Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Báwo Ni Kí N Ṣe Lo Ìgbésí Ayé Mi?
“Ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹ̀lẹ̀ lọ́jọ́ iwájú kì í kọ́kọ́ jọ mí lójú. Ṣùgbọ́n bó ṣe di pé ó kù dẹ̀dẹ̀ kí n jáde ilé ẹ̀kọ́, ó túbọ̀ wá ń yé mi síwájú sí i pé inú ayé lèmi náà mà ń lọ yìí, níbi tí màá ti máa ṣiṣẹ́ gidi. Tí màá sì dẹni ń fowó gbọ́ bùkátà ara mi.”— Alex, ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún.
NÍGBÀ tó o wà lọ́mọdé, ṣé o máa ń ronú nípa ohun tó o máa fẹ́ láti dà bó o bá dàgbà? Kí wá lèrò ẹ báyìí nípa àwọn nǹkan tó o máa ń rò yẹn? Ṣé bí wàá ṣe máa gbọ́ bùkátà ara ẹ bó o bá dàgbà máa ń kọ ẹ́ lóminú? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, kì í ṣe ìwọ nìkan. Ìwé Career Coaching Your Kids, tó sọ nípa báwọn ọmọ ṣe lè ṣèpinnu lórí ohun tí wọ́n fẹ́ dà lọ́la, sọ pé: “Ọ̀kan lára olórí ìṣòro tó máa ń kojú àwọn ọ̀dọ́ ni bí wọ́n á ṣe pinnu irú iṣẹ́ tí wọ́n á máa ṣe bí wọ́n bá dàgbà.”
Ó sì wá lè jẹ́ pé ọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ tí wàá máa ṣe ò tiẹ̀ sí lọ́kàn ẹ rárá báyìí. Nítorí ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àtimáa gbádùn ara ẹ lohun tó jẹ ẹ́ lógún. Kò sóhun tó burú nínú pé kó o gbádùn ara ẹ, nítorí pé Bíbélì sọ fún ẹ pé kó o “gbádùn ayé ẹ nígbà tó o ṣì wà ní ọ̀dọ́!” (Oníwàásù 11:9, Contemporary English Version) Bó ti wù kó rí ṣá, àkókò tó bójú mu pé kó o bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa bó o ṣe máa lo ìgbésí ayé ẹ nìyí o. Òwe 14:15 sọ pé: “Afọgbọ́nhùwà máa ń ronú nípa àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” Báwo lo ṣe lè ronú nípa àwọn ìṣísẹ̀ tìẹ?
“Mọ Ibi Tó O Forí Lé”
Ká sọ pé ò ń wéwèé láti rìnrìn àjò tó fi ọ̀pọ̀ kìlómítà jìn síbi tó ò ń gbé. Ó ṣeé ṣe kó o kọ́kọ́ wá ẹni júwe ọ̀nà fún ẹ kó o lè pinnu ọ̀nà tó máa dáa jù lọ láti gbà. Bó ṣe yẹ kó rí náà nìyẹn bó o bá ń wéwèé nípa ọjọ́ iwájú. Michael, ọ̀dọ́mọkùnrin kan tó ń ṣiṣẹ́ ní ọ̀kan lára ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà báyìí, sọ pé: “Ọ̀kan-ò-jọ̀kan làwọn nǹkan tó o lè yàn láti ṣe.” Báwo lo wá ṣe lè mú ọ̀kan lára àwọn ohun tó wà fún ẹ láti yàn yẹn o? Michael sọ pé: “Gbogbo ẹ̀ sinmi lórí bó o bá ṣe fẹ́ láti lo ìgbésí ayé ẹ.”
Bó o bá ṣe fẹ́ lo ìgbésí ayé ẹ la lè fi wé ibi tó ò ń lọ gan-an. Kò dájú pé wàá débẹ̀ bó o bá kàn ń rìn káàkiri láìmọ ibi tó ò ń lọ. Ohun tí ì bá sàn jù ni pé kó o ní kẹ́nì kan tún ibi tó ò ń lọ júwe fún ẹ. Kó o sì forí lé ibẹ̀ ní tààràtà. Bó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ò ń tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ ìyànjú tó wà nínú ìwé Òwe 4:26 nìyẹn, níbi tó ti sọ pé: “Mú ipa ọ̀nà ẹsẹ̀ rẹ jọ̀lọ̀.” Ìtumọ̀ Bíbélì Contemporary English Version túmọ̀ gbólóhùn náà báyìí: “Mọ ibi tó o forí lé.”
Bí ọdún ti ń gorí ọdún, ọ̀pọ̀ ìpinnu pàtàkì ni wàá ṣe nípa ìjọsìn, iṣẹ́, ìgbéyàwó, ìdílé, àtàwọn ọ̀ràn pàtàkì mìíràn. Ó máa rọrùn fún ẹ láti ṣe àwọn ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání bó o bá kọ́kọ́ mọ ibi tó o forí lé. Bó o sì ṣe ń finú ro ibi tí wàá gbé ọ̀ràn ara ẹ gbà, kókó kan wà tó ò gbọ́dọ̀ gbójú fò dá.
“Rántí Ẹlẹ́dàá Rẹ”
Bó o bá fẹ́ láyọ̀ ní tòótọ́, o gbọ́dọ̀ fi ọ̀rọ̀ Sólómọ́nì ọlọgbọ́n Ọba náà sọ́kàn pé: “Rántí Ẹlẹ́dàá rẹ nígbà tí o ṣì wà ní ọ̀dọ́.” (Oníwàásù 12:1, Today’s English Version) Ìfẹ́ láti máa ṣe ohun tó wu Ọlọ́run ló yẹ kó mú ọ yan irú ọ̀nà tí wàá máa tọ̀ nígbèésí ayé ẹ.
Kí nìdí tíyẹn fi ṣe pàtàkì? Bíbélì sọ nínú Ìṣípayá 4:11 pé: “Jèhófà, àní Ọlọ́run wa, ìwọ ni ó yẹ láti gba ògo àti ọlá àti agbára, nítorí pé ìwọ ni ó dá ohun gbogbo, àti nítorí ìfẹ́ rẹ ni wọ́n ṣe wà, tí a sì dá wọn.” Bẹ́ẹ̀ ni, gbogbo ẹ̀dá láyé àti lọ́run ló jẹ Ẹlẹ́dàá ní gbèsè ọpẹ́. Ṣé ò ń dúpẹ́ pé ó fún ọ ní “ìyè àti èémí àti ohun gbogbo”? (Ìṣe 17:25) Ṣéyẹn ò wá mú kó o rí i bí ohun tó pọn dandan pé kó o fún Jèhófà Ọlọ́run ni ohun kan padà kó o lè fi hàn pé o mọrírì gbogbo ohun tó ti ṣe fún ẹ?
Níwọ̀n bí ọ̀pọ̀ lára àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti fi Ẹlẹ́dàá wọn sọ́kàn, wọ́n ti yàn láti ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Òótọ́ tó sì wà níbẹ̀ ni pé iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún gbayì lọ́pọ̀lọpọ̀, ó sì tún máa ń mú kéèyàn gbádùn ìbùkún tí kò lóǹkà. (Málákì 3:10) Àmọ́, ó yẹ kéèyàn kọ́kọ́ ronú nípa rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, bi ara rẹ pé, ‘Kí lohun tí mo lè ṣe, iṣẹ́ ọwọ́ wo ni mo sì mọ̀ tí mo lè máa fi gbọ́ bùkátà ara mi bí mo bá ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún?’
Kelly, tó ti di ọmọ ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n báyìí, ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣètò ohun tó máa ṣe látìgbà tó ti wà lọ́mọdé. Ó dá a lójú gbangba pé òun á wọṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Nígbà tó kù díẹ̀ kí Kelly pé ọmọ ogún ọdún, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ronú irú iṣẹ́ táá fẹ́ láti máa ṣe. Ó sọ pé: “Mo rí i pé ó pọn dandan kí n kọ́ irú iṣẹ́ tí màá lè fi máa gbọ́ bùkátà ara mi lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́.”
Kelly kọ́ iṣẹ́ tó jẹ mọ́ ìtọ́jú eyín nílé ẹ̀kọ́ gíga kan téèyàn ti ń kọ́ṣẹ́ ọwọ́. Kódà, ó tiẹ̀ gbégbá orókè níbi ìdíje kan tí ìjọba ìpínlẹ̀ ṣètò. Àmọ́ àṣeyọrí tó ṣe ò mú kó gbàgbé nípa ètò tó ti ní lórí ohun tó fẹ́ fi ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe. Kelly sọ pé: “Yàtọ̀ sí iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún tí mo fẹ́ láti ṣe, àmọ́ ni gbogbo èyí tó kù.” Kelly ṣì ń gbádùn iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Ó sọ pé: “Mo mọ̀ pé kò sí ìpinnu míì tí mo lè ṣe tó o dáa jùyẹn lọ.”
Béèrè Ìmọ̀ràn
Bó o bá wà ní ìrìn àjò lọ síbì kan tó ò mọ̀ dunjú, àfàìmọ̀ lo ò ní béèrè pé kẹ́nì kan tún júwe ọ̀nà fún ẹ, bí wọ́n bá tiẹ̀ ti júwe fún ẹ tẹ́lẹ̀. O lè ṣe bẹ́ẹ̀ náà bó o bá ń gbèrò bó o ṣe máa lo ìgbésí ayé ẹ. Fọgbọ́n ọlọ́gbọ́n ṣọgbọ́n. Òwe 20:18 sọ pé: “Ìmọ̀ràn ni a fi ń fìdí àwọn ìwéwèé múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in.” Ọ̀dọ̀ àwọn òbí ẹ ni ibì kan pàtàkì tó o ti lè rí ìtọ́sọ́nà. O sì tún lè wá ìmọ̀ràn lọ sọ́dọ̀ àwọn Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn, tí wọ́n ń fi ọgbọ́n Ọlọ́run gbé ìgbé ayé wọn. Roberto tiẹ̀ sọ pé “àwọn àgbà tí wọ́n jẹ́ àpẹẹrẹ rere nínú ìjọ rẹ tàbí ládùúgbò ni kó o máa fi ṣe àwòkọ́ṣe. Wọ́n lè sọ àwọn nǹkan kan tó máa jẹ́ ìyàlẹ́nu fún ẹ.”
Ju ẹnikẹ́ni yòówù lọ, Jèhófà Ọlọ́run fẹ́ láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o bàa lè ṣe ìpinnu tó máa mú kó o láyọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ nínú ìgbésí ayé ẹ. Nítorí náà, sọ fún un pé kó jẹ́ kó o ‘máa bá a lọ ní ríróye ohun tí ìfẹ́ rẹ̀ jẹ́’ nípa ọjọ́ iwájú rẹ. (Éfésù 5:17) Bó o bá fi gbogbo àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, “òun fúnra rẹ̀ yóò . . . mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.”—Òwe 3:5, 6.
O lè rí púpọ̀ sí i lára ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ èdè Gẹ̀ẹ́sì tá a pè ní “Young People Ask . . . ” nínú ìkànnì wa orí Íńtánẹ́ẹ̀tì tí àdírẹ́sì rẹ̀ jẹ́ www.watchtower.org/ypa
OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ
◼ Kí lo lè ṣe, iṣẹ́ ọwọ́ wo lo sì mọ̀?
◼ Ǹjẹ́ o lè ronú àwọn ọ̀nà tó o lè gbà máa lo ohun tó o mọ̀ láti fi yin Jèhófà?
◼ Èwo nínú àwọn iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún tá a mẹ́nu kàn nínú àpilẹ̀kọ yìí ló wù ẹ́?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 16]
Ó LÈ SÚNNI KAN ÒGIRI
Bíbélì sọ pé: “Àwọn tí ó pinnu láti di ọlọ́rọ̀ máa ń ṣubú sínú ìdẹwò àti ìdẹkùn àti ọ̀pọ̀ ìfẹ́-ọkàn tí í ṣe ti òpònú, tí ó sì ń ṣeni lọ́ṣẹ́, èyí tí ń ri ènìyàn sínú ìparun àti ègbé.” Ojú ẹni máa là á rí ìyọnu! Ìlépa ọlà sì lè súnni kan ògiri bíi kó ránni lóko gbèsè, kó kóni sí àníyàn, ó sì lè ba àjọṣe ẹni pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́ pátápátá.—1 Tímótì 6:9, 10.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17, 18]
IṢẸ́ AṢÁÁJÚ-Ọ̀NÀ
Akéde aṣáájú-ọ̀nà ni Kristẹni kan tó jẹ́ àpẹẹrẹ rere, tó ti ṣèrìbọmi, tó sì ti múra tán láti máa fi àádọ́rin wákàtí wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run lóṣooṣù. Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àti ìrírí àwọn aṣáájú-ọ̀nà máa ń sọ wọ́n di ọ̀jáfáfá lẹ́nu iṣẹ́ fífi Bíbélì kọ́ni.
IṢẸ́ ÌSÌN BẸ́TẸ́LÌ
Àwọn tó jẹ́ ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì máa ń sìn ní ẹ̀ka ilé iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà níbi tí wọ́n ti ń ṣèrànwọ́ láti kọ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, láti tẹ̀ wọ́n àti láti kó wọn ránṣẹ́ sáwọn ìjọ. Àǹfààní iṣẹ́ ìsìn mímọ́ ni iṣẹ́ kọ̀ọ̀kan tá à ń ṣe ní Bẹ́tẹ́lì jẹ́.
SÍSÌN NÍBI TÁ A TI NÍLÒ ÀWỌN ONÍWÀÁSÙ PÚPỌ̀ SÍ I
Ó ṣeé ṣe fáwọn aṣáájú-ọ̀nà kan láti ṣí lọ síbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run púpọ̀ sí i. Àwọn kan máa ń kọ́ èdè míì wọ́n sì máa ń sìn nílẹ̀ àjèjì níbi tí ìjọ tó ń sọ èdè yẹn wà.
ṢÍṢE IṢẸ́ KÁRÍ AYÉ
Àwọn tó ń ṣiṣẹ́ kárí ayé máa ń rìnrìn àjò lọ sáwọn orílẹ̀-èdè mìíràn láti lọ bá wọn kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba àti àwọn ẹ̀ka iléeṣẹ́. Èyí jẹ́ irú iṣẹ́ ìsìn mímọ́ tá a lè fi wé tàwọn èèyàn tó kọ́ tẹ́ńpìlì Sólómọ́nì.—1 Àwọn Ọba 8:13-18.
ILÉ Ẹ̀KỌ́ IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́
Nínú ilé ẹ̀kọ́ yìí la ti máa ń fi ọ̀sẹ̀ mẹ́jọ gbáko dá àwọn alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó jẹ́ àpọ́n, tó sì tóótun lẹ́kọ̀ọ́ lórí ọ̀ràn nípa ìṣètò àti sísọ̀rọ̀ níwájú àwùjọ. A máa ń yan àwọn kan tó bá jáde nílé ẹ̀kọ́ yìí láti sìn ní orílẹ̀-èdè wọn; a sì rán àwọn mìíràn lọ sí ilẹ̀ òkèèrè.
IṢẸ́ MÍṢỌ́NNÁRÌ
A máa ń fún àwọn aṣáájú-ọ̀nà tó bá tóótun, tára wọn dá ṣáṣá tí agbára wọn sì gbé e ní ìdálẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè ṣiṣẹ́ ìsìn ní ilẹ̀ òkèèrè. Àwọn míṣọ́nnárì ń gbádùn ìgbésí ayé alárinrin, tó sì ń fọkàn ẹni balẹ̀.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
WHAT WILL I DO WITH MY LIFE?
Ètò táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbé jáde lórí fídíò yìí [kò sí lédè Yorùbá], ní àwọn ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò aláìfọ̀rọ̀ bọpo bọyọ̀ nínú. Àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò wá láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, Brazil, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti ilẹ̀ Jámánì. Ó máa tó wà láwọn èdè mélòó kan sí i.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
“Kéèyàn ṣáà ti gbé ohun tó fẹ́ ṣe ka iwájú ara ẹ̀.”—Michael, ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
“Mi ò mọ ìpinnu tó dáa ju èyí lọ tí mo lè ṣe.”—Kelly, tó ti ṣe aṣáájú-ọ̀nà fọ́dún mẹ́fà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
“Máa fi àwọn tó jẹ́ àpẹẹrẹ rere ṣe àwòkọ́ṣe.”—Roberto, ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì