ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • lmd ẹ̀kọ́ 7
  • Má Jẹ́ Kó Sú Ẹ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Má Jẹ́ Kó Sú Ẹ
  • Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn—Máa Sọ Wọ́n Dọmọ Ẹ̀yìn
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tí Pọ́ọ̀lù Ṣe
  • Kí La Rí Kọ́ Lára Pọ́ọ̀lù?
  • Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù
  • Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀
    Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn—Máa Sọ Wọ́n Dọmọ Ẹ̀yìn
  • Sọ Ohun Táwọn Èèyàn Nífẹ̀ẹ́ Sí
    Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn—Máa Sọ Wọ́n Dọmọ Ẹ̀yìn
  • Máa Ní Sùúrù
    Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn—Máa Sọ Wọ́n Dọmọ Ẹ̀yìn
  • Ìgbà Wo Ló Yẹ Ká Pa Dà Lọ Sọ́dọ̀ Àwọn Tó Fetí sí Ọ̀rọ̀ Wa?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
Àwọn Míì
Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn—Máa Sọ Wọ́n Dọmọ Ẹ̀yìn
lmd ẹ̀kọ́ 7

PA DÀ LỌ

Àpọ́sítélì Pọ́ọ́lù ń wàásù ìhìnrere fáwọn èèyàn ní gbọ̀ngàn ilé ìwé kan.

Ìṣe 19:8-10

Ẹ̀KỌ́ 7

Má Jẹ́ Kó Sú Ẹ

Ìlànà: “Wọ́n ń kọ́ni láìdábọ̀, wọ́n sì ń kéde ìhìn rere.”—Ìṣe 5:42.

Ohun Tí Pọ́ọ̀lù Ṣe

Àpọ́sítélì Pọ́ọ́lù ń wàásù ìhìnrere fáwọn èèyàn ní gbọ̀ngàn ilé ìwé kan.

FÍDÍÒ: Pọ́ọ̀lù Ò Rẹ̀wẹ̀sì ní Éfésù

1. Wo FÍDÍÒ yìí, tàbí kó o ka Ìṣe 19:8-10. Lẹ́yìn náà, kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  1. Dípò kí Pọ́ọ̀lù rẹ̀wẹ̀sì nígbà táwọn kan ta kò ó, báwo ló ṣe fi hàn pé òun ní àforítì tó sì ran àwọn tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ lọ́wọ́?

  2. Ọjọ́ mélòó síra ni Pọ́ọ̀lù ń pa dà lọ sọ́dọ̀ àwọn tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, báwo ló sì ṣe pẹ́ tó tó fi ṣe bẹ́ẹ̀?

Kí La Rí Kọ́ Lára Pọ́ọ̀lù?

2. Ó yẹ ká múra tán láti máa lo àkókò tó pọ̀ tó, ká sì máa ṣiṣẹ́ kára láti pa dà lọ sọ́dọ̀ àwọn tá a wàásù fún, ká lè bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù

3. Lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn lásìkò tó rọrùn fún wọn. Bi ara ẹ pé: ‘Ìgbà wo lẹni náà máa ń ráyè jù? Ibo ló sì ti máa ń rọ̀ ọ́ lọ́rùn jù láti bá mi sọ̀rọ̀?’ Múra tán láti lọ sọ́dọ̀ ẹ̀, kódà tí àkókò náà ò bá rọrùn fún ẹ.

4. Ẹ jọ ṣàdéhùn. Gbogbo ìgbà tẹ́ ẹ bá ti parí ọ̀rọ̀ yín ni kó o máa béèrè ìgbà tó tún máa ráyè. Rí i pé o pa dà lọ lásìkò tẹ́ ẹ fi àdéhùn sí.

5. Má sọ̀rètí nù. Tó bá jẹ́ pé ẹnì kan kì í sábà sí nílé tàbí pé kì í fi bẹ́ẹ̀ ráyè, má rò pé ńṣe lẹni náà ò fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. (1 Kọ́r. 13:4, 7) Òótọ́ ni pé o ò ní jẹ́ kó sú ẹ, síbẹ̀ má fàkókò ẹ ṣòfò.—1 Kọ́r. 9:26.

TÚN WO

Ìṣe 10:42; 1 Kọ́r. 9:22, 23; 2 Kọ́r. 4:1; Gál. 6:9

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́