ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 8/1 ojú ìwé 3-4
  • Ṣé Àìṣèdájọ́ Òdodo Kò Ṣeé Yẹ̀ Sílẹ̀ Ni?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Àìṣèdájọ́ Òdodo Kò Ṣeé Yẹ̀ Sílẹ̀ Ni?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Onírúurú Ọ̀nà Ìkà Ti Àìṣèdájọ́ Òdodo
  • Àìṣèdájọ́ Òdodo Ha Jẹ́ Nǹkan Bàbàrà Bí?
  • Ṣé Ìdájọ́ Òdodo Máa Wà?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Ohun Tó Yẹ Ká Ṣe Táwọn Èèyàn Bá Rẹ́ Wa Jẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
  • O Lè Fara Da Àìṣẹ̀tọ́!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 8/1 ojú ìwé 3-4

Ṣé Àìṣèdájọ́ Òdodo Kò Ṣeé Yẹ̀ Sílẹ̀ Ni?

“Láìfi ohun gbogbo tí ń ṣẹlẹ̀ pè, mo ṣì nígbàgbọ́ pé àwọn ènìyàn lọ́kàn rere. N kò wulẹ̀ lè gbé ìrètí mi ka ìpìlẹ̀ kan tí ó kún fún ìdàrúdàpọ̀, ìnira, àti ikú ni.”—Anne Frank.

ANNE FRANK, ọ̀dọ́mọbìnrin Júù kan, ọmọ ọdún 15, ló kọ àwọn ọ̀rọ̀ dídunni wọra wọnnì sínú ìwé àkọsílẹ̀ ojoojúmọ́ rẹ̀, nígbà tí ó kù díẹ̀ kí ó kú. Ó ti lé ní ọdún méjì tí ìdílé rẹ̀ ti wà nípamọ́, nínú yàrá abẹ́ òrùlé kan ní Amsterdam. A fọ́ ìrètí rẹ̀ fún ayé kan tí ó sàn jù yángá nígbà tí alamí kan lọ táṣìírí ibi tí wọ́n fara pa mọ́ sí fún ìjọba Nazi. Lọ́dún tí ó tẹ̀ lé e, ní 1945, ibà táífọ́ọ̀dù pa Anne sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Bergen-Belsen. Irú jàǹbá bẹ́ẹ̀ dé bá mílíọ̀nù mẹ́fà àwọn Júù mìíràn.

Ète bíburú jáì tí Hitler gbé kalẹ̀ láti pa àwùjọ ènìyàn kan run yán-ányán-án lè jẹ́ ọ̀ràn àìfìdájọ́ òdodo bá ẹ̀yà ìran kan lò lọ́nà tí ó tí ì burú jù lọ, ní ọ̀rúndún wa yìí, ṣùgbọ́n kì í ṣe ìyẹn nìkan ló ṣẹlẹ̀. Ní ọdún 1994, ó lé ní ìdajì mílíọ̀nù àwọn Tutsi tí a pa nípakúpa ní Rwanda, kìkì nítorí pé wọ́n jẹ́ ẹ̀yà “tí ó yàtọ̀.” Nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní sì rèé, nǹkan bí mílíọ̀nù kan àwọn ará Armenia ni ó kú nínú rògbòdìyàn bíbá ẹ̀yà ìran kan kanlẹ̀ pátápátá.

Onírúurú Ọ̀nà Ìkà Ti Àìṣèdájọ́ Òdodo

Kì í ṣe ìparun ẹ̀yà ni ọ̀nà kan ṣoṣo tí a kì í gbà ṣèdájọ́ òdodo. Àìṣèdájọ́ òdodo nínú ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà ń ti nǹkan bí ìdá kan nínú márùn-ún aráyé sínú ipò òṣì tí ń fojú ẹni gbolẹ̀ títí ayé. Síbẹ̀síbẹ̀, ẹgbẹ́ ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn ti Agbóguntòwò-Ẹrú Kárí Ayé ṣírò pé, èèyàn tí ó lé ní 200,000,000 ṣì wà lóko ẹrú. Ó ṣeé ṣe kí àwọn ẹrú tí ó wà lágbàáyé lónìí ju àwọn tí ó ti wà nígbàkígbà rí nínú ìtàn. Wọ́n lè má máa lù wọ́n ní gbàǹjo o, ṣùgbọ́n ipò iṣẹ́ wọn lọ́pọ̀ ìgbà burú ju ti ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ẹrú ìgbàanì.

Àìṣèdájọ́ òdodo nínú ọ̀ràn òfin ń fi ẹ̀tọ́ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn dù wọ́n. Ẹgbẹ́ Ajàfẹ́tọ̀ọ́ Ọmọnìyàn Lágbàáyé nínú ìròyìn rẹ̀ ti ọdún 1996 sọ pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ojoojúmọ́ ni a ń hùwà ìkà bíburú jáì sí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn níbì kan lágbàáyé. Àwọn òtòṣì àti àwọn tí kò rọ́wọ́ mú láwùjọ, ní pàtàkì, àwọn obìnrin, ọmọdé, àwọn àgbàlagbà àti àwọn olùwá-ibi-ìsádi, ní a sábà máa ń hùwà yìí sí.” Ìròyìn náà sọ pé: “Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, ètò ìṣọ̀kan orílẹ̀-èdè ti fẹ́ẹ́ forí ṣánpọ́n, kò sì sí ọlá àṣẹ òfin èyíkéyìí tí ó lè gba àwọn mẹ̀kúnnù lọ́wọ́ àwọn alágbára.”

Lọ́dún 1996, ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ó lé ní ọgọ́rùn-ún ni a fi sí àhámọ́, tí a sì dá lóró. Ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí pẹ̀lú, ẹgbẹẹgbàárùn-ún ènìyàn ti di àwátì, tí ó sì hàn gbangba pé àwọn aláàbòòlú tàbí ẹgbẹ́ àwọn apániláyà ni ó jí wọn gbé. Ọ̀pọ̀ nínú wọn ni a kúkú ti gbà pé wọ́n ti kú.

Lóòótọ́, lọ́nà tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀, ogun kì í jà lọ́nà tó bá ìdájọ́ òdodo mu, ṣùgbọ́n kàkà kéwé àgbọn dẹ̀, líle ló ń le sí i. Àwọn aráàlú, títí kan àwọn obìnrin àti ọmọdé ni àwọn ogun òde òní ń fojú sùn. Bẹ́ẹ̀ rèé, èyí kì í wulẹ̀ ṣe nítorí jíjù tí a ń ju bọ́ǹbù sí àwọn ìlú ńláńlá láìbìkítà. Nígbà tí ogun bá ń lọ lọ́wọ́, ó ti di àṣà láti máa fipá bá àwọn àgbà obìnrin àti àwọn sisí lò pọ̀, ọ̀pọ̀ ẹgbẹ́ ọlọ̀tẹ̀ sì ti fipá jí àwọn ọmọdé gbé láti lè kọ́ wọn ní bí a ṣeé pànìyàn. Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ lórí ìtẹ̀sí bẹ́ẹ̀, ìròyìn Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè “Ipa Tí Ogun Ń Ní Lórí Àwọn Ọmọdé” sọ pé: “Àwọn olùgbé ayé tí ń pọ̀ sí i ni a ti bá ìwà wọn jẹ́ pátápátá.”

Kò sí iyèméjì rárá pé bíba ìwà ẹni jẹ́ yìí ti yọrí sí ayé kan tí àìṣèdájọ́ òdodo ti gbilẹ̀—ì báà jẹ́ ní ti ẹ̀yà ìran, ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, ọ̀ràn òfin, tàbí ti ológun. Dájúdájú, èyí kì í ṣe ohun tuntun. Ní ohun tí ó lé ní ẹgbàá-lé-lẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún sẹ́yìn, wòlíì Hébérù kan dárò pé: “Òfin ti di ahẹrẹpẹ, kò ní láárí mọ́, a kò sì ṣèdájọ́ òdodo mọ́. Àwọn ẹni ibi ń kó àwọn olódodo nífà, a sì ń yí ìdájọ́ òdodo po.” (Hábákúkù 1:4, Today’s English Version) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àìṣèdájọ́ òdodo ti fìgbà gbogbo wọ́pọ̀, kò sí àní-àní pé ọ̀rúndún ogún yìí jẹ́ sànmánì kan tí àìṣèdájọ́ òdodo ga dé ìwọ̀n tuntun.

Àìṣèdájọ́ Òdodo Ha Jẹ́ Nǹkan Bàbàrà Bí?

Bí ìwọ alára bá nírìírí àìṣèdájọ́ òdodo, oó mọ̀ pé nǹkan bàbàrà ni. Nǹkan bàbàrà ni nítorí tí ó ń fi ẹ̀tọ́ láti jẹ́ aláyọ̀ du ọ̀pọ̀ jù lọ ìran ènìyàn. Ó tún jẹ́ nǹkan bàbàrà nítorí pé àìṣèdájọ́ òdodo sábà máa ń ru ìforígbárí afẹ̀jẹ̀wẹ̀ sókè, ẹ̀wẹ̀, ó sì ń mú kí àìṣèdájọ́ òdodo túbọ̀ máa gogò sí i.

Àlàáfíà àti ayọ̀ ní ìsopọ̀ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú ìdájọ́ òdodo, ṣùgbọ́n àìṣèdájọ́ òdodo máa ń mú kí ìrètí wọmi, ó sì ń ba ẹ̀mí-nǹkan-yóò-dára jẹ́. Gẹ́gẹ́ bí Anne Frank ṣe ṣàwárí lọ́nà tí ó báni nínú jẹ́, àwọn ènìyàn kò lè gbé ìrètí wọn ka ìpìlẹ̀ tí ó kún fún ìdàrúdàpọ̀, ìnira, àti ikú. Gẹ́gẹ́ bí tirẹ̀, gbogbo wa ni a ń yán hànhàn fún ohun kan tí ó sàn jù.

Ìfẹ́ yìí ti sún àwọn ènìyàn olóòótọ́ ọkàn láti gbìyànjú mú ìdájọ́ òdodo wá sáwùjọ dé ìwọ̀n kan. Nítorí ìyẹn, Ìpolongo Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Lágbàáyé tí Àpéjọ Gbogbogbòò ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ṣàmúlò ní ọdún 1948, sọ pé: “Gbogbo ènìyàn ni a bí lómìnira, tí wọ́n sì ní iyì àti ẹ̀tọ́ ọgbọọgba. A fi ìrònú àti ẹ̀rí ọkàn jíǹkí wọn, wọ́n sì gbọ́dọ̀ fi ẹ̀mí ará bá ara wọn lò.”

Àwọn ọ̀rọ̀ onílàákàyè nìwọ̀nyí jẹ́, ṣùgbọ́n ọ̀nà aráyé ṣì jìn gan-an sí góńgó tí wọ́n ṣìkẹ́ yẹn—àwùjọ onídàájọ́ òdodo níbi tí olúkúlùkù ti ń gbádùn ẹ̀tọ́ ọgbọọgba, tí olúkúlùkù sì ń fi ẹ̀mí ará bá ọmọnìkejì rẹ̀ lò. Gẹ́gẹ́ bí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ Ìpolongo àjọ UN ti sọ, bí ọwọ́ bá lè tẹ góńgó yìí, yóò jẹ́ “ìpìlẹ̀ fún òmìnira, ìdájọ́ òdodo, àti àlàáfíà nínú ayé.”

Àìṣèdájọ́ òdodo ha ti wọ àwùjọ ènìyàn lẹ́wù tó bẹ́ẹ̀ tí kò fi ní ṣeé mú kúrò bí? Tàbí a óò ha fi ìpìlẹ̀ lílágbára lélẹ̀ fún òmìnira, ìdájọ́ òdodo, àti àlàáfíà bí? Bí a óò bá ṣe bẹ́ẹ̀, ta wá ni yóò fi ìpìlẹ̀ ọ̀ún lélẹ̀, tí yóò sì wá rí i dájú pé gbogbo ènìyàn jàǹfààní nínú rẹ̀?

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]

UPI/Corbis-Bettmann

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́