ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 7/11 ojú ìwé 10-12
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Rí Ọ̀rẹ́ Tí Ọ̀rọ̀ Wa Bára Mu?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Rí Ọ̀rẹ́ Tí Ọ̀rọ̀ Wa Bára Mu?
  • Jí!—2011
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ÌṢÒRO 1: Yíya ara ẹni sọ́tọ̀
  • ÌṢÒRO 2: Wíwá ọ̀rẹ́ lọ́ranyàn
  • Máa Lo Ìdánúṣe
  • Kí Nìdí Táwọn Ẹgbẹ́ Mi Ò Fi Gba Tèmi?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Kí Ló Dé Tí Ẹnikẹ́ni Kì Í Dá Sí Mi?
    Jí!—2007
  • Ṣó Yẹ Kí N Ní Ọ̀rẹ́ Míì?
    Jí!—2009
  • Kí Nìdí Tí Mi Ò Fi Ní Ọ̀rẹ́ Kankan?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
Àwọn Míì
Jí!—2011
g 7/11 ojú ìwé 10-12

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Rí Ọ̀rẹ́ Tí Ọ̀rọ̀ Wa Bára Mu?

“Ọmọ ọdún mọ́kànlélógún ni mí. Àmọ́, àwọn tá a jọ jẹ́ ẹgbẹ́ kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ lágbègbè wa, torí náà àwọn ọmọ tó ṣì wà níléèwé girama tàbí àwọn tó ti ṣègbéyàwó ni mo máa ń bá rìn. Ọ̀rọ̀ ìdánwò làwọn ọmọléèwé girama sábà máa ń sọ, àmọ́ ní tàwọn tó ti ṣègbéyàwó, ọ̀rọ̀ a fẹ́ sanwó tibí sanwó tọ̀hún ló sábà máa ń pọ̀ jù nínú ọ̀rọ̀ tiwọn. Kò sí èyí tó ṣe pàtàkì sí mi nínú méjèèjì. Ó máa dáa gan-an tí mo bá rí àwọn tọ́rọ̀ wa jọ bára mu!”—Carmen.a

Ó FẸ́RẸ̀Ẹ́ jẹ́ pé gbogbo èèyàn ló ń fẹ́ kí àwọn ẹlòmíì gba ti wọn, láìka ọjọ́ orí wọn sí. Kò sí iyè méjì pé ó máa ń ṣe ìwọ náà bẹ́ẹ̀. Ìdí nìyẹn tó fi máa ń dunni táwọn ẹlòmíì bá pani tì tàbí tí wọn ò káni sí, bíi pé o kì í ṣèèyàn. Michaela ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún kan sọ nípa ara rẹ̀ pé: “Ó máa ń ṣe mí bíi pé, kò sẹ́ni tó rí tèmi rò rárá.”

Àmọ́ ṣá o, tó bá jẹ́ pé Kristẹni ni ẹ́, o ní “ẹgbẹ́ àwọn ará” tó o lè yàn lọ́rẹ̀ẹ́. (1 Pétérù 2:17) Pẹ̀lú ìyẹn náà, nígbà míì ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé àwọn èèyàn ò kà ẹ́ sí. Helena ọmọ ogún ọdún sọ pé: “Ẹ̀yìn ni mo máa ń jókòó sí nínú mọ́tò tá a bá ń bọ̀ láti ìpàdé, tí màá máa sunkún. Bí mo ṣe ń sápá láti ní àwọn ọ̀rẹ́, bẹ́ẹ̀ ni mo máa ń ní ìjákulẹ̀.”

Kí lo lè ṣe tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé àwọn èèyàn ò kà ẹ́ sí? Ká tó dáhùn ìbéèrè yẹn, jẹ́ ká kọ́kọ́ ṣàgbéyẹ̀wò (1) irú àwọn èèyàn tó ṣòro fún ẹ jù lọ láti yàn lọ́rẹ̀ẹ́ àti (2) bó o ṣe máa ń hùwà tó o bá wà láàárín wọn.

Fi àmì ✔ sẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn tó ṣòro fún ẹ láti yàn lọ́rẹ̀ẹ́.

1. Ọjọ́ orí

□ àwọn ojúgbà rẹ □ àwọn ọ̀dọ́ tó jù ẹ́ lọ □ àwọn àgbàlagbà

2. Ohun tí wọ́n ń ṣe

Àwọn èèyàn tí wọ́n

□ jẹ́ eléré ìdárayá □ lẹ́bùn àrà ọ̀tọ̀ □ jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n

3. Irú ẹni tí wọ́n jẹ́

Àwọn èèyàn tí wọ́n

□ ní ìgboyà □ gbajúmọ̀ □ wà nínú ẹgbẹ́ kan

Ní báyìí fi àmì ✔ sẹ́gbẹ̀ẹ́ gbólóhùn tó ṣàpèjúwe bó o ṣe máa ń ṣe nígbà tó o bá wà pẹ̀lú irú àwọn èèyàn tó o fàmì sí lókè.

□ Mo máa ń díbọ́n pé mo nífẹ̀ẹ́ sí ohun tí wọ́n ń ṣe tàbí pé mo lè ṣe ohun tí wọ́n ń ṣe

□ Mi ò kì í sọ̀rọ̀ nípa ohun tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí, ohun tí èmi nífẹ̀ẹ́ sí ni mo máa ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.

□ Mo máa ń jókòó jẹ́ẹ́, mo sì máa ń wá bí mo ṣe máa kúrò láàárín wọn.

Ní báyìí tó o ti mọ irú àwọn èèyàn tó máa ń ṣòro gan-an fún ẹ láti yàn lọ́rẹ̀ẹ́ àti ohun tó o máa ń ṣe tó o bá wà pẹ̀lú wọn, a lè wá jíròrò ohun tó o lè ṣe láti mú kí nǹkan túbọ̀ rọrùn sí i. Lákọ̀ọ́kọ́, ó yẹ kó o mọ àwọn nǹkan tó lè mú kó ṣòro fún ẹ láti ní ọ̀rẹ́ àti bó o ṣe lè yẹra fún àwọn nǹkan náà.

ÌṢÒRO 1: Yíya ara ẹni sọ́tọ̀

Ìpèníjà. Tó o bá wà pẹ̀lú àwọn tí ohun tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí tàbí ẹ̀bùn àbímọ́ni wọn yàtọ̀ sí tìrẹ, o lè máa wo ara rẹ pé o dá yàtọ̀ láàárín wọn, àgàgà tó o bá tún wá jẹ́ onítìjú èèyàn. Anita, ọmọ ọdún méjìdínlógún sọ pé: “Mi ò fẹ́ràn kí n máa dá ìjíròrò sílẹ̀, ẹ̀rù máa ń bà mí pé ohun tí kò tọ́ ni màá sọ.”

Ohun tí Bíbélì sọ. “Ẹni tí ń ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ yóò máa wá ìyánhànhàn onímọtara-ẹni-nìkan; gbogbo ọgbọ́n gbígbéṣẹ́ ni yóò ta kété sí.” (Òwe 18:1) Kò sí àní-àní pé, téèyàn bá ń ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀, ńṣe ló máa mú kí ọ̀rọ̀ náà burú sí i. Tó o bá ń ya ara rẹ sọ́tọ̀, ìṣòro náà kò ní yanjú, ńṣe lá máa le sí i. Ìyẹn ni pé, ńṣe ni wàá máa ti orí ìṣòro kan bọ́ sí òmíràn: Bó o bá ń dá nìkan wà, á túbọ̀ máa ṣe ẹ́ bíi pé o kò bẹ́gbẹ́ mu, èyí á sì mú kí o má ṣe fẹ́ máa dá sí àwọn ẹlòmíì mọ́, wàá wá dẹni tó ń dá wà, èyí á wá jẹ́ kó o túbọ̀ gbà pé o kò bẹ́gbẹ́ mu rárá. Tí o kò bá wá nǹkan ṣe sí i, bí wàá ṣe máa bá a yí nìyẹn, ìṣòro náà kò sì ní yanjú!

“Àwọn èèyàn ò lè mọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ. Tí o kò bá sọ ohun tó o fẹ́, ọwọ́ rẹ kò lè tẹ nǹkan náà. Tó bá jẹ́ pé o kì í dá sí àwọn ẹlòmíì, o kò lè ní ọ̀rẹ́ kankan. Ìwọ fúnra rẹ gbọ́dọ̀ sapá. Kò dáa kó o máa ronú pé ojúṣe onítọ̀hún ni láti bá ẹ sọ̀rọ̀. Bí ẹni méjì bá fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́, àwọn méjèèjì ló gbọ́dọ̀ sapá kí ọ̀rẹ́ wọn lè wọ̀.”—Melinda, ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún.

ÌṢÒRO 2: Wíwá ọ̀rẹ́ lọ́ranyàn

Ìpèníjà. Àwọn kan máa ń wá ọ̀rẹ́ lọ́ranyàn débi tí wọ́n á fi bẹ̀rẹ̀ sí í kó ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́, èrò wọn ni pé ó sàn kéèyàn kàn ṣáà wá ẹni bá rìn ju kéèyàn máà lọ́rẹ̀ẹ́ rárá lọ. René ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sọ pé: “Inú mi máa ń bà jẹ́ gan-an torí pé mi ò sí lára ẹgbẹ́ tó gbajúmọ̀ jù lọ níléèwé, débi tó fi máa ń ṣe mi bíi pé, tó bá gba pé kí n kó sí wàhálà torí kí wọ́n lè gba tèmi, mo ṣe tán.

Ohun tí Bíbélì sọ. “Ẹni tí ó bá ń ní ìbálò pẹ̀lú àwọn arìndìn yóò rí láburú.” (Òwe 13:20) Má ṣi ẹsẹ Bíbélì yìí lóye o, “àwọn arìndìn” tí ẹsẹ yẹn sọ lè máà jẹ́ ọ̀dẹ̀ tàbí aláìmọ̀kan o. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọn tiẹ̀ lè wà lára àwọn ọmọ tó mọ̀wé jù lọ níléèwé. Àmọ́ tó bá jẹ́ pé wọn kì í tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì, arìndìn ni wọ́n lójú Ọlọ́run. Ńṣe lo sì máa ṣe ara rẹ ní jàǹbá tó o bá lọ ń ṣe bí ẹranko kan tó ń jẹ́ ọ̀gà tó máa ń pààrọ̀ àwọ̀ rẹ̀, nítorí kó o lè bẹ́gbẹ́ mu.—1 Kọ́ríńtì 15:33.

“Kì í ṣe ẹnikẹ́ni téèyàn bá ṣáà ti rí ló lè yàn lọ́rẹ̀ẹ́. O kò ní fẹ́ yan àwọn ọ̀rẹ́ tí wọ́n máa ń fẹ́ kó o yí irú ẹni tó o jẹ́ pa dà nígbà tó o bá wà lọ́dọ̀ wọn. Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ látọkàn wá, tí wọ́n á sì dúró tì ẹ́ nígbàkigbà lo máa fẹ́ yàn.”—Paula, ọmọ ọdún mọ́kànlélógún.

Máa Lo Ìdánúṣe

Má ṣe dúró dìgbà táwọn ẹlòmíì á fi wá pè ẹ́ pé kó o wá di ọ̀rẹ́ àwọn. Gene ọmọ ọdún mọ́kànlélógún sọ pé: “A ò lè máa fìgbà gbogbo retí pé kí àwọn èèyàn wá bá wa. Àwa náà ní láti lọ bá wọn.” Àbá méjì kan rèé tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀:

Yan àwọn tó dàgbà jù ẹ́ lọ lọ́rẹ̀ẹ́. Nǹkan bí ọgbọ̀n ọdún ni Jónátánì fi ju Dáfídì lọ, síbẹ̀ àwọn méjèèjì jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́.b (1 Sámúẹ́lì 18:1) Ẹ̀kọ́ wo lo rí kọ́ nínú èyí? O lè yan àwọn àgbàlagbà lọ́rẹ̀ẹ́ kí ọ̀rọ̀ yín sì bára mu! Rò ó wò ná, kí nìdí tó fi jẹ́ pé àwọn ojúgbà rẹ nìkan lo fẹ́ yàn lọ́rẹ̀ẹ́, tó o sì wá ń ṣàròyé pé o kò lọ́rẹ̀ẹ́? Ńṣe nìyẹn á dà bí ẹni tí ebi pa kú ní ibì kan tí kò jìnnà sí odò, bẹ́ẹ̀ àwọn ẹja wà nínú odò yẹn tí wọ́n ń ṣeré kiri! Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, àwọn èèyàn rere wà yí ẹ ká tó o lè yàn lọ́rẹ̀ẹ́ tí ọ̀rọ̀ yín á sì bára mu. Ọ̀nà kan tó o sì lè gbà rí wọn ni pé, kó o wá àwọn tí kì í ṣe ojúgbà rẹ tó o lè yàn lọ́rẹ̀ẹ́.

“Mọ́mì mi sọ fún mi pé kí n gbìyànjú láti máa bá àwọn tó dàgbà jù mí lọ nínú ìjọ sọ̀rọ̀. Wọ́n sọ pé ó máa yà mí lẹ́nu láti rí i pé ọ̀pọ̀ ọ̀nà ni ọ̀rọ̀ wa fi bara mu. Òótọ́ lọ̀rọ̀ náà, torí pé ní báyìí mo ti wá ní ọ̀rẹ́ tó pọ̀!” —Helena, ọmọ ogún ọdún.

Kọ́ bí wọ́n ṣe ń bá èèyàn sọ̀rọ̀. Bíbá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ máa ń gba ìsapá, ní pàtàkì tó bá jẹ́ pé onítìjú èèyàn ni ẹ́. Àmọ́, o lè ṣe é. Ohun tó o máa ṣe ni pé, wàá máa (1) fetí sílẹ̀, (2) béèrè ìbéèrè, àti (3) fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwọn ẹlòmíì jẹ ọ́ lógún.

“Mo máa ń gbìyànjú láti máa fetí sílẹ̀ táwọn ẹlòmíì bá ń sọ̀rọ̀ dípò tó fi máa jẹ́ pé èmi nìkan ni màá máa sọ̀rọ̀. Tí mo bá sì ń sọ̀rọ̀, mi ò kì í fi bẹ́ẹ̀ sọ̀rọ̀ ńpa ara mi tàbí kí n máa sọ ohun tí kò dáa nípa àwọn ẹlòmíì.”—Serena, ọmọ ọdún méjìdínlógún.

“Bí ẹnì kan bá fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa ohun kan tí mi ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀, ńṣe ni mo máa ń sọ pé kó ṣàlàyé fún mi, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kí ẹni náà túbọ̀ bá mi sọ̀rọ̀.”—Jared ọmọ ọdún mọ́kànlélógún.

Bó bá jẹ́ pé èèyàn jẹ́jẹ́ tí kì í fi bẹ́ẹ̀ sọ̀rọ̀ ni ẹ́, kò sóhun tó burú nínú ìyẹn. Kì í ṣe pé kó o wá sọ ara rẹ di abẹbẹlúbẹ o! Àmọ́ tó o bá rí i pé ọ̀rọ̀ ìwọ àtàwọn míì kò bára mu, gbìyànjú àwọn àbá tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí. Ó lè wá máa ṣe ẹ́ bíi tí Leah, tó sọ pé: “Onítìjú èèyàn ni mí, torí náà mo máa ń mú ara mi lọ́ranyàn láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀. Àmọ́, kó o tó lè ní ọ̀rẹ́, o ní láti jẹ́ ẹni tó lọ́yàyà. Torí náà, mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ báyìí.”

O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí pa dà.

b Ó jọ pé Dáfídì kò tíì pé ọmọ ogún ọdún nígbà tóun àti Jónátánì di ọ̀rẹ́.

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

OHUN TÁWỌN OJÚGBÀ Ẹ SỌ

“Ó kéré tán, mo máa ń gbìyànjú láti bá ẹnì kan ti mo ronú pé mi ò tíì bá sọ̀rọ̀ rí ní ìpàdé Kristẹni sọ̀rọ̀. Mo ti wá rí i pé, tí èèyàn bá kàn kí ẹnì kan, ó lè mú kí ẹ̀yin méjèèjì di ọ̀rẹ́!”

“Ó rọrùn fún mi láti kàn máa ronú pé àwọn èèyàn ò fẹ́ràn mi, àti pé kò sí bí mo ṣe lè mú wọn lọ́rẹ̀ẹ́. Ó gba ìsapá gan-an kí n tó lè ṣe nǹkan kan nípa ẹ̀. Àmọ́, ó ṣe mí láǹfààní gan-an nígbà tí mo lo ìdánúṣe, ó sì jẹ́ kí n lè máa hùwà ọmọlúwàbí.”

“Díẹ̀díẹ̀ ni mo wá dẹni tó ń bá àwọn àgbàlagbà sọ̀rọ̀. Kò rọrùn fún mi nígbà tí mo kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀! Àmọ́, ó ṣe mí láǹfààní gan-an, torí pé nígbà tí mo ṣì kéré, mo ní àwọn ọ̀rẹ́ adúrótini tí wọn kì í fi mí sílẹ̀ nígbà ìṣòro.”

[Àwọn àwòrán]

Lauren

Reyon

Carissa

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 12]

O Ò ṢE BÉÈRÈ LỌ́WỌ́ ÀWỌN ÒBÍ RẸ?

Ṣé ó máa ń ṣòro fún yín láti yan ọ̀rẹ́ tí ọ̀rọ̀ yín bára mu nígbà tẹ́ ẹ wà lọ́dọ̀ọ́? Irú àwọn èèyàn wo ló máa ń ṣòro fún yín jù lọ láti yàn lọ́rẹ̀ẹ́? Ọgbọ́n wo lẹ wá ta sí ọ̀rọ̀ náà?

․․․․․

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

ÌṢÒRO ÌDÁNIKÀNWÀ

Mo DÁ NÌKAN WÀ,

ó sì mú kó

máa ṣe mí  . . . ↓

. . . bíi pé

MI Ò BẸ́GBẸ́ MU, èyí sì

↑ mú kí n . . .

. . . MÁ ṢE DÁ SÍ ÀWỌN ẸLÒMÍÌ, ←

ìyẹn sì mú kó máa

ṣe mí bíi pé . . .

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́