Kíláàsì Kọkànlélọ́gọ́rùn-ún Ti Gilead Jẹ́ Onítara Fún Iṣẹ́ Àtàtà
ẸLẸ́DÀÁ wa, Jèhófà Ọlọ́run, jẹ́ onítara fún iṣẹ́ àtàtà, bẹ́ẹ̀ náà sì ni Ọmọkùnrin rẹ̀, Jésù Kristi. Gẹ́gẹ́ bí àwòfiṣàpẹẹrẹ wa, Jésù fi ìtara hàn nípa ṣíṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn fún un, èyí tí ó ní nínú fífi “ara rẹ̀ fúnni nítorí wa kí òun baà lè . . . wẹ̀ mọ́ fún ara rẹ̀ àwọn ènìyàn kan tí wọ́n jẹ́ tirẹ̀ lọ́nà àkànṣe pàtàkì, àwọn onítara fún iṣẹ́ àtàtà.” (Títù 2:14) Láìṣe àní àní, àwọn mẹ́ḿbà 48 ti kíláàsì kọkànlélọ́gọ́rùn-ún ti Watchtower Bible School of Gilead ti fi ìtara wọn hàn fún iṣẹ́ àtàtà. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege fún àwọn míṣọ́nnárì wọ̀nyí wáyé ní September 7, 1996, ní Ibùdó Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Watchtower ní Patterson, New York.
Ìmọ̀ràn Gbígbéṣẹ́ Láti Máa Bá Jíjẹ́ Onítara Nìṣó
Carey Barber, mẹ́ḿbà kan lára Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso, tí ó ti lé ní 70 ọdún nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ni alága ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege náà. Nínú ọ̀rọ̀ àkọ́sọ rẹ̀, Arákùnrin Barber pe àfiyèsí sí ìgbòkègbodò wíwàásù àti kíkọ́ni ti Jésù, ẹni tí í ṣe “ìmọ́lẹ̀ ayé.” (Jòhánù 8:12) Ó tọ́ka sí i pé, Jésù kò fi ipa iṣẹ́ ọlọ́lá yẹn mọ sọ́dọ̀ ara rẹ̀ ṣùgbọ́n ó rọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ wọn tàn bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́. (Mátíù 5:14-16) Àǹfààní iṣẹ́ ìsìn yìí túbọ̀ ń mú kí ìgbésí ayé Kristẹni ní ìtúmọ̀, ó sì gbé ẹrù iṣẹ́ bàǹtàbanta lé àwọn tí ‘ń rìn gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ ìmọ́lẹ̀’ léjìká.—Éfésù 5:8.
Lẹ́yìn ọ̀rọ̀ àkọ́sọ wọ̀nyẹn, a ké sí Don Adams ti Ọ́fíìsì Ìṣekòkárí ní orílé iṣẹ́ ní Brooklyn. Ó sọ̀rọ̀ lórí kókó ẹ̀kọ́ náà “A Ń Tẹ̀ Síwájú, A Kò Fà Sẹ́yìn.” Arákùnrin Adams pe àfiyèsí sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gilead fúnra rẹ̀ àti ète rẹ̀—láti mú kí ìwàásù ìhìn rere náà tàn kálẹ̀ dé àwọn ilẹ̀ òkèèrè. Ó sọ̀rọ̀ nípa ìtẹ̀síwájú ètò àjọ Ọlọ́run, èyí tí ó ti mú ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jáde jákèjádò ayé ní èdè tí ó lé ní 300. Ìwé náà, Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, tí a tẹ̀ jáde ní 1995, ti wà ní èdè 111, a sì ti ṣètò láti tẹ àwọn èdè míràn sí i. Lọ́wọ́lọ́wọ́, ó ti di irinṣẹ́ pàtàkì ní ríran àwọn ọmọ ẹ̀yìn tuntun ti Jésù lọ́wọ́ láti dórí ṣíṣe ìyàsímímọ́ àti batisí láàárín oṣù díẹ̀ péré. Nítorí náà, àwọn míṣọ́nnárì tuntun náà yóò ní àwọn àrànṣe lórí Bíbélì tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde lọ́wọ́ fún iṣẹ́ wọn.
Lẹ́yìn èyí, Lyman Swingle, mẹ́ḿbà kan lára Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso, sọ̀rọ̀ lórí kókó náà, “Ẹ Máa Bá A Nìṣó Ní Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìsìn Mímọ́ Ọlọ́wọ̀ Yín fún Jèhófà,” tí a gbé ka Ìṣípayá 7:15. Níwọ̀n bí Jèhófà fúnra rẹ̀ ti jẹ́ Ọlọ́run aláyọ̀, ṣíṣiṣẹ́ sìn ín nígbà gbogbo ni ohun tí ń mú ẹnì kan láyọ̀. (Tímótì Kìíní 1:11) Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí iṣẹ́ ìsìn aláyọ̀ yìí, ogunlọ́gọ̀ ńlá ti onírúurú ènìyàn láti orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ ayé ti wá láti jọ́sìn rẹ̀. Jálẹ̀ àwọn ọdún wọ̀nyí, àwọn tí Ilé Ẹ̀kọ́ Gilead ti dá lẹ́kọ̀ọ́ ti nípìn-ín nínú ríran ọ̀pọ̀ àwọn wọ̀nyí lọ́wọ́ láti dórí níní ìmọ̀ pípéye ti òtítọ́. Nítorí náà, a ní gbogbo ìdí láti gbà gbọ́ pé Jèhófà yóò máa bá a nìṣó láti bù kún àwọn tí a ń rán jáde nísinsìnyí láti kó ọ̀pọ̀ mẹ́ḿbà ogunlọ́gọ̀ tí ń pọ̀ sí i náà jọ.
“Ríronú Lórí Ìdùnnú Jèhófà” ni kókó ọ̀rọ̀ tí Daniel Sydlik tẹnu mọ́, ti òun pẹ̀lú jẹ́ mẹ́ḿbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso. Ó fi hàn pé gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run, títí kan àwọn míṣọ́nnárì tuntun, ní àǹfààní kíkọ́ àwọn ènìyàn ní ọ̀nà ìyè àìnípẹ̀kun àti bí wọ́n ṣe lè lo ìgbésí ayé lọ́nà dídára jù lọ nísinsìnyí. Arákùnrin Sydlik sọ pé: “Ìkọ́ni jẹ́ iṣẹ́ tí ń mú èrè wá fúnni. Ó ń hàn lójú àwọn tí ń kọ́ni àti lójú àwọn tí ń kẹ́kọ̀ọ́.” (Orin Dáfídì 16:8-11) Ó ṣàyọlò ọ̀rọ̀ míṣọ́nnárì kan ní Estonia tí ó wí pé, “A ní ìhìn iṣẹ́ títóbi lọ́lá jù lọ ní gbogbo ilẹ̀ ayé, ojú wa ni ó sì ń fi í hàn.” Ìrísí ojú wa lè ṣí ọ̀pọ̀ àǹfààní sílẹ̀, ó sì lè ru ọkàn-ìfẹ́ sókè. Àwọn ènìyàn ń fẹ́ láti mọ ohun tí ń mú kí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà jẹ́ aláyọ̀. Arákùnrin Sydlik gbani nímọ̀ràn pé: “Nítorí náà ẹ fún ìrísí ojú yín ní àfiyèsí. Àwọn ènìyàn ń gbádùn rírí àwọn tí wọ́n jẹ́ aláyọ̀.”
Ulysses Glass, tí ó ti nípìn-ín nínú kíkọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Gilead láti orí kíláàsì kejìlá ní 1949, bá àwùjọ náà sọ̀rọ̀ lórí kókó náà pé “Pẹ̀lú Sùúrù, Ẹ Pa Ọkàn Yín Mọ́.” Kí ni sùúrù? Ó túmọ̀ sí dídúró jẹ́ẹ́ dé ohun kan, fífi ìfaradà hàn lábẹ́ ipò tí ń ru ìbínú sókè tàbí lábẹ́ másùn máwo. Onísùúrù lè ṣàkóso ara rẹ̀; aláìnísùúrù máa ń kánjú, ó sì ń tètè bínú. Arákùnrin Glass sọ pé: “Ọ̀pọ̀ rò pé sùúrù ń fi àìlera tàbí àìlèṣèpinnu hàn,” ṣùgbọ́n “lójú Jèhófà okun àti ète ni ó fi hàn.” (Òwe 16:32) Èrè wo ni ó wà nínú níní sùúrù? Òwe àwọn ará China kan sọ pé: “Sùúrù lákòókò ìbínú ìṣẹ́jú kan yóò gbà ọ́ lọ́wọ́ làásìgbò ọgọ́rùn-ún ọjọ́.” Arákùnrin Glass sọ pé: “Sùúrù ń mú kí àkópọ̀ ìwà ẹnì kan dára sí i. Lọ́nà àpèjúwe, ó ń fi ọ̀dà adányinrin tí kì í ṣá kun àwọn ànímọ́ rere mìíràn. Ó ń mú kí ìgbàgbọ́ wuni, kí àlàáfíà wà pẹ́ títí, kí ìfẹ́ sì dúró gbọn-in.”
Mark Noumair, tí ó ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí míṣọ́nnárì ní Kenya fún ọdún 11, tí ó sì jẹ́ olùkọ́ ní Gilead báyìí, sọ pé: “Àǹfààní ni ó jẹ́ láti rí iṣẹ́ àyànfúnni gbà láti ọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run nípasẹ̀ ètò àjọ rẹ̀.” Bí ó ṣe ń bá ẹṣin ọ̀rọ̀ náà, “Láìjẹ́ Pé O Nígbàgbọ́, O Kò Ní Lè Pẹ́ Lẹ́nu Rẹ̀,” lọ, Arákùnrin Noumair pe àfiyèsí sí àpẹẹrẹ Ọba Áhásì ti Júdà. Aísáyà mú un dá ọba náà lójú pé Jèhófà yóò tì í lẹ́yìn nínú iṣẹ́ àyànfúnni rẹ̀, ṣùgbọ́n, síbẹ̀, Áhásì kùnà láti gbẹ́kẹ̀ lé E. (Aísáyà 7:2-9) Arákùnrin Noumair wá tọ́ka sí i pé, àwọn míṣọ́nnárì—ní tòótọ́, gbogbo wa—ní láti ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà láti baà lè wà fún ìgbà pípẹ́ nínú iṣẹ́ àyànfúnni wọn ti ìṣàkóso Ọlọ́run. Àwọn ìpèníjà pàtàkì ti iṣẹ́ àyànfúnni míṣọ́nnárì ń béèrè ìgbàgbọ́ lílágbára. Arákùnrin Noumair sọ pé: “Ẹ máa fi sọ́kàn nígbà gbogbo pé, kò sí ipò tí ó pé pérépéré nínú ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan yìí.”
Àwọn Ìrírí Tí Ń Fún Ìgbòkègbodò Onítara Níṣìírí
Nígbà tí ìdálẹ́kọ̀ọ́ wọn ní Gilead ń lọ lọ́wọ́, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà, ní òpin ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan, máa ń lo àkókò nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ fún gbogbo ènìyàn, èyí tí yóò tún jẹ́ ohun tí ó jẹ wọ́n lógún jù lọ nínú iṣẹ́ àyànfúnni míṣọ́nnárì wọn. Wallace Liverance, mẹ́ḿbà kan nínú àwọn olùkọ́ àti olùṣàbójútó Gilead, fọ̀rọ̀ wá akẹ́kọ̀ọ́ 15 lẹ́nu wò, àwọn tí wọ́n sọ ìrírí wọn. Lẹ́yìn náà, Leon Weaver ti Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn àti Lon Schilling ti Ìgbìmọ̀ Tí Ń Darí Ilé Bẹ́tẹ́lì fọ̀rọ̀ wá àwọn mẹ́ḿbà ìgbìmọ̀ ẹ̀ka láti Áfíríkà àti Latin America lẹ́nu wò, àwọn tí wọ́n sọ ìrírí láti pápá míṣọ́nnárì, tí wọ́n sì ní àwọn ìmọ̀ràn rere mélòó kan fún àwọn míṣọ́nnárì tí ń kẹ́kọ̀ọ́ yege. Ní Sierra Leone, a sọ pé, ìpín 90 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn tí wọ́n ṣe ìrìbọmi ní ọdún iṣẹ́ ìsìn 1995 ni ó jẹ́ pé àwọn míṣọ́nnárì ni wọ́n ràn wọ́n lọ́wọ́. Ẹ wo irú àkọsílẹ̀ àtàtà ní ti ìgbòkègbodò onítara tí èyíinì jẹ́!
Paríparí rẹ̀, Milton Henschel, ààrẹ Society, bá àwùjọ 2,734 sọ̀rọ̀ lórí kókó ẹ̀kọ́ náà, “Ètò Àjọ Jèhófà Tí A Lè Fojú Rí Jẹ́ Aláìlẹ́gbẹ́.” Kí ni ó mú kí ètò àjọ Ọlọ́run jẹ́ èyí tí kò láfiwé? Kì í ṣe títóbi rẹ̀ tàbí agbára rẹ̀, ṣùgbọ́n òkodoro òtítọ́ náà ni pé, ìlànà òdodo Ọlọ́run àti ìpinnu ìdájọ́ rẹ̀ ni ó ń darí rẹ̀. Ní ìgbàanì, àwọn ènìyàn Jèhófà, orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, ni a fi ẹrù iṣẹ́ ìkéde mímọ́ ọlọ́wọ̀ rẹ̀ lé lọ́wọ́, èyí tí ó mú kí orílẹ̀-èdè náà jẹ́ aláìlẹ́gbẹ́. (Róòmù 3:1, 2) Lónìí, ètò àjọ Jèhófà wà níṣọ̀kan bí ó ṣe ń ṣiṣẹ́ lábẹ́ ìdarí Jésù Kristi. (Mátíù 28:19, 20) Ó ń gbèèrú, ó ń gbilẹ̀ sí i. Ètò àjọ mìíràn ha wà lórí ilẹ̀ ayé tí Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso rẹ̀ ń yẹ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, Bíbélì, wò, kí wọ́n tó ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì bí? Ní àwọn ọ̀nà wọ̀nyí àti ní àwọn ọ̀nà míràn, ètò àjọ Jèhófà tí a lè fojú rí jẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ ní tòótọ́.
Ìtòlẹ́sẹẹsẹ lílárinrin kan wá sí ìparí pẹ̀lú fífúnni ní ìwé ẹ̀rí àti kíka lẹ́tà kíláàsì, tí ń fi ìmọrírì wọn hàn fún ìdálẹ́kọ̀ọ́ àkànṣe náà.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 22]
Ìsọfúnni Oníṣirò Nípa Kíláàsì
Iye àwọn orílẹ̀-èdè tí a ṣojú fún: 9
Iye àwọn orílẹ̀-èdè tí a yanni sí: 12
Iye àwọn akẹ́kọ̀ọ́: 48
Ìpíndọ́gba ọjọ́ orí: 31.7
Ìpíndọ́gba ọdún nínú òtítọ́: 13.8
Ìpíndọ́gba ọdún nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún: 9.8
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Kíláàsì Kọkànlélọ́gọ́rùn-ún ti Watchtower Bible School of Gilead Tí Ń Kẹ́kọ̀ọ́ Yege
Nínú orúkọ tí ó wà nísàlẹ̀ yìí, a fi nọ́ńbà sí ìlà láti iwájú lọ sí ẹ̀yìn, a sì kọ orúkọ láti ọwọ́ òsì sí ọwọ́ ọ̀tún ní ìlà kọ̀ọ̀kan.
(1) Swint, H.; Zezenski, A.; Highfield, L.; Mercado, S.; Diehl, A.; Chavez, V.; Smith, J.; Selenius, S. (2) Kurtz, D.; Clark, C.; Leisborn, J.; Mortensen, W.; Bromiley, A.; Toikka, L.; Marten, A.; Smith, D. (3) Zezenski, D.; Bjerregaard, L.; Garafalo, B.; Kaldal, L.; Chavez, E.; Fröding, S.; Khan, R.; Selenius, R. (4) Swint, B.; Bjerregaard, M.; Garafalo, P.; Holmblad, L.; Keyzer, M.; Fröding, T.; Palfreyman, J.; Palfreyman, D. (5) Minguez, L.; Leisborn, M.; Mercado, M.; Kurtz, M.; Diehl, H.; Toikka, J.; Clark, S.; Khan, A. (6) Minguez, F.; Marten, B.; Highfield, L.; Holmblad, B.; Bromiley, K.; Kaldal, H.; Mortensen, P.; Keyzer, R.