Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn
Lílọ Wàásù Fáwọn Èèyàn Níbi Iṣẹ́ Wọn
KÍ LOHUN kan náà tó ṣẹlẹ̀ sí àpọ́sítélì Mátíù, Pétérù, Áńdérù, Jákọ́bù àti Jòhánù? Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn ni pé ibi iṣẹ́ wọn ni gbogbo wọ́n wà nígbà tí Jésù pè wọ́n. Ẹnu iṣẹ́ ẹja pípa ni Pétérù, Áńdérù, Jákọ́bù àti Jòhánù wà nígbà tí Jésù pè wọ́n, pé: “Ẹ máa tọ̀ mí lẹ́yìn.” Inú ọ́fíìsì àwọn olówó orí ni Mátíù wà nígbà tí Jésù pè é pé kó wá di ọmọ ẹ̀yìn òun.—Mátíù 4:18-21; 9:9.
Wíwàásù fáwọn èèyàn níbi iṣẹ́ wọn máa ń láṣeyọrí gan-an. Nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Japan mọ̀ bẹ́ẹ̀, wọ́n pawọ́ pọ̀ sapá lẹ́nu àìpẹ́ yìí láti lo ọ̀nà yìí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn. Kí ni ìyọrísí rẹ̀? Láàárín oṣù mélòó kan, ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìpadàbẹ̀wò ni wọ́n ṣe, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ nǹkan bí àádọ́ta lé nígbà [250] ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Wo àwọn ìrírí tó tẹ̀ lé e yìí.
Òjíṣẹ́ alákòókò kíkún kan ní ìlú Tokyo rí olùdarí ilé oúnjẹ kan tó jẹ́ pé nǹkan bí ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn ni Ẹlẹ́rìí kan ti bá a sọ̀rọ̀ nílé ìwé nígbà tó ṣì kéré. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé nígbà yẹn, ọ̀gá yìí ò fi bẹ́ẹ̀ lóye ohun tí wọ́n sọ, ó dẹni tó nífẹ̀ẹ́ sí Bíbélì. Nísinsìnyí tí wọ́n tún wá ta á jí, kíá ló tẹ́wọ́ gba ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, èyí tí wọ́n ń fi ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun ṣe.a Síwájú sí i, ó ṣètò láti máa ka Bíbélì ní alaalẹ́ kó tó lọ sùn.
Aṣáájú ọ̀nà àkànṣe kan lọ sí ọ́fíìsì kan. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò bá ọ̀gá ilé iṣẹ́ náà níbẹ̀, ọmọbìnrin tó bá ọ̀gá yìí gbé tẹlifóònù rẹ̀ béèrè pé: “Ṣé ẹ lé rán mi sílẹ̀ dè wọ́n?” Bí wọ́n ṣe bára wọn sọ̀rọ̀ díẹ̀ lórí tẹlifóònù, ọmọbìnrin yìí jáde wá bá a pé ó wu òun láti máa ka Bíbélì. Aṣáájú ọ̀nà àkànṣe yìí ṣètò láti bá a mú Bíbélì kan wá, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí bá a ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì níbi ìgbafẹ́ kan nítòsí ibẹ̀ láràárọ̀ kó tó lọ wọṣẹ́.
Ní ọ́fíìsì mìíràn, ọkùnrin kan rí i pé ẹnì kan tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ gba Ilé Ìṣọ́ àti Jí! àmọ́ ó yára kó wọn dà nù bí Ẹlẹ́rìí tó fún un ṣe yísẹ̀ padà. Nígbà tí ọkùnrin náà délé, ó sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí fún aya rẹ̀ tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí, ó wá ní ká ní wọ́n dé ọ̀dọ̀ òun ni, òun ì bá tiẹ̀ gbọ́rọ̀ wọn díẹ̀. Ọmọ rẹ̀ obìnrin tó fetí kọ́ ohun tó wí yìí wá sọ fún Ẹlẹ́rìí kan tó fi àwọn iléeṣẹ́ yẹn ṣe ìpínlẹ̀ tó ti ń wàásù. Ẹlẹ́rìí náà ò sì jáfara tó fi lọ sọ́dọ̀ ọkọ obìnrin yìí ní ọ́fíìsì rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí bá a ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Láìpẹ́, ọkùnrin náà bẹ̀rẹ̀ sí wá sípàdé ọjọ́ Sunday déédéé.
Lílọ wàásù fáwọn èèyàn níbi iṣẹ́ tún yọrí sí àwọn àǹfààní mìíràn pẹ̀lú. Ọ̀pọ̀ akéde ní Japan ti dẹni tó jáfáfá nínú ṣíṣe ìpadàbẹ̀wò láwọn ibi ìtajà, iléeṣẹ́ àti láwọn ọ́fíìsì. Láfikún, ọ̀pọ̀ àwọn tó ti di aláìṣiṣẹ́mọ́ ni wọ́n ti tipa ọ̀nà ìwàásù yìí wá kàn, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí báwọn ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́. Àṣeyọrí tí wọ́n ṣe kì í ṣe kékeré. Láìpẹ́ yìí, ìjọ kan láàárín gbùngbùn Tokyo ròyìn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì méjìdínláàádọ́fà [108], tó ju ìlọ́po méjì iye tí wọ́n ṣe léṣìí lọ.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ṣe é.