Friday
“Jèhófà yóò fi àlàáfíà jíǹkí àwọn èèyàn rẹ̀”—Sáàmù 29:11
ÀÁRỌ̀
9:20 Fídíò Orin
9:30 Orin 86 àti Àdúrà
9:40 Ọ̀RỌ̀ ALÁGA: Jèhófà Ni “Ọlọ́run Tó Ń Fúnni Ní Àlàáfíà” (Róòmù 15:33; Fílípì 4:6, 7)
10:10 ÀPÍNSỌ ÀSỌYÉ: Ìfẹ́ Máa Ń Jẹ́ Ká Ní Àlàáfíà Tòótọ́
• Ìfẹ́ Tá A Ní fún Ọlọ́run (Mátíù 22:37, 38; Róòmù 12:17-19)
• Ìfẹ́ Tá A Ní fún Ọmọnìkejì Wa (Mátíù 22:39; Róòmù 13:8-10)
• Ìfẹ́ Tá A Ní fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run (Sáàmù 119:165, 167, 168)
11:05 Orin 24 àti Ìfilọ̀
11:15 BÍBÉLÌ KÍKÀ BÍ ẸNI ṢE ERÉ ÌTÀN: Jékọ́bù Nífẹ̀ẹ́ Àlàáfíà (Jẹ́nẹ́sísì 26:12–33:11)
11:45 “Àlàáfíà Ni Òdodo Tòótọ́ Máa Mú Wá” (Àìsáyà 32:17; 60:21, 22)
12:15 Orin 97 àti Àkókò Ìsinmi
Ọ̀SÁN
1:35 Fídíò Orin
1:45 Orin 144
1:50 ÀPÍNSỌ ÀSỌYÉ: Jẹ́ Kí Àlàáfíà Tí Ọlọ́run Ṣèlérí Máa Múnú Rẹ Dùn
• “Àwọn Ìránṣẹ́ Mi Máa Jẹun . . . Àwọn Ìránṣẹ́ Mi Máa Mu” (Àìsáyà 65:13, 14)
• ‘Wọ́n Á Kọ́ Ilé, Wọ́n Á sì Gbin Ọgbà Àjàrà’ (Àìsáyà 65:21-23)
• “Ìkookò àti Ọ̀dọ́ Àgùntàn Máa Jẹun Pa Pọ̀” (Àìsáyà 11:6-9; 65:25)
• “Kò Sí Ẹnì Kankan Tó Ń Gbé Ibẹ̀ Tó Máa Sọ Pé: ‘Ara Mi Ò Yá’” (Àìsáyà 33:24; 35:5, 6)
• “Ó Máa Gbé Ikú Mì Títí Láé” (Àìsáyà 25:7, 8)
2:50 Orin 35 àti Ìfilọ̀
3:00 ÀPÍNSỌ ÀSỌYÉ: Máa Ṣe Ohun Táá Jẹ́ Kí Àlàáfíà Wà Nínú Ìdílé Rẹ
• Ẹ Nífẹ̀ẹ́ Ara Yín, Kẹ́ Ẹ sì Máa Bọ̀wọ̀ fún Ara Yín (Róòmù 12:10)
• Ẹ Jọ Máa Sọ̀rọ̀ Dáadáa (Éfésù 5:15, 16)
• Ẹ Máa Pawọ́ Pọ̀ Ṣe Nǹkan (Mátíù 19:6)
• Ẹ Máa Sin Jèhófà Pa Pọ̀ (Jóṣúà 24:15)
3:55 Máa Ti “Ọmọ Aládé Àlàáfíà” Lẹ́yìn Tọkàntọkàn (Àìsáyà 9:6, 7; Títù 3:1, 2)
4:15 Má Ṣe Jẹ́ Kí Ohun Tí Ayé Ń Pè Ní Àlàáfíà Tàn Ẹ́ Jẹ! (Mátíù 4:1-11; Jòhánù 14:27; 1 Tẹsalóníkà 5:2, 3)
4:50 Orin 112 àti Àdúrà Ìparí