Ìyàtọ̀ Tó Wà Láàárín Ọlọ́rọ̀ àti Tálákà Ń Pọ̀ Sí I
“Ìlọsíwájú ti ṣẹlẹ̀ nínú ọ̀ràn dídín ipò òṣì kù lágbàáyé láàárín àádọ́ta ọdún tó kọjá ju bó ṣe rí láàárín ọ̀rúndún márùn-ún tó ṣáájú.” Ìwé UNDP Today, tí Àjọ Ìwéwèé fún Ìdàgbàsókè ní Àjọ Ìparapọ̀ Orílẹ̀-Èdè ṣe ló sọ ọ̀rọ̀ yìí. “Láti ọdún 1960 làwọn orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà ti ṣe é tí iye àwọn ọmọdé tó ń kú ò fi pọ̀ mọ́. Wọ́n rí sí i pé ìṣẹ̀lẹ̀ àìjẹunkánú dín kù sí ìwọ̀n ìlàta, wọ́n sì ṣe é kí iye àwọn tó ń [forúkọ sílẹ̀] láti kàwé fi ìdá kan nínú mẹ́rin pọ̀ sí i.” Ṣùgbọ́n, ìwé kan náà yìí sọ pé, bí gbogbo ìtẹ̀síwájú yìí ṣe ń lọ, àwọn tó wà ní ipò òṣì “ṣì pọ̀” jákèjádò ayé.
Èyí tó wá burú jù ni pé ìwà àìṣẹ̀tọ́ ń pọ̀ sí i láwùjọ, ó sì ń gbèèràn láàárín àwùjọ kan sí òmíràn. Catherine Bertini, ọ̀gá àgbà Ẹ̀ka Àbójútó Ọ̀ràn Oúnjẹ Lágbàáyé ní Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, sọ pé: “Táa bá fi wé bó ṣe rí lọ́dún kan sẹ́yìn, àwọn èèyàn púpọ̀ sí i lebi ń pa lágbàáyé, tí wọn ò jẹun kánú.” Ní gidi, nǹkan bí òjìlélẹ́gbẹ̀rin mílíọ̀nù èèyàn lebi ń pa lọ́sàn-án lóru ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, èyí tó lé ní bílíọ̀nù kan lára wọn ni kì í rí omi tó dáa láti mu, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ tó bílíọ̀nù kan ààbọ̀ èèyàn tó jẹ́ pé owó iṣẹ́ òòjọ́ tí wọn ń gbà ò tó dọ́là kan. Mary Robinson, tó jẹ́ Ọ̀gá Àgbà Ẹ̀ka Àbójútó Ọ̀ràn Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ní Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, kìlọ̀ pé, “inú ewu la wà, ewu pé a óò dé ibì kan tí ayé á ti pín sí méjì, kò sì ní jẹ́ ti pípín sí àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà àti àwọn tó ti gòkè àgbà o, àmọ́ á pín sí àwọn tó ti gòkè àgbà tán àti àwọn tí kò lè gòkè àgbà mọ́.”
Kí ló máa ná àwùjọ àgbáyé òde òní tí àwọn èèyàn ibẹ̀ jẹ́ bílíọ̀nù mẹ́fà láti dí àlàfo ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn ọlọ́rọ̀ àti àwọn tálákà? Ó lè máà tó béèyàn ṣe rò. Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ṣírò pé àá nílò bílíọ̀nù mẹ́sàn-án dọ́là (dọ́là kan ààbọ̀ lóríjorí) sí i lọ́dún láti lè pèsè ìmọ́tótó àti omi tó mọ́ tónítóní jákèjádò ayé àti pé àá tún nílò bílíọ̀nù mẹ́tàlá dọ́là sí i (nǹkan bíi dọ́là méjì lóríjorí) lọ́dún kí gbogbo èèyàn ayé lè wà nílera, kí wọ́n sì jẹun kánú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iye owó yìí jọjú, ó jọ pé kò tó nǹkan tí a bá fi wé iye tí gbogbo ayé ń ná lórí àwọn iṣẹ́ mìíràn. Láti ṣàpèjúwe èyí, lọ́dún kan lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ayé ná irinwó lé márùndínlógójì bílíọ̀nù dọ́là (àádọ́rin dọ́là lóríjorí) sórí ìpolówó ọjà, wọ́n sì ná okòódínlẹ́gbẹ̀rin bílíọ̀nù dọ́là (àádóje dọ́là lóríjorí) sórí ọ̀ràn ogun. Ó ṣe kedere pé, dídí àlàfo ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn tó ní lọ́wọ́ àti àwọn tí ò ní kì í ṣe ọ̀ràn wíwá owó tó pọ̀ gan-an bí kò ṣe ọ̀ràn gbígbé àwọn ohun pàtàkì tó yẹ ká kọ́kọ́ mú ṣe kalẹ̀.