Àwọn Wo Ni Ojúlówó Ońṣẹ́ Àlàáfíà?
NÍ May 31, 1996, àwọn orísun ìròyìn kéde ohun tí ó dà bí ìhìn iṣẹ́ àlàáfíà. Ní ọjọ́ tí ó ṣáájú rẹ̀, a mú ìwé àṣẹ kan tí ìjọba fọwọ́ sí jáde tí ó mú un dáni lójú pé, Benjamin Netanyahu, ẹni tí ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ di olórí ìjọba ilẹ̀ Ísírẹ́lì, ti “fi gbogbo ara jìn fún rírí sí i pé ìpàdé àlàáfíà, àlàáfíà àti ààbò, láàárín orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àti gbogbo àwọn aládùúgbò rẹ̀, títí kan àwọn ilẹ̀ Palẹ́sìnì ń bá a nìṣó.”
Ìbò Netanyahu tí a pariwo rẹ̀ fáyé gbọ́ mú kí ọ̀pọ̀ ṣe kàyéfì bóyá àlàáfíà ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn lè ṣeé ṣe. Bí ó bá lè ṣeé ṣe, àwọn orílẹ̀-èdè míràn ha lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ bí, ní gbígbàgbé aáwọ̀ wọn?
Dájúdájú, ó rọrùn láti ṣèlérí àlàáfíà ju láti mú un wá lọ. Ní mímọ èyí, ọ̀pọ̀ ń ṣiyè méjì. Gẹ́gẹ́ bí Hemi Shalev, tí ó jẹ́ akọ̀ròyìn ṣe kọ ọ́, “ìdajì àwọn ènìyàn tí ó wà ní Ísírẹ́lì nísinsìnyí ń ní èrò pé ìràpadà ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé, àwọn yóò kù sí gbà gbọ́ pé, ó ti kó sínú ipò pípániláyà tí ó kún fún ìjìyà, tí kò sì ní ọ̀nà àbájáde.” Ní àkópọ̀, ó wí pé: “Àwọn kan ń yọ̀; àwọn mìíràn ń sunkún.”
Bí ọ̀ràn ènìyàn ti rí nìyẹn nínú ìsapá rẹ̀ láti mú àlàáfíà wá. Ṣíṣẹ́gun tí aṣáájú kan àti àwọn alátìlẹ́yìn rẹ̀ bá ṣẹ́gun ń túmọ̀ sí ìparun fún àwọn alátakò rẹ̀. Àìnítẹ̀ẹ́lọ́rùn ń yọrí sí rírídìí ẹ̀tàn, rírìdìí ẹ̀tàn sì sábà máa ń yọrí sí ọ̀tẹ̀. Yálà ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn, Latin America, Ìlà Oòrùn Europe, tàbí níbikíbi mìíràn—ìsapá aráyé láti mú àlàáfíà wá jẹ́ ẹ̀tàn pátápátá.
Ojúlówó Àlàáfíà Sún Mọ́lé!
Láàárín àkókò tí ọ̀ràn àlàáfíà ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn fi jẹ́ kókó ìròyìn fífanimọ́ra, a gbọ́ ìhìn iṣẹ́ àlàáfíà míràn. Èyí kì í ṣe ọ̀rọ̀ ìṣèlú tí a polongo fáyé gbọ́; bẹ́ẹ̀ sì ni kì í ṣe àdéhùn àlàáfíà láàárín àwọn orílẹ̀-èdè. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìhìn iṣẹ́ yìí polongo àlàáfíà tí yóò wà nípasẹ̀ Ìjọba Ọlọ́run nìkan ṣoṣo. Níbo ni a ti gbọ́ ìhìn iṣẹ́ yìí? Ní èyí tí ó lé ní 1,900 Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Ońṣẹ́ Àlàáfíà Ọlọ́run” tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe jákèjádò ayé ní 1996 sí 1997 ni.
Ní àwọn àpéjọpọ̀ wọ̀nyí, a mú un ṣe kedere pé, kò sí ìṣàkóso ẹ̀dà ènìyàn kankan tí ó lè mú àlàáfíà àti ààbò tòótọ́ wá. Èé ṣe? Nítorí pé, èyí yóò béèrè fún mímú òpin dé bá gbogbo nǹkan tí ń já àlàáfíà wa gbà lójoojúmọ́. Àlàáfíà tòótọ́ túmọ̀ sí jíjí láràárọ̀ láìsí fífi ogun àti ìwà ipá dáyà jáni. Ó túmọ̀ sí pé, kò sí ìwà ọ̀daràn mọ́, kò sì fífi àgádágodo sẹ́nu ilẹ̀kùn wa mọ́, kò sí bíbẹ̀rù àtirìn ní òpópónà mọ́, kò sí àwọn ìdílé tí wọ́n pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ mọ́. Ìjọba wo lórí ilẹ̀ ayé ni ó lè ṣàṣeparí gbogbo ìyẹn? Ní tòótọ́, ìjọba wo lórí ilẹ̀ ayé ni yóò tilẹ̀ lórí láyà láti ṣèlérí èyí?
Ṣùgbọ́n, Ìjọba Ọlọ́run lè mú àwọn nǹkan wọ̀nyí wá, yóò sì ṣe bẹ́ẹ̀. Bíbélì ṣèlérí pé: “Wò ó! Àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé, òun yóò sì máa bá wọn gbé, wọn yóò sì máa jẹ́ ènìyàn rẹ̀. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò sì wà pẹ̀lú wọn. Òun yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.” (Ìṣípayá 21:3, 4) Ẹ wo ìtura tí ìyẹn yóò mú wá fún aráyé tí ń jìyà!
Ìlérí Jèhófà Ọlọ́run kì í ṣe ìlérí asán. Bíbélì mú un dá wa lójú pé: “Ọlọ́run kì í ṣe ènìyàn tí yóò fi ṣèké; bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ọmọ ènìyàn tí yóò fi ronú pìwà dà: a máa wí, kí ó má sì ṣeé bí? tàbí a máa sọ̀rọ̀ kí ó má mú un ṣẹ?” (Númérì 23:19) Bẹ́ẹ̀ ni, ohun tí Ọlọ́run ti ṣèlérí yóò ṣẹ—fún ìbùkún gbogbo àwọn tí wọ́n mú ìdúró wọn síhà ọ̀dọ̀ rẹ̀.
Àwọn Ońṣẹ́ Àlàáfíà Ọlọ́run
A mọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bí ẹni mowó nítorí fífi ìtara wàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run. Lọ́dọọdún, wọ́n máa ń para pọ̀ lo ohun tí ó lé ní bílíọ̀nù kan wákàtí ní ṣíṣàjọpín ìhìn iṣẹ́ Bíbélì tí ń múni lọ́kàn yọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Èyí jẹ́ ní mímú àwọn ọ̀rọ̀ Jésù ṣẹ pé: “A óò sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.” (Mátíù 24:14) Ní tòótọ́, “ìhìn rere” ni ìhìn iṣẹ́ tí Àwọn Ẹlẹ́rìí ń mú wá jẹ́, nítorí pé ó ń pòkìkí Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀run gẹ́gẹ́ bí ìrètí kan ṣoṣo fún aráyé. Ẹ sì wo irú ìrètí tí ó dájú fún ọjọ́ ọ̀la tí èyí jẹ́!
Àní nísinsìnyí pàápàá, Ìjọba Ọlọ́run ń mú kí ojúlówó ìdè àlàáfíà àti ìfẹ́ ará wà láàárín àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀. Jésù wí pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” (Jòhánù 13:35) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń sakun láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú olórí ohun yìí tí a ń béèrè lọ́wọ́ ìsìn Kristẹni tòótọ́. Ní ìyọrísí rẹ̀, tiwọn jẹ́ àgbàyanu ẹgbẹ́ àwọn ará tí ń mú kí àwọn Júù àti àwọn Arab, àwọn ará Croatia àti àwọn Serbia, àwọn Hutu àti àwọn Tutsi, wà ní ìṣọ̀kan. Àlàáfíà yí tí ọ̀pọ̀ jù lọ aráyé lè fi lálàá lásán wà níkàáwọ́ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé.
Ìṣírí láti máa bá a nìṣó ní fífi àwọn ìlànà Bíbélì sílò àti láti máa bá a nìṣó ní wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ni a tẹnu mọ́ nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Ońṣẹ́ Àlàáfíà Ọlọ́run.” A rọ̀ ọ́ láti ka ìròyìn tí ó tẹ̀ lé e yìí nípa àpéjọpọ̀ ọlọ́jọ́ mẹ́ta amúnilóríyá, tí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ti ń gbádùn.