ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • bm apá 1 ojú ìwé 4
  • Ẹlẹ́dàá Dá Èèyàn Sínú Párádísè

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹlẹ́dàá Dá Èèyàn Sínú Párádísè
  • Kí Ló Wà Nínú Bíbélì?
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • A Lè Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Tọkọtaya Ẹ̀dá Ènìyàn Àkọ́kọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Báwo Ni Ìgbésí Ayé Ṣe Rí Nínú Ọgbà Édẹ́nì?
    Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé
  • A Sọ Párádísè Nù
    Kí Ló Wà Nínú Bíbélì?
  • Ọlọ́run Dá Ọkùnrin àti Obìnrin Àkọ́kọ́
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
Àwọn Míì
Kí Ló Wà Nínú Bíbélì?
bm apá 1 ojú ìwé 4
Ádámù àti Éfà wà nínú ọgbà Édẹ́nì, àwọn ẹranko sì yí wọn ká

Apá 1

Ẹlẹ́dàá Dá Èèyàn Sínú Párádísè

Ọlọ́run dá ọ̀run àti ayé ó sì tún dá àwọn ohun alààyè sórí ilẹ̀; ó dá ọkùnrin àti obìnrin pípé kan, ó fi wọ́n sínú ọgbà ẹlẹ́wà, ó sì fún wọn láṣẹ tí wọ́n á máa tẹ̀ lé

Àwọn kìnnìún, ẹyẹ àti ẹtu nínú ọgbà Édẹ́nì

GBÓLÓHÙN tó o fẹ́ kà yìí làwọn èèyàn pè ní gbólóhùn tó gbajúmọ̀ jù lọ tẹ́nikẹ́ni tíì lò rí láti fi bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀. ‘Ní àtètèkọ́ṣe Ọlọ́run dá ọ̀run òun ayé.’ (Jẹ́nẹ́sísì 1:1, Bibeli Mimọ) Gbólóhùn ọlọ́lá-ńlá tó rọrùn yìí ni Bíbélì lò láti fi ṣàlàyé Ẹni tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú Ìwé Mímọ́, ìyẹn Jèhófà, Ọlọ́run Olódùmarè. Ẹsẹ àkọ́kọ́ nínú Bíbélì fi hàn pé Ọlọ́run ni Ẹlẹ́dàá gbogbo àgbá-ńlá ayé àtọ̀run, tó fi mọ́ orí ilẹ̀ ayé tó sọ wá lọ́jọ̀ sí yìí. Àwọn ẹsẹ tó tẹ̀ lé e ṣàlàyé pé láàárín àkókò gígùn kan, tí Bíbélì pè ní ọjọ́ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, Ọlọ́run ń bá a nìṣó láti múra orí ilẹ̀ ayé tó jẹ́ ibùgbé wa sílẹ̀ nípa ṣíṣẹ̀dá àwọn ohun àgbàyanu tó wà nínú ayé wa.

Èyí tó wá pabanbarì jù lọ lára ohun tí Ọlọ́run dá sórí ilẹ̀ ayé ni àwa èèyàn. Èèyàn jẹ́ ẹ̀dá tí Ọlọ́run dá láwòrán ara rẹ̀, ó mú kó ṣeé ṣe fún un láti fi àwọn ànímọ́ bí ìfẹ́ àti ọgbọ́n jọ Jèhófà. Erùpẹ̀ ilẹ̀ ni Ọlọ́run fi dá èèyàn. Ọlọ́run pe èèyàn tó kọ́kọ́ dá ní Ádámù, lẹ́yìn náà ló fi í sínú Párádísè tó wà nínú ọgbà Édẹ́nì. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló gbin ọgbà yẹn, ó sì mú kí onírúurú igi eléso hù síbẹ̀.

Ọlọ́run rí i pé kò tọ́ kí ọkùnrin náà máa dá gbé. Ó mú egungun ìhà Ádámù ó fi ṣe obìnrin kan, ó sì mú un wá fún ọkùnrin náà pé kó fi ṣaya, nígbà tó ṣe, Ádámù pe orúkọ aya rẹ̀ ní Éfà. Inú Ádámù dùn débi tó fi kéwì pé: “Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, èyí ni egungun nínú àwọn egungun mi àti ẹran ara nínú ẹran ara mi.” Ọlọ́run ṣàlàyé pé: “Ìdí nìyẹn tí ọkùnrin yóò ṣe fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀ tí yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀, wọn yóò sì di ara kan.”—Jẹ́nẹ́sísì 2:22-24; 3:20.

Àṣẹ méjì ni Ọlọ́run pa fún Ádámù àti Éfà. Àkọ́kọ́, ó ní kí wọ́n máa ro ilẹ̀ ayé tó jẹ́ ibùgbé wọn, kí wọ́n máa tọ́jú rẹ̀, kí wọ́n sì fi ọmọ kún inú rẹ̀. Èkejì, ó ní kí wọ́n má ṣe jẹ èso igi kan ṣoṣo lára àwọn igi tó wà nínú ọgbà ńlá náà, ìyẹn “igi ìmọ̀ rere àti búburú.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:17) Bí wọ́n bá ṣàìgbọràn, wọ́n á kú. Àwọn àṣẹ yìí ni Ọlọ́run lò láti fún ọkùnrin àti obìnrin náà láǹfààní láti fi hàn pé wọ́n tẹ́wọ́ gba òun gẹ́gẹ́ bí Olùṣàkóso wọn. Ìgbọràn wọn á tún fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run wọ́n sì mọyì ohun tó ṣe fún wọn. Kò sí ìdí kankan tí wọn ò fi ní fara mọ́ àkóso onífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Kò sí àléébù kankan lára àwọn ẹ̀dá pípé wọ̀nyẹn. Bíbélì sọ fún wa pé: “Ọlọ́run rí ohun gbogbo tí ó ti ṣe, sì wò ó! ó dára gan-an ni.”—Jẹ́nẹ́sísì 1:31.

—A gbé e ka Jẹ́nẹ́sísì orí 1 àti 2.

  • Báwo ni Bíbélì ṣe ṣàpèjúwe ìṣẹ̀dá èèyàn àti ilẹ̀ ayé tó jẹ́ ibùgbé wọn?

  • Irú ìgbé ayé wo ni Ọlọ́run mú kó ṣeé ṣe fún ọkùnrin àti obìnrin?

  • Àṣẹ wo ni Ọlọ́run pa fún tọkọtaya àkọ́kọ́?

ORÚKỌ ỌLỌ́RUN

Ìwé Mímọ́ lo ọ̀kan-ò-jọ̀kan orúkọ oyè fún Ọlọ́run, irú bí Ẹlẹ́dàá àti Ọlọ́run Olódùmarè. Àwọn orúkọ oyè kan tẹnu mọ́ àwọn ànímọ́ Ọlọ́run, bí ìjẹ́mímọ́ rẹ̀, agbára rẹ̀, ìdájọ́ òdodo rẹ̀, ọgbọ́n rẹ̀ àti ìfẹ́ rẹ̀. Àmọ́, Ọlọ́run tún fún ara rẹ̀ ní orúkọ àdáni kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀, ìyẹn ni Jèhófà. Nínú àwọn èdè tí wọ́n fi kọ Bíbélì ní ìpilẹ̀ṣẹ̀, orúkọ Ọlọ́run yìí fara hàn ní ìgbà ẹgbẹ̀rún méje [7,000], inú Jẹ́nẹ́sísì 2:4 ni Bíbélì sì ti kọ́kọ́ lò ó. Orúkọ náà Jèhófà, túmọ̀ sí “Alèwílèṣe.” Èyí tuni nínú torí ó jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run lè mú ohunkóhun tó bá jẹ́ ète rẹ̀ ṣẹ, ìlérí èyíkéyìí tó bá ṣe ò sì lè kùnà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́