Orin 118
Ẹ Fìdùnnú Tẹ́wọ́ Gba Ara Yín
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Ẹ káàbọ̀ gbogbo ẹ̀yin tẹ́ẹ pé jọ
Láti wá gbọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
Ó ní ká gba òtítọ́ òun ìyè;
Ọpẹ́ àtọkànwá la sì fi ńtẹ́wọ́ gbàá.
2. A dúpẹ́ fún àwọn arákùnrin,
Wọ́n ńtẹ́wọ́ gbà wá, wọ́n sì ńtọ́ wa.
Ká máa ka àwọn bẹ́ẹ̀ sẹ́ni ọ̀wọ́n.
A ńtẹ́wọ́ gba àwọn míì
tó bá wa pé jọ.
3. Gbogbo aráyé ni Ọlọ́run ńpè,
Káwọn tó ńfẹ́ òótọ́ lè róòótọ́.
Ọlọ́run ńtipa Ọmọ rẹ̀ pè wá.
Ẹ fìdùnnú gba ara yín tọwọ́tẹsẹ̀.
(Tún wo Jòh. 6:44; Fílí. 2:29; Ìṣí. 22:17.)