ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 10/07 ojú ìwé 24
  • Jẹ́ Kí Ìlànà Wà Tí Ìdílé Gbọ́dọ̀ Máa Tẹ̀ Lé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jẹ́ Kí Ìlànà Wà Tí Ìdílé Gbọ́dọ̀ Máa Tẹ̀ Lé
  • Jí!—2007
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Dandan Ni Kí Wọ́n Ṣe Òfin Nínú Ilé?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Àwọn Òfin Yìí Ò Wa Pọ̀ Jù Bí?
    Jí!—2007
  • Òfin Yìí Ò Wa Pọ̀ Jù!
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
Àwọn Míì
Jí!—2007
g 10/07 ojú ìwé 24

Ọ̀nà 4

Jẹ́ Kí Ìlànà Wà Tí Ìdílé Gbọ́dọ̀ Máa Tẹ̀ Lé

Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì? Ọ̀gbẹ́ni Ronald Simons, tó jẹ́ onímọ̀ nípa ìbágbépọ̀ ẹ̀dá ní yunifásítì kan, ìyẹn University of Georgia, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, sọ pé: “Òótọ́ tó wà níbẹ̀ ni pé, àwọn ọmọ máa ń ṣe dáadáa bí ìlànà tí wọ́n ní láti tẹ̀ lé bá yé wọn, tí wọ́n sì mọ̀ pé àwọn ò lè mú un jẹ́ báwọn bá ré ìlànà náà kọjá. Láìsí irú àwọn ìlànà tí ò gba gbẹ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ á máa ṣe tinú wọn, wọ́n á ya onímọ̀-tara-ẹni nìkan, wọn ò ní láyọ̀, wọ́n á sì mú káyé nira fún gbogbo ẹní bá yí wọn ká.” Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ lọ́nà tó rọrùn láti yéni pé: “Ẹniti o fẹ [ọmọ rẹ̀] a maa tète nà a.”—Òwe 13:24, Bibeli Mimọ.

Ìṣòro tó wà ńbẹ̀: Jíjẹ́ káwọn ọmọ mọ irú ìwà tó o fẹ́ kí wọ́n máa hù àtèyí tí wọn ò gbọ́dọ̀ hù àti rírí sí i pé wọ́n ń tẹ̀ lé ohun tó o sọ fún wọn máa gba àkókò, ìsapá àti àtẹnumọ́. Ó sì dà bíi pé gbogbo ọmọdé ló máa ń fẹ́ tàpá sírú ìlànà bẹ́ẹ̀. Nígbà tí Mike àti Sonia tí wọ́n ń tọ́ ọmọ méjì ń sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro náà, wọ́n sọ pé: “Àwọn ọmọdé kéré lóòótọ́, àmọ́ wọ́n ní èrò tiwọn àtàwọn nǹkan tó ń wù wọ́n, àti pé gẹ́gẹ́ bí aláìpé àwọn náà lè dẹ́ṣẹ̀.” Àwọn òbí tó sọ̀rọ̀ yìí fẹ́ràn àwọn ọmọbìnrin wọn gan-an ni. Síbẹ̀ wọ́n gbà pé, “Ìgbà míì wà táwọn ọmọ máa ń ṣorí kunkun tó sì jẹ́ tiwọn nìkan ló máa ń yé wọn.”

Ohun tó lè ràn yín lọ́wọ́: Máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ọ̀nà tí Jèhófà gbà báwọn ọmọ Ísírẹ́lì lò. Ọ̀nà kan tó gbà fìfẹ́ tó ní sáwọn èèyàn rẹ̀ hàn ni pé ó mú kí òfin tó fẹ́ kí wọ́n máa tẹ̀ lé yé wọn. (Ẹ́kísódù 20:2-17) Ó sì tún ṣàlàyé ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wọ́n bí wọ́n bá rú àwọn òfin náà.—Ẹ́kísódù 22:1-9.

Nítorí náà, o ò ṣe kúkú ṣàkọsílẹ̀ àwọn òfin tàbí ìlànà tó o bá ronú pé àwọn ọmọ gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé. Àwọn òbí kan dábàá pé kírú òfin tàbí ìlànà bẹ́ẹ̀ má ṣe gùn gbọ̀ọ̀rọ̀ gbọọrọ, bóyá kó má ju nǹkan bíi márùn-ún lọ. Báwọn ìlànà tó wà lákọọ́lẹ̀ fáwọn tó wà nínú ìdílé láti máa tẹ̀ lé ò bá pọ̀, á rọrùn láti tẹ̀ lé, èèyàn á sì lè tètè rántí wọn. Lẹ́yìn yẹn, tún ṣe àkọsílẹ̀ ìjìyà tó wà fún ẹni tí kò bá tẹ̀ lé àwọn ìlànà náà. Rí i dájú pé irú ìyà bẹ́ẹ̀ ò pọ̀ ju ẹ̀ṣẹ̀ tẹ́nì kan dá lọ, àti pé o ṣe tán láti fìyà jẹ ẹni tó bá rúfin náà. Ẹ jọ máa yẹ àwọn ìlànà náà wò déédéé, kí gbogbo yín, ìyá, àwọn ọmọ, àtìwọ náà bàa lè mọ ohun tó yẹ kẹ́ ẹ máa ṣe.

Bí ẹnikẹ́ni bá tẹ ìlànà náà lójú, ojú ẹsẹ̀ ni kẹ́ ẹ jẹ́ kó dáhùn fún un. Àmọ́, kó jẹ́ lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́, síbẹ̀ láìgba gbẹ̀rẹ́ àti láìṣègbè. Ohun kan tẹ́yin òbí ò gbọ́dọ̀ gbàgbé ni pé bẹ́ ẹ bá ń bínú, ṣe ni kẹ́ ẹ fọwọ́ wọ́nú títí tára yín á fi silé kẹ́ ẹ tó fìyà jẹ ẹni tó bá tọ́ sí. (Òwe 29:22) Àmọ́ ṣá o, ẹ má ṣe fọ̀rọ̀ falẹ̀, ẹ má ṣe wojú. Bẹ́ ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ á máa ronú pé àwọn ìlànà ọ̀hún ò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì. Èyí bá ohun tí Bíbélì sọ mu pé: “Nítorí pé a kò fi ìyára kánkán mú ìdájọ́ ṣẹ lòdì sí iṣẹ́ búburú, ìdí nìyẹn tí ọkàn-àyà àwọn ọmọ ènìyàn fi di líle gbagidi nínú wọn láti ṣe búburú.”—Oníwàásù 8:11.

Ọ̀nà míì wo lo lè gbà lo àṣẹ rẹ lọ́nà tó máa ṣàǹfààní fáwọn ọmọ rẹ?

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 24]

“Kí ọ̀rọ̀ yín Bẹ́ẹ̀ ni sáà túmọ̀ sí Bẹ́ẹ̀ ni, Bẹ́ẹ̀ kọ́ yín, Bẹ́ẹ̀ kọ́”—Mátíù 5:37

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́