ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 4/11 ojú ìwé 31
  • Ǹjẹ́ O Ní Àwọn Àfojúsùn Tí Ọwọ́ Rẹ Lè Tẹ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ O Ní Àwọn Àfojúsùn Tí Ọwọ́ Rẹ Lè Tẹ̀?
  • Jí!—2011
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọrọ̀ Ha Lè Mú Ọ Láyọ̀ Bí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn, Má Ṣe Nífẹ̀ẹ́ Owó àti Ohun Ìní
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Ojúlówó Aásìkí Ń Bọ̀ Nínú Ayé Tuntun ti Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Máa Lépa Àwọn Nǹkan Tẹ̀mí Kó O Lè Ṣe Ara Rẹ Láǹfààní
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
Àwọn Míì
Jí!—2011
g 4/11 ojú ìwé 31

Ǹjẹ́ O Ní Àwọn Àfojúsùn Tí Ọwọ́ Rẹ Lè Tẹ̀?

● Kí lo fẹ́ fi ìgbésí ayé rẹ ṣe? Ṣé o kì í retí ohun tó pọ̀ jù àbí àwọn nǹkan tí apá rẹ kò lè ká lo máa ń ronú nípa wọn? Ẹnì kan tó máa ń kíyè sí ìṣesí ẹ̀dá fúnni ní ìmọ̀ràn yìí: ‘Èyí tí ojú rí sàn ju ìròkáàkiri ìfẹ́ lọ; asán ni èyí pẹ̀lú àti ìmúlẹ̀mófo.’—Oníwàásù 6:9. Bíbélì Mímọ́.

‘Èyí tí ojú rí’ tọ́ka sí ipò tá a wà lọ́wọ́lọ́wọ́ àtàwọn nǹkan tí ọwọ́ èèyàn lè tẹ̀ lóòótọ́. Kò sí ohun tó burú nínú kéèyàn gbìyànjú láti ṣe ohun tó máa mú kí ìgbésí ayé rẹ̀ sunwọ̀n sí i. Ohun tí ẹsẹ Bíbélì yìí ń sọ ni pé, ẹni tó gbọ́n kì í lépa àwọn nǹkan tó kọjá agbára rẹ̀. Ó lè jẹ́ òkìkí, ọrọ̀, ọkọ tàbí aya tí kò kù síbì kan tàbí ìlera pípé ló ń lépa.

Láfikún sí i, àwọn tí ọwọ́ wọn tẹ ohun tí wọ́n ń lépa, irú bíi kíkó ohun ìní jọ, lè tún máa wá sí i. Bíbélì sọ láìfọ̀rọ̀ bọpo bọyọ̀ pé: “Olùfẹ́ fàdákà kì yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú fàdákà, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ olùfẹ́ ọlà kì yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú owó tí ń wọlé wá. Asán ni èyí pẹ̀lú.” (Oníwàásù 5:10) Àmọ́, àwọn tó gbọ́kàn lé Ọlọ́run máa ń jẹ́ kí ohun tí wọ́n ní tẹ́ wọn lọ́rùn, ìyẹn ‘èyí tí ojú [wọn] rí.’ Wọ́n fara mọ́ òótọ́ ọ̀rọ̀ yìí pé: “A kò mú nǹkan kan wá sínú ayé, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì lè mú ohunkóhun jáde.”—1 Tímótì 6:7.

Ọlọ́run dá àwa èèyàn ní ọ̀nà tó jẹ́ pé jíjọ́sìn Ọlọ́run lọ́nà tí ó tọ́ ló máa ń fún wa ní ayọ̀ tó pọ̀ jù lọ. (Mátíù 5:3) Báwo la ṣe lè ṣe é? Jésù Kristi sọ pé: “Ènìyàn kì yóò wà láàyè nípasẹ̀ oúnjẹ nìkan ṣoṣo, bí kò ṣe nípasẹ̀ gbogbo àsọjáde tí ń jáde wá láti ẹnu Jèhófà.” (Mátíù 4:4) Inú Bíbélì la ti rí àwọn òótọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn, wọ́n sì wà fún gbogbo wa lọ́fẹ̀ẹ́.

A rí irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ nínú Sáàmù 37:4. Ó kà pé: “Máa ní inú dídùn kíkọyọyọ nínú Jèhófà, òun yóò sì fún ọ ní àwọn ìbéèrè tí ó ti inú ọkàn-àyà rẹ wá.” Níwọ̀n bí Jèhófà ti jẹ́ Ọlọ́run Olódùmarè, ó máa fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ ní ohun tí ẹ̀dá èèyàn èyíkéyìí kò lè fún wọn: ìlera pípé, ààbò, àti ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè orí ilẹ̀-ayé. (Lúùkù 23:43; Ìṣípayá 21:3, 4) Tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ìlérí yìí, ó dájú àwọn ìlérí yìí á tẹ̀ wá lọ́wọ́.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́