Bẹ́ Ẹ Ṣe Lè Mú Kí Ilé Yín Jẹ́ Ibi Ààbò
Ọ̀RỌ̀ tó bani nínú jẹ́ gan-an ni Bíbélì lò láti fi ṣàlàyé bí ọ̀pọ̀ èèyàn á ṣe rí ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” tá à ń gbé yìí. Ó ní àwọn èèyàn á jẹ́ “aláìní ìfẹ́ni àdánidá.” (2 Tímótì 3:1, 3, 4) Ìbọ́mọdé-ṣèṣekúṣe tó ń gbilẹ̀ nínú ìdílé báyìí jẹ́ ẹ̀rí tó ṣe kedere pé àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì yìí ń nímùúṣẹ. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí Bíbélì lò ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ yìí, ìyẹn aʹstor·gos, túmọ̀ sí “àìsí ìfẹ́ni àdánidá” lédè Gẹ̀ẹ́sì. Òdì kejì ló jẹ́ sí irú ìfẹ́ tó yẹ kó máa jọba láàárín àwọn tó ti inú ìdílé kan náà wá, pàápàá jù lọ ìfẹ́ tó yẹ kó wà láàárín àwọn òbí àtàwọn ọmọ.a Bẹ́ẹ̀ sì rèé, àárín àwọn tó bára wọn tan lọ́nà yìí gan-an ni ìbọ́mọdé-ṣèṣekúṣe ti máa ń wáyé.
Àwọn olùṣèwádìí kan sọ pé àwọn ọkùnrin ló sábà máa ń dá ìbọ́mọdé-ṣèṣekúṣe láṣà nínú ilé. Irú ọkùnrin bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ bàbá ọmọ náà, ọkọ míì tí ìyá ẹ̀ lọ fẹ́, tàbí ọkùnrin míì tó jẹ́ ìbátan tó sún mọ́ ọmọ náà. Ó tún wọ́pọ̀ pé káwọn ìbátan míì tó jẹ́ ọkùnrin máa bá àwọn ọmọdé ṣèṣekúṣe. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọdébìnrin ló pọ̀ jù lára àwọn tí wọ́n máa ń bá ṣèṣekúṣe, kò yọ àwọn ọmọdékùnrin náà sílẹ̀. Àwọn obìnrin tó jẹ́ abọ́mọdé-ṣèṣekúṣe náà ò ṣaláì pọ̀ díẹ̀. Àfàìmọ̀ kó máa jẹ́ pé irú ìbọ́mọdé-ṣèṣekúṣe táwọn èèyàn kì í sábà ròyìn ẹ̀ ni tàwọn tẹ̀gbọ́n tàbúrò tí wọ́n jọ ń gbé, síbẹ̀ tí wọ́n ń bára wọn sùn. Èyí àgbà tàbí èyí tó lágbára jù á fọgbọ́n tan èyí tó kéré sí i tàbí tí kò lágbára tó o lára àwọn àbúrò ẹ̀ ọkùnrin tàbí obìnrin, á sì bá a lò pọ̀. Ó dájú pé nǹkan ẹ̀gbin gbáà ni gbogbo ìyẹn á jẹ́ sí ẹ̀yin òbí.
Kí lẹ lè ṣe tírú àwọn ìṣòro bí èyí ò fi ní máa wáyé nínú ilé yín? Ohun kan tó dájú ni pé àwọn ìlànà kan wà tí ò fàyè gba bíbá ẹnikẹ́ni ṣèṣekúṣe. Ó dára kí gbogbo ẹni tó bá jẹ́ ara ìdílé èyíkéyìí kọ́ nípa àwọn ìlànà náà kí wọ́n sì mọrírì wọn. Inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí í ṣe Bíbélì nibi tó dára jù lọ tá a ti lè rí irú ìtọ́sọ́nà bẹ́ẹ̀.
Ohun Tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Sọ Nípa Bó Ṣe Yẹ Ká Máa Bára Wa Gbé
Ọ̀nà tí gbogbo ìdílé lè gbà sá fún ìbọ́mọdé-ṣèṣekúṣe ni pé kí wọ́n máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà inú Bíbélì tó dá lórí bó ṣe yẹ ká máa hùwà. Bíbélì kì í fọ̀rọ̀ bọpo bọyọ̀ bó bá kan ọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀. Kì í sọ ọ́ ní àsọbàjẹ́, síbẹ̀ ó máa ń sọ ọ́ lọ́nà tó ṣe pàtó tó sì lọ sórí kókó. Ó fi hàn pé Ọlọ́run ṣètò ìbálòpọ̀ lọ́nà tó fi máa mú kí tọkọtaya gbádùn ara wọn. (Òwe 5:15-20) Àmọ́, kò fàyè gba kí àwọn tí kò gbéra wọn níyàwó máa bára wọn lò pọ̀. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì ò fàyè gba ìbálòpọ̀ láàárín ìbátan. Nínú Léfítíkù orí 18, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ onírúurú ìbálòpọ̀ láàárín ìbátan ni Ọlọ́run dẹ́bi fún. Kíyè sí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ná: “Ọkùnrin èyíkéyìí nínú yín kò gbọ́dọ̀ sún mọ́ ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ ìbátan rẹ̀ tímọ́tímọ́ nípa ti ara láti tú u sí ìhòòhò [láti ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú rẹ̀]. Èmi ni Jèhófà.”—Léfítíkù 18:6.
Jèhófà ka ìbálòpọ̀ láàárín ìbátan mọ́ ara àwọn “ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí” tó máa yọrí sí ikú fún ẹni tó bá dán an wò. (Léfítíkù 18:26, 29) Ó ṣe kedere pé ìlànà tí Ẹlẹ́dàá gbé kalẹ̀ lórí àwọn ọ̀ràn wọ̀nyí kì í ṣe èyí tá a lè fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn. Lónìí, ọwọ́ kan náà ni ọ̀pọ̀ àwọn alákòóso fi mú bíbọ́mọdé-ṣèṣekúṣe nínú ìdílé, òfin wọn ò fàyè gbarú ẹ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, òfin máa ń sọ pé ohun tó bá fà á tí àgbàlagbà fi bá ọmọdé lò pọ̀, ó ti fipá bá a sùn nìyẹn. Kí nìdí tá a fi lè pe irú ẹ̀ ní ìfipá-báni-lòpọ̀ bí kò bá la ìfipá-múni lọ?
Ọ̀pọ̀ àwọn aláṣẹ ti wá rí i pé òótọ́ ni ohun tí Bíbélì ti ń sọ nípa àwọn ọmọdé látìgbà yìí wá, ìyẹn ni pé ó dà bí i pé wọ́n kì í lè ronú bí i ti àgbàlagbà. Bí àpẹẹrẹ, Òwe 22:15 sọ pé: “Ọkàn-àyà ọmọdékùnrin ni ìwà òmùgọ̀ dì sí.” Ọlọ́run sì tún mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti kọ̀wé pé: “Nígbà tí mo jẹ́ ìkókó, mo máa ń . . . ronú bí ìkókó, gbèrò bí ìkókó; ṣùgbọ́n nísinsìnyí tí mo ti wá di ọkùnrin, mo ti fi òpin sí àwọn ìwà ìkókó.”—1 Kọ́ríńtì 13:11.
Kò sí bí ọmọdé kan ṣe lè mọ gbogbo ohun tó wé mọ́ ìbálòpọ̀, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ohun tó máa tìdí ẹ̀ yọ bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́. Nítorí náà, káàkiri ibi gbogbo làwọn èèyàn ti gbà pé bí wọ́n bá tiẹ̀ bá ọmọdé lò pọ̀, ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ò yé e. Ohun tíyẹn túmọ̀ sí ni pé, bí àgbàlagbà kan (tàbí ẹnì kan tó ti bàlágà) bá bá ọmọdé kan lò pọ̀, irú ẹni bẹ́ẹ̀ ò lè dára ẹ̀ láre nípa sísọ pé kíkọ̀ tọ́mọ náà ò kọ̀ ló fà á tàbí kó sọ pé ọmọ náà ló sọ pé òun fẹ́ bẹ́ẹ̀. Àgbàlagbà tó bá dán irú ẹ̀ wò fipá bá ọmọ náà lò pọ̀ ni. Ìwà ọ̀daràn gbáà ló hù yẹn, ó sì máa ṣẹ̀wọ̀n ẹ̀. Òun tó fipá bá ẹlòmíì lò ló máa dáhùn fún un, kì í ṣe ẹni tó jókòó ara ẹ̀ jẹ́jẹ́ tó lọ fipá bá lò.
Àmọ́, ó bani nínú jẹ́ pé ọ̀pọ̀ irú ìwà ọ̀daràn bẹ́ẹ̀ làwọn èèyàn ń ṣe láṣegbé lóde òní. Bí àpẹẹrẹ, nílẹ̀ Ọsirélíà, wọ́n ti fojú bù ú pé ìdá mẹ́wàá péré lára ìdá ọgọ́rùn-ún abọ́mọdé-ṣèṣekúṣe ni wọ́n ń jẹ́jọ́, díẹ̀ lára wọn nilé ẹjọ́ sì ń dẹ́bi fún. Bí nǹkan sì ṣe rí láwọn ilẹ̀ míì náà nìyẹn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kékeré ni ìjọba lè ṣe lára ọ̀ràn náà, fífi ìlànà Bíbélì sílò lè ṣe èyí tó pọ̀ lára ẹ̀ nínú ilé àwọn tó jẹ́ Kristẹni.
Àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ̀ pé Ọlọ́run tó mú kí wọ́n kọ àwọn ìlànà wọ̀nyẹn sínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò tíì yí padà. Gbogbo ohun tá à ń ṣe ló ń rí, tó fi mọ́ èyí tó pa mọ́ lójú ọ̀pọ̀ èèyàn. Bíbélì sọ pé: “Ohun gbogbo wà ní ìhòòhò àti ní ṣíṣísílẹ̀ gbayawu fún ojú ẹni tí a óò jíhìn fún.”—Hébérù 4:13.
Àwa la máa dáhùn fún un níwájú Ọlọ́run bá a bá ṣàìgbọràn sí òfin rẹ̀ tá a sì pa àwọn ẹlòmíì lára. Lọ́wọ́ mìíràn ẹ̀wẹ̀, ó máa ń bù kún wa bá a bá ń ṣègbọràn sáwọn òfin wíwúlò tó ṣe nípa bó ṣe yẹ kí nǹkan rí nínú ìdílé. Kí ni díẹ̀ lára àwọn òfin wọ̀nyí?
Ìdílé Tí Ìfẹ́ So Pọ̀ Ṣọ̀kan
Bíbélì sọ fún wa pé: “Ìfẹ́ . . . jẹ́ ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.” (Kólósè 3:14) Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ, ìfẹ́ kì í wulẹ̀ ṣe bí nǹkan kàn ṣe rí lára. Ohun tó máa ń sún èèyàn ṣe la fi ń dá a mọ̀, ìyẹn ni ohun tó máa ń mú kéèyàn hù níwà àti ohun tó máa ń jẹ́ kéèyàn yẹra fún. (1 Kọ́ríńtì 13:4-8) Ohun tí fífi ìfẹ́ hàn nínú ìdílé túmọ̀ sí ni pé kéèyàn máa ṣe ohun tó buyì kún àwọn tó jẹ́ ara ìdílé, kéèyàn máa bọ̀wọ̀ fún wọn, kéèyàn sì máa fi inú rere hàn sí wọn. Ó túmọ̀ sí pé kéèyàn mọ ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé, kéèyàn sì máa bá wọn lò lọ́nà bẹ́ẹ̀. Ipò tó lọ́lá tó sì ṣe pàtàkì ni Ọlọ́run to ẹnì kọ̀ọ̀kan sí.
Gẹ́gẹ́ bí olórí ìdílé, bàbá ni kó jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ tí yóò máa fi ìfẹ́ hàn. Ó gbọ́dọ̀ mọ̀ pé Ọlọ́run ò fún baba tó jẹ Kristẹni lómìnira pé kó jẹ́ òǹrorò tàbí ẹni tó ń ṣi agbára ẹ̀ lò lórí aya àtàwọn ọmọ ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ń wo Kristi gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ tó yẹ kóun máa tẹ̀ lé láti lo ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olórí. (Éfésù 5:23, 25) Nítorí náà, ó ń fìwà pẹ̀lẹ́ àti ìfẹ́ bá aya rẹ̀ lò, ó sì ń fi sùúrù àti ìwà jẹ́jẹ́ báwọn ọmọ ẹ̀ gbé. Kì í fi ọ̀ràn ààbò wọn ṣeré, kò sì kọ ohun tó lè ná an nítorí àtigbà wọ́n lọ́wọ́ ìjàngbọ̀n, ìyànjẹ, tàbí ohun tí ò ní jẹ́ kí wọ́n lè fọkàn tánni mọ́ àti ohun tó lè wu wọ́n léwu.
Bákan náà sì tún ni ojúṣe ìyàwó, tó sì tún jẹ́ ìyá àwọn ọmọ nínú ilé, ṣe pàtàkì tó sì tún ń buyì kúnni. Bíbélì lo ọgbọ́n àdámọ́ni táwọn ẹranko tó jẹ́ ìyà ní láti fi ṣàpèjúwe bí Jèhófà àti Jésù ṣe máa ń dáàbò boni. (Mátíù 23:37) Bó ṣe yẹ káwọn ìyá tó jẹ́ èèyàn náà máa dáàbò bo àwọn ọmọ wọn lójú méjèèjì nìyẹn. Ìfẹ́ tó bá ní sí wọn á jẹ́ kó tètè máa fi ọ̀ràn ààbò àti ire wọn ṣáájú nínú ohun gbogbo tó bá ń ṣe. Àwọn òbí ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí lílo agbára nílòkulò, bíbúmọ́ni, tàbí kíkó jìnnìjìnnì báni wọ ọ̀rọ̀ àwọn méjèèjì tàbí bí wọ́n ṣe ń bá àwọn ọmọ wọn lò; bẹ́ẹ̀ ni wọn ò sì gbọ́dọ̀ jẹ́ káwọn ọmọ wọn máa fi irú ànímọ́ bẹ́ẹ̀ bára wọn lò.
Bí àwọn tó wà nínú ìdílé bá ń bọ̀wọ̀ fúnra wọn tí wọ́n sì ń buyì fúnra wọn, wọ́n á lè máa bara wọn sọ̀rọ̀ lọ́nà tí ń gbéni ró. Òǹkọ̀wé William Prendergast sọ pé: “Ó yẹ kí gbogbo òbí máa báwọn ọmọ wọn kékeré àtàwọn tó ti bàlágà fikùnlukùn lójoojúmọ́ àti nígbà gbogbo.” Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ó dà bíi pé ọ̀nà tó dára jù lọ láti gbà yanjú ìṣòro ìbọ́mọdé-ṣèṣekúṣe nìyí.” Kódà, irú ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ onífẹ̀ẹ́ tó ń wáyé lemọ́lemọ́ yẹn gan-an ni Bíbélì dá lábàá. (Diutarónómì 6:6, 7) Báwọn òbí bá fi ìlànà yìí sílò, ilé á di ibi tí oníkálùkù á ti lè sọ ohun tó bá wà lọ́kàn ẹ̀ fàlàlà àti láìfòyà.
Òótọ́ ni pé inú ayé búburú là ń gbé, kò sì sí béèyàn ṣe lè kòòré gbogbo ìbọ́mọdé-ṣèṣekúṣe. Síbẹ̀, kò sóhun tá a lè fi wé kéèyàn máa gbé nínú ilé tí kò ti sí ewu. Bí ohunkóhun bá pa ẹnikẹ́ni lára níta, ó mọ̀ pé òun nílé tóun lè sá wá, níbi tóun á ti rí ìtùnú tí wọ́n á sì bá òun kẹ́dùn. Ibi ààbò gbáà nirú ilé bẹ́ẹ̀ jẹ́, ibi téèyàn lè forí pa mọ́ sí nínú ayé tó kún fún wàhálà yìí. Ǹjẹ́ kí Ọlọ́run bù kún ọ bó o ti ń sapá láti mú kí ìdílé tìẹ náà rí bẹ́ẹ̀!
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wọ́n tún túmọ̀ ọ̀rọ̀ Gíríìkì àtijọ́ náà báyìí: “Ọlọ́kàn líle sí ìbátan.” Nítorí náà, bó ṣe kà nínú ìtumọ̀ Bíbélì kan nìyí: “Wọ́n á . . . ṣaláìní ìfẹ́ yíyẹ sáwọn ará ilé wọn.”
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
ÀWỌN ÀBÁ NÍPA BÍ ÌBỌ́MỌDÉ-ṢÈṢEKÚṢE Ò ṢE NÍ WÁYÉ NÍNÚ ILÉ
Íńtánẹ́ẹ̀tì: Báwọn ọmọ ẹ bá ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì, o gbọ́dọ̀ tọ́ wọn sọ́nà kí wọ́n má bàa ṣì í lò. Àìmọye ibi téèyàn ti lè máa wo àwòrán oníhòòhò ló wà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn ò sì mọ́ àwọn ibi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ àtàwọn ìkànnì míì táwọn èèyàn ti lè kàn síra wọn. Àwọn abọ́mọdé-ṣèṣekúṣe máa ń wá àwọn ọmọdé lọ sáwọn ibi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ orí kọ̀ǹpútà yìí kí wọ́n bàa lè tàn wọ́n kí wọ́n sì bá wọn ṣèṣekúṣe. Ó bọ́gbọ́n mu kí kọ̀ǹpútà náà wà ní gbalasa níbi tá á ti rọrùn fún òbí láti máa bójú tó ìlò rẹ̀. Àwọn ọmọ kò gbọ́dọ̀ fún ẹnikẹ́ni ní ìsọfúnni nípa ara wọn àfi báwọn òbí wọn bá mọ̀ nípa ẹ̀, wọn ò sì gbọ́dọ̀ fìpàdé síbikíbi pẹ̀lú ẹni tí wọ́n bá bá pàdé lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì.—Sáàmù 26:4.
Ọtí Líle: Lọ́pọ̀ ìgbà tí ẹnì kan bá bá ọmọdé kan ṣèṣekúṣe, ṣe ló máa ń já sí pé onítọ̀hún ti mutí yó. Ó ti wá hàn kedere báyìí pé àmujù ọtí máa ń sọ àwọn àgbàlagbà di aláìmojú àti aláìmọra; kì í sì í jẹ́ kójú tì wọ́n láti hùwà tí kò tọ́ sí wọn. Lédè kan ṣá, ìyẹn náà tún jẹ́ ọ̀kan lára ìdí tó fi yẹ kéèyàn ṣègbọràn sí ìmọ̀ràn Bíbélì pé ká sá fún àmujù ọtí àti mímutí lámuyó.—Òwe 20:1; 23:20, 31-33; 1 Pétérù 4:3.
Dídá Wà: Obìnrin kan níran ohun tó ṣẹlẹ̀, ó sọ pé: “Lẹ́yìn ikú Màmá mi, iyàrá bàbá mi nìkan ni aṣọ ẹnu-ọ̀nà wà, yàrá wọn nìkan ló sì ní ilẹ̀kùn. Gbayawu làwa yòókù wà, kódà kò sí ilẹ̀kùn níbi tá a ti ń wẹ̀.” Kò sí èyí tí bàbá mi ò bá ṣèṣekúṣe nínú àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin. Torí náà, gbogbo ẹni bá wà nínú ìdílé gbọ́dọ̀ mọ̀ pé gbogbo ìgbà kọ́ lèèyàn máa ń ṣí ara sílẹ̀. Bó ṣe jẹ́ pé ìgbà míì máa ń wà táwọn òbí kì í múra tàbí bọ́ra sílẹ̀ lójú àwọn ọmọ, bẹ́ẹ̀ náà ló yẹ káwọn òbí mọ̀ pé ó láwọn àkókò táwọn ọmọ náà á fẹ́ múra tàbí bọ́ra sílẹ̀, ó sì yẹ káwọn náà ṣe gáfárà fún wọn pàápàá bí wọ́n bá ṣe ń dàgbà sí i. Ohun táwọn òbí tó gbọ́n bá ń retí lọ́dọ̀ ọmọ wọn làwọn náa máa ń ṣe fọ́mọ.—Mátíù 7:12.