Ríran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Láti Mọ Àwọn Ohun Tí Ọlọ́run Ń Béèrè
“Àìgbọ́dọ̀máṣe wà lórí mi. Ní ti gidi, ègbé ni fún mi bí èmi kò bá polongo ìhìn rere!”—KỌ́RÍŃTÌ KÍNÍ 9:16.
1, 2. (a) Iṣẹ́ alápá méjì wo ni Jèhófà ń béèrè pé kí a nípìn-ín nínú rẹ̀? (b) Kí ni àwọn aláìlábòsí ọkàn gbọ́dọ̀ mọ̀ kí wọ́n baà lè di ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run?
JÈHÓFÀ ní ìhìn rere fún aráyé. Ó ní Ìjọba kan, ó sì fẹ́ kí gbogbo ènìyàn níbi gbogbo gbọ́ nípa rẹ̀! Gbàrà tí a bá ti mọ̀ nípa ìhìn rere yìí, Ọlọ́run ń béèrè pé kí a ṣàjọpín rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Iṣẹ́ alápá méjì ni èyí jẹ́. Lákọ̀ọ́kọ́, a gbọ́dọ̀ pòkìkí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Nínú àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ nípa “ìparí ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan,” Jésù wí pé: “A óò sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.”—Mátíù 24:3, 14.
2 Apá kejì tí iṣẹ́ yìí ní kan kíkọ́ àwọn tí wọ́n dáhùn pa dà lọ́nà rere sí ìpòkìkí Ìjọba náà lẹ́kọ̀ọ́. Lẹ́yìn àjíǹde rẹ, Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ àwùjọ ńlá pé: “Nítorí náà ẹ lọ kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọkùnrin àti ti ẹ̀mí mímọ́, ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́. Sì wò ó! mo wà pẹ̀lú yín ní gbogbo àwọn ọjọ́ títí dé ìparí ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan.” (Mátíù 28:19, 20) ‘Ohun tí Kristi ti pa láṣẹ’ kò pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ rẹ̀; ó kọ́ àwọn ẹlòmíràn láti pa àwọn àṣẹ tàbí ohun tí Ọlọ́run ń béèrè mọ́. (Jòhánù 14:23, 24; 15:10) Nípa báyìí, kíkọ́ àwọn ẹlòmíràn láti ‘máa pa ohun tí Kristi ti pa láṣẹ mọ́’ ní ríràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ àwọn ohun tí Ọlọ́run ń béèrè nínú. Àwọn aláìlábòsí ọkàn gbọ́dọ̀ kúnjú ìwọ̀n àwọn ohun tí Ọlọ́run ń béèrè kí wọ́n baà lè di ọmọ abẹ́ Ìjọba rẹ̀.
3. Kí ni Ìjọba Ọlọ́run, kí sì ni yóò ṣàṣeparí tí ó mú kí ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà jẹ́ ìhìn rere tó bẹ́ẹ̀?
3 Kí ni Ìjọba Ọlọ́run? Kí sì ni yóò ṣe tí ó mú kí ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà jẹ́ ìhìn rere tó bẹ́ẹ̀? Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ìjọba ti ọ̀run. Ó ṣeyebíye gidigidi ní ọkàn Jèhófà, nítorí pé nípasẹ̀ rẹ̀ ni òun yóò sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́, ní sísọ ọ́ di mímọ́ kúrò lọ́wọ́ gbogbo ẹ̀gàn. Ìjọba náà ni ohun èlò tí Jèhófà yóò lò láti mú kí ìfẹ́ inú rẹ̀ di ṣíṣe lórí ilẹ̀ ayé bíi ti ọ̀run. Ìdí nìyẹn tí Jésù fi kọ́ wa láti gbàdúrà fún Ìjọba Ọlọ́run láti dé, tí ó sì rọ̀ wá láti fi í sí ipò kíní nínú ìgbésí ayé wa. (Mátíù 6:9, 10, 33) Ìwọ ha rí ìdí tí Jèhófà fi mú un ní ọ̀kúnkúndùn tó bẹ́ẹ̀ pé kí a kọ́ àwọn ẹlòmíràn nípa Ìjọba rẹ̀?
Ìpèníjà Ni Ó Jẹ́ Ṣùgbọ́n Kì í Ṣe Ẹrù Ìnira
4. Báwo ni a ṣe lè ṣàkàwé rẹ̀ pé ojúṣe wa láti wàásù ìhìn rere kì í ṣe ẹrù ìnira?
4 Ó ha jẹ́ ẹrù ìnira láti wàásù ìhìn rere yìí bí? Bẹ́ẹ̀ kọ́ rárá! Láti ṣàkàwé: Ojúṣe bàbá ni láti pèsè nípa ti ara fún ìdílé rẹ̀. Kíkùnà láti ṣe bẹ́ẹ̀ jẹ́ ohun kan náà bíi kíkọ ìgbàgbọ́ Kristẹni. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Dájúdájú bí ẹni kan kò bá pèsè fún àwọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ tirẹ̀, àti ní pàtàkì fún àwọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ mẹ́ńbà agbo ilé rẹ̀, òun ti sẹ́ níní ìgbàgbọ́ ó sì burú ju ẹni tí kò ní ìgbàgbọ́.” (Tímótì Kíní 5:8) Ṣùgbọ́n, ojúṣe yẹn ha jẹ́ ẹrù ìnira fún ọkùnrin Kristẹni bí? Kò rí bẹ́ẹ̀ bí ó bá nífẹ̀ẹ́ ìdílé rẹ̀, nítorí ìyẹn ń mú kí ó fẹ́ láti pèsè fún wọn.
5. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ wíwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn jẹ́ ojúṣe, èé ṣe tí ó fi yẹ kí inú wa dùn láti nípìn-ín nínú rẹ̀?
5 Bákan náà, iṣẹ́ wíwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn jẹ́ ojúṣe, ohun kan tí a ń béèrè, tí ìwàláàyè wa pàápàá sinmi lé. Pọ́ọ̀lù sọ ọ́ lọ́nà yí pé: “Àìgbọ́dọ̀máṣe wà lórí mi. Ní ti gidi, ègbé ni fún mi bí èmi kò bá polongo ìhìn rere!” (Kọ́ríńtì Kíní 9:16; fi wé Ìsíkẹ́ẹ̀lì 33:7-9.) Ṣùgbọ́n, ìfẹ́ ni ó ń sún wa láti wàásù, kì í ṣe nítorí pé ó jẹ́ iṣẹ́ kan tí a gbọ́dọ̀ ṣe. Ní pàtàkì jù lọ, a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n a tún nífẹ̀ẹ́ àwọn aládùúgbò wa, a sì mọ bí ó ti ṣe pàtàkì tó pé kí wọ́n gbọ́ ìhìn rere. (Mátíù 22:37-39) Ó ń fún wọn ní ìrètí ọjọ́ ọ̀la. Láìpẹ́, Ìjọba Ọlọ́run yóò ṣàtúnṣe àìṣèdájọ́ òdodo, yóò mú gbogbo ìnilára kúrò, yóò sì mú àlàáfíà àti ìṣọ̀kan pa dà sípò—gbogbo rẹ̀ yóò jẹ́ ìbùkún àìnípẹ̀kun fún àwọn tí wọ́n bá jọ̀wọ́ ara wọn fún ìṣàkóso òdodo rẹ̀. Inú wa kò ha dùn, a kò ha sì yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ láti ṣàjọpín irú ìhìn rere bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn bí?—Orin Dáfídì 110:3.
6. Èé ṣe tí iṣẹ́ wíwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn fi gbé ìpèníjà gidi dìde?
6 Ní ọwọ́ kan náà, iṣẹ́ wíwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn yí ń gbé ìpèníjà gidi dìde. Àwọn ènìyàn yàtọ̀ síra. Gbogbo ènìyàn kọ́ ni ó ní ọkàn ìfẹ́ kan náà tàbí agbára kan náà. Àwọn kan kàwé gan-an, nígbà tí àwọn mìíràn kò sì fi bẹ́ẹ̀ kàwé. Ìwé kíkà—tí ó fìgbà kan rí jẹ́ ohun ìgbádùn tí a yàn láàyò—ní a sábà máa ń wò bí iṣẹ́ takuntakun nísinsìnyí. Ìmọ̀ọ́kà-máfẹ̀ẹ́kà, tí a túmọ̀ sí “ànímọ́ tàbí ipò jíjẹ́ ẹni tí ó lè kàwé, ṣùgbọ́n tí kò ní ọkàn ìfẹ́ nínú ṣíṣe bẹ́ẹ̀,” jẹ́ ìṣòro tí ń pọ̀ sí i, àní ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n fọwọ́ sọ̀yà pé ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn mọ̀ ọ́n kọ mọ̀ ọ́n kà. Nígbà náà, báwo ni a ṣe lè ran àwọn ènìyàn tí wọ́n ní onírúurú ipò àtilẹ̀wá àti onírúurú ọkàn ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ láti mọ ohun tí Ọlọ́run ń béèrè?—Fi wé Kọ́ríńtì Kíní 9:20-23.
A Mú Wa Gbára Dì Lọ́nà Yíyẹ Láti Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́
7. Báwo ni “olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú” ṣe mú wa gbára dì láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti mọ àwọn ohun tí Ọlọ́run ń béèrè?
7 Ó máa ń túbọ̀ rọrùn láti ṣe iṣẹ́ takuntakun kan bí o bá ní irin iṣẹ́ tàbí ohun èlò tí ó yẹ. Irin iṣẹ́ tí ó yẹ fún iṣẹ́ kan pàtó lónìí ni a lè yí pa dà lọ́la tàbí kí a tilẹ̀ pààrọ̀ rẹ̀ nítorí àìní tí ń yí pa dà. Bákan náà ni ó rí ní ti iṣẹ́ àṣẹ wa láti pòkìkí ìhìn iṣẹ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run. Láti àwọn ọdún wọ̀nyí wá, “olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú” ti pèsè irin iṣẹ́ tí ó bá a mu wẹ́kú fún wa, àwọn ìtẹ̀jáde tí a pète ní pàtàkì fún dídarí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ilé. (Mátíù 24:45) A tipa báyìí mú wa gbára dì láti ran àwọn ènìyàn “gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti . . . ahọ́n” lọ́wọ́ láti mọ àwọn ohun tí Ọlọ́run ń béèrè. (Ìṣípayá 7:9) Láti ìgbà dé ìgbà, a ń pèsè àwọn ohun èlò tuntun láti kúnjú àwọn àìní tí ń yí pa dà nínú pápá ayé. Ẹ jẹ́ kí a gbé àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò.
8. (a) Ipa wo ni ìwé náà, “Jẹki Ọlọrun Jẹ Olõtọ,” kó nínú mímú kí ìmọ̀ ẹ̀kọ́ Bíbélì tẹ̀ síwájú? (b) Kí ni ohun èlò fún iṣẹ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí a pèsè ní 1968, báwo sì ni a ṣe ṣeé lọ́nà àrà ọ̀tọ̀? (d) Báwo ni ìwé Otitọ ṣe ṣèrànwọ́ nínú iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn?
8 Láti 1946 sí 1968, ìwé náà, “Jẹki Ọlọrun Jẹ Olõtọ,” ni a lò gẹ́gẹ́ bí ohun èlò lílágbára fún ìmọ̀ ẹ̀kọ́ Bíbélì, a sì tẹ 19,246,710 ẹ̀dà jáde ní èdè 54. Fún ọ̀pọ̀ ọdún, ìwé náà, Otitọ ti Nsinni Lọ si Iye Aiyeraiye, tí a mú jáde ní 1968 ni a lò lọ́nà gbígbéṣẹ́ ní kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn olùfìfẹ́hàn. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, ó wọ́pọ̀ pé kí àwọn kan kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún láìṣe ìbatisí. Ṣùgbọ́n, ohun èlò yí ni a pète pé kí ó ní akẹ́kọ̀ọ́ náà nínú, ní fífún un níṣìírí láti fi ohun tí ó ń kọ́ sí ìlò. Kí ni ìyọrísí rẹ̀? Ìwé náà, Jehovah’s Witnesses—Proclaimers of God’s Kingdom, wí pé: “Fún ọdún iṣẹ́ ìsìn mẹ́ta náà tí ó bẹ̀rẹ̀ ní September 1, 1968, tí ó sì parí ní August 31, 1971, a batisí àròpọ̀ iye ènìyàn tí ó jẹ́ 434,906—tí ó ju ìlọ́po méjì iye tí a batisí nínú ọdún iṣẹ́ ìsìn mẹ́ta tí ó ṣáájú!” Láti ìgbà tí a ti mú un jáde, ìwé Otitọ ti ní ìpínkiri tí ó bùáyà—ó ju 107,000,000 ní èdè 117.
9. Kí ni apá pàtàkì tí ìwé Walaaye ní, ipa wo ni ó sì ní lórí òtú àwọn olùpòkìkí Ìjọba?
9 Ní 1982, ìwé Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye di ìwé pàtàkì tí a ń fi darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Irin iṣẹ́ yìí ní ohun tí ó ju 150 àwọn àkàwé aláwòrán, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní àkọlé àwòrán tí ó nítumọ̀, tí ó ṣàlàyé kókó ẹ̀kọ́ tí àwọn àwòrán náà ní ní tààràtà. Ìtẹ̀jáde Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti February 1983 wí pé: “Fun nkan bii 20 ọdún ni ‘Jẹ Ki Ọlọrun Jẹ Olootọ’ fi jẹ iwe wa pataki fun ikẹkọọ (lati 1946 titi de aarin awọn ọdun 1960) o ju 1,000,000 awọn olukede Ijọba naa titun ti wọn darapọ mọ iye wa. Lẹhin naa ni a tun fi 1,000,000 awọn akede kun un nigba ti Otitọ ti Nsinni Lọ Si Iye Ayeraye tun di iwe pataki fun ikọni lẹkọọ lẹhin ti a mu un jade ni 1968. Ni lilo iwe wa titun naa, Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye, a o ha ri ilọsoke iru kannaa ni iye awọn akede Ijọba naa bi? Dajudaju, bi eyiini ba jẹ ifẹ Jehofah!” Ó hàn gbangba pé ìfẹ́ Jèhófà ni, nítorí pé láti 1982 sí 1995, a fi iye tí ó ju 2,700,000 kún òtú àwọn olùpòkìkí Ìjọba!
10. Kí ni irin iṣẹ́ tuntun tí a pèsè ní 1995, èé sì ti ṣe tí ó fi yẹ kí ó mú kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ìtẹ̀síwájú tí ó yára kánkán dé ìwọ̀n àyè kan nípa tẹ̀mí?
10 Jésù wí pé: “Ìkórè pọ̀, ṣùgbọ́n ìwọ̀nba díẹ̀ ni àwọn òṣìṣẹ́.” (Mátíù 9:37) Ní tòótọ́, ìkórè náà pọ̀. Púpọ̀ sí i ṣì wà láti ṣe. Ní àwọn ilẹ̀ kan, àwọn ènìyàn ní láti dúró di ìgbà tí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yóò fi kàn wọ́n. Nítorí náà, kí ó baà lè ṣeé ṣe láti tan ìmọ̀ Ọlọ́run kálẹ̀ lọ́nà tí ó túbọ̀ yá sí i, ní 1995, “olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú” pèsè irin iṣẹ́ tuntun kan, ìwé olójú ewé 192 tí a pe àkọlé rẹ̀ ní Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Ohun èlò ṣíṣeyebíye yìí kò sọ̀rọ̀ lórí àwọn ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ èké. Ó gbé òtítọ́ Bíbélì kalẹ̀ ní ọ̀nà tí ń gbéni ró. A retí pé yóò mú kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ìtẹ̀síwájú tí ó yára kánkán dé ìwọ̀n àyè kan nípa tẹ̀mí. Ìwé Ìmọ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí í ní ipa lórí pápá ayé pẹ̀lú 45,500,000 ẹ̀dà tí a ti tẹ̀ ní èdè 125, tí a sì tún ti ń túmọ̀ sí àfikún èdè 21 lọ́wọ́lọ́wọ́.
11. Irin iṣẹ́ tí ó gbéṣẹ́ wo ni a pèsè láti ran àwọn wọnnì tí kò mọ̀ọ́kọmọ̀ọ́kà tàbí tí kò lè kàwé dáradára lọ́wọ́, báwo sì ní ó ṣe ṣe bẹbẹ nínú ètò ìkọ́ni wa kárí ayé?
11 Látìgbà dégbà, ‘ẹrú olùṣòtítọ́’ ti pèsè àwọn irin iṣẹ́ tí a pète fún àwùjọ kan pàtó, tàbí àwùjọ tí ó kéré níye. Fún àpẹẹrẹ, àwọn ènìyàn tí wọ́n nílò ìrànwọ́ àrà ọ̀tọ̀ nítorí ipò àtilẹ̀wá wọn ní ti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ tàbí ti ìsìn ńkọ́? Báwo ni a ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ àwọn ohun tí Ọlọ́run ń béèrè? Ní 1982, a rí ohun tí a nílò gan-an gbà—ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32 náà, Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae! Ìtẹ̀jáde aláwòrán mèremère rẹpẹtẹ yìí ti jẹ́ irin iṣẹ́ gbígbéṣẹ́ láti kọ́ àwọn tí kò mọ̀ọ́kọmọ̀ọ́kà tàbí tí kò lè kàwé dáradára. Ó ní ìgbékalẹ̀ tí ó rọrùn, tí ó sì lè tètè yéni nípa àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì nínú Ìwé Mímọ́. Láti ìgbà tí a ti mú un jáde, ìwé pẹlẹbẹ náà, Gbádùn Iwalaaye, ti ṣe bẹbẹ nínú ètò ìkọ́ni wa kárí ayé. A ti tẹ iye tí ó lé ní 99,860,000 ẹ̀dà ní èdè 227, tí ó mú kí ó jẹ́ ìtẹ̀jáde tí a tí ì túmọ̀ sí èdè tí ó pọ̀ jù lọ tí Watch Tower Society tí ì mú jáde títí di ìsinsìnyí!
12, 13. (a) Láti 1990, kí ni ọ̀nà tuntun tí ‘olùṣòtítọ́ ẹrú’ ti pèsè láti dé ọ̀dọ̀ àwọn àwùjọ olùgbọ́ tí wọ́n wà káàkiri? (b) Báwo ni a ṣe lè lo àwọn fídíò Society nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa? (d) Kí ni irin iṣẹ́ tuntun tí a pèsè ní lọ́ọ́lọ́ọ́ láti ṣèrànwọ́ nínú iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn tí a ń ṣe?
12 Ní àfikún sí àwọn ìtẹ̀jáde, bẹ̀rẹ̀ láti 1990, ‘olùṣòtítọ́ ẹrú’ ti pèsè àwọn ọ̀nà ìtọ́ni fún wa tí ó fúnni ni àwọn ọ̀nà tuntun láti gbà dé ọ̀dọ̀ àwùjọ olùgbọ́ tí wọ́n wà káàkiri—kásẹ́ẹ̀tì fídíò. Ní October ọdún yẹn, a mú fídíò oníṣẹ̀ẹ́jú 55 náà, Jehovah’s Witnesses—The Organization Behind the Name, jáde—fídíò àkọ́kọ́ tí Watch Tower Society yóò mú jáde. Ìgbékalẹ̀ ẹlẹ́wà, tí ó kún fún ìsọfúnni, tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó ní èdè tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 35, fi ètò àjọ àwọn olùfọkànsìn Jèhófà hàn tí wọ́n ń pa àṣẹ Jésù mọ́ láti pòkìkí ìhìn rere náà ní gbogbo ilẹ̀ ayé. A ṣe fídíò náà ní pàtàkì láti ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn tí a ń ṣe. Àwọn akéde Ìjọba kò fi àkókò ṣòfò láti lo irin iṣẹ́ tuntun yìí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá. Àwọn kan fi sínú àpò wọn, tí wọ́n ṣe tán láti fi í han àwọn ènìyàn tí wọ́n ní ọkàn-ìfẹ́ tàbí láti yá wọn. Kété lẹ́yìn tí a mú un jáde, alábòójútó arìnrìn-àjò kan kọ̀wé pé: “Fídíò ti di ọ̀nà kan ní ọ̀rúndún kọkànlélógún láti dé inú àti ọkàn àyà àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn, nítorí náà, ìrètí wa ni pé fídíò yí yóò wulẹ̀ jẹ́ àkọ́kọ́ nínú ọ̀pọ̀ fídíò tí Society yóò lò láti mú kí iṣẹ́ Ìjọba kárí ayé tẹ̀ síwájú.” Ní tòótọ́, a ti pèsè ọ̀pọ̀ fídíò sí i, títí kan ọ̀wọ́ alápá mẹ́ta náà, The Bible—A Book of Fact and Prophecy àti Jehovah’s Witnesses Stand Firm Against Nazi Assault. Bí àwọn fídíò Society bá wà ní èdè rẹ, ìwọ ha ti lò wọ́n nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá rẹ bí?a
13 Ní lọ́ọ́lọ́ọ́, a pèsè irin iṣẹ́ tuntun kan, ìwé pẹlẹbẹ náà, Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?, láti ràn wá lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn tí a ń ṣe. Èé ṣe tí a fi tẹ̀ ẹ́ jáde? Báwo ni a ṣe lè lò ó?
Ṣíṣàyẹ̀wò Irin Iṣẹ́ Tuntun
14, 15. Ta ni a ṣe ìwé pẹlẹbẹ náà, Béèrè, fún, kí ni ó sì ń bẹ nínú rẹ̀?
14 Ìtẹ̀jáde tuntun náà, Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?, ni a ṣe fún àwọn ènìyàn tí wọ́n gbà gbọ́ nínú Ọlọ́run, tí wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún Bíbélì. Àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò títí kan àwọn míṣọ́nnárì tí a kọ́ ní Gilead, tí wọ́n ní ìrírí fún ọ̀pọ̀ ọdún ní àwọn ilẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà ṣèrànwọ́ nínú ṣíṣètò ìwé pẹlẹbẹ yìí. Ó ní ẹ̀kún rẹ́rẹ́ kókó ẹ̀kọ́, ní kíkárí àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì nínú Bíbélì. Àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ tani jí, ó rọrùn, ó sì ṣe tààràtà. Lọ́wọ́ kan náà, ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò rọrùn jù. Kì í ṣe pé ó wulẹ̀ pèsè “wàrà” ṣùgbọ́n ó tún pèsè “oúnjẹ líle” láti inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, lọ́nà kan tí gbogbo ènìyàn yóò lè lóye.—Hébérù 5:12-14.
15 Ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, àwọn akéde Ìjọba ní onírúurú ilẹ̀ ti béèrè fún irú ìtẹ̀jáde bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́. Fún àpẹẹrẹ, ẹ̀ka Watch Tower Society ní Papua New Guinea kọ̀wé pé: “Àwọn ẹ̀kọ́ ìsìn tí ń forí gbárí ti mú kí ọkàn àwọn ènìyàn pòrúurùu. Wọ́n ń fẹ́ gbólóhùn òtítọ́ tí ó ṣe ṣàkó, tí àwọn ẹsẹ Bíbélì mélòó kan tí wọ́n lè yẹ̀ wò nínú Bíbélì tiwọn fúnra wọn tì lẹ́yìn. Wọ́n ń fẹ́ ìgbékalẹ̀ tí ó ṣe kedere, tí ó sì ṣe pàtó nípa ohun tí Ọlọ́run ń béèrè lọ́wọ́ àwọn Kristẹni tòótọ́, wọ́n sì fẹ́ mọ àwọn àṣà àti ìwà tí òun kò tẹ́wọ́ gbà.” Ìwé pẹlẹbẹ náà, Béèrè, ni ohun náà gan-an tí a nílò láti ran irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí Ọlọ́run ń béèrè.
16. (a) Ní pàtàkì, ta ni yóò jàǹfààní láti inú àwọn àlàyé rírọrùn tí ó wà nínú ìwé pẹlẹbẹ tuntun náà? (b) Báwo ni àwọn tí ń bẹ ní ìpínlẹ̀ rẹ ṣe lè jàǹfààní láti inú ìwé pẹlẹbẹ náà, Béèrè?
16 Báwo ni o ṣe lè lo ohun èlò tuntun yìí? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, o lè lò ó láti bá àwọn ènìyàn tí wọn kò lè kàwé dáradára tàbí tí wọ́n lè má ní ìtẹ̀sí láti kàwé ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́.b Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lè jàǹfààní láti inú àlàyé rírọrùn tí ó wà nínú ìwé pẹlẹbẹ náà. Lẹ́yìn ṣíṣàtúnyẹ̀wò ẹ̀dà ìwé pẹlẹbẹ yìí tí a kọ́kọ́ fi ránṣẹ́, àwọn ẹ̀ka Watch Tower kọ ohun tí ó tẹ̀ lé e yìí pé: “Ìwé pẹlẹbẹ náà yóò wúlò gidigidi ní apá ibi púpọ̀ ní orílẹ̀-èdè tí àwọn ènìyàn kò ti ní ìtẹ̀sí láti jókòó kàwé púpọ̀.” (Brazil) “Ọ̀pọ̀ àjèjì tí wọ́n ṣí wá ń bẹ, tí wọn kò lè ka èdè ìbílẹ̀ wọn, síbẹ̀ tí ó sì ṣòro díẹ̀ fún wọn láti ka èdè Faransé. A lè lo ìwé pẹlẹbẹ yìí gẹ́gẹ́ bí àrànṣe láti bá irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ṣèkẹ́kọ̀ọ́.” (Faransé) O ha lè ronú nípa àwọn ènìyàn tí ń bẹ ní ìpínlẹ̀ rẹ tí wọ́n lè jàǹfààní láti inú ìwé pẹlẹbẹ náà, Béèrè?
17. Lọ́nà wo ni ìwé pẹlẹbẹ náà yóò gbà wúlò ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, èé sì ti ṣe?
17 Lọ́nà kejì, ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, ìwé pẹlẹbẹ náà yóò wúlò fún bíbẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run láìka bí wọ́n ṣe kàwé tó sí. Àmọ́ ṣáá o, a gbọ́dọ̀ sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Ṣùgbọ́n nínú àwọn ọ̀ràn kan, ó lè rọrùn jù láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwé pẹlẹbẹ. Lẹ́yìn náà, ní àkókò tí ó bá a mu wẹ́kú, a gbọ́dọ̀ yí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà pa dà sínú ìwé Ìmọ̀, ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa tí ó ṣe pàtàkì, tí a sì fọwọ́ sí. Ní ti lílo ìwé pẹlẹbẹ náà, Béèrè, àwọn ẹ̀ka Watch Tower kọ̀wé pé: “Bíbẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kò rọrùn, ó sì dà bíi pé ṣíṣeéṣe láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ máa ń pọ̀ sí i nígbà tí àwọn akéde bá bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìwé pẹlẹbẹ.” (Germany) “Ìwé pẹlẹbẹ kan bí èyí yóò gbéṣẹ́ jù lọ ní bíbẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tuntun, èyí tí a lè máa bá nìṣó lẹ́yìn náà nínú ìwé Ìmọ̀.” (Ítálì) “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará Japan kàwé gan-an, ìmọ̀ tí ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn ní nípa Bíbélì àti àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ pàtàkì kò tó nǹkan. Ìwé pẹlẹbẹ náà yóò jẹ́ àtẹ̀gùn gbígbéṣẹ́ sínú ìwé Ìmọ̀.”—Japan.
18. Kí ni ó yẹ kí a rántí ní ti kíkúnjú ìwọ̀n àwọn ohun tí Ọlọ́run ń béèrè?
18 Àwọn ẹ̀ka Society káàkiri ayé béèrè fún ìwé pẹlẹbẹ yìí, a sì ti fọwọ́ sí títúmọ̀ rẹ̀ sí èdè 221. Ǹjẹ́ kí ìtẹ̀jáde tuntun yìí já sí ìrànwọ́ ṣíṣeyebíye ní ríràn wá lọ́wọ́ láti ṣètìlẹyìn fún àwọn ẹlòmíràn láti mọ ohun tí Jèhófà Ọlọ́run ń béèrè lọ́wọ́ wọn. Ní tiwa, ẹ jẹ́ kí a rántí pé kíkúnjú ìwọ̀n àwọn ohun tí Ọlọ́run ń béèrè, títí kan àṣẹ náà láti wàásù, kí a sì sọni di ọmọ ẹ̀yìn, ń fún wa ní àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ láti fi han Jèhófà bí a ṣe nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tó. Bẹ́ẹ̀ ni, ohun tí Ọlọ́run ń béèrè lọ́wọ́ wa kì í ṣe ẹrù ìnira. Ó jẹ́ ọ̀nà ìgbésí ayé tí ó dára jù lọ!—Orin Dáfídì 19:7-11.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìwé náà, Jehovah’s Witnesses—Proclaimers of God’s Kingdom, wí pé: “Lọ́nàkọnà, àwọn kásẹ́ẹ̀tì fídíò kò gbapò ìwé tí a ń tẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni kò gbapò ìjẹ́rìí. Àwọn ìtẹ̀jáde Society ń bá a nìṣó láti máa kó ipa pàtàkì nínú títan ìhìn rere náà kálẹ̀. Iṣẹ́ ilé dé ilé tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe ṣì jẹ́ apá iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn tí a gbé karí ìpìlẹ̀ lílágbára nínú Ìwé Mímọ́. Bí ó ti wù kí ó rí, kásẹ́ẹ̀tì fídíò wá ń ṣàléékún ìwọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí irin iṣẹ́ gbígbéṣẹ́ fún gbígbé ìgbàgbọ́ ró nínú àwọn ìlérí ṣíṣeyebíye ti Jèhófà, ó sì ń súnni láti mọrírì ohun tí òun ń mú kí ó ṣeé ṣe lórí ilẹ̀ ayé ní ọjọ́ wa.”
b Fún àlàyé lórí bí ó ṣe lè darí ìkẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwé pẹlẹbẹ náà, Béèrè, wo ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà “Irin Iṣẹ́ Tuntun Láti Ran Àwọn Ènìyàn Lọ́wọ́ Láti Mọ Àwọn Ohun Tí Ọlọ́run Ń Béèrè,” ní ojú ìwé 16 àti 17.
Ìwọ Ha Lè Ṣàlàyé Bí?
◻ Iṣẹ́ alápá méjì wo ni Jèhófà ń béèrè pé kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ nípìn-ín nínú rẹ̀?
◻ Èé ṣe tí ojúṣe wa láti wàásù àti láti sọni di ọmọ ẹ̀yìn kì í fi í ṣe ẹrù ìnira fún wa?
◻ Kí ni àwọn irin iṣẹ́ tí “olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú” ti pèsè fún wa nínú iṣẹ́ wíwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn tí a ń ṣe?
◻ Ta ni a ṣe ìwé pẹlẹbẹ náà, Béèrè, fún, báwo sì ni a óò ṣe lò ó nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Iṣẹ́ wíwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn tí a ń ṣe kì í ṣe ẹrù ìnira
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
“Jẹki Ọlọrun Jẹ Olõtọ” (1946, a ṣàtúnyẹ̀wò rẹ̀ ní 1952): 19,250,000 ní èdè 54
“Otitọ ti Nsinni Lọ si Iye Aiyeraiye” (1968): 107,000,000 ní èdè 117 (Ti èdè Faransé ni a fi hàn)
“Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye” (1982): 80,900,000 ní èdè 130 (Ti èdè Rọ́ṣíà ni a fi hàn)
“Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun” (1995): 45,500,000 ní èdè 125 (Ti èdè Germany ni a fi hàn)