ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 6/1 ojú ìwé 25-27
  • Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́yege Gileadi Rí ‘Ayọ̀ Púpọ̀ Nínú Fífúnni’

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́yege Gileadi Rí ‘Ayọ̀ Púpọ̀ Nínú Fífúnni’
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ọ̀rọ̀ Ìdágbére fún Ìṣítí
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ ti Ọ̀sán Ní Ọlọ́kan-⁠Ò-Jọ̀kan
  • Ọpọ Ojihin Iṣẹ Ọlọrun Sii fun Ikore Yika Ayé
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ile-ẹkọ Gilead Pé 50 Ọdun Ó Sì Ń Ṣaṣeyọri!
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́yege Gilead—“Àwọn Ojúlówó Míṣọ́nnárì!”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ẹ Máa Yọ̀ Nínú Jèhófà Kí Ẹ Sì Kún fún Ìdùnnú
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 6/1 ojú ìwé 25-27

Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́yege Gileadi Rí ‘Ayọ̀ Púpọ̀ Nínú Fífúnni’

NÍ SUNDAY, March 6, 1994, ìdílé Beteli ní orílé-iṣẹ́ àgbáyé ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa àti àwọn àlejò kórajọ fún àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ alájọyọ̀ kan​—⁠ìkẹ́kọ̀ọ́yege kíláàsì kẹrìndínlọ́gọ́rùn-⁠ún ti Watchtower Bible School of Gilead. Nínú àlàyé ìnasẹ̀-ọ̀rọ̀ rẹ̀, alága ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà Karl F. Klein, ẹni tí ó ti sìn nínú Ẹgbẹ́ Olùṣàkoso ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fún ohun tí ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹ̀wádún méjì, sọ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ 46 náà pé: “Jesu wí pé ayọ̀ púpọ̀ ń bẹ nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ. Bẹ́ẹ̀ ni yóò rí nínú iṣẹ́-àyànfúnni míṣọ́nnárì yín​—⁠bí ẹ bá ti ń fúnni tó, bẹ́ẹ̀ ni ayọ̀ yín yóò ti pọ̀ tó.”​—⁠Iṣe 20:⁠35.

Àwọn Ọ̀rọ̀ Ìdágbére fún Ìṣítí

Ọ̀wọ́ àwọn ọ̀rọ̀-àsọyé fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà tẹ̀lé e. Leon Weaver, mẹ́ḿbà Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka-Iṣẹ́ Iṣẹ́-Ìsìn, ṣe ìgbékalẹ̀ ẹsin-ọ̀rọ̀ náà “Ìfaradà Ń Yin Jehofa Lógo.” Gbogbo wa ni a ń dojúkọ àdánwò. (2 Korinti 6:​3-⁠5) Arákùnrin Weaver sọ̀rọ̀ àkíyèsí pé: “Nígbà tí a bá wà lábẹ́ ìkìmọ́lẹ̀, ó rọrùn púpọ̀ láti gbáralé araawa.” Bí ó ti wù kí ó rí, ó rán àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà létí pé: “Ohunkóhun yòówù tí ẹ bá níláti dojúkọ níti àdánwò tí ó wọ́pọ̀ fún gbogbo ènìyàn, Jehofa lọ́kàn-ìfẹ́ nínú rẹ̀. Òun kì yóò yọ̀ọ̀da láé pé kí a dán yín wò rékọjá ohun tí ẹ lè faradà.”​—⁠1 Korinti 10:⁠13.

“Ẹ Máa Fìgbà Gbogbo Ṣìkẹ́ Iṣẹ́-Àyànfúnni Yín” ni àkòrí ọ̀rọ̀-àsọyé tí ó tẹ̀lé e, tí Lyman Swingle ti ẹgbẹ́ olùṣàkóso sọ̀rọ̀ lé lórí. Àwọn ọmọ Israeli kìí fìgbà gbogbo yan ibi tí wọn yóò gbé àti ohun tí wọn yóò ṣe. Ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ni a yan apákan ìpín ilẹ̀ fún, a sì yan àwọn iṣẹ́ pàtó fún àwọn ọmọ Lefi láti ṣe. Bákan náà, ọ̀pọ̀ àwọn tí ń bẹ nínú àkànṣe iṣẹ́-ìsìn alákòókò kíkún lónìí​—⁠àwọn bíi míṣọ́nnárì àti mẹ́ḿbà ìdílé Beteli⁠—​kìí pinnu ibi tí wọn yóò gbé àti iṣẹ́ tí wọn yóò ṣe fúnraawọn. Bí ẹnìkan bá ní ìmọ̀lára àìdánilójú nípa iṣẹ́-àyànfúnni rẹ̀ ń kọ́? Arákùnrin Swingle wí pé, “Bí ẹ bá fi tọkàntara wo Olórí Aṣojú ìgbàgbọ́ wa, Jesu, tí ẹ sì gbé àpẹẹrẹ rẹ̀ yẹ̀wò tímọ́tímọ́, kì yóò rẹ̀ yín.”​—⁠Heberu 12:​2, 3.

Tẹ̀lé e ni Leonard Pearson, ti Ìgbìmọ̀ Oko Watchtower sọ̀rọ̀ lórí kókó-ọ̀rọ̀ náà “Ẹ Tẹjúmọ́ Ọ̀kánkán Gan-⁠an.” Ó wí pé: “Ẹ lè ní kámẹ́rà tí ó dára jùlọ, àyíká tí ó lẹ́wà jùlọ láti ya fọ́tò, ipò àyíká dídára wẹ́kú, síbẹ̀ kí ẹ ya fọ́tò tí kò dára tó​—⁠bí kámẹ́rà yín kò bá wo ọ̀kánkán gan-⁠an.” Bí awò ìyàwòrán kan tí ó ní ojú fífẹ̀, ojú-ìwòye wa gbọ́dọ̀ kó iṣẹ́ ìwàásù tí a ń ṣe kárí-ayé pọ̀. A kò gbọ́dọ̀ gbàgbé àwòrán ńlá náà láé. Arákùnrin Pearson wí pé: “Àwọn wọnnì tí wọ́n ń wo araawọn kì yóò láyọ̀ nínú iṣẹ́-àyànfúnni wọn. Àwọn wọnnì tí wọ́n ń wo Jehofa àti iṣẹ́ tí ó ti fi lé wọn lọ́wọ́ láti ṣe yóò kẹ́sẹjárí.”

“Ohun Púpọ̀ Láti Ṣọpẹ́ Fún” ni àkòrí ọ̀rọ̀-àsọyé tí ó tẹ̀lé e tí John E. Barr, mẹ́ḿbà mìíràn ti Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso sọ̀rọ̀ lé lórí. Arákùnrin Barr fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ní ìṣílétí pé, “Ẹ máṣe sọ ìmọ̀lára ìkúnfún ọpẹ́ yín sí Jehofa nù láé. Òun ni ọ̀kan lára àwọn orísun títóbi jùlọ fún ìtẹ́lọ́rùn, láìka irú iṣẹ́-àyànfúnni tí o ní sí.” Ìṣarasíhùwà ìmọpẹ́ẹ́dá sún Dafidi láti kọ̀wé pé: “Okùn títa bọ́ sọ́dọ̀ mi ní ibi dáradára; lóòótọ́, èmi ní ogún rere.” (Orin Dafidi 16:⁠6) Arákùnrin Barr wí pé: “Ẹ ní irú ogún àfiṣúra bẹ́ẹ̀ nínú nínímọ̀lára pé ẹ súnmọ́ Jehofa nínú ìgbésí-ayé yín ojoojúmọ́. Jehofa kì yóò mú irú ipò-ìbátan yẹn kúrò lọ́dọ̀ yín níwọ̀n ìgbà tí ẹ bá ṣì ń wò ó gẹ́gẹ́ bí ohun kan tí ó ṣètẹ́wọ́gbà tí ẹ ń ṣọpẹ́ fún.”

Jack Redford tí ó jẹ́ olùkọ́ ní ilé-ẹ̀kọ́ Gileadi ni ó sọ̀rọ̀ tẹ̀lé e lórí ẹṣin-ọ̀rọ̀ náà “Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Lo Ahọ́n Rẹ?” Ẹ wo ìbàjẹ́ tí ọ̀rọ̀ àìnírònú lè ṣe! (Owe 18:21) Báwo ni a ṣe lè mú ahọ́n wá sábẹ́ ìdarí? Arákùnrin Redford dáhùn pé, “Ẹ gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ fún èrò-inú yín ní ìdálẹ́kọ̀ọ́, nítorí pé ohun tí ń bẹ nínú iyè-inú àti ọkàn-àyà ni ahọ́n ń gbé jáde.” (Matteu 12:​34-⁠37) Jesu fúnni ní àpẹẹrẹ títayọlọ́lá; ó lo ahọ́n rẹ̀ láti gbé orúkọ Jehofa ga. Arákùnrin Redford sọ fún kíláàsì náà pé, “Lónìí ìyàn gbígbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ Jehofa ń bẹ. Ẹ̀yin mọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn. Ẹ ní ‘ahọ́n àwọn ẹni tí a kọ́ lẹ́kọ̀ọ́,’ Nítorí náà ẹ jẹ́ kí èrò-inú àti ọkàn-àyà tí a yàsímímọ́ ní kíkún fún Jehofa máa darí ahọ́n yín.”​—⁠Isaiah 50:⁠4.

Ìjẹ́pàtàkì àdúrà ní a tẹnumọ́ nínú ọ̀rọ̀-àsọyé náà “Ìwọ Ha Ń Rìn Bí Ẹni Pé O Wà Níwájú Jehofa Bí?” Ulysses Glass, akọ̀wé ìforúkọsílẹ̀ fún ilé-ẹ̀kọ́ náà, ṣàlàyé pé: “Bí baba kan bá ṣiṣẹ́ kára láti ṣètìlẹ́yìn fún ìdílé rẹ̀ ṣùgbọ́n tí kò jẹ́ bá wọn sọ̀rọ̀ tí kò sì jẹ́ sọ àwọn ọ̀rọ̀ ìfẹ́ni, ìdílé rẹ̀ lè parí èrò sí pé ète ìsúnniṣe rẹ̀ jẹ́ ti iṣẹ́ kan tí kò gbádùnmọ́ni dípò kí ó jẹ́ ti ìfẹ́. Bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni ó rí fún wa. Ọwọ́ wa lè dí nínú iṣẹ́-ìsìn Ọlọrun. Ṣùgbọ́n bí a kò bá gbàdúrà, iṣẹ́ kan ni a wulẹ̀ ya araawa sí mímọ́ fún nígbà náà dípò tí ìbá fi jẹ́ fún Baba ọ̀run onífẹ̀ẹ́ kan.”

Theodore Jaracz, ti Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso, sọ̀rọ̀ lórí ẹṣin-ọ̀rọ̀ náà “Ìdí Tí Ogunlọ́gọ̀ Àwọn Ènìyàn fi Ń Darapọ̀ Mọ́ Àwọn Ènìyàn Ọlọrun.” Lọ́dọọdún ọgọ́rọ̀ọ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ènìyàn ni wọ́n ń rọ́ wá sínú ètò-àjọ Jehofa. (Sekariah 8:23) Kí ni ń fi àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa hàn gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn Ọlọrun? Èkínní, wọ́n gba gbogbo Bibeli gbọ́ gẹ́gẹ́ bí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. (2 Timoteu 3:16) Èkejì, wọ́n jẹ́ aláìdásí tọ̀tún tòsì níti ọ̀ràn ìṣèlú. (Johannu 17:16) Ẹ̀kẹta, wọ́n jẹ́rìí sí orúkọ Ọlọrun. (Johannu 17:26) Ẹ̀kẹrin, wọ́n fi ìfẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ hàn. (Johannu 13:35; 15:13) Pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí tí ó ṣeé gbáralé wọ̀nyí, a lè fi àìṣojo ‘polongo awọn ìtayọlọ́lá ẹni naa tí ó pè wá jáde kúrò ninu òkùnkùn bọ́ sínú ìmọ́lẹ̀ àgbàyanu rẹ̀ káàkiri.’​—⁠1 Peteru 2:⁠9, NW.

Lẹ́yìn àwọn ọ̀rọ̀-àsọyé tí ń runisókè wọ̀nyí, gbogbo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ 46 náà gba ìwé-ẹ̀rí. A yanṣẹ́ fún wọn ní ilẹ̀ 16 yíká ayé.

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ ti Ọ̀sán Ní Ọlọ́kan-⁠Ò-Jọ̀kan

Ní ọ̀sán Donald Krebs ti Ìgbìmọ̀ Beteli darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé-Ìṣọ́nà tí a kékúrú. Lẹ́yìn náà ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege náà ṣe ìgbékalẹ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ kan tí ó ní àkòrí náà “Ọgbọ́n Ń Kígbe Lóde.” (Owe 1:20) Wọ́n ṣe ìtúngbéjáde àwọn ìrírí tí ń mérè wá tí wọ́n ní nínú iṣẹ́ ìjẹ́rìí òpópónà àti ti àgbègbè ìpínlẹ̀ iṣẹ́-ajé. Nítòótọ́, Jehofa ń bùkún àwọn wọnnì tí wọ́n bá lo ìgboyà láti wàásù láìjẹ́-bí-àṣà. Akẹ́kọ̀ọ́yege kan wí pé, “Ó wù mí láti máa ronú pé a dàbí akọ́rọ́ lọ́wọ́ àwọn angeli olùkórè. Bí òye-iṣẹ́ wa bá ti mú tó, bẹ́ẹ̀ ni iṣẹ́ tí àwọn angeli náà yóò lò wá láti ṣe yóò ti pọ̀ tó.” (Fiwé Ìfihàn 14:⁠6.) Ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà tún ní ìgbékalẹ̀ àwòrán slide nínú tí ó mú àwọn àwùjọ náà rìnrìn-àjò ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ lọ sí Bolivia, Malta, àti Taiwan​—⁠mẹ́ta lára àwọn orílẹ̀-èdè tí a rán àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege láti kíláàsì yìí lọ.

Tẹ̀lé e, Wallace àti Jane Liverance​—⁠tí wọ́n ti jẹ́ míṣọ́nnárì fún ọdún 17​—⁠ni a fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò. Ní October 1993 a késí wọn lọ sí Oko Watchtower, níbi tí Arákùnrin Liverance ti ń ṣiṣẹ́sìn nísinsìnyí gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ Gileadi.

Ìgbékalẹ̀ onírìísí ìran mẹ́rin tí ó ní àkọlé náà “Bíbọlá fún Àwọn Ẹni Títóye ní Àwọn Ọdún Ìgbà Ogbó Wọn” tẹ̀lé e. Bí àwọn ènìyàn ti ń gòkè àgbà, ìbẹ̀rù dídi aláìwúlò àti ẹni tí a patì lè jẹ ìgbọ́kànlé ara-ẹni tí wọ́n ní run. (Orin Dafidi 71:⁠9) Ìgbékalẹ̀ wíwọnilọ́kàn yìí fihàn bí gbogbo ènìyàn nínú ìjọ ṣe lè ṣètìlẹ́yìn fún irúfẹ́ àwọn arúgbó tí wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́ bẹ́ẹ̀.

Lẹ́yìn orin àti àdúrà ìparí, gbogbo àwọn 6,220 tí wọ́n wà níkàlẹ̀ ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ Jersey City àti àwọn gbọ̀ngàn tí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀pọ̀ ń tàtaré ìsọfúnni sí ni ara tù. A fi àdúrà wa sin àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege náà lọ sí ibi iṣẹ́ àyànfúnni wọn titun. Ǹjẹ́ kí wọ́n lè máa báa nìṣó láti ní ìrírí ayọ̀ títóbi jù tí ń wá láti inú fífúnni.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 26]

Àwọn Àkójọ Ìsọfúnni Nípa Kíláàsì

Iye àwọn orílẹ̀-èdè tí a ṣojú fún: 9

Iye àwọn orílẹ̀-èdè tí a yàn wọ́n sí: 16

Iye àwọn akẹ́kọ̀ọ́: 46

Ìpíndọ́gba ọjọ́-orí: 33.85

Ìpíndọ́gba iye ọdún nínú òtítọ́: 16.6

Ìpíndọ́gba iye ọdún nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ alákòókò kíkún: 12.2

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 27]

Fífún Malta ní Àfiyèsí Àkànṣe

KRISTẸNDỌM dí òtítọ́ Bibeli lẹ́nu ní Malta fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Àwọn míṣọ́nnárì Gileadi tí a rán lọ síbẹ̀ gbẹ̀yìn, Frederick Smedley àti Peter Bridle, kékọ̀ọ́yege ní kíláàsì kẹjọ nígbà náà lọ́hùn-⁠ún ní ọdún 1947. Bí ó ti wù kí ó rí, a fàṣẹ ọba mú wọn a sì lé wọn jáde kúrò ní Malta láìpẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n débẹ̀. Ìwé 1948 Yearbook of Jehovah’s Witnesses ròyìn pé: “Àkókò tí àwọn míṣọ́nnárì méjèèjì wọ̀nyí ti lo ní kóòtù àti pẹ̀lú àwọn ìjòyè òṣìṣẹ́ ilẹ̀ náà ti pọ̀ tó èyí tí wọ́n lò fún ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ wọn, kìkì nítorí àtakò Ẹgbẹ́ Àwọn Àlùfáà Olùṣàkóso ti Roman Katoliki. Àwọn àlùfáà náà sọ pé àwọn Katoliki ni wọ́n ni Malta olúkúlùkù ènìyàn yòókù sì gbọ́dọ̀ jáde kúrò.” Nísinsìnyí, ní nǹkan bí ọdún 45 lẹ́yìn náà, àwọn míṣọ́nnárì mẹ́rin láti kíláàsì kẹrìndínlọ́gọ́rùn-⁠ún ti Gileadi ni a ti yàn sí Malta.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Kíláàsì Kẹrìdínlọ́gọ́rùn-⁠ún ti Watchtower Bible School of Gilead tí Ń Kẹ́kọ̀ọ́yege

Nínú àkọsílẹ̀ lẹ́sẹẹsẹ ní ìsàlẹ̀, àwọn ìlà ni a tò láti iwájú lọ sẹ́yìn, a sì to àwọn orúkọ lẹ́sẹẹsẹ láti òsì sí ọ̀tún ní ìlà kọ̀ọ̀kan.

(1) Ehlers, P.; Giese, M.; Sellman, S.; Zusperregui, J.; Rowe, S.; Jackson, K.; Scott, T. (2) Liehr, T.; Garcia, I.; Garcia, J.; Fernández, A.; Davidson, L.; Liidemann, P.; Gibson, L.; Juárez, C. (3) Fouts, C.; Pastrana, G.; Claeson, D.; Fernández, L.; Walls, M.; Dressen, M.; Pastrana, F.; Burks, J. (4) Burks, D.; Scott, S.; Jackson, M.; Mauray, H.; Juárez, L.; Zusperregui, A.; Brorsson, C.; Rowe, C. (5) Sellman, K.; Liidemann, P.; Davidson, C.; Mauray, S.; Walls, D.; Dressen, D.; Schaafsma, G.; Liehr, S. (6) Claeson, T.; Gibson, T.; Giese, C.; Ehlers, D.; Fouts, R.; Schaafsma, S.; Brorsson, L.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́