ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w99 8/15 ojú ìwé 4-7
  • Gbádùn “Ìyè Tòótọ́”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Gbádùn “Ìyè Tòótọ́”
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Ìyè Tòótọ́” Nígbà Náà
  • “Ìyè Tòótọ́” Dájú Ṣáká—Gbá A Mú Gírígírí!
  • “Sawo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun”
    “Sawo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun”
  • Jèhófà Ń Mú Ìlérí Rẹ̀ Ṣẹ Fún Àwọn Olùṣòtítọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ní Ìgbẹ́kẹ̀lé Pé Jehofa Yóò Mú Ète Rẹ̀ Ṣẹ
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ìgbésí Ayé Nínú Ayé Tuntun Alálàáfíà Kan
    Ìgbésí Ayé Nínú Ayé Tuntun Alálàáfíà Kan
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
w99 8/15 ojú ìwé 4-7

Gbádùn “Ìyè Tòótọ́”

JÈHÓFÀ Ọlọ́run ti fún ènìyàn lágbára àtironú nípa ayérayé. (Oníwàásù 3:11) Èyí ló ń mú kí àwọn ènìyàn di ọ̀lẹ pátápátá nígbà tí ikú bá dé, àmọ́ ṣá o, ó tún ń ru ìfẹ́ kan sókè nínú wọn, ìyẹn ni ìfẹ́ láti wà láàyè, tó máa ń wu ènìyàn ṣáá.

Bíbélì Mímọ́, tó jẹ́ Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí, fún wa ní ìrètí àgbàyanu. (2 Tímótì 3:16) Jèhófà, tó jẹ́ pé ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìfẹ́ pin sí, kò jẹ́ dá ènìyàn pẹ̀lú agbára àtilóye ohun tí ayérayé túmọ̀ sí, kó sì wá sọ pé, ojú ni èèyàn fi rí i, ète rẹ̀ ò ní bà á, pé èèyàn kò ní lè wà láàyè ju ọdún díẹ̀ lọ. Èrò náà pé Ọlọ́run lè dá wa fún ìyà kò bá ànímọ́ rẹ̀ mu rárá. A kò dá wa bí “àwọn ẹran tí kì í ronú, tí a bí lọ́nà ti ẹ̀dá fún mímú àti píparun.”—2 Pétérù 2:12.

Ohun tó “dára gan-an” ni Jèhófà Ọlọ́run ṣe ní ti dídá tí ó dá Ádámù àti Éfà pẹ̀lú àbùdá àtilóye ohun tí ayérayé túmọ̀ sí; ó dá wọn pẹ̀lú ète pé kí wọ́n wà láàyè títí láé. (Jẹ́nẹ́sísì 1:31) Áà ó mà ṣe o, tọkọtaya àkọ́kọ́ ṣi òmìnira ìfẹ́ inú táa fún wọn lò, wọ́n ṣàìgbọràn sí òfin tí Ẹlẹ́dàá náà ti ṣàlàyé rẹ̀ yékéyéké, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ pàdánù ìjẹ́pípé wọn ìpilẹ̀ṣẹ̀. Ohun tó yọrí sí ni pé, wọ́n kú, lẹ́yìn tí wọ́n tàtaré àìpé àti ikú sórí àwọn àtọmọdọ́mọ wọn.—Jẹ́nẹ́sísì 2:17; 3:1-24; Róòmù 5:12.

Bíbélì kò fi wá sínú òkùnkùn nípa ète ìgbésí ayé àti ohun tí ikú túmọ̀ sí. Ó sọ pé “kò sí iṣẹ́ tàbí ìhùmọ̀ tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n” ní ipò òkú àti pé àwọn òkú “kò mọ nǹkan kan rárá.” (Oníwàásù 9:5, 10) Lédè mìíràn, àwọn òkú ti kú fin-ínfin-ín. Ẹ̀kọ́ àìleèkú ọkàn kò bá Bíbélì mu rárá, nítorí náà kò sí ọ̀ràn àdììtú kankan tó nílò àlàyé nípa ipò àwọn òkú.—Jẹ́nẹ́sísì 3:19; Sáàmù 146:4; Oníwàásù 3:19, 20; Ìsíkíẹ́lì 18:4.a

Ọlọ́run ní ète kan; kò dá ilẹ̀ ayé “lásán.” Ó mọ ọ́n kí àwọn ènìyàn pípé lè “máa gbé inú rẹ̀” nínú ipò párádísè, Ọlọ́run kò sì tí ì yí ète rẹ̀ yìí padà. (Aísáyà 45:18; Málákì 3:6) Láti lè mú ète yìí ṣẹ, ó rán Ọmọ rẹ̀ wá sí ayé. Nítorí tí Jésù Kristi ṣe olóòótọ́ títí dójú ikú, ó pèsè ọ̀nà láti ra aráyé padà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Àní, Jésù wí pé: “Nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.”—Jòhánù 3:16.

Tipẹ́tipẹ́ sẹ́yìn, Ọlọ́run ṣèlérí pé òun yóò dá “ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun.” (Aísáyà 65:17; 2 Pétérù 3:13) Ìyẹn yóò kan yíyan àwùjọ àwọn Kristẹni olóòótọ́ kan tí wọ́n níye, fún ìyè ti ọ̀run. Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú Jésù Kristi yóò jẹ́ apá pàtàkì nínú ìjọba náà. Bíbélì tọ́ka sí èyí gẹ́gẹ́ bí “ìjọba ọ̀run,” tàbí “ìjọba Ọlọ́run,” tí yóò ṣàkóso lórí “àwọn ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé.” (Mátíù 4:17; 12:28; Éfésù 1:10; Ìṣípayá 5:9, 10; 14:1, 3) Lẹ́yìn tí Ọlọ́run bá ti pa gbogbo àwọn tí kò ṣèfẹ́ rẹ run kúrò lágbàáyé, tó sì sọ ayé di mímọ́, yóò wá mú àwùjọ ènìyàn tuntun tí wọ́n jẹ́ olódodo wá, tàbí “ilẹ̀ ayé tuntun.” Lára àwọn wọ̀nyí ni, àwọn tí Ọlọ́run yóò pa mọ́ la ìparun ètò burúkú ti àwọn nǹkan ìsinsìnyí já. (Mátíù 24:3, 7-14, 21; Ìṣípayá 7:9, 13, 14) Àwọn tí a mú padà wá sí ìyè nípasẹ̀ ìlérí àjíǹde yóò wá dara pọ̀ mọ́ wọn.—Jòhánù 5:28, 29; Ìṣe 24:15.

“Ìyè Tòótọ́” Nígbà Náà

Nígbà tí Ọlọ́run ń mú àpèjúwe amúniláyọ̀ táa ṣe nípa ìyè nínú Párádísè ilẹ̀ ayé lọ́jọ́ iwájú dáni lójú, ó wí pé: “Wò ó! Mo ń sọ ohun gbogbo di tuntun.” (Ìṣípayá 21:5) Kò ṣeé ṣe fún ènìyàn láti lóye gbogbo àgbàyanu iṣẹ́ tí Ọlọ́run yóò ṣe fún aráyé lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. Ọlọ́run yóò dá párádísè kan tó kárí ayé, tí yóò dà bí ti Édẹ́nì. (Lúùkù 23:43) Gẹ́gẹ́ bó ti rí ní Édẹ́nì, àwọn àwọ̀ mèremère tó jojú ní gbèsè, ìró tó dùn-ún gbọ́, àti nǹkan àjẹpọ́nnulá yóò pọ̀ rẹpẹtẹ. Òṣì àti àìtó oúnjẹ yóò di ohun àtijọ́, nítorí Bíbélì ti sọ nípa àkókò náà pé: “Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.” (Ìṣípayá 21:4; Sáàmù 72:16) Kò sí ẹnì kan tí yóò tún sọ pé, “Àìsàn ń ṣe mí,” nítorí àmódi yóò ti di ohun táa ti mú kúrò pátápátá. (Aísáyà 33:24) Bẹ́ẹ̀ ni, gbogbo ohun tí ń fa ìrora ni yóò ti pòórá, títí kan ọ̀tá aráyé tó ti wà tipẹ́tipẹ́ yẹn, ikú. (1 Kọ́ríńtì 15:26) Nínú ìran àgbàyanu kan nípa “ilẹ̀ ayé tuntun,” ìyẹn ni àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn tuntun lábẹ́ ìṣàkóso Kristi, àpọ́sítélì Jòhánù gbọ́ ohùn kan tí ń sọ pé: “[Ọlọ́run] yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́.” Kí ló tún lè mú ìtùnú ńlá àti ayọ̀ wa ju ìmúṣẹ ìlérí Ọlọ́run yìí?

Nígbà tí Bíbélì ń ṣàpèjúwe ìyè ní ọjọ́ ọ̀la, ní pàtàkì, ó tẹnu mọ́ ipò tí yóò mú ìtẹ́lọ́rùn ní ti ìwà híhù àti nípa tẹ̀mí wá fún ènìyàn. Gbogbo ipò ìgbésí ayé tó dáa tí aráyé ti ń jà fún láìkẹ́sẹjárí títí di ìsinsìnyí ni ọwọ́ wa yóò tẹ̀ pátápátá. (Mátíù 6:10) Lára èyí ni ìfẹ́ fún ìdájọ́ òdodo, èyí tí kò tí ì tẹ̀ wá lọ́wọ́ nítorí pé àwọn òǹrorò tí ń nini lára ló ti ń fìyà jẹ àwọn tí kò lẹ́nu ọ̀rọ̀ láti ọjọ́ tó ti pẹ́. (Oníwàásù 8:9) Onísáàmù náà kọ̀wé àsọtẹ́lẹ̀ kan tó sọ nípa ipò tí yóò wà lábẹ́ ìṣàkóso Kristi pé: “Ní àwọn ọjọ́ rẹ̀ ni ìwà òdodo yóò gbilẹ̀, àlàáfíà yóò sì pọ̀.”—Sáàmù 72:7, The New Jerusalem Bible.

Ẹ̀tọ́ ọgbọọgba tún jẹ́ ohun mìíràn ti ọ̀pọ̀ ti lépa kọ́wọ́ wọn ṣáà lè tẹ̀ ẹ́. Nígbà “àtúndá,” Ọlọ́run yóò mú ẹ̀mí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà kúrò. (Mátíù 19:28) A óò máa buyì kan náà fún gbogbo ènìyàn. Èyí kò ní jẹ́ ẹ̀mí ìbánilò lọ́gbọọgba tí ìjọba kan tó le koko gbé kani lórí. Kàkà bẹ́ẹ̀, gbogbo ohun tí ń fa kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà la óò mú kúrò, títí kan ẹ̀mí ìwọra àti ìgbéraga tó ń mú kí àwọn èèyàn máa fẹ́ jẹ gàbà lé àwọn ẹlòmíràn lórí tàbí láti kó dúkìá rẹpẹtẹ jọ. Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Dájúdájú, wọn yóò kọ́ ilé, wọn yóò sì máa gbé inú wọn; dájúdájú, wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì máa jẹ èso wọn. Wọn kì yóò kọ́lé fún ẹlòmíràn gbé; wọn kì yóò gbìn fún ẹlòmíràn jẹ.”—Aísáyà 65:21, 22.

Ẹ wo ìyà ńlá tí ìtàjẹ̀sílẹ̀ nínú ogun àdájà àti àpawọ́pọ̀jà ti fi jẹ àwọn èèyàn! Èyí ti ń bá a bọ̀ láti ìgbà tí a ti pa Ébẹ́lì títí di àkókò àwọn ogun tó ń jà lọ́wọ́lọ́wọ́. Ẹ wògbà táwọn èèyàn ti ń retí, tí wọ́n sì ti ń dúró de àlàáfíà pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ dé, àmọ́ tó jẹ́ òtúbáńtẹ́ ló ń já sí! Nínú Párádísè tí a óò mú padà bọ̀ sípò, gbogbo ènìyàn ni yóò jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà àti ọlọ́kàn tútù; wọn yóò “rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.”—Sáàmù 37:11.

Aísáyà 11:9 sọ pé: “Ilẹ̀ ayé yóò kún fún ìmọ̀ Jèhófà bí omi ti bo òkun.” Àìpé táa ti jogún, jẹ́ ọ̀kan lára àwọn kókó mìíràn tí kò mú kó ṣeé ṣe fún wa lónìí láti lóye ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ yẹn lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. Bí ìmọ̀ pípé nípa Ọlọ́run yóò ṣe mú kí a wà níṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀ àti bí ìyẹn yóò ṣe yọrí sí ayọ̀, gbogbo ìyẹn la ó mọ̀ bó bá yá. Ṣùgbọ́n, níwọ̀n ìgbà tí Ìwé Mímọ́ ti ń sọ fún wa pé Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run tí agbára, ọgbọ́n, ìdájọ́ òdodo àti ìfẹ́ rẹ̀ jẹ́ àgbàyanu, a lè ní ìdánilójú pé òun yóò gbọ́ gbogbo àdúrà tí àwọn olùgbé “ilẹ̀ ayé tuntun” náà bá gbà.

“Ìyè Tòótọ́” Dájú Ṣáká—Gbá A Mú Gírígírí!

Lójú ọ̀pọ̀lọpọ̀, ìyè ayérayé nínú ayé kan tí ó sàn jù wulẹ̀ jẹ́ àlá tàbí ẹ̀tàn lásán. Ṣùgbọ́n, lójú àwọn tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ tòótọ́ nínú ìlérí Bíbélì, ìrètí yìí dájú ṣáká. Bí ìdákọ̀ró ló rí fún ìwàláàyè wọn. (Hébérù 6:19) Gẹ́gẹ́ bí ìdákọ̀ró ti ń mú kí ọkọ̀ òkun ó dúró sójú kan, tí kò ní jẹ́ kí ó sú lọ, bẹ́ẹ̀ ni ìrètí ìyè ayérayé ń mú kí àwọn ènìyàn dúró gbọn-in, ó ń jẹ́ kí ọkàn wọn balẹ̀, ó sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìṣòro ńlá nínú ìgbésí ayé, àní kí wọ́n tilẹ̀ lè borí wọn.

A lè ní ìdánilójú pé Ọlọ́run yóò mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Ó tilẹ̀ ti jẹ́ kó dá wa lójú nípa bíbúra, nípa jíjẹ́jẹ̀ẹ́ tí kò ní ṣàìmúṣẹ. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Nígbà tí ó pète láti fi àìlèyípadà ìpinnu rẹ̀ hàn lọ́pọ̀ yanturu fún àwọn ajogún ìlérí náà, Ọlọ́run mú ìbúra kan wọ̀ ọ́, pé, nípasẹ̀ ohun àìlèyípadà méjì, nínú èyí tí kò ṣeé ṣe fún Ọlọ́run láti purọ́, kí àwa . . . lè ní ìṣírí tí ó lágbára láti gbá ìrètí tí a gbé ka iwájú wa mú.” (Hébérù 6:17, 18) “Ohun àìlèyípadà méjì” náà tí Ọlọ́run kò lè ṣàìmúṣẹ ni ìlérí rẹ̀ àti ìbúra rẹ̀, orí èyí tí a gbé ìrètí wa kà.

Ìgbàgbọ́ nínú ìlérí Ọlọ́run ń mú ìtùnú ńlá àti okun tẹ̀mí wá fún wa. Jóṣúà, aṣáájú àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì, ní irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀. Nígbà tí Jóṣúà sọ ọ̀rọ̀ ìdágbére rẹ̀ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó ti darúgbó, ó sì mọ̀ pé òun ò ní pẹ́ kú mọ́. Síbẹ̀, ó fi agbára àti ìdúróṣinṣin tí kò ṣeé mì hàn, èyí tó wá láti inú ìgbẹ́kẹ̀lé pátápátá tó ní nínú ìlérí Ọlọ́run. Lẹ́yìn tí Jóṣúà sọ pé òun ń lọ “ní ọ̀nà gbogbo ilẹ̀ ayé,” ìyẹn ni ọ̀nà tó ń sin gbogbo aráyé lọ sí ikú, ó wá sọ pè: “Ẹ̀yin sì mọ̀ dáadáa ní gbogbo ọkàn-àyà yín àti ní gbogbo ọkàn yín pé kò sí ọ̀rọ̀ kan tí ó kùnà nínú gbogbo ọ̀rọ̀ rere tí Jèhófà Ọlọ́run yín sọ fún yín. Gbogbo wọn ti ṣẹ fún yín. Kò sí ọ̀rọ̀ kan lára wọn tí ó kùnà.” Bẹ́ẹ̀ ni, ìgbà mẹ́ta ni Jóṣúà sọ ọ́ lásọtúnsọ pé Ọlọ́run máa ń mú gbogbo ìlérí rẹ̀ ṣẹ.—Jóṣúà 23:14.

Ìwọ pẹ̀lú lè ní irú ìgbàgbọ́ kan náà nínú ìlérí Ọlọ́run ti ayé tuntun tí a óò gbé kalẹ̀ láìpẹ́. Nípa fífi taratara kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìwọ yóò wá mọ ẹni tí Jèhófà jẹ́ àti ìdí tó fi yẹ kóo gbẹ́kẹ̀ lé e pátápátá. (Ìṣípayá 4:11) Ábúráhámù, Sárà, Ísákì, Jékọ́bù, àti àwọn ẹni olóòótọ́ ìgbàanì mìíràn ní ìgbàgbọ́ tí kò ṣeé mì, èyí tí wọ́n gbé ka ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìmọ̀ nípa Ọlọ́run tòótọ́, Jèhófà. Ìrètí wọn kò mì, láìka pé wọn “kò . . . rí ìmúṣẹ àwọn ìlérí náà” sí, nígbà tí wọ́n ṣì wà láàyè. Síbẹ̀, “wọ́n rí wọn lókèèrè réré, wọ́n sì fi inú dídùn tẹ́wọ́ gbà wọ́n.”—Hébérù 11:13.

Nísinsìnyí tí a ti lóye àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, a ti wá mọ̀ pé “ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè” ti sún mọ́lé, nígbà tí a óò mú ìwà ibi kúrò lórí ilẹ̀ ayé. (Ìṣípayá 16:14, 16) Bíi ti àwọn ọkùnrin olóòótọ́ ìgbàanì, a ò gbọ́dọ̀ sọ ìrètí nù nínú àwọn nǹkan tí yóò ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ fún Ọlọ́run sún wa ṣiṣẹ́ fún “ìyè tòótọ́.” Ayé tuntun náà tí ó sún mọ́lé ń pèsè ohun amóríyá kan fún àwọn tí wọ́n lo ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà, tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Irú ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ gbọ́dọ̀ jẹ́ èyí tí a mú dàgbà láti bàa lè jèrè ojú rere Ọlọ́run, kí a sì rí ààbò rẹ̀ ní ọjọ́ ńlá rẹ̀, èyí tó ti sún mọ́lé.—Sefanáyà 2:3; 2 Tẹsalóníkà 1:3; Hébérù 10:37-39.

Nítorí náà, ṣé ìyè wù ọ́? Ṣé o fẹ́ “ìyè tòótọ́”—ìyẹn ni pé kí o wà láàyè gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ tí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà, tó ní ìrètí ọjọ́ ọ̀la aláyọ̀, àní, ìránṣẹ́ tó ní ìrètí ìyè ayérayé? Bó bá jẹ́ ohun tóò ń lépa nìyẹn, kọbi ara sí ìṣílétí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà, ẹni tó kọ̀wé pé kí a má ṣe ‘gbé ìrètí wa ka ọrọ̀ àìdánilójú, bí kò ṣe lé Ọlọ́run.’ Pọ́ọ̀lù ń bá a nìṣó pé: “Jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú àwọn iṣẹ́ àtàtà,” èyí tí ń bọlá fún Ọlọ́run, kí o bàa lè “di ìyè tòótọ́ mú gírígírí.”—1 Tímótì 6:17-19.

Nípa títẹ́wọ́gba ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń lọni, o lè ní ìmọ̀ tí ó “túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 17:3) Lọ́nà tí ó fi ìfẹ́ hàn, ìpè bíi ti baba sí ọmọ yìí wà nínú Bíbélì, èyí tó kà pé: “Ọmọ mi, má gbàgbé òfin mi, kí ọkàn-àyà rẹ sì pa àwọn àṣẹ mi mọ́, nítorí ọjọ́ gígùn àti ọ̀pọ̀ ọdún ìwàláàyè àti àlàáfíà ni a ó fi kún un fún ọ.”—Òwe 3:1, 2.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí kókó yìí, wo ìwé pẹlẹbẹ náà, Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú?, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́