Àbẹ̀wò sí Ilé Elégbòogi Kan ní China
KWOK KIT ti ń ṣàìsàn fún ọjọ́ mélòó kan, nítorí náà, ó pinnu láti lọ rí dókítà. Nítorí pé ó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ China, ó yàn láti lọ rí oníṣègùn ìbílẹ̀ China kan. Ọ̀rẹ́ ìdílé rẹ̀ kan mọ dókítà kan tó jẹ́ oníṣègùn ìbílẹ̀, tó ní ṣọ́ọ̀bù kan tó ti ń ta egbòogi ìbílẹ̀ ní tòsí. Ọ̀rẹ́ Kwok Kit náà sọ fún un pé oníṣègùn náà lè ka àgbo fún un tí yóò wo àìsàn tó ń ṣe é.
Ní China, gẹ́gẹ́ bó ṣe rí ní èyí tó pọ̀ jù lọ ní ìhà gúúsù Ìlà Oòrùn Éṣíà, ìyàtọ̀ wà gan-an láàárín kí èèyàn lọ rí dókítà níbẹ̀ àti kí èèyàn lọ rí dókítà ní àwọn orílẹ̀-èdè Ìwọ̀ Oòrùn ayé. Ní Ìwọ̀ Oòrùn ayé, lílọ rí dókítà sábà máa ń jẹ́ sísọ tẹ́lẹ̀ pé èèyàn fẹ́ wá rí dókítà, lílọ sí ọ́fíìsì dókítà náà, kí dókítà ṣe àyẹ̀wò ẹni, àti kí ó kọ oògùn fúnni. Lẹ́yìn náà, aláìsàn náà gbọ́dọ̀ lọ síbi tí wọ́n ti ń gba oògùn kí wọ́n lè kó oògùn tí dókítà kọ fún un. Ní ti dókítà kan ní ilẹ̀ China, ìlànà náà túbọ̀ rọrùn ju ìyẹn lọ. Wàá gba ṣọ́ọ̀bù alágbo lọ, níbi tí ó ti sábà máa ń ṣẹlẹ̀ pé oníṣègùn kan ń gbé ibẹ̀, tí onítọ̀hún á sì tún jẹ́ dókítà lọ́nà ìṣègùn ti China. Ó lè yẹ̀ ọ́ wò, kó mọ àìsàn tó ń ṣe ọ́, kó wọn egbòogi fún ọ, kó sì sọ bí o ṣe máa lò ó fún ọ—gbogbo ìyẹn nígbà ìbẹ̀wò kan ráńpẹ́!a
A Ha Lè Pe Ewé ní Oògùn Bí?
Nígbà tó jẹ́ pé àwọn oríṣiríṣi oògùn òyìnbó, àti abẹ́rẹ́ mọ́ ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ará Ìwọ̀ Oòrùn ayé lára, síbẹ̀ irú àwọn oògùn wọ̀nyẹn ṣì jẹ́ ṣẹ̀ṣẹ̀dé. Fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún, àwọn èèyàn ti gbára lé fífi àwọn ohun tí Ọlọ́run dá ṣèwòsàn. Fún àpẹẹrẹ, àwọn oníṣègùn tí wọ́n jẹ́ ọmọ Hébérù ní àwọn àkókò tí a kọ Bíbélì lo àwọn nǹkan bí òróró, básámù, àti wáìnì láti fi ṣèwòsàn. (Aísáyà 1:6; Jeremáyà 46:11; Lúùkù 10:34) Ó ṣe kedere pé wọ́n máa ń fi ìṣù ọ̀pọ̀tọ́ gbígbẹ lẹ́ oówo kó lè sàn.—2 Àwọn Ọba 20:7.
Ní gidi, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo orílẹ̀-èdè tàbí èèyàn ló ti lo egbòogi àti onírúurú àgbo rí láti fi wo àìsàn àti àrùn kan. Kódà, ọ̀pọ̀ nǹkan amóúnjẹ-tasánsán tí wọ́n ń fi sínú oúnjẹ lónìí ni wọ́n ti kọ́kọ́ lò gẹ́gẹ́ bí egbòogi. Èyí kì í ṣe pé irú àṣà bẹ́ẹ̀ máa ń fìgbà gbogbo yọrí sí rere. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìgbàgbọ́ nínú ohun asán àti àìmọ̀kan sábà máa ń wọ ọ̀ràn náà. Síbẹ̀síbẹ̀, irú àwọn ọ̀nà bẹ́ẹ̀ tí wọ́n ń gbà tọ́jú aláìsàn ti wà láti ọdún gbọ́nhan. Kódà, díẹ̀ lára àwọn oògùn tó wọ́pọ̀ jù lọ lónìí ni wọ́n mú láti ara igi.
Àbá Èrò Orí àti Àṣà Ìṣègùn Ilẹ̀ China
Fífi egbòogi wo àìsàn jẹ́ apá pàtàkì nínú ìtàn ilẹ̀ China. Ìtàn ìṣẹ̀ǹbáyé sọ pé Huang Di, Olú Ọba Aláwọ̀ Ìyeyè, ló kọ ìwé Nei Jing, tí í ṣe ìlànà ìtọ́jú àwọn àìsàn pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́, tí àwọn oníṣègùn ilẹ̀ China ṣì ń gbé yẹ̀ wò dòní.b Ìlànà yìí, tí àríyànjiyàn ti wà nípa ìgbà tí wọ́n kọ ọ́, sọ̀rọ̀ nípa ọ̀pọ̀ àwọn ohun kan náà tí ìwé ìṣègùn tí wọ́n ṣe ní Ìwọ̀ Oòrùn ayé yóò sọ. Ohun tó jíròrò kò mọ sórí àwárí àìsàn, àwọn àmì àrùn, àwọn okùnfà àrùn, ìtọ́jú àrùn, àti ìdènà àwọn àrùn ṣùgbọ́n ó tún sọ nípa ìgbékalẹ̀ ara àti bí àwọn ẹ̀yà ara ṣe ń ṣiṣẹ́.
Gẹ́gẹ́ bí ó ti rí gẹ́lẹ́ nípa ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àkọ́mọ̀ọ́ṣe ní ìhà Gúúsù ìlà oòrùn Éṣíà, ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ yin àti yang ní ipa tó lágbára lórí àbá èrò orí àti àṣà ìṣègùn ilẹ̀ China. Nínú ọ̀ràn yìí, yin dúró fún ohun tútù, yang sì dúró fún ohun gbígbóná—wọ́n tún dúró fún ọ̀pọ̀ ohun mìíràn tó jẹ́ òdì kejì ara wọn.c Ní àfikún sí i, ibi tí okun ara wà ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà akupọ́ńṣọ̀, jẹ́ ìhà kan tí wọ́n máa ń gbé yẹ̀ wò láti ṣàwárí àìsàn àti ìtọ́jú rẹ̀. Wọ́n á wá júwe àwọn ewé àti oúnjẹ tí wọ́n rò pé ó tutù tàbí tó gbóná fúnni láti gbógun ti ohun tó fa àìṣedéédéé yin àti yang lára aláìsàn náà.
Fún àpẹẹrẹ, wọ́n a sọ pé ara aláìsàn kan tó ní àrùn ibà ń gbóná, nítorí náà àwọn ewé tí wọ́n sọ pé ó ń mú nǹkan tutù ni wọ́n á júwe fún un. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kì í dárúkọ yin àti yang mọ́ ní pàtó, àwọn ìlànà kan náà ni wọ́n ṣì ń lò láti mọ bí wọn yóò ṣe tọ́jú aláìsàn. Ṣùgbọ́n báwo ni dókítà onímọ̀ ìṣègùn ilẹ̀ China ṣe ń ṣàwárí àìsàn tó ń ṣeni? Báwo sì ni ṣọ́ọ̀bù tí wọ́n ti ń ta egbòogi ṣe rí? Láti mọ̀, ẹ ò ṣe jẹ́ ká tẹ̀ lé Kwok Kit lọ sí ṣọ́ọ̀bù tí ọ̀rẹ́ rẹ̀ júwe fún un?
Ṣọ́ọ̀bù Àwọn Egbòogi Tó Ṣàjèjì
Ìyàlẹ́nu ṣẹlẹ̀ o! Lónìí, Kwok Kit ní láti dúró díẹ̀ kó tó rí dókítà. Ó jọ pé ọ̀fìnkìn ń jà, nítorí náà aláìsàn méjì ti débẹ̀ ṣáájú rẹ̀. Ẹ jẹ́ ká máa fìyẹn wò yíká inú ṣọ́ọ̀bù náà.
Bí a ṣe wọlé, ohun tó kọ́kọ́ gba àfiyèsí wa ni àwọn nǹkan gbígbẹ tí wọ́n kó jọ gègèrè—olú, oríṣi ìgbín scallop, abalone, ọ̀pọ̀tọ́, kóró èso igi, àti àwọn ohun jíjẹ mìíràn—tí wọ́n kó sínú àwọn àpótí tó wà ní ṣíṣí sílẹ̀ lẹ́nu ọ̀nà àbáwọlé. Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn ohun jíjẹ pẹ̀lú wà níbẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn kan lára wọn lè wà lára egbòogi tí wọ́n máa júwe fúnni.
Nígbà tí a wo ibòmíràn, a ṣàkíyèsí àwọn pẹpẹ onígíláàsì tí wọ́n gbé kọ́ sí ẹ̀gbẹ́ méjèèjì inú ṣọ́ọ̀bù tóóró náà. Àwọn ewé, ohun àmúṣọrọ̀ inú ilẹ̀, àti ẹ̀yà ara àwọn ẹranko tó ti gbẹ tó ṣọ̀wọ́n tàbí àwọn tó jẹ́ àkànṣe tó sì wọ́n gan-an ló wà lórí àwọn pẹpẹ náà. Nígbà tí a wò ó dáadáa, a ṣàkíyèsí ìwo ìgalà, àwọn péálì, àti àwọn aláǹgbá àti àwọn ẹja gbígbẹ olórí bíi ti ẹṣin, bákan náà la rí àwọn ohun ṣíṣàjèjì mìíràn. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ a máa ń rí àwọn nǹkan bí ìwo àgbáǹréré, àpò òróòro béárì, àti ẹ̀yà ara àwọn ẹranko mìíràn lórí àwọn àtẹ bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí a kì í rí wọn mọ́ nítorí wọ́n ti fòfin dè wọ́n.
Ní apá ibòmíràn nínú ṣọ́ọ̀bù náà, a rí páálí tí wọ́n di àwọn ewé tó wà fún wíwo àwọn àrùn tó wọ́pọ̀ bí ọ̀fìnkìn àti inú rírun sí, a sì tún rí àwọn egbòogi China tí wọ́n kì sínú àwọn ìgò tí wọ́n tò jọ síbì kan. Ìwọ sáà ti sọ ohun tó ń ṣe ọ́ fún akọ̀wé ṣọ́ọ̀bù náà, òun á sì fún ọ ní egbòogi tí wọ́n kì sínú ìgò tàbí kó ka àwọn ewé oríṣiríṣi tí wọ́n dì pọ̀ fún ọ, yóò sì sọ fún ọ bí o ṣe máa sè é tóo bá délé.
Lẹ́gbẹ̀ẹ́ kan ògiri, lẹ́yìn akọ̀wé ṣọ́ọ̀bù náà, a ṣàkíyèsí àwọn pẹpẹ tí wọ́n to àwọn ìgò gígùn sí, tí onírúurú gbòǹgbò igi, ewé, àti ẹ̀ka igi wà. Àwọn egbòogi wọ̀nyí ni àwọn oníbàárà mọ̀ dáadáa, wọ́n sì lè rà wọ́n láti fi tọ́jú ara wọn tàbí kí wọ́n lọ sè wọ́n. Ní ẹ̀gbẹ́ kejì inú ṣọ́ọ̀bù náà, kọ́ńbọ́ọ̀dù kan wà níbẹ̀ tó ga kan àjà, wọ́n to àwọn àpótí púpọ̀ tó ti gbó sínú rẹ̀. Wọ́n ń pè é ni baizigui, tàbí “kọ́ńbọ́ọ̀dù ọgọ́rùn-ún ọmọdé,” nítorí pé àpótí tó máa ń wà nínú irú kọ́ńbọ́ọ̀dù egbòogi bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ ọgọ́rùn-ún tàbí kó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn àpótí wọ̀nyí ń jẹ́ kí wọ́n lè tètè máa mú àwọn ewé tí wọ́n sábà máa ń kà fún àwọn èèyàn, àwọn tí wọ́n sábà máa ń lò jù sì wà ní àwọn apá ibi tí wọ́n á ti lè tètè mú wọn. Wọn kì í sábà kọ orúkọ sára àwọn àpótí náà. Àwọn akọ̀wé tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ náà mọ ibi pàtó tí ewé kọ̀ọ̀kan wà.
Ṣàkíyèsí bí akọ̀wé náà ṣe jáfáfá tó bó ṣe ń wọn àwọn ewé náà fún obìnrin kan tó ń tajà fún. Ó ń lo òṣùwọ̀n kan láti Éṣíà, tó jẹ́ ẹlẹgẹ́ ṣùgbọ́n tó sì ń wọn nǹkan dáadáa—ó jẹ́ igi kan tí wọ́n sàmì sí lára, tí wọ́n fi okùn mẹ́ta gbé páànù roboto kan kọ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ kan rẹ̀ tí wọ́n sì gbé òṣùwọ̀n kan tó ṣeé sún sí ẹ̀gbẹ́ kejì rẹ̀. Ó mọ̀ pé àwọn ewé kan lè pààyàn tí a bá lò ó jù, nítorí náà ó gbọ́dọ̀ kíyè sí bó ṣe ń wọ̀n wọ́n. Kì í ṣe gbogbo ohun tí wọ́n ń tà níbẹ̀ ni wọ́n máa ń wọ̀n. Nísinsìnyí, a rí i tó ń bu onírúurú ewé tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdajì ẹ̀kúnwọ́ rẹ̀ láti inú àpótí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, tó sì ń dà wọ́n sínú bébà tí wọ́n fi ń pọ́n nǹkan. Òótọ́ lo sọ, ewé tó ṣà yìí tún ní ìkarahun kòkòrò cicada nínú. Bó ṣe ń di àwọn ewé tó ṣà jọ náà ló ń sọ fún obìnrin náà bó ṣe máa sè é.
Oríṣiríṣi ọ̀nà ni a ń gbà se ewé tí wọ́n bá kà fúnni, oríṣiríṣi ọ̀nà ni a sì ń gbà lò ó. Àwọn kan jẹ́ àgúnmu. Ẹni tí àìsàn ń ṣe yóò dà wọ́n sínú omi lílọ́wọ́ọ́rọ́ yóò sì gbé e mu. Àwọn kan jẹ́ ìyẹ̀fun. Oyin ni wọ́n fi ń lò wọ́n tàbí kí wọ́n fi àwọn oríṣi ọtí kan lò wọ́n. Ṣùgbọ́n, ó ní kí obìnrin yìí lo ọ̀nà tó wọ́pọ̀ jù lọ, ìyẹn pé kó sè é ní àgbo. Èyí túmọ̀ sí pé yóò se àwọn ewé náà nínú ìpó fún nǹkan bí wákàtí kan. Lẹ́yìn náà, yóò wá máa mu àgbo náà díẹ̀díẹ̀ ní wákàtí mélòó kan síra wọn. Bí obìnrin náà bá fẹ́ àwọn ewé tí wọ́n kà fún un náà sí i, ó wulẹ̀ ní láti padà wá sí ṣọ́ọ̀bù náà ni, wọ́n á sì tún ṣà á fún un.
Ó ti wá kan Kwok Kit báyìí láti lọ rí dókítà. Ṣùgbọ́n dókítà kò wo ìwọ̀n ìfúnpá rẹ̀, kò sì wọn bí ọkàn-àyà rẹ̀ ṣe ń lù kìkì sí. Ṣùgbọ́n ó béèrè lọ́wọ́ Kwok Kit pé báwo ló ṣe ń ṣe é. Ṣé ó ń rí oorun sùn? Ṣé oúnjẹ ń dà nínú rẹ̀ dáadáa, ṣé ó ń lè jẹun, ṣé àwọn ìfun rẹ̀ ń ṣiṣẹ́ dáadáa, ìdíwọ̀n ooru ara rẹ̀ ńkọ́, báwo ni awọ ara rẹ̀ ti rí àti àwọ̀ rẹ̀? Dókítà yẹ ojú rẹ̀ wò dáadáa àti àwọ̀ tí ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí ahọ́n rẹ̀ ní. Ní báyìí, ó ti ń yẹ ìwọ̀n ìlùkìkì ọkàn-àyà Kwok Kit wò nípa fífọwọ́ tẹ ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní ọrùn ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì lọ́nà tó yàtọ̀ síra, ìlànà yìí ni wọ́n gbà gbọ́ pé ó ń fi ipò tí onírúurú ẹ̀yà ara wà hàn. Kódà, dókítà náà tilẹ̀ ń ṣàkíyèsí òórùn èyíkéyìí tó ṣàjèjì tó bá gbọ́! Kí wá ló ń ṣe ọ̀rẹ́ wa o? Kò yani lẹ́nu láti mọ̀ pé ọ̀fìnkìn ló ń yọ Kwok Kit lẹ́nu. Ó nílò ìsinmi, kó sì mu omi púpọ̀ àti àgbo tí wọ́n kà fún un pé kó lọ sè, kó sì mu. Àgbo náà yóò korò, ṣùgbọ́n yóò jẹ́ kí ara rẹ̀ yá. Ní àfikún sí sísọ fún Kwok Kit pé kó yàgò fún àwọn oúnjẹ kan, dókítà náà tilẹ̀ ṣe inúure sí Kwok Kit, ó fún un ní èso kan tí kò ní jẹ́ kí ẹnu rẹ̀ máa korò lẹ́yìn tó bá mu àgbo rẹ̀.
Nítorí náà, Kwok Kit kó àgbo tí wọ́n kà fún un, ó sì bá tirẹ̀ lọ. Owó tó san fún rírí dókítà àti egbòogi tí wọ́n kà fún un kò tó ogún dọ́là—owó pọ́ọ́kú ni. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ewé náà kò ní woni sàn lọ́nà ìyanu ṣùgbọ́n ó yẹ kí ara Kwok Kit yá láàárín ọjọ́ mélòó kan péré. Ṣùgbọ́n kò gbọ́dọ̀ ṣe àṣìṣe tí àwọn kan ṣe, kó rò pé tí òun bá mu ún púpọ̀ ni ara òun á fi tètè yá. A sábà máa ń gbọ́ pé lílò tí àwọn èèyàn kan lo àwọn oríṣi egbòogi kan jù ló mú kó yọ wọ́n lẹ́nu gan-an.
Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ìlànà tó ń díwọ̀n egbòogi tó yẹ láti lò tàbí tó ń darí àwọn oníṣègùn ìbílẹ̀ China. Èyí ti ṣínà fún àwọn ọ̀gbẹ̀rì oníṣègùn àti títa àwọn àgbo tó léwu tí wọ́n ń sọ pé ó lè woni sàn. Nígbà náà, a wá lóye ìdí tó fi jẹ́ pé bí ọ̀pọ̀ aláìsàn ní ilẹ̀ Éṣíà bá fẹ́ yan oníṣègùn ìbílẹ̀ China tó máa tọ́jú wọn, wọ́n máa ń gbẹ́kẹ̀ lé àmọ̀ràn tí àwọn ẹbí àti àwọn ọ̀rẹ́ wọn tímọ́tímọ́ bá fún wọn.
Lóòótọ́, kò sí irú ìtọ́jú èyíkéyìí—yálà èyí tí wọ́n fi ewé tàbí oògùn òyìnbó ṣe—tó lè wo gbogbo àìsàn tán. Ṣùgbọ́n, ilé elégbòogi ní ilẹ̀ China àti dókítà tó jẹ́ oníṣègùn ìbílẹ̀ ṣì jẹ́ apá kan ìgbésí ayé wọn ní Éṣíà.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Jí! kò sọ pé irú ìtọ́jú kan pàtó ló dára láti wo àìsàn. Àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ rí i dájú pé irú ìtọ́jú èyíkéyìí tí wọ́n bá gbà kò lòdì sí àwọn ìlànà Bíbélì.
b Olú Ọba Aláwọ̀ Ìyeyè náà, tó jẹ́ alákòóso tó gbajúmọ̀ tó jẹ ṣáájú Zhou, ni ìtàn sọ pé ó ṣàkóso láti ọdún 2697 sí 2595 ṣááju Sànmánì Tiwa. Ṣùgbọ́n, ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ló gbà gbọ́ pé ìgbà tí ìṣàkóso Zhou dópin ni wọ́n tó kọ ìwé Nei Jing, tó jẹ́ láti nǹkan bí ọdún 1100 sí 250 ṣááju Sànmánì Tiwa.
c Lẹ́tà èdè China náà “yin” túmọ̀ sí “ìbòòji” tàbí “òjìji” táa bá ní ká sọ ọ́ láìlábùlà, ó sì dúró fún òkùnkùn, ohun tó tutù, tàbí ẹ̀yà obìnrin. “Yang,” tí í ṣe òdì kejì rẹ̀, dúró fún àwọn ohun tó ń dán yinrin, ohun tó gbóná, tàbí ẹ̀yà ọkùnrin.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
A lè rí àwọn èròjà tó ṣàjèjì, títí kan àwọn ẹja gbígbẹ olórí bíi ti ẹṣin ní àwọn ṣọ́ọ̀bù tí wọ́n ti ń ta egbòogi
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
Wọ́n ń fara balẹ̀ wọn àwọn gbòǹgbò igi gbígbẹ, ewé, àti ẹ̀ka igi