ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 10/8 ojú ìwé 17-21
  • Ohun Tó Sàn Ju Lílókìkí Nínú Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tó Sàn Ju Lílókìkí Nínú Ayé
  • Jí!—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bí Mo Ṣe Yan Iṣẹ́ Orin Kíkọ Láàyò
  • Bí Mo Ṣe Tún Èrò Mi Pa
  • Àwọn Ìpinnu Tí Mo Ṣe Lórí Iṣẹ́ Mi
  • Mo Dúró Lórí Ìpinnu Tí Mo Ṣe
  • “Níbo Ni Ìgbàgbọ́ Rẹ Wà?”
  • Mo Bẹ̀rẹ̀ Isẹ́ Alábòójútó Arìnrìn-Àjò
  • Bí Mo Ṣe Lo Àwọn Nǹkan Tí Mo Kọ́ Nígbà Tí Mo Wà Lọ́mọdé
  • Àwọn Ìrírí Mi Lẹ́nu Iṣẹ́ Arìnrìn-Àjò
  • Mo Dúpẹ́ Pé Ohun Tí Mo Yàn Ni Mo Yàn
  • Ogún-Ìní Ṣíṣọ̀wọ́n ti Kristian Kan
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Títẹ̀ Lé Ipasẹ̀ Àwọn Òbí mi
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • “Inú Rere Rẹ Onífẹ̀ẹ́ Sàn Ju Ìyè”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ogún Wa Nípa Tẹ̀mí Tí Ó Dọ́ṣọ̀
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
Àwọn Míì
Jí!—2004
g04 10/8 ojú ìwé 17-21

Ohun Tó Sàn Ju Lílókìkí Nínú Ayé

GẸ́GẸ́ BÍ CHARLES SINUTKO ṢE SỌ Ọ́

Ní ọdún 1957, wọ́n ní kí n wá kọrin fún ọ̀sẹ̀ mẹ́tàlá gbáko ní ìlú Las Vegas, ní ìpínlẹ̀ Nevada, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, wọ́n á sì máa fún mi ní ẹgbẹ̀rún kan dọ́là lọ́sẹ̀. Báwọn èèyàn bá sì gbádùn orin mi, wọ́n á tún gbà mí láyè kí n kọrin fún àádọ́ta ọ̀sẹ̀ sí i. Ìyẹn á sọ owó tí màá gbà di ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta dọ́là, ọmọdé owó kọ́ lowó yìí lákòókò yẹn. Ẹ jẹ́ kí n ṣàlàyé bó ṣe di pé wọ́n ń fiṣẹ́ olówó gọbọi yìí lọ̀ mí àti ohun tó mú kó ṣòro fún mi láti pinnu bóyá kí n gbà á tàbí kí n má gbà á.

NÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ Ukraine, tó wà ní ìlà oòrùn Yúróòpù, ni wọ́n bí bàbá mi sí lọ́dún 1910. Ní ọdún 1913, ìyá rẹ̀ mú un wá sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà níbi tó ti padà lọ bá ọkọ rẹ̀. Bàbá mi ṣègbéyàwó lọ́dún 1935, ọdún kan lẹ́yìn náà ni wọ́n bí mi ní ìlú Ambridge, ní ìpínlẹ̀ Pennsylvania. Láìpẹ́, láìjìnnà sí àkókò náà làwọn ẹ̀gbọ́n bàbá mi méjì tí wọ́n jẹ́ ọkùnrin di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Nígbà témi àtàwọn àbúrò mi ọkùnrin mẹ́ta ṣì kéré, ìlú New Castle ní ìpínlẹ̀ Pennsylvania ni ìdílé wa ń gbé, ìyá wa sì fìgbà díẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí. Kò sí èyí tó di Ẹlẹ́rìí nínú àwọn òbí mi lákòókò yẹn, ṣùgbọ́n bàbá mi gbà pé ohun tó bá wu àwọn ẹ̀gbọ́n òun ni wọ́n lè gbà gbọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé láti kékeré ni bàbá wa ti kọ́ wa láti nífẹ̀ẹ́ ilẹ̀ bàbá wa, kò fára mọ́ kí ẹnì kan máa dí ẹlòmíì lọ́wọ́ ṣíṣe ẹ̀sìn tó bá wù ú.

Bí Mo Ṣe Yan Iṣẹ́ Orin Kíkọ Láàyò

Àwọn òbí mi gbà pé alóyinlóhùn ni mí, nítorí náà wọ́n rúnpá rúnsẹ̀ sí i láti rí i pé mo di olórin. Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́fà tàbí méje, bàbá mi á gbé mi nà ró sí orí káńtà nílé ìgbafàájì alẹ́, màá wá máa kọrin, màá sì máa ta gìtá sí i. Orin tí mo máa ń kọ ni “Ìyá lalábàárò.” Orin yẹn ṣàpèjúwe àwọn ànímọ́ tó yẹ kí ìyá tó ṣabiyamọ ní, ìparí orin yẹn sì máa ń múni ronú gan-an ni. Àwọn ọkùnrin tó wà nílé ìgbafẹ́ náà, tí wọ́n ti máa ń gbà á pé á máa hó yèè, wọ́n á sì máa sọ owó sínú ate bàbá mi.

Ilé iṣẹ́ rédíò WKST tó wà ní New Castle ni mo ti kọ́kọ́ ṣe ètò orí rédíò, lọ́dún 1945, nígbà náà lọ́hùn-ún orin àdúgbò ni mò ń kọ. Nígbà tó yá mo bẹ̀rẹ̀ sí kọ àwọn orin tí wọ́n máa ń kọ lórí ètò Hit Parade tí wọ́n máa ń ṣe lórí rédíò alátagbà níbi tí wọ́n ti máa ń kọ orin mẹ́wàá àkọ́kọ́ nínú àwọn orín tó lòde. Lọ́dún 1950 ni mo kọ́kọ́ yọ lórí tẹlifíṣọ̀n lórí ètò Paul Whiteman. Títí di báyìí laráyé ṣì ń fẹ́ràn bó ṣe lo orin George Gershwin tí wọ́n ń pè ní “Rhapsody in Blue.” Láìpẹ́ sígbà yẹn ni bàbá mi ta ilé wa tó wà ní ìpínlẹ̀ Pennsylvania a sì kó lọ sí àgbègbè Los Angeles ní ìpínlẹ̀ California kí n lè tẹ̀ síwájú nínú iṣẹ́ orin kíkọ.

Bàbá mi jà fitafita fún mi gan-an o, kò pẹ́ tí mo fi ní ètò tèmi lórí rédíò ní ìlú Pasadena mo sì tún ní ètò ọlọ́gbọ̀n ìṣẹ́jú tí mo máa ń ṣe lórí tẹlifíṣọ̀n nílùú Hollywood. Ilé iṣẹ́ Capitol Records ni mo ti máa ń gba ohùn sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ olórin Ted Dale tí wọ́n pọ̀ gan-an mo sì di ọ̀kan lára àwọn akọrin ní ilé iṣẹ́ rédíò alátagbà ti CBS. Lọ́dún 1955, a gbé eré orín lọ síbi Adágún Omi Tahoe ní àríwá ìpínlẹ̀ California. Nígbà tí mo wà níbẹ̀ ni mo térò ara mi pa, mo padà lẹ́yìn ohun tí mò ń lé.

Bí Mo Ṣe Tún Èrò Mi Pa

Ṣáájú ìgbà yẹn ni ẹ̀gbọ́n bàbá mi tó ń jẹ́ John, tí òun náà ti kó kúrò ní Pennsylvania lọ sí ìpínlẹ̀ California fún mi ní ìwé “Jeki Ọlọrun Jẹ Olõtọ.”ab Mo mú ìwé náà dání lọ síbi Adágún Omi Tahoe. Lẹ́yìn tá a ti parí eré wa tó kẹ́yìn, lẹ́yìn tí aago méjìlá òru ti kọjá, mo bẹ̀rẹ̀ sí ka ìwé náà kí n tó lọ sùn. Inú mi dùn gan-an ni nígbà tí mo rí bí Bíbélì ṣe dáhùn àwọn ìbéèrè tó ti ń jẹ mí lọ́kàn.

Kò pẹ́ sígbà yẹn ni mo bẹ̀rẹ̀ sí jókòó sí àyíká ibi tá a ti ń ṣeré alẹ́ lẹ́yìn tá a bá ti ṣeré tán, tí màá sí máa bá àwọn òṣèré bíi tèmi sọ̀rọ̀, nígbà míì orí ọ̀rọ̀ la máa wà títí di ìdájí. Lára àwọn àkòrí tá a máa ń jíròrò ni bí ìgbésí ayé á ṣe rí lẹ́yìn ikú, ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìjìyà àti bóyá àwọn èèyàn ṣì máa fọwọ́ ara wọn pa ara wọn àti orí ilẹ̀ ayé run. Lóṣù bíi mélòó kan lẹ́yìn ìgbà náà, ìyẹn ní July 9, 1955, nígbà ìpàdé àgbègbè táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní pápá ìṣeré Wrigley Field nílùú Los Angeles, ni mo fẹ̀rí ìyàsímímọ́ mi láti sin Jèhófà Ọlọ́run hàn nípa ṣíṣe ìrìbọmi.

Kò tó oṣù mẹ́fà sígbà yẹn, láàárọ̀ ọjọ́ Kérésìmesì ọdún 1955, Henry Russell tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí bíi tèmi ní kí n sin òun lọ ká jọ lọ rí Jack McCoy, ọ̀gbẹ́ni kan tó ń fi orín ṣòwò. Henry fúnra rẹ̀ ni olùdarí orin níléeṣẹ́ NBC. Nígbà tá a sì débẹ̀, Jack ní káwọn ọmọ ẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta àti ìyàwó ẹ̀ jókòó kí wọ́n fetí sí wa bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń já àwọn ẹ̀bùn Kérésìmesì tí wọ́n gbà ni. Láìpẹ́ sígbà náà lòun àtìyàwó ẹ̀ di Ẹlẹ́rìí.

Láàárín àkókò yìí, mo bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ màmá mi lẹ́kọ̀ọ́, tọkàntọkàn ló sì fi gba òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, ó di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì di aṣáájú-ọ̀nà, ìyẹn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Nígbà tó yá àwọn àbúrò mi ọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà ṣèrìbọmi wọ́n sì ṣe nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà fún ìgbà díẹ̀. Lóṣù September ọdún 1956, nígbà tí mo wà lọ́mọ ogún ọdún, mo di aṣáájú-ọ̀nà.

Àwọn Ìpinnu Tí Mo Ṣe Lórí Iṣẹ́ Mi

Láàárín àkókò yìí George Murphy tó jẹ́ ọ̀rẹ́ alágbàtà mi sọ pé òun á gbé mi lárugẹ. George ti bá wọn ṣe ọ̀pọ̀ sinimá láàárín ọdún 1930 sí 1949. Pẹ̀lú bí Murphy ṣe bá mi lo ẹsẹ̀ sí i báyìí, oṣù December ọdún 1956 ni mo yọ nínú eré tí Jackie Gleason ṣe lórí tẹlifíṣọ̀n CBS, ní ìlú New York. Ohun tó wá gbé mi sáyé gan-an nìyẹn nítorí pé àwọn èèyàn tó wo eré yẹn tó mílíọ̀nù lọ́nà ogún. Nígbà tí mo wà ní New York ni mo dé olú ilé iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Brooklyn fún ìgbà àkọ́kọ́.

Lẹ́yìn tí mo ti bá wọn ṣe nínú eré Gleason tán, mo bá ilé iṣẹ́ ìgbohùnsílẹ̀ Metro-Goldwyn-Mayer ṣàdéhùn pé màá bá wọn kópa nínú eré fọ́dún méje. Gbogbo ìgbà ni wọ́n máa ń fi mí sínú eré TV Western tá a máa ń ṣe lórí tẹlifíṣọ̀n. Nígbà tó yá, ẹ̀rí ọkàn mi bẹ̀rẹ̀ sí dà mí láàmú nítorí pé ó gba pé kí n ṣe bí atatẹ́tẹ́ àti tàbọntàbọn nínú eré, ńṣe lèyí sì máa ń mú kí n ṣe bí ẹní tó ń ṣèṣekúṣe tó sì tún máa ń hu àwọn ìwà mìíràn tí kò yẹ Kristẹni. Nítorí náà, mo fi iṣẹ́ yẹn sílẹ̀. Àwọn tá a jọ wà lẹ́nu iṣẹ́ eré ṣíṣe rò pé orí mi ti dàrú ni.

Àkókò yẹn ni nǹkan tí mo sọ ní ìbẹ̀rẹ̀ ṣẹlẹ̀, ìyẹn bí wọ́n ṣe fi iṣẹ́ olówó ńlá lọ̀ mí pé kí n wá lọ máa ṣeré ní Las Vegas. Ọ̀sẹ̀ ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká wa ló yẹ kí n lọ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́. Bí mi ò bá lọ gba iṣẹ́ yẹn lákòókò yẹn, àǹfààní yẹn á fò mí ru. Ọkàn mi ńṣe kámi-kàmì-kámi lórí ọ̀ràn yìí nítorí pé bàbá mi ti ń retí ọjọ́ tí ọwọ́ mi á bẹ̀rẹ̀ sí tẹ owó jaburata! Mo sì ronú pé ó yẹ kí n sanjọ́ fún gbogbo ìlàkàkà rẹ̀ láti rí i pé mo di ẹni ńlá.

Nítorí náà, mo fọ̀rọ̀ lọ alábòójútó olùṣalága ìjọ wa, ìyẹn Carl Park, tóun náà jẹ́ olórin tó sì ti fìgbà kan rí jẹ́ atagòjé láwọn ọdún 1920, nílé iṣẹ́ rédíò WBBR ní New York. Mo ṣàlàyé fún un pé tí mo bá gba iṣẹ́ yìí, á ṣeé ṣe fún mi láti máa ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà jálẹ̀ ìgbésí ayé mi, láìsí pé mò ń táwọ́ ná. Ó sọ fún mi pé: “Mi ò lè sọ ohun tó o máa ṣe fún ọ, ṣùgbọ́n màá ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mọ ìpinnu tí wàá ṣe.” Ó bi mí léèrè pé: “Ṣé wàá lọ bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù bá fẹ́ wá bẹ ìjọ wa wò lọ́sẹ̀ yìí?” Ó tún wá fi kún un pé, “Kí lo rò pé Jésù á fẹ́ kó o ṣe?”

Ọ̀rọ̀ náà yé mi kọjá ibi tí ò sọ ọ́ dé. Nígbà tí mo sọ fún bàbá mi pé mo ti pinnu pé mi ò ní lọ gba iṣẹ́ tó ń dúró dè mí ní Las Vegas yẹn, ó sọ pé mo fẹ́ ba ayé òun jẹ́. Lóru ọjọ́ yẹn kò tètè sùn ó ń dúró dè mí pẹ̀lú ìbọn ìléwọ́ rẹ̀ lọ́wọ́. Ó fẹ́ pa mí, ṣùgbọ́n ó ti sùn lọ fọnfọn nígbà tí mo fi máa dé, ó ní láti jẹ́ pé ó ti mutí jù lálẹ́ ọjọ́ yẹn ló fà á. Lẹ́yìn náà ló fẹ́ para ẹ̀ sí ibi ìgbọ́kọ̀sí nípa gbígbé imú síbi ọ̀pá èéfín mọ́tò. Mo ké ìbòòsí, àwọn èèyàn sì bá mi dóòlà ẹ̀mí rẹ̀.

Ọ̀pọ̀ nínú ìjọ wa ló ń bẹ̀rù bàbá mi nítorí pé ó máa ń bínú fùfù ṣùgbọ́n alábòójútó àyíká wa Roy Dowell ò bẹ̀rù rẹ̀. Nígbà tí Roy lọ rí bàbá mi, bàbá mi ṣẹnu fóró sọ fún un pé nígbà tí wọ́n bí mi, kò sẹ́ni tó lérò pé mo lè yè é. Bàbá mi ti ṣèlérí fún Ọlọ́run pé bí mo bá yè, òun á yọ̀ǹda mi fún iṣẹ́ Ọlọ́run. Roy bi í léèrè bóyá ó ti rò ó rí pé Ọlọ́run lè máa retí pé kó mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Ńṣe ni ẹnu ya bàbá mi. Roy wá bi í léèrè pé, “Bí iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún bá yẹ Ọmọ Ọlọ́run, kí ló dé tí kò yẹ ọmọ tìẹ náà?” Lẹ́yìn ìjíròrò yìí, ó dà bíi pé bàbá mi ti gbà kí n ṣe ohun tó bá wù mí.

Nígbà tó di oṣù January ọdún 1957, Shirley Large wá láti Kánádà, òun àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, wọ́n wá kí àwọn ọ̀rẹ́ wọn. Nígbà tí mo bá Shirley àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ jáde nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ilé-dé-ilé lọ̀rọ̀ èmi àti ẹ̀ wọ̀. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni Shirley sìn mí lọ́ sí gbọ̀ngàn àríyá Hollywood Bowl, níbi tí èmi àti Pearl Bailey ti kọrin.

Mo Dúró Lórí Ìpinnu Tí Mo Ṣe

Ní oṣù September ọdún 1957, wọ́n yàn mí pé kí n lọ ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe ní ìpínlẹ̀ Iowa. Nígbà tí mo sọ fún bàbá mi pé mo ti pinnu láti gba iṣẹ́ náà, ńṣe ló mí kanlẹ̀ hìn-ìn. Kò mọ ohun tó fà á tó fi múmú láyà mi tó bẹ́ẹ̀. Mo wakọ̀ lọ sí Hollywood láti lọ fagi lé gbogbo àdéhùn orin kíkọ tí mo ṣe. Lára àwọn tí mo bá ṣàdéhùn pé màá ṣiṣẹ́ fún nígbà yẹn ni gbajúmọ̀ ọba orin náà, Fred Waring. Ó sọ fún mi pé tí mi ò bá mú àdéhùn mi láti kọrin ṣẹ, mi ò tún ní láǹfààní láti kọrin mọ́. Mo fún un lésì pé fífi tí mò ń fiṣẹ́ orin sílẹ̀ yìí, kí n bàa lè ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi fún Jèhófà Ọlọ́run ni.

Ọ̀gbẹ́ni Waring tẹ́tí sílẹ̀ títí mo fi sọ gbogbo nǹkan tí mo ní í sọ, bó sì ṣe fi sùúrù fèsì yà mí lẹ́nu. Ó ní: “Ọmọ ọlọ́mọ, ó dùn mí pé o fẹ́ fi iṣẹ́ dáadáa yìí sílẹ̀, ṣùgbọ́n ẹnu iṣẹ́ orin yìí ni mo ti lo gbogbo ìgbésí ayé mi mo sì ti wá rí i pé kì í kàn ṣe ká kọrin nìkan ni ìgbésí ayé wà fún. Ọlọ́run á máa fìbùkún sí gbogbo nǹkan tó o bá dáwọ́ lé o.” Mo ṣì rántí bí mo ṣe ń wakọ̀ lọ sílé lọ́jọ́ náà tèmi ti omijé ayọ̀ lójú mi, inú mi dùn pé mo ti di òmìnira, mo lè lo ìyókù ìgbésí ayé mi nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.

“Níbo Ni Ìgbàgbọ́ Rẹ Wà?”

Nílùú Strawberry Point ní ìpínlẹ̀ Iowa, táwọn tó wà níbẹ̀ ò ju ẹgbẹ̀fà lọ, ni mo ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà pẹ̀lú Joe Triff, ẹnì kejì mi. Shirley wá kí wa níbẹ̀ a sì sọ̀rọ̀ nípa ìgbéyàwó. Mi ò ní kọ́bọ̀ nípamọ́, òun náà ò sì ní eépìnnì. Ìkáwọ́ bàbá mi sì ni gbogbo owó tí mo tù jọ wà. Ìyẹn ni mo fi ṣàlàyé fún Shirley pé: “Mo fẹ́ fẹ́ ọ o, ṣùgbọ́n kí la ó fi máa gbọ́ bùkátà ara wa? Gbogbo owó tí mo ní nílé lóko ò ju ogójì dọ́là tí wọ́n máa ń fún mi lóṣù láti gbọ́ bùkátà mi gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe.” Wẹ́rẹ́ báyìí bó ṣe máa ń sọ ọ̀rọ̀ kàǹkà náà ló bi mí pé: “Há haá, Charles, níbo ni ìgbàgbọ́ rẹ wà? Jésù sọ pé tá a bá kọ́kọ́ wá Ìjọba Ọlọ́run àti òdodo rẹ̀, òun á fi àwọn nǹkan tá a nílò kún un fún wa.” (Mátíù 6:33) Ó tán, bọ́rọ̀ ṣe yanjú nìyẹn o. Ní November 16, ọdun 1957 la ṣègbéyàwó.

Mò ń kọ́ bàbá àgbẹ̀ kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì létí ìlú Strawberry Point. Bàbá yìí fi pákó kọ́lé kótópó kan tó gùn ní mítà mẹ́rin, ìyẹn ẹsẹ̀ méjìlá níbùú lóòró sórí ilẹ̀ rẹ̀ tó wà nínú pápá. Kò síná mànàmáná, kò sí omi ẹ̀rọ kò sì sí balùwẹ̀. Àmọ́ tá a bá lè gbébẹ́ o, kò ní gba kọ́bọ̀ lọ́wọ́ wa. Ilé àtijọ́ pátápátá ni, àmọ́ a wò ó pé ṣebí ká ti ríbi sùn tó bá dalẹ́ ni, nígbà tó jẹ́ pé látàárọ̀ dalẹ́, òde ẹ̀rí la máa wà.

Ìsun omi kan nítòsí ibẹ̀ ni mo ti máa ń pọ̀n omi. Iná igi là ń dá láti mú ilé móoru tá a sì ń fi iná karosín kàwé lálẹ́; sítóòfù oníkarosín ni Shirley fi ń dáná. Ọpọ́n tó ti gbó la fi ń wẹ̀. A máa ń gbọ́ báwọn ìkookò ṣe ń hu láàjìn òru, inú àwa méjèèjì sì dùn pé a jọ wà fúnra wa tá a sì ń sin Jèhófà pa pọ̀ níbi tí wọ́n ti nílò àwọn Kristẹni òjíṣẹ́ gan-an. Bill Malenfant àti Sandra ìyàwó ẹ̀, táwọn méjèèjì ń sìn báyìí ní orílé-iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Brooklyn, ń sìn bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe nígbà yẹn ní Decorah ní ìpínlẹ̀ Iowa tó fi nǹkan bí ọgọ́rùn-ún kìlómítà jìnnà sí wa. Wọ́n máa ń wá bá wa lo ọjọ́ kan lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀ ìjọ kékeré kan táwọn mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n wà níbẹ̀, fìdí múlẹ̀ ní ìlú Strawberry Point.

Mo Bẹ̀rẹ̀ Isẹ́ Alábòójútó Arìnrìn-Àjò

Ní oṣù May, ọdún 1960, wọ́n ní ká wá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àyíká, ìyẹn iṣẹ́ òjíṣẹ́ arìnrìn-àjo. Ìpínlẹ̀ North Carolina ni àyíká àkọ́kọ́ tá a bójú tó wà, lára àwọn ìlú tá a sì máa ń bẹ̀ wò níbẹ̀ ni ìlú Raleigh, Greensboro àti ìlú Durham àti ọ̀pọ̀ ìgbèríko kéékèèké mìíràn. Nǹkan dẹrùn díẹ̀ sí i fún wa níbẹ̀ nítorí pé a láǹfààní láti dé sọ́dọ̀ àwọn ìdílé tí wọ́n ń gbé níbi tí iná mànàmáná wà, kódà wọ́n tún ní ilé ìyàgbẹ́ tí wọ́n kọ́ mọ́lé. Àmọ́ a máa ń bẹ̀rù nígbà tá a bá wà lọ́dọ̀ àwọn tí wọn ò kọ́ ilé ìyàgbẹ́ mọ́lé nítorí bí wọ́n ṣe máa ń kílọ̀ fún wa. Wọ́n á ní ká ṣọ́ra nítorí àwọn ejò copperhead àti ejò àgbàfúùfúù tí wọ́n máa ń wà lójú ọ̀nà tá a lè gbà dé ibi tí ṣáláńgá wà!

Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1963, wọ́n gbé wa lọ sí àyíká kan ní ìpínlẹ̀ Florida, ìbẹ̀ ni mo ti kárùn pericarditis, àrùn yìí le débi pé díẹ̀ ló kù kí n kú. Bóyá ǹ bá tiẹ̀ kú, tí kì í bá ṣe ọpẹ́lopẹ́ tọkọtaya Bob àti Ginny Mackey tí wọ́n wá láti ìlú Tampa.c Wọ́n gbé mi lọ sọ́dọ̀ dókítà, kódà wọ́n san gbogbo owó tí wọ́n fi tọ́jú mi.

Bí Mo Ṣe Lo Àwọn Nǹkan Tí Mo Kọ́ Nígbà Tí Mo Wà Lọ́mọdé

Nígbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 1963, wọ́n pè mí sí New York láti wá báwọn ṣe lára iṣẹ́ tó so mọ́ ṣíṣètò àpéjọ ńlá kan táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fẹ́ ṣe níbẹ̀. Mo bá Milton Henschel, tó jẹ́ agbẹnusọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ síbi ètò ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò orí rédíò kan tí Larry King ṣe atọ́kùn rẹ̀. Títí dòní, èèkàn ṣì ni Ọ̀gbẹ́ni King lára àwọn tó ń ṣètò ìjíròrò lórí tẹlifíṣọ̀n. Ó fọ̀wọ̀ wa wọ̀ wá gan-an lọ́jọ́ yìí, ó tó bíi wákàtí kan lẹ́yìn tí ètò náà ti parí tó fi béèrè ọ̀pọ̀ ìbéèrè nípa iṣẹ́ wa.

Ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn yẹn kan náà, Harold King, míṣọ́nnárì kan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ tú sílẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n àwọn Kọ́múníìsì ní orílẹ̀-èdè Ṣáínà ṣèbẹ̀wò sí orílé-iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí. Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, ó bá àwọn èèyàn bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin [700] tí wọ́n kóra jọ sọ̀rọ̀, ó sọ díẹ̀ lára ìrírí rẹ̀ ó sì ṣàlàyé bí ọdún mẹ́rin tí òun lò nínú àhámọ́ ànìkànwà ṣe fún ìgbàgbọ́ òun lókun. Nígbà tó wà lẹ́wọ̀n, ó kọ àwọn orin tó dá lórí Bíbélì àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni.

Ní ìrọ̀lẹ̀ ọjọ́ mánigbàgbé yẹn, mo bá wọn kọ orin “Lati Ile de Ile,” èyí tó wà nínú ìwé orin táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò báyìí. Àwọn tá a jọ kọrin ọ̀hún ni Audrey Knorr, Karl Klein àti Fred Franz, àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n ti ń sin Jèhófà bọ̀ látọjọ́ pípẹ́ tí wọ́n sì ti kọ́ bí wọ́n ṣe máa lo ohùn gbẹ̀du. Nathan Knorr tó léwájú nínú iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí nígbà náà ní kí n kọ orin náà ní Àpéjọ “Ìhìn Rere Àìnípẹ̀kun” tá a ṣe ní Pápá Ìṣeré Yankee, mo sì kọ ọ́.

Àwọn Ìrírí Mi Lẹ́nu Iṣẹ́ Arìnrìn-Àjò

Nígbà tí mò ń sìn nílùú Chicago, ní ìpínlẹ̀ Illinois, ohun mánigbàgbé méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló ṣẹlẹ̀. Àkọ́kọ́ ni pé ìyàwó mi rí Vera Stewart tó wáàsù fún òun àti ìyá ẹ̀ lórílẹ̀-èdè Kánádà láàárín àwọn ọdún 1940. Ó máa ń dùn mọ́ Shirley, tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kànlá nígbà náà, bó ṣe ń gbọ́ nípa ìlérí Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì. Ó béèrè lọ́wọ́ Vera pé, “Ṣé o rò pé mo lè rí inú ayé tuntun yẹn wọ̀?” Vera dá a lóhùn pé, “Èmi ò rí nǹkan tó ní kó o má wọbẹ̀.” Kò sí èyí tó gbàgbé bí wọ́n ṣe sọ ọ̀rọ̀ yẹn lọ́jọ́ náà nínú wọn. Látìgbà tí Shirley ti pàdé Vera yẹn ló ti mọ̀ pé ohun tó wu òun láti ṣe ni pé kóun máa sin Jèhófà.

Èkejì ni pé Ẹlẹ́rìí kan bi mí bóyá mo rántí pé mo rí àpò ànàmá kan tó wúwo tó ìlàjì àpò ìrẹsì, níbi gọ̀bì ilé wa nígbà òtútù ọdún 1958. Mo kúkú rí i lóòótọ́. A rí i lẹ́yìn tá a tiraka délé nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan tí ìjì ń jà tí yìnyín sì ń já bọ́! Lóòótọ́, a ò mọ ibi tí àpò ànàmá náà ti wá o, ṣùgbọ́n a gbà pé ìpèsè Jèhófà ni. Yìnyín dídì tó kúnlẹ̀ ò jẹ́ ká lè jáde kúrò nínú ilé fọ́jọ́ márùn-ún ṣùgbọ́n ayọ̀ bá a ṣe ń fi ànàmá dá oríṣiríṣi àrà lóúnjẹ ń múnu wa dùn, a fi ànàmá ṣe pankéèkì, a yan án, a dín in, a gún un a sì tún sè é lọ́bẹ̀! Kò kúkú sóúnjẹ míì. Arákùnrin tó gbé ànàmá yìí wá fún wa ò mọ̀ wá, kò mọ ibi tá à ń gbé, ó ṣáà mọ̀ pé nǹkan ò ṣẹnuure fáwọn aṣáájú-ọ̀nà kan tó wà nítòsí rẹ̀ lákòókò yẹn. Ó sọ pé ó kàn sọ sóun lọ́kàn pé kóun bẹ̀rẹ̀ sí wádìí ibi tí tọkọtaya tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó yìí ń gbé. Àwọn àgbẹ̀ mọ aládùúgbò wọn bí ẹni mowó, tórí náà, kò pẹ́ tí wọ́n fi júwe ilé kótópó tá à ń gbé fún un, ó sì korí bọ inú yìnyín láti gbé ànàmá náà wá.

Mo Dúpẹ́ Pé Ohun Tí Mo Yàn Ni Mo Yàn

Lọ́dún 1993, lẹ́yìn tí mo ti lo ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n lẹ́nu iṣẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò, ìlera mi ti jagọ̀ débi pé mo ní láti fi àǹfààní iṣẹ́ ìsìn yẹn sílẹ̀. Èmi àti ìyàwó mi di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe tí ò lera, ẹnu iṣẹ́ yẹn la ṣì wà títí dòní. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó máa ń dùn mí pé mi ò lókun láti ṣiṣẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò mọ́, inú mi ṣì dùn pé mo lo okun mi bí mo ṣe lò ó.

Ọ̀nà ọ̀tọ̀ làwọn àbúrò mi mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yà sí. Owó làwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ń lé kiri nígbẹ̀yìngbẹ́yín, kò sì sí èyí tó ń sin Jèhófà nínú wọn mọ́ báyìí. Bàbá wa ṣèrìbọmi lọ́dún 1958. Òun àti màmá wa ti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti mọ Jèhófà, láti ya ìgbésí ayé wọn sí mímọ́ fún Un kí wọ́n sì ṣèrìbọmi. Àwọn méjèèjì kú lọ́dún 1999. Èyí túmọ̀ sí pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìpinnu tí mo ṣe láti kọ òkìkí àti ọrọ̀ nínú ayé ló mú kí bàbá mi àti ọ̀pọ̀ àwọn tóun àti ìyá mi ti fi òtítọ́ Bíbélì kọ́ ní ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun. Mo máa ń dà á rò lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan pé, ‘Ǹjẹ́ màá ṣì máa sin Jèhófà lọ ká ní mi ò ṣèpinnu tí mo ṣe níbẹ̀rẹ̀ yẹn?’

Ní nǹkan bí ọdún márùn-ún lẹ́yìn tí mo fi iṣẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò sílẹ̀, ara mi gbé kánkán díẹ̀ sí i, ó sì ṣeé ṣe fún mi láti ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi. Mò ń sìn báyìí bí alábòójútó olùṣalága ní ìjọ kan nílùú Desert Hot Springs, ní ìpínlẹ̀ California. Mo tún láǹfààní láti máa sìn gẹ́gẹ́ bí adelé alábòójútó àyíká àti nínú àwọn ìgbìmọ̀ àkànṣe lórí ìdájọ́, mo sì máa ń kọ́ wọn ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Ìsìn Aṣáájú Ọ̀nà lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan.

Títí dòní, mi ò lọ́rẹ́ẹ̀ míì tó dà bíi Shirley ìyàwó mi. Kò sí ọ̀dọ̀ ẹni tí mo lè wà tó lè dùn mọ́ mi bíi tiẹ̀. A máa ń sọ̀rọ̀ wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ lórí àwọn nǹkan tẹ̀mí, àwọn òtítọ́ Bíbélì tá à ń jíròrò máa ń dùn mọ́ wa gan-an ni. Mo ṣì máa ń dúpẹ́ láwọn ìgbà kọ̀ọ̀kan tí mo bá rántí àwọn ìbéèrè tó béèrè wẹ́rẹ́ lọ́jọ́ kìíní àná, léyìí tó lé ní ọdún mẹ́tàdínláàádọ́ta báyìí pé, “Há haá, Charles, níbo ni ìgbàgbọ́ rẹ wà?” Báwọn tọ́kọtaya Kristẹni tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó bá lè máa bí ara wọn nírú ìbéèrè bẹ́ẹ̀, mi ò lè sọ bí àwọn tá á máa nírú ayọ̀ àti ìbùkún táwa ti ní nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún á ṣe pọ̀ tó.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a John Sinutko jẹ́ Ẹlẹ́rìí olóòótọ́ fún Jèhófà títí tó fi kú lọ́dún 1996 lẹ́ni ọdún méjìléláàádọ́rùn-ún.

b Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde ṣùgbọ́n a ò tẹ̀ ẹ́ mọ́.

c Ìtẹ̀jáde Jí! ti January 8, 1976, ojú ìwé 11-15, gbé ìtàn tí Bob Mackey fẹnu ara ẹ̀ sọ jáde nípa bó ṣe kojú àrùn ẹ̀gbà.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

John, ẹ̀gbọ́n bàbá mi rèé lọ́dún 1935, ọdún yẹn náà ló ṣèrìbọmi

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Ilé onígi kótópó tá à ń gbé

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Fọ́tò kan táwọn òbí mi tí wọ́n ṣe olóòótọ́ dójú ikú yà lọ́dún 1975

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Èmi àti Shirley rèé báyìí

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́