ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JEREMÁYÀ 39-43
Jèhófà Máa San Olúkúlùkù Lẹ́san Níbàámu Pẹ̀lú Iṣẹ́ Rẹ̀
Sedekáyà ṣàìgbọ́ràn sí Jèhófà, ó kọ̀ láti fi ara rẹ̀ sábẹ́ Bábílónì
Ìṣojú Sedekáyà ni wọ́n ṣe pa àwọn ọmọkùnrin rẹ̀. Lẹ́yìn náà, wọ́n fọ́ ojú rẹ̀, wọ́n fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ bàbà dè é, wọ́n fi sí ẹ̀wọ̀n ní Bábílónì, ibẹ̀ ló sì kú sí
Ebedi-mélékì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó tún tọ́jú Jeremáyà wòlíì Jèhófà
Jèhófà sọ pé òun máa dáàbò bo Ebedi-mélékì nígbà tí Júdà bá pa run
Jeremáyà fìgboyà wàásù fún ọ̀pọ̀ ọdún kí Jerúsálẹ́mù tó pa run
Jèhófà dáàbò bo Jeremáyà nígbà táwọn ọ̀tá gbógun ti Jerúsálẹ́mù, ó sì mú kí àwọn ará Bábílónì tú u sílẹ̀