ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JEREMÁYÀ 35-38
Ebedi-mélékì Jẹ́ Onígboyà àti Onínúure
Ebedi-mélékì jẹ́ ìjòyè láàfin Ọba Sedekáyà, èèyàn dáadáa sì ni
Ó lo ìgboyà, ó sì gbé ìgbésẹ̀ lójú ẹsẹ̀ láti lọ bá Ọba Sedekáyà kó lè yọ Jeremáyà jáde nínú kòtò ẹlẹ́rẹ̀
Ó fi àwọn àgékù aṣọ àti aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ sí abíyá Jeremáyà kí okùn tí wọ́n fi ń fà á sókè má bàa ṣe é léṣe; èyí fi hàn pé ó jẹ́ onínúure