Ẹ̀KỌ́ 58
Wọ́n Pa Jerúsálẹ́mù Run
Àìmọye ìgbà làwọn èèyàn Júdà ń ṣàìgbọràn sí Jèhófà, tí wọ́n sì ń bọ̀rìṣà. Ọ̀pọ̀ ọdún ni Jèhófà fi ràn wọ́n lọ́wọ́. Ó rán àwọn wòlíì láti kìlọ̀ fún wọn, àmọ́ wọn ò gba ìkìlọ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n ń fi àwọn wòlíì náà ṣe yẹ̀yẹ́. Kí wá ni Jèhófà ṣe fáwọn aláìgbọràn yìí?
Nebukadinésárì ọba Bábílónì ti bá ọ̀pọ̀ ìlú jagun, ó sì ń ṣẹ́gun wọn. Nígbà tó kọ́kọ́ ṣẹ́gun Jerúsálẹ́mù, ó mú Ọba Jèhóákínì, àwọn ìjòyè, àwọn jagunjagun àtàwọn oníṣẹ́ ọwọ́, ó sì kó gbogbo wọn lọ sí Bábílónì. Ó tún kó àwọn nǹkan iyebíye tó wà nínú tẹ́ńpìlì Jèhófà lọ. Lẹ́yìn náà, Nebukadinésárì fi Sedekáyà jẹ ọba Júdà.
Níbẹ̀rẹ̀, Sedekáyà máa ń ṣe ohun tí Nebukadinésárì fẹ́. Àmọ́ àwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká àtàwọn wòlíì èké gba Sedekáyà nímọ̀ràn pé kó ṣàìgbọràn sí ọba Bábílónì. Ṣùgbọ́n, Jeremáyà kìlọ̀ fún un pé: ‘Tó o bá ṣàìgbọràn, wọ́n máa pa àwọn èèyàn Júdà, kò ní sí oúnjẹ nílùú, àwọn èèyàn á sì máa ṣàìsàn.’
Lẹ́yìn ọdún mẹ́jọ tí Sedekáyà ti ń ṣàkóso, ó ṣàìgbọràn sí ọba Bábílónì. Ó ní káwọn ọmọ ogun Íjíbítì jẹ́ káwọn jọ bá Bábílónì jagun. Ni Nebukadinésárì bá rán àwọn ọmọ ogun ẹ̀ láti lọ dojú ìjà kọ Jerúsálẹ́mù, àwọn ọmọ ogun ẹ̀ sì yí ìlú náà ká. Jeremáyà wá sọ fún Sedekáyà pé: ‘Jèhófà sọ pé tó o bá fi ara ẹ sábẹ́ Bábílónì, wọn ò ní pa ẹ́, ìlú náà ò sì ní pa run. Àmọ́ tó o bá ṣàìgbọràn, wọ́n máa dáná sun Jerúsálẹ́mù, wọ́n á sì mú ẹ lẹ́rú.’ Sedekáyà sọ pé: ‘Àfi kí n bá wọn jagun!’
Ọdún kan ààbọ̀ lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ ogun Bábílónì fọ́ ògiri Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì finá sun ìlú náà. Wọ́n dáná sun tẹ́ńpìlì, wọ́n pa ọ̀pọ̀ èèyàn, wọ́n sì kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ lẹ́rú.
Sedekáyà sá kúrò ní Jerúsálẹ́mù, àmọ́ àwọn ará Bábílónì sáré tẹ̀ lé e. Wọ́n wá mú un nítòsí ìlú Jẹ́ríkò, wọ́n sì mú un lọ sọ́dọ̀ Nebukadinésárì. Ọba Bábílónì ní kí wọ́n pa àwọn ọmọ Sedekáyà níṣojú Sedekáyà fúnra ẹ̀. Lẹ́yìn náà, Nebukadinésárì fọ́ ojú Sedekáyà, ó sì fi sẹ́wọ̀n. Ibẹ̀ ni Sedekáyà kú sí. Àmọ́ Jèhófà ṣèlérí fáwọn èèyàn Júdà pé: ‘Lẹ́yìn àádọ́rin (70) ọdún, màá dá a yín pa dà sílùú yín ní Jerúsálẹ́mù.’
Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ tí wọ́n kó lẹ́rú lọ sí Bábílónì? Ṣé wọ́n á máa jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà nìṣó?
“Jèhófà Ọlọ́run, Olódùmarè, àní òótọ́ àti òdodo ni àwọn ìdájọ́ rẹ.”—Ìfihàn 16:7