Àràmàǹdà Itẹ́ Òkú
LÁTỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ ECUADOR
NÍ ÌLÚ tó ń jẹ́ Ibarra, ní àríwá Quito tí í ṣe olú ìlú Ecuador, itẹ́ òkú kan wà níbẹ̀ tó yani lẹ́nu—el cementerio de los pobres (Itẹ́ Òkú Àwọn Òtòṣì). Kí ló mú un kó yàtọ̀? Àwọn àwòrán tí wọ́n yà gàdàgbàgàdàgbà sára ògiri rẹ̀ níta wá láti inú àwọn ìwé tí Watch Tower Society ṣe!a Ojú ewé keje ìwé Ìṣípayá—Òtéńté Rẹ Títóbi Lọ́lá Kù Sí Dẹ̀dẹ̀! ni wọ́n ti mú àwòrán tó wà láàárín ògiri náà. Wọ́n kọ ọ̀rọ̀ tó tẹ̀ lé e yìí sí òkè àwòrán Jòhánù, lédè Sípéènì pé: “Ìjọba Ọlọ́run túmọ̀ sí òdodo àti àlàáfíà àti ìdùnnú. Róòmù 14:17.” Àwọn ọ̀rọ̀ inú ìwé Mátíù 11:28 ló wà lápá òsì, ó kà pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá, tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, èmi yóò sì tù yín lára,” láti inú Ìtumọ̀ Ayé Tuntun. Láìsí àní-àní, ògiri itẹ́ òkú yìí wá di ohun tó ń darí àwọn èèyàn sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Láti ṣe ohun tí òfin béèrè, èèyàn gbọ́dọ̀ gba àṣẹ kó tó lo àwọn àpilẹ̀kọ tàbí àwòrán inú ìwé tí Watch Tower ṣe, ó sì gbọ́dọ̀ kọ ọ́ síbẹ̀ pé Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania ló ni wọ́n.