‘Ó Lẹ́sẹ̀ Nílẹ̀, Ó Sì Wọni Lọ́kàn’
Ọ̀KAN lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ilẹ̀ Faransé sọ pé: “Bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀la lọ n óò máa lò ó nínú iṣẹ́ ìwàásù, nítorí àwọn àlàyé rẹ̀ lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, wọ́n sì wọni lọ́kàn ni ti gidi.” Ẹlẹ́rìí kan ní United States kọ̀wé pé: “Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni mo kà á, n kò lè dúró di ìgbà tí n óò bá lò ó nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá, níwọ̀n bí a ti máa ń pàdé ọ̀pọ̀ ènìyàn tí wọ́n ń dágunlá, tí wọn kò sì gbẹ́kẹ̀ lé Bíbélì.” Kí ni wọ́n ń ṣàpèjúwe? Ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32 tí a pè ní, Ìwé Kan Tí Ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn, tí Watch Tower Society mú jáde ní Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ìgbàgbọ́ Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” tí a ṣe ní ọdún 1997 sí 1998 ni.
A kọ ìwé yìí pẹ̀lú àwùjọ kan pàtó lọ́kàn—àwọn tí ó ṣeé ṣe kí wọ́n jẹ́ ọ̀mọ̀wé ṣùgbọ́n tí ohun tí wọ́n mọ̀ nípa Bíbélì kò tó nǹkan. Ọ̀pọ̀ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ní àwọn èrò kan pàtó nípa Bíbélì, bí wọn kò tilẹ̀ tí ì kà á rí. Ète ìwé pẹlẹbẹ yìí ni láti mú kí òǹkàwé náà gbà gbọ́ dájú pé, ó kéré tán, ó yẹ kí ó ṣàyẹ̀wò Bíbélì. Ìwé pẹlẹbẹ náà kò fipá mú òǹkàwé láti gbà pé Bíbélì jẹ́ ìwé tí Ọlọ́run mí sí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ kí àwọn kókó náà sọ̀rọ̀ fúnra wọn. Àwọn ọ̀rọ̀ tí a kọ kì í ṣe àwọn ọ̀rọ̀ kàbìtìkàbìtì ṣùgbọ́n ó ṣe kedere, ó sì ṣe tààrà.
Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀rọ̀ tí a ṣàyọlò wọn lókè yìí ti fi hàn, àwọn tí wọ́n wá sí àpéjọpọ̀ hára gàgà láti lo ìwé pẹlẹbẹ náà nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá wọn. Fún àpẹẹrẹ, ní ilẹ̀ Faransé, a ṣètò ìgbétásì ìjẹ́rìí àkànṣe kan láti wáyé ní ọjọ́ 23 àti 24 nínú oṣù August, nígbà tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọ̀dọ́ olùbẹ̀wò jákèjádò ayé yóò pé jọ ní Paris fún Ọjọ́ Àwọn Ọ̀dọ́ Lágbàáyé. Nǹkan bí 2,500 Ẹlẹ́rìí (tí ọ̀pọ̀ jù lọ wọ́n jẹ́ ọmọ ọdún 16 sí 30 ọdún) fi 18,000 ẹ̀dà ìwé pẹlẹbẹ náà sóde ní èdè Faransé, German, Gẹ̀ẹ́sì, Italian, Polish, àti Spanish.
Ní gbogbo ọ̀nà, ẹ jẹ́ kí a lo ìwé pẹlẹbẹ yìí, Ìwé Kan Tí Ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn, nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Ǹjẹ́ kí ìtẹ̀jáde yìí jẹ́ ohun ṣíṣeyebíye tí yóò mú un dá àwọn ènìyàn onírònú lójú pé ó yẹ kí wọ́n fúnra wọn ṣàyẹ̀wò Bíbélì.