ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 4/15 ojú ìwé 16-21
  • Ìdí Tí Ìjọsìn Tòótọ́ Fi Ń Rí Ìbùkún Ọlọrun Gbà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìdí Tí Ìjọsìn Tòótọ́ Fi Ń Rí Ìbùkún Ọlọrun Gbà
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Èso Wo Ni Ìsìn Tòótọ́ Gbọ́dọ̀ Mú Jáde?
  • Ìsìn Ìfẹ́, Kì í Ṣe Ti Ìkórìíra
  • Ọlọrun Ń Bù Kún Ìwà àti Ẹ̀kọ́ Tí Ó Mọ́ Gaara
  • ‘Òtítọ́ Yoo Dá Yín Sílẹ̀ Lómìnira’
  • Orúkọ Tí Ó Yàtọ̀ Gédégbé
  • Ìjọsìn Tó Ní Ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Ṣíṣe Isin Mimọgaara fun Lilaaja
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ọ̀nà Tó Tọ́ Láti Jọ́sìn Ọlọ́run
    Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?
  • Gbogbo Ìsìn Ni Inú Ọlọ́run Ha Dùn Sí Bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 4/15 ojú ìwé 16-21

Ìdí Tí Ìjọsìn Tòótọ́ Fi Ń Rí Ìbùkún Ọlọrun Gbà

“Ẹ yin Jah, ẹ̀yin ènìyàn! Ìgbàlà ati ògo ati agbára jẹ́ ti Ọlọrun wa, nitori òótọ́ ati òdodo ni awọn ìdájọ́ rẹ̀.”—ÌṢÍPAYÁ 19:1, 2.

1. Báwo ni Babiloni Ńlá yóò ṣe wá sí òpin rẹ̀?

“BABILONI ŃLÁ” ti ṣubú ní ojú ìwòye Ọlọrun, ó sì dojú kọ ìparun yán-ányán-an nísinsìnyí. Àsọtẹ́lẹ̀ Bibeli tọ́ka sí i pé aṣẹ́wó onísìn kárí ayé yìí ni a óò parun láti ọwọ́ àwọn àlè rẹ̀ olóṣèlú láìpẹ́; òpin rẹ̀ yóò jẹ́ lójijì àti lọ́gán. Ìṣípayá Jesu sí Johannu ní àwọn ọ̀rọ̀ aláṣọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí nínú pé: “Áńgẹ́lì alókunlágbára kan sì gbé òkúta kan tí ó dàbí ọlọ ńlá sókè ó sì fi í sọ̀kò sínú òkun, ó wí pé: ‘Lọ́nà yii pẹlu ìgbésọnù yíyára ni a óò fi Babiloni ìlú-ńlá títóbi naa sọ̀kò sísàlẹ̀, a kì yoo sì tún rí i mọ́ láé.’”—Ìṣípayá 18:2, 21.

2. Báwo ni àwọn ìránṣẹ́ Jehofa yóò ṣe hùwà padà sí ìparun Babiloni?

2 Ìsọ̀rí àwùjọ kan nínú ayé Satani yóò dárò ìparun Babiloni Ńlá, ṣùgbọ́n dájúdájú, kì yóò jẹ́ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun, yálà lọ́run tàbí lórí ilẹ̀ ayé. Igbe ayọ̀ wọn sí Ọlọrun yóò jẹ́: “Ẹ yin Jah, ẹ̀yin ènìyàn! Ìgbàlà ati ògo ati agbára jẹ́ ti Ọlọrun wa, nitori òótọ́ ati òdodo ni awọn ìdájọ́ rẹ̀. Nitori pé ó ti mú ìdájọ́ ṣẹ ní kíkún sórí aṣẹ́wó ńlá naa tí ó fi àgbèrè rẹ̀ sọ ilẹ̀-ayé di ìbàjẹ́, ó sì ti gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ awọn ẹrú rẹ̀ lára rẹ̀.”—Ìṣípayá 18:9, 10; 19:1, 2.

Èso Wo Ni Ìsìn Tòótọ́ Gbọ́dọ̀ Mú Jáde?

3. Àwọn ìbéèrè wo ní ń fẹ́ ìdáhùn?

3 Níwọ̀n bí a óò ti fọ ilẹ̀ ayé mọ́ kúrò lọ́wọ́ ìsìn èké, irú ìjọsìn wo ni yóò ṣẹ́ kù? Lónìí, báwo ni a ṣe lè pinnu irú àwùjọ ìsìn tí yóò la ìparun ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé ti Satani já? Kí ni èso òdodo tí àwùjọ yìí yóò mú jáde? Ó kéré tán, ohun mẹ́wàá wà tí a fi lè dá ìjọsìn tòótọ́ Jehofa mọ̀ yàtọ̀.—Malaki 3:18; Matteu 13:43.

4. Kí ni ohun àbéèrèfún àkọ́kọ́ fún ìjọsìn tòótọ́, báwo sì ni Jesu ṣe fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ ní ti èyí?

4 Lákọ̀ọ́kọ́ náà, àwọn Kristian tòótọ́ gbọ́dọ̀ gbé ipò ọba aláṣẹ tí Jesu kú fún lárugẹ—ipò ọba aláṣẹ Bàbá rẹ̀. Jesu kò jọ̀wọ́ ìwàláàyè rẹ̀ fún ìlépa ìṣèlú, ẹ̀yà, ẹ̀yà ìran, tàbí ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà kankan. Ó fi Ìjọba Bàbá rẹ̀ ṣáájú gbogbo góńgó ìṣèlú Júù tàbí ìyípadà tegbòtigaga. Ó fi àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fèsì sí agbára ayé tí Satani fi lọ̀ ọ́: “Kúrò lọ́dọ̀ mi, Satani! Nitori a kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Jehofa Ọlọrun rẹ ni iwọ gbọ́dọ̀ jọ́sìn, oun nìkanṣoṣo sì ni iwọ gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́-ìsìn mímọ́-ọlọ́wọ̀ fún.’” Ó mọ̀ láti inú Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu pé Jehofa ni Ọba Aláṣẹ tòótọ́ lórí ilẹ̀ ayé gbogbo. Láìfọ̀rọ̀ bọpobọyọ̀, àwùjọ ìsìn wo ní ń ṣètìlẹyìn fún àkóso Jehofa dípò àwọn ètò ìṣèlú ayé yìí?—Matteu 4:10; Orin Dafidi 83:18.

5. (a) Ojú wo ni àwọn olùjọsìn tòótọ́ ní láti fi wo orúkọ Ọlọrun? (b) Kí ni ó fi hàn pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa bọlá fún orúkọ náà?

5 Ohun àbéèrèfún kejì ni pé ìjọsìn tòótọ́ gbọ́dọ̀ gbé orúkọ Ọlọrun ga, kí ó sì sọ ọ́ di mímọ́. Olódùmarè fi orúkọ rẹ̀, Jehofa (tí àwọn ìtumọ̀ Bibeli kan pè ní Yahweh) hàn, fún àwọn ènìyàn rẹ̀ Israeli, a sì lò ó ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìgbà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu. Ṣáájú ìgbà náà pàápàá, Adamu, Efa, àti àwọn mìíràn mọ orúkọ náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò bọ̀wọ̀ fún un ní gbogbo ìgbà. (Genesisi 4:1; 9:26; 22:14; Eksodu 6:2) Bí àwọn atúmọ̀ èdè ní Kirisẹ́ńdọ̀mù àti àwọn Júù tilẹ̀ yọ orúkọ àtọ̀runwá náà kúrò nínú Bibeli wọn, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fún orúkọ náà ní ipò àti ọ̀wọ̀ tí ó yẹ ẹ́ nínú Bibeli New World Translation of the Holy Scriptures. Wọ́n bọlá fún orúkọ náà, àní gẹ́gẹ́ bí àwọn Kristian ní ìjímìjí ti ṣe. Jakọbu jẹ́rìí sí i pé: “Simeoni ti ṣèròyìn ní kínníkínní bí Ọlọrun ti yí àfiyèsí rẹ̀ sí awọn orílẹ̀-èdè fún ìgbà àkọ́kọ́ lati mú awọn ènìyàn kan fún orúkọ rẹ̀ jáde lati inú wọn. Ọ̀rọ̀ awọn Wòlíì sì fohùnṣọ̀kan pẹlu èyí, . . . ‘kí awọn wọnnì tí ó ṣẹ́kù lára awọn ènìyàn naa lè fi taratara wá Jehofa, papọ̀ pẹlu awọn ènìyàn gbogbo awọn orílẹ̀-èdè, awọn ènìyàn tí a fi orúkọ mi pè, ni Jehofa wí, ẹni tí ń ṣe nǹkan wọnyi.’”—Ìṣe 15:14-17; Amosi 9:11, 12.

6. (a) Kí ni ohun àbéèrèfún kẹta fún ìjọsìn tòótọ́? (b) Báwo ni Jesu àti Danieli ṣe tẹnu mọ́ ìṣàkóso Ìjọba? (Luku 17:20, 21)

6 Ohun àbéèrèfún kẹta fún ìjọsìn tòótọ́ ni pé ó ní láti gbé Ìjọba Ọlọrun ga gẹ́gẹ́ bí ojútùú kan ṣoṣo tí ó ní ọlá àṣẹ, tí ó sì lè yanjú àwọn ìṣòro àkóso aráyé. Ní kedere, Jesu kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti gbàdúrà pé kí Ìjọba náà dé, fún ìṣàkóso Ọlọrun láti gba àkóso ilẹ̀ ayé. A mí sí Danieli láti sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn ọjọ́ ìkẹyìn pé: “Ọlọrun ọrun yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀, èyí tí a kì yóò lè parun títí láé . . . yóò sì fọ́ túútúú, yóò sì pa gbogbo ìjọba [ti ayé, ti ìṣèlú] wọ̀nyí run, ṣùgbọ́n òun óò dúró títí láéláé.” Àwọn wo ni wọ́n ti fi hàn nípa ìwà wọn ní ọ̀rúndún ogún yìí, pé wọ́n ń ṣètìlẹyìn fún Ìjọba náà láìyẹsẹ̀—ṣé àwọn ìsìn Babiloni Ńlá ni tàbí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa?—Danieli 2:44; Matteu 6:10; 24:14.

7. Ojú wo ni àwọn olùjọsìn tòótọ́ fi ń wo Bibeli?

7 Ohun àbéèrèfún kẹrin láti lè rí ìtẹ́wọ́gbà Ọlọrun ni pé, àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọrun ní láti gbé Bibeli lárugẹ gẹ́gẹ́ bí Ọ̀rọ̀ onímìísí Ọlọrun. Nítorí náà, wọn kò ní di ẹran ìjẹ fún àwọn aṣelámèyítọ́ Bibeli, tí ń gbìyànjú láti rẹ Bibeli sílẹ̀ sí ipò iṣẹ́ ọwọ́ ẹ̀dá ènìyàn lásán pẹ̀lú gbogbo ìkùdíẹ̀káàtó tí èyí yóò yọrí sí. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa gbà gbọ́ pé Bibeli ni Ọ̀rọ̀ onímìísí Ọlọrun, àní gẹ́gẹ́ bí Paulu ti kọ̀wé sí Timoteu pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọrun mí sí ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́nisọ́nà, fún mímú awọn nǹkan tọ́, fún ìbániwí ninu òdodo, kí ènìyàn Ọlọrun lè pegedé ní kíkún, tí a mú gbaradì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo.”a Nítorí náà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa mú Bibeli gẹ́gẹ́ bí amọ̀nà wọn, ìwé tí ó wà fún ìgbésí ayé wọn ojoojúmọ́, àti orísun ìrètí wọn fún ọjọ́ ọ̀la.—2 Timoteu 3:16, 17.

Ìsìn Ìfẹ́, Kì í Ṣe Ti Ìkórìíra

8. Kí ni ohun àbéèrèfún karùn-ún fún ìjọsìn tòótọ́?

8 Báwo ni Jesu ṣe ya àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tòótọ́ sọ́tọ̀? Ìdáhùn rẹ̀ mú wa dórí kókó pàtàkì karùn-ún tí a fi ń dá ìjọsìn tòótọ́ mọ̀ yàtọ̀. Jesu wí pé: “Emi ń fún yín ní àṣẹ titun kan, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nìkínní kejì; gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti nífẹ̀ẹ́ yín, pé kí ẹ̀yin pẹlu nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nìkínní kejì. Nipa èyí ni gbogbo ènìyàn yoo fi mọ̀ pé ọmọ-ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” (Johannu 13:34, 35) Báwo ni Jesu ṣe fi ìfẹ́ yìí hàn? Nípa fífi ìwàláàyè rẹ̀ lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìràpadà. (Matteu 20:28; Johannu 3:16) Èé ṣe tí ojúlówó ìfẹ́ fi jẹ́ ànímọ́ pàtàkì fún àwọn Kristian tòótọ́? Johannu ṣàlàyé pé: “Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹ jẹ́ kí a máa bá a lọ ní nínífẹ̀ẹ́ ara wa lẹ́nìkínní kejì, nitori pé ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni ìfẹ́ ti wá . . . Ẹni tí kò bá nífẹ̀ẹ́ kò tí ì mọ Ọlọrun, nitori Ọlọrun jẹ́ ìfẹ́.”—1 Johannu 4:7, 8.

9. Àwọn wo ni wọ́n fi ìfẹ́ tòótọ́ hàn, báwo sì ni?

9 Ní àkókò wa, àwọn wo ni wọ́n fi irú ìfẹ́ yìí hàn, àní lójú ìkórìíra ẹ̀yà ìran, orílẹ̀-èdè, tàbí ìran? Àwọn wo ni wọ́n ti yege àdánwò ńlá náà, àní dójú ikú, kí ìfẹ́ wọn baà lè lékè? A ha lè sọ pé àwọn àlùfáà Kátólíìkì àti àwọn obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé tí wọ́n jẹ́wọ́ pé àwọn jẹ̀bi pípa ẹ̀yà run ní ìpakúpa, èyí tí ó wáyé ní Rwanda ní 1994 ni bí? Ṣe Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti Serbia tàbí àwọn Kátólíìkì Croatia tí wọ́n ti lọ́wọ́ nínú “pípa ẹ̀yà kan run” àti àwọn ìwà míràn tí kò tọ́ sí Kristian nínú ogun abẹ́lé ní Balkan ni bí? Àbí àwùjọ àlùfáà Kátólíìkì tàbí ti àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì tí wọ́n bu ẹ̀tù sí iná ẹ̀tanú àti ìkórìíra ní Àríwá Ireland ní àwọn ẹ̀wádún díẹ̀ tí ó ti kọjá ni bí? Dájúdájú, a kò lè fi ẹ̀sùn kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa pé wọ́n lọ́wọ́ nínú irú ìforígbárí bẹ́ẹ̀. Wọ́n jìyà ní àwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n àti àwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́, àní títí dé ojú ikú, kàkà kí wọ́n da ìfẹ́ Kristian wọn.—Johannu 15:17.

10. Èé ṣe tí àwọn Kristian tòótọ́ fi dúró láìdásí tọ̀túntòsì?

10 Ohun àbéèrèfún kẹfà fún ìjọsìn tí Ọlọrun tẹ́wọ́ gbà ni àìdásítọ̀túntòsì nípa àlámọ̀rí ìṣèlú ayé yìí. Èé ṣe tí àwọn Kristian kò fi gbọ́dọ̀ dá sí tọ̀túntòsì nínú ìṣèlú? Paulu, Jakọbu, àti Johannu fún wa ní àwọn ìdí tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ fún ìdúró yẹn. Aposteli Paulu kọ̀wé pé Satani ni “ọlọrun ètò-ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan yii,” tí ń lo gbogbo ọ̀nà tí ó bá lè gbà láti fọ́ èrò inú àwọn aláìgbàgbọ́, títí kan ìṣèlú tí ń fa ìpín yẹ́lẹyẹ̀lẹ. Jakọbu ọmọ ẹ̀yìn náà sọ pé “ìṣọ̀rẹ́ pẹlu ayé jẹ́ ìṣọ̀tá pẹlu Ọlọrun,” aposteli Johannu sì sọ pé “gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú naa.” Nítorí náà, Kristian tòótọ́ kò lè fi ìfọkànsìn rẹ̀ sí Ọlọrun báni dọ́rẹ̀ẹ́ nípa lílọ́wọ́ nínú ìṣèlú àti agbára ayé Satani tí ó ti díbàjẹ́.—2 Korinti 4:4; Jakọbu 4:4; 1 Johannu 5:19.

11. (a) Ojú wo ni àwọn Kristian fi ń wo ogun? (b) Ìdí tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu wo ni ó wà fún ìdúró yìí? (2 Korinti 10:3-5)

11 Lójú ìwòye àwọn ohun àbéèrèfún méjì tí ó ṣáájú yìí, ìkeje ṣe kedere, pé àwọn Kristian olùjọsìn tòótọ́ kò ní láti kópa nínú ogun. Níwọ̀n bí ìsìn tòótọ́ ti jẹ́ ẹgbẹ́ àwọn ará kárí ayé tí a gbé karí ìfẹ́, nígbà náà kò sí ohun tí ó lè pín “gbogbo ẹgbẹ́ awọn arákùnrin . . . ninu ayé” níyà tàbí dojú wọn dé. Jesu kọ́ wa ní ìfẹ́, kì í ṣe ìkórìíra; ó kọ́ wa ní àlàáfíà, kì í ṣe ogun. (1 Peteru 5:9; Matteu 26:51, 52) “Ẹni burúkú” kan náà, Satani, tí ó sún Kaini láti pa Abeli ń bá a nìṣó láti máa gbin ìkórìíra sáàárín aráyé àti láti ru ìforígbárí àti ìtàjẹ̀sílẹ̀ sókè nítorí ìpinyà ìṣèlú, ti ìsìn, àti ti ẹ̀yà ìran. Láìka ohun tí yóò ná wọn sí, àwọn Kristian tòótọ́ ‘kò kọ́ ogun mọ́.’ Lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, wọn ti ‘fi idà wọn rọ ọ̀bẹ plau, wọn sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ dòjé.’ Wọ́n ń mú èso àlàáfíà ti ẹ̀mí Ọlọrun jáde.—1 Johannu 3:10-12; Isaiah 2:2-4; Galatia 5:22, 23.

Ọlọrun Ń Bù Kún Ìwà àti Ẹ̀kọ́ Tí Ó Mọ́ Gaara

12. (a) Kí ni ohun àbéèrèfún kẹjọ, ṣùgbọ́n ìpinyà ní ti ìsìn wo ni o lè tọ́ka sí? (b) Báwo ni Paulu ṣe tẹnu mọ́ ohun àbéèrèfún kẹjọ?

12 Ìṣọ̀kan Kristian ni ohun àbéèrèfún kẹjọ fún ìjọsìn tòótọ́. Ṣùgbọ́n, ìpín yẹ́lẹyẹ̀lẹ àwọn ìsìn Kirisẹ́ńdọ̀mù kò tí ì ṣe ìrànlọ́wọ́ kankan nínú ọ̀ràn yìí. Ọ̀pọ̀ lára àwọn ẹ̀yà ìsìn tí wọ́n sọ pé ó ṣe pàtàkì jù lọ, ni wọ́n ti tú ká yẹ́lẹyẹ̀lẹ sí onírúurú ẹ̀ka, ìyọrísí rẹ̀ sì ni ìdàrúdàpọ̀. Fún àpẹẹrẹ, wo ìsìn Baptist ní United States, tí a pín sí Baptist Àríwá (Àwọn Ṣọ́ọ̀ṣì American Baptist ní United States ti America) àti Baptist Gúúsù (Southern Baptist Convention), àti pẹ̀lú sí ọ̀pọ̀ àwùjọ Baptist míràn tí ó ti jẹ́ ìyọrísí ìyapa. (Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ World Christian Encyclopedia, ojú ìwé 714) Ọ̀pọ̀ ìpinyà ti wáyé nítorí pé ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ tàbí ìṣàkóso ṣọ́ọ̀ṣì yàtọ̀ síra (fún àpẹẹrẹ, Presbyterian, Episcopalian, Congregational). Ìpinyà Kirisẹ́ńdọ̀mù jọra pẹ̀lú ti àwọn ìsìn tí kì í ṣe ti Kirisẹ́ńdọ̀mù—yálà ìsìn Buddha, Islam, tàbí Hindu. Ìmọ̀ràn wo ni aposteli Paulu fún àwọn Kristian ìjímìjí? “Wàyí o mo gbà yín níyànjú, ẹ̀yin ará, nípasẹ̀ orúkọ Oluwa wa Jesu Kristi pé kí gbogbo yín máa sọ̀rọ̀ ní ìfohùnṣọ̀kan, ati pé kí ìpínyà máṣe sí láàárín yín, ṣugbọn kí a lè so yín pọ̀ ṣọ̀kan rẹ́gírẹ́gí ninu èrò-inú kan naa ati ninu ìlà ìrònú kan naa.”—1 Korinti 1:10; 2 Korinti 13:11.

13, 14. (a) Kí ni ‘jíjẹ́ mímọ́’ túmọ̀ sí? (b) Báwo ni a ṣe ń mú ìjọsìn tòótọ́ wà ní mímọ́ tónítóní?

13 Kí ni ohun àbéèrèfún kẹsàn-án fún ìsìn tí Ọlọrun tẹ́wọ́ gbà? Ìlànà Bibeli kan ni a sọ nínú Lefitiku 11:45 pé: “Kí ẹ̀yin kí ó jẹ́ mímọ́, nítorí pé mímọ́ ni Èmi.” Aposteli Peteru tún ohun àbéèrèfún yìí sọ nígbà tí ó kọ̀wé pé: “Ní ìbámu pẹlu Ẹni Mímọ́ tí ó pè yín, kí ẹ̀yin fúnra yín pẹlu di mímọ́ ninu gbogbo ìwà yín.”—1 Peteru 1:15.

14 Kí ni jíjẹ́ mímọ́ yìí dọ́gbọ́n túmọ̀ sí? Pé àwọn olùjọsìn Jehofa ní láti jẹ́ mímọ́ nípa tẹ̀mí àti ti ìwà híhù. (2 Peteru 3:14) Kò sí àyè fún àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ àmọ̀ọ́mọ̀dá, tí kò ronú pìwà dà, àwọn tí wọ́n ń fojú ẹ̀gàn wo ẹbọ ìràpadà Kristi nípa ìwà wọn. (Heberu 6:4-6) Jehofa ń béèrè pé kí ìjọ Kristian wà ní mímọ́ tónítóní. Báwo ni a ṣe ń ṣàṣeparí ìyẹn? Ní apá kan, nípa títẹ̀ lé ọ̀nà ìdájọ́ ìyọlẹ́gbẹ́ àwọn tí wọ́n kó èérí bá ìjọ.—1 Korinti 5:9-13.

15, 16. Àwọn ìyípadà wo ni ọ̀pọ̀ Kristian ṣe nínú ìgbésí ayé wọn?

15 Ṣáájú mímọ òtítọ́ Kristian, ọ̀pọ̀ ń gbé ìgbésí ayé onígbọ̀jẹ̀gẹ́, aláfẹ́, àti onímọtara-ẹni-nìkan. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ nípa Kristi yí wọn padà, wọ́n sì ti rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ wọn gbà. Paulu fi tìtaratìtara sọ èyí nígbà tí ó kọ̀wé pé: “Kínla! Ẹ̀yin kò ha mọ̀ pé awọn aláìṣòdodo ènìyàn kì yoo jogún ìjọba Ọlọrun? Kí a máṣe ṣì yín lọ́nà. Kì í ṣe awọn àgbèrè, tabi awọn abọ̀rìṣà, tabi awọn panṣágà, tabi awọn ọkùnrin tí a pamọ́ fún awọn ète tí ó lòdì sí ti ẹ̀dá, tabi awọn ọkùnrin tí ń bá ọkùnrin dàpọ̀, tabi awọn olè, tabi awọn oníwọra ènìyàn, tabi awọn ọ̀mùtípara, tabi awọn olùkẹ́gàn, tabi awọn alọ́nilọ́wọ́gbà ni yoo jogún ìjọba Ọlọrun. Síbẹ̀ ohun tí awọn kan lára yín sì ti jẹ́ rí nìyẹn. Ṣugbọn a ti wẹ̀ yín mọ́.”—1 Korinti 6:9-11.

16 Ẹ̀rí wà pé Jehofa ń tẹ́wọ́ gba àwọn tí wọ́n bá ronú pìwà dà àwọn ìṣe wọn tí kò bá ìwé mímọ́ mu, tí wọ́n yí pada, tí wọ́n sì di ọmọlẹ́yìn tòótọ́ fún Kristi àti àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀. Wọ́n nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò wọn ní tòótọ́ bí ara wọn, wọ́n sì ń fi hàn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà, irú bíi títẹra mọ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí ń pèsè ìhìn iṣẹ́ ìyè fún gbogbo àwọn tí wọn yóò gbọ́.—2 Timoteu 4:5.

‘Òtítọ́ Yoo Dá Yín Sílẹ̀ Lómìnira’

17. Kí ni ohun àbéèrèfún kẹwàá fún ìjọsìn tòótọ́? Fúnni ní àwọn àpẹẹrẹ.

17 Ohun àbéèrèfún kẹwàá wà tí Jehofa ní fún àwọn wọnnì tí ń jọ́sìn rẹ̀ ní ẹ̀mí àti òtítọ́—ẹ̀kọ́ mímọ́ gaara. (Johannu 4:23, 24) Jesu sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ óò sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yoo sì dá yín sílẹ̀ lómìnira.” (Johannu 8:32) Òtítọ́ Bibeli ń dá wa sílẹ̀ lómìnira kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ tí ń tàbùkù sí Ọlọrun, irú bí àìleèkú ọkàn, ọ̀run àpáàdì, àti pọ́gátórì. (Oniwasu 9:5, 6, 10; Esekieli 18:4, 20) Ó ń dá wa sílẹ̀ lómìnira kúrò lọ́wọ́ ohun ìjìnlẹ̀ Babiloni ti “Mẹ́talọ́kan Mímọ́ Jù Lọ” ti Kirisẹ́ńdọ̀mù. (Deuteronomi 4:35; 6:4; 1 Korinti 15:27, 28) Ìgbọràn sí òtítọ́ Bibeli ń yọrí sí àwọn ènìyàn onífẹ̀ẹ́, ẹlẹ́mìí ìbìkítà, onínú rere, àti aláàánú. Ìsìn Kristian tòótọ́ kò fìgbà kankan ṣe ìtìlẹ́yìn fún àwọn aforóyaró, aláìráragba-nǹkan-sí tí ń ṣèwádìí àdámọ̀, irú bíi Tomás de Torquemada, tàbí àwọn oníkòórìíra adógunsílẹ̀, irú bíi ti àwọn tí ń gbé Ogun Ìsìn póòpù lárugẹ. Síbẹ̀, Babiloni Ńlá ti mú irú èso yìí jáde jálẹ̀ ìtàn, ó kéré tán, bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà Nimrodu títí di ìsinsìnyí.—Genesisi 10:8, 9.

Orúkọ Tí Ó Yàtọ̀ Gédégbé

18. (a) Àwọn wo ni wọ́n dé ojú ìwọ̀n àwọn ohun àbéèrèfún mẹ́wẹ̀ẹ̀wá fún ìjọsìn tòótọ́, báwo sì ni? (b) Kí ni a gbọ́dọ̀ ṣe lẹ́nì kọ̀ọ̀kan láti jogún ìbùkún tí ó wà ní iwájú wa?

18 Àwọn wo lónìí ni wọ́n ń mú àwọn ohun àbéèrèfún mẹ́wẹ̀ẹ̀wá yìí ní ti ìjọsìn tòótọ́ ṣẹ? Àwọn wo ni àwọn mìíràn mọ fún ìpàwàtítọ́mọ́ àti ẹ̀mí àlàáfíà wọ́n? Káàkiri àgbáyé, a mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa pé wọn “kì í ṣe apákan ayé.” (Johannu 15:19; 17:14, 16; 18:36) A dá àwọn ènìyàn Jehofa lọ́lá láti jẹ́ orúkọ mọ́ ọn àti láti jẹ́ Ẹlẹ́rìí rẹ̀, àní gẹ́gẹ́ bí Jesu Kristi ti jẹ́ ẹlẹ́rìí olùṣòtítọ́ fún Bàbá rẹ̀. A ń jẹ́ orúkọ mímọ́ náà, a sì mọ ẹrù iṣẹ́ wa láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ìyẹ́n dúró fún. Àti, gẹ́gẹ́ bí àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀, ẹ wo àǹfààní ológo tí ó wà ní iwájú wa! Ìyẹn ni ti jíjẹ́ apá kan ìdílé aráyé onígbọràn, tí ó wà ní ìṣọ̀kan, tí ń jọ́sìn Ọba Aláṣẹ Àgbáyé nínú paradise kan tí a mú pada bọ̀ sípò níhìn-ín lórí ilẹ̀ ayé. Láti lè gba irú ìbùkún bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ kí a máa bá a nìṣó láti jẹ́ kí a mọ̀ wá mọ ìjọsìn tòótọ́ náà àti láti máa fi inú dídùn jẹ́ orúkọ náà Ẹlẹ́rìí Jehofa “nitori òótọ́ ati òdodo ni awọn ìdájọ́ rẹ̀”!—Ìṣípayá 19:2; Isaiah 43:10-12; Esekieli 3:11.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn ìtumọ̀ Bibeli fúnra wọn kọ́ ni Ọlọrun mí sí. Ọ̀nà tí a gbà kọ àwọn ìtumọ̀, lè fi bí a ti lóye èdè ìpìlẹ̀ tí a fi kọ Bibeli sílẹ̀ tó hàn.

Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?

◻ Ojú wo ni àwọn ìránṣẹ́ Jehofa fi ń wo ìparun Babiloni Ńlá?

◻ Kí ni àwọn ohun àbéèrèfún pàtàkì fún ìjọsìn tòótọ́?

◻ Báwo ni òtítọ́ ṣe dá ọ sílẹ̀ lómìnira?

◻ Ọlá àkànṣe wo ni a ní gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jehofa?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń wàásù, wọ́n sì ń kọ́ni ní ìhìn rere Ìjọba Ọlọrun

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Àwọn Kristian tòótọ́ ti máa ń fìgbà gbogbo wà láìdásí tọ̀túntòsì nínú ìṣèlú àti ogun ayé

[Credit Line]

Ọkọ̀ òfuurufú: Pẹ̀lù ìyọ̀ọ̀da onínúure láti ọwọ́ Ministry of Defense, London

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́