Saturday
“Ẹ sa gbogbo ipá yín kó lè bá yín . . . láìní èérí àti àbààwọ́n àti ní àlàáfíà”—2 Pétérù 3:14
ÀÁRỌ̀
9:20 Fídíò Orin
9:30 Orin 58 àti Àdúrà
9:40 ÀPÍNSỌ ÀSỌYÉ: Múra Tán Láti Kéde “Ìhìn Rere Àlàáfíà”
• Jẹ́ Kí Iná Ìtara Ẹ Máa Jó (Róòmù 1:14, 15)
• Múra Sílẹ̀ Dáadáa (2 Tímótì 2:15)
• Máa Lo Àǹfààní Tó Bá Yọ (Jòhánù 4:6, 7, 9, 25, 26)
• Pa Dà Lọ Sọ́dọ̀ Àwọn Tó Nífẹ̀ẹ́ Sọ́rọ̀ Ẹ (1 Kọ́ríńtì 3:6)
• Ran Àwọn Tó Ò Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Túbọ̀ Sún Mọ́ Jèhófà (Hébérù 6:1)
10:40 Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Ẹ Fi Ayé Yín Ṣe Ohun Táá Jẹ́ Kí Ọkàn Yín Balẹ̀! (Mátíù 6:33; Lúùkù 7:35; Jémíìsì 1:4)
11:00 Orin 135 àti Ìfilọ̀
11:10 FÍDÍÒ: Ọkàn Àwọn Ará Wa Balẹ̀ Bí Wọ́n Tiẹ̀ Ń Dojú Kọ . . .
• Àtakò
• Àìsàn
• Ìṣòro Àìlówó Lọ́wọ́
• Àjálù
11:45 ÌRÌBỌMI: Ẹ Máa Rìn “ní Ọ̀nà Àlàáfíà” (Lúùkù 1:79; 2 Kọ́ríńtì 4:16-18; 13:11)
12:15 Orin 54 àti Àkókò Ìsinmi
Ọ̀SÁN
1:35 Fídíò Orin
1:45 Orin 29
1:50 ÀPÍNSỌ ÀSỌYÉ: Ẹ Yẹra fún Ohun Tó Lè Ba Àlàáfíà Jẹ́
• Kéèyàn Máa Fọ́nnu (Éfésù 4:22; 1 Kọ́ríńtì 4:7)
• Ìlara (Fílípì 2:3, 4)
• Àìṣòótọ́ (Éfésù 4:25)
• Òfófó Tó Ń Pani Lára (Òwe 15:28)
• Ìbínú Òdì (Jémíìsì 1:19)
2:45 FÍDÍÒ: Jèhófà Ń Darí Wa ní Ọ̀nà Àlàáfíà—Apá 1 (Àìsáyà 48:17, 18)
3:15 Orin 130 àti Ìfilọ̀
3:25 ÀPÍNSỌ ÀSỌYÉ: ‘Máa Wá Àlàáfíà, Kó O sì Máa Lépa Rẹ̀’ . . .
• Má Tètè Máa Bínú (Òwe 19:11; Oníwàásù 7:9; 1 Pétérù 3:11)
• Máa Tọrọ Àforíjì (Mátíù 5:23, 24; Ìṣe 23:3-5)
• Máa Dárí Jini Fàlàlà (Kólósè 3:13)
• Máa Sọ Ohun Tó Máa Ṣe Àwọn Èèyàn Láǹfààní (Òwe 12:18; 18:21)
4:15 Má Ṣe Jẹ́ Kí Àlàáfíà Tó Wà Láàárìn Wa Bà Jẹ́ (Éfésù 4:1-6)
4:50 Orin 113 àti Àdúrà Ìparí