ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 4/1 ojú ìwé 3-5
  • Ominira Tootọ—Lati Orisun Wo?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ominira Tootọ—Lati Orisun Wo?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • A Ṣi Ominira Lò
  • Ìdè-Ìsìnrú Fun Isin Èké
  • Awọn Eniyan Olominira Ṣugbọn Ti Wọn Yoo Jíhìn
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Kíkókìkí Ayé Titun Olómìnira Ti Ọlọrun
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • “Eto Ayé Titun” Ti Eniyan Ha Sunmọle Bi?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Kí Ni Òmìnira Ìsìn Túmọ̀ Sí fún Ọ?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 4/1 ojú ìwé 3-5

Ominira Tootọ—Lati Orisun Wo?

“Kì í ṣe ti eniyan ti ń rìn kódà lati dari ìṣísẹ̀ rẹ̀. Tọ́ mi sọ́nà, Óò Jehofa.”—JEREMAYA 10:23, 24, New World Translation, (Gẹẹsi)

1, 2. Oju wo ni ọpọ julọ awọn eniyan fi wo ominira, ṣugbọn ohun miiran wo ni ó tun yẹ lati gbeyẹwo?

LAISI iyemeji iwọ mọriri ominira tootọ. Iwọ fẹ́ lati ni ominira lati sọ      awọn oju-iwoye rẹ jade, ni ominira lati pinnu ibi ati bí iwọ yoo ṣe      maa gbé. O fẹ́ lati yan iṣẹ ti iwọ yoo ṣe, yan ounjẹ, orin, awọn ọ̀rẹ́ rẹ. Ọpọlọpọ awọn nǹkan, ńlá ati kekere ni o yànláàyò. Kò sí ẹnikan ti ori rẹ̀ pé ti ó fẹ́ di ẹrú fun awọn oluṣakoso apàṣẹwàá, pẹlu yíyàn fàlàlà ti kò tó nǹkan tabi ki ó má sí ọ̀kankan rárá.

2 Bi o ti wu ki o ri, iwọ kò ha tun ni fẹ́ ayé kan nibi ti iwọ ati awọn miiran bakan naa yoo ti janfaani lati inu ominira tootọ? Iwọ kò ha ni fẹ ayé kan nibi ti a o ti pa ominira mọ́ kí igbesi-aye olukuluku baa lè fihan lẹkunrẹrẹ julọ? Bi ó bá sì ṣeeṣe, iwọ kò ha tun ni fẹ́ ayé kan ti ó bọ́ lọwọ ibẹru, iwa ọdaran, ebi, òṣì, biba ayika jẹ́, aisan, ati ogun? Dajudaju iru awọn ominira bẹẹ fanilọkanmọra gidigidi.

3. Eeṣe ti a fi mọriri ominira?

3 Eeṣe ti awa eniyan fi nimọlara gidigidi tobẹẹ nipa ominira? Bibeli wi pe: ‘Nibi ti ẹmi Jehofa bá wà, nibẹ ni ominira gbé wà.’ (2 Kọrinti 3:17) Nitori naa Jehofa ni Ọlọrun ominira. Ati niwọn bi o ti dá wa ni ‘aworan ati irisi’ rẹ̀, ó fi ominira ifẹ-inu jíǹkí wa kí á baa lè mọriri ki a sì janfaani lati inu ominira.—Jẹnẹsisi 1:26.

A Ṣi Ominira Lò

4, 5. Ọna wo ni a ti gbà ṣi ominira lo jalẹ ìtàn?

4 Jalẹ ìtàn araadọta-ọkẹ awọn eniyan ni a ti mú lẹ́rú, dálóró, tabi pa nitori pe awọn miiran ṣi ominira ifẹ-inu lò. Bibeli rohin pe ni nǹkan bii 3,500 ọdun sẹhin, “awọn ará Ijibiti . . . mú awọn ọmọ Isirẹli sìn labẹ iwa ìkà rírorò. Wọn sì ń baa lọ lati mú igbesi-aye wọn korò pẹlu isinru lilekoko.” (Ẹkisodu 1:13, 14, NW) Iwe gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopedia Americana sọ pe ni ọrundun kẹrin B.C.E., awọn ẹrú ni Anteni ati awọn ilu Giriiki meji miiran fi nǹkan bii 4 si 1 tayọ iye awọn eniyan ti wọn ń gbé. Orisun yii tun sọ pe: “Ni Roomu ẹrú kò ni ẹ̀tọ́ kankan ni ipilẹṣẹ. A lè pa á fun aṣiṣe ti o kere julọ.” Compton’s Encyclopedia ṣakiyesi pe: “Ni Roomu iṣẹ àfokunṣe awọn ẹrú ni ó jẹ́ ipilẹ orilẹ-ede naa. . . . Ninu pápá awọn ẹrú sábà maa ń ṣiṣẹ ninu ìdè ẹ̀wọ̀n. A ń dè wọn papọ ni alẹ́ a sì ń tì wọn mọ́ inu túbú ńlá, eyi ti ó wọlẹ dé ìdajì.” Niwọn bi ọpọlọpọ awọn ẹrú ti wà lominira nigba kan ri, finuro bi o ti ṣoro tó lati tẹwọgba irú igbesi-aye ti a dilọwọ wọnyẹn!

5 Fun ọpọ ọrundun, Kristẹndọmu lọwọ ninu òwò ẹrú atẹniloriba. Iwe gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia sọ pe: “Lati awọn ọdun 1500 si awọn ọdun 1800, awọn ará Europe kó nǹkan bii 10 million awọn ẹrú alawọ dudu lati Africa lọ sí apá Iwọ-oorun Ilaji Ayé.” Ni ọrundun lọna 20 yii, araadọta-ọkẹ awọn òǹdè ni a mú ṣiṣẹ ni àṣekú tabi ṣekupa ni àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Nazi nitori ti ilana eto ijọba. Awọn ojiya ipalara ní ọpọlọpọ Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ninu awọn ti a fi sẹwọn nitori pe wọn kọ̀ lati ti iṣakoso Nazi aṣekupani lẹhin.

Ìdè-Ìsìnrú Fun Isin Èké

6. Bawo ni isin èké ṣe sọ awọn eniyan di ẹrú ni Kenani igbaani?

6 Ìdè-ìsìnrú ti o jẹ jade lati inu fifaramọ isin èké tun wà. Fun apẹẹrẹ, ni Kenani igbaani, awọn ọmọ ni a fi rúbọ si Moleki. A sọ pe ìléru ń jó ninu ère gàgàrà ọlọrun èké yii. Awọn alàyè ọmọ ni a ń jù sori apá ère naa ti o nà gbalaja siwaju, ni yiyi gbirigbiri gba ori awọn apá naa bọ́ sinu iná nisalẹ. Ani awọn ọmọ Isirẹli kan tilẹ ṣe ijọsin èké yii. Ọlọrun sọ pe wọn ń mu ‘awọn ọmọkunrin ati awọn ọmọbinrin wọn la iná kọja fun Moleki, ohun ti oun kò palaṣẹ fun wọn, bẹẹ ni kò sì wá sinu ọkan-aya oun lati ṣe ohun irira yii.’ (Jeremaya 32:35, NW) Anfaani wo ni Moleki mú wa fun awọn olujọsin rẹ̀? Awọn orilẹ-ede Kenani ati ijọsin Moleki dà lonii? Gbogbo wọn ti pòórá. Iyẹn ni ijọsin èké, ijọsin ti a gbé ka kì í ṣe ori otitọ bikoṣe ori irọ́.—Aisaya 60:12.

7. Aṣa amunigbọnriri wo ni ó jẹ́ apakan isin Aztec?

7 Ni ọpọ ọrundun sẹhin ni Central America, awọn Aztec ni a mulẹru sinu isin èké. Awọn ọlọrun àdáni wà, ipá àdánidá ni a jọsin gẹgẹ bi awọn ọlọrun, oniruuru igbokegbodo ninu igbesi-aye ojoojumọ ní ọlọrun tirẹ̀, awọn irugbin ni ọlọrun tiwọn, kódà ipara-ẹni paapaa ni ọlọrun kan. Iwe naa The Ancient Sun Kingdoms of the Americas rohin pe: “Ijọba Aztec ni Mexico ni a ṣetojọ lati òkè délẹ̀ ki ó baa lè ṣetilẹhin, ki ó sì tipa bẹẹ tu awọn agbara àìrí lójú, pẹlu ọpọlọpọ ọkan-aya eniyan bi o ti lè pọ̀ tó lati fifun wọn. Ẹ̀jẹ̀ ni ohun mímu awọn ọlọrun naa. Lati rí awọn ojiya ipalara yiyẹ ti a kó nígbèkùn fun ìrúbọ sí awọn ọlọrun, awọn ogun keekeeke àjààdabọ̀ ni wọn wà.” Nigba ti a ya tẹmpili aboríṣóńṣó bìdírẹ̀kẹ̀tẹ̀ kan sí mímọ́ ni 1486, ẹgbẹẹgbẹrun awọn ojiya ipalara “ni a tò sori ìlà ni diduro de ìdádùbúlẹ̀ gbalaja sori okuta ìrúbọ. Ọkan-aya wọn ni a gé jade ti a sì nà soke sí oòrùn fun akoko ráńpẹ́” lati tu ọlọrun oòrùn loju. The World Book Encyclopedia sọ pe: “Awọn olujọsin maa ń jẹ apakan ara ojiya ipalara naa nigba miiran.” Sibẹ, awọn àṣà wọnni kò gba Ilẹ-ọba Aztec tabi isin èké rẹ̀ là.

8. Ki ni olùfọ̀nàhanni kan ní lati sọ nipa ipaniyan ode-oni kan ti o pọ lọpọlopọ rekọja eyi ti ó wáyé laaarin awọn Aztec?

8 Nigba kan awọn alejo ń rin yika ile akojọ ohun ìṣẹ̀ǹbáyé kan nibi ti igbá ìpàtẹ kan ti fi abọrẹ̀ Aztec ti ń gé ọkan-aya ọdọmọkunrin kan jade han. Nigba ti olùfọ̀nàhanni ṣalaye ipatẹ naa, ìpayà mú diẹ lara awujọ arinrin-ajo naa. Olùfọ̀nàhanni naa sọ lẹhin naa pe: “Mo rí i pe ọkàn yin bajẹ nipa àṣà Aztec ti fifi awọn ọdọmọkunrin rubọ si awọn ọlọrun abọriṣa. Sibẹ, ni ọrundun lọna 20 yii, araadọta-ọkẹ awọn ọdọmọkunrin ni a ti fi rubọ si ọlọrun ogun. Iyẹn ha fi ohunkohun sànjù bi?” Otitọ ni pe ninu ogun awọn olori isin gbogbo awọn orilẹ-ede a maa gbadura fun iṣẹgun wọn a sì bukun awọn ọmọ-ogun bi o tilẹ jẹ pe awọn eniyan ti ń se iru isin kan naa niye igba ni wọn maa ń wà ni ìhà odikeji ti wọn ń pa araawọn.—1 Johanu 3:10-12; 4:8, 20, 21; 5:3.

9. Aṣa wo ni ó gbẹmi awọn ọ̀dọ́ pupọ sii ju eyikeyii miiran lọ ninu ìtàn?

9 Fifi awọn ọ̀dọ́ rubọ si Moleki, si awọn ọlọrun Aztec, tabi si ogun ni pípa awọn ọmọ ti a kò tíì bí ninu ìṣẹ́yún ti tayọ rekọja, nǹkan bii 40 tabi 50 ọkẹ ni ọdun kan yika ayé. Iye ti a ṣẹ́yún wọn danu ní kìkì ọdun mẹta ti o kọja pọ pupọ ju aadọta-ọkẹ lọna ọgọrun-un eniyan ti a pa ninu gbogbo awọn ogun ọrundun yii. Ni ìgbà melookan, lọdọọdun, ọmọ pupọ sii ju gbogbo awọn eniyan ti a pa ni ọdun 12 iṣakoso Nazi ni a ń ṣẹ́yún wọn danu. Ni awọn ẹwadun ẹnu aipẹ yii awọn ọmọ ti wọn fi ẹgbẹẹgbẹrun pọ niye sii ju gbogbo awọn wọnni ti a fi rubọ si Moleki tabi si awọn ọlọrun Aztec ni a ti ṣẹ́yún wọn danu. Sibẹ ọpọlọpọ (bi kii bá ṣe ọpọ julọ) awọn wọnni ti wọn ṣẹ́yún, tabi ti wọn ṣẹ́yún funni, fẹnu jẹwọ isin kan.

10. Ki ni ọ̀nà miiran ti a gbà sọ awọn eniyan di ẹrú fun isin èké?

10 Isin èké mú awọn eniyan lẹ́rú ni awọn ọna miiran pẹlu. Fun apẹẹrẹ, ọpọlọpọ gbagbọ pe awọn òkú walaaye ninu ayé ẹmi. Iyọrisi iru igbagbọ èké kan bẹẹ ni ibẹru ati ijọsin awọn babanla ti wọn ti kú kí wọn baa lè rí awọn anfaani ti wọn tànmọ́-ọ̀n gbà lati ọdọ wọn. Eyi sọ awọn eniyan di ẹrú fun awọn adáhunṣe, abẹ́mìílò, ati awọn alufaa ti wọn ń tọ̀ lọ pẹlu èrò lati ran alaaye lọwọ lati tu awọn òkú loju. Ó dara ki a beere ibeere naa pe, Abajade kankan ha wà kuro ninu iru imunisinru bẹẹ bi?—Deutaronomi 18:10-12; Oniwaasu 9:5, 10.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4, 5]

Jalẹ ìtàn awọn kan ti ṣi ominira ifẹ-inu wọn lò lati sọ awọn ẹlomiran di ẹrú

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́