáàmù 67:6; 72:16) Bẹ́ẹ̀ ni, olúkúlùkù àwọn tí ń gbé lórí ilẹ̀ ayé yóò wá “jẹ nínú àǹfààní náà”!

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́