ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 4/1 ojú ìwé 3-4
  • Wàá Láyọ̀ Tó O Bá Lóye Bíbélì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wàá Láyọ̀ Tó O Bá Lóye Bíbélì
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Kan Tó Lè Fún Gbogbo Èèyàn Láyọ̀
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Bibeli—Ìwé Kan Tí Ó Yẹ Kí A Lóye Rẹ̀
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • 1. Gbàdúrà Pé Kí Ọlọ́run Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Púpọ̀ Sí I Nípa Bíbélì?
    Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Púpọ̀ Sí I Nípa Bíbélì?
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 4/1 ojú ìwé 3-4

Wàá Láyọ̀ Tó O Bá Lóye Bíbélì

ÀWỌN ọ̀rọ̀ tó jẹ́ òtítọ́ tó sì ṣeyebíye ló wà nínú Bíbélì, àtọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni wọ́n sì ti wá. Ó sọ ìdí tá a fi wà láàyè fún wa, ó tún sọ ìdí tí aráyé fi ń rí ìpọ́njú, àti bí ọjọ́ iwájú ẹ̀dá èèyàn ṣe máa rí. Bíbélì kọ́ wa bá a ṣe lè ní ayọ̀, bá a ṣe lè láwọn ọ̀rẹ́, àti bá a ṣe lè rí ojútùú sáwọn ìṣòro wa. Èyí tó ṣe pàtàkì jù ni pé, a lè mọ̀ nípa Ẹlẹ́dàá wa, Jèhófà, tó tún jẹ́ Baba wa ọ̀run. Irú ìmọ̀ yìí máa ń fúnni láyọ̀ ó sì ń jẹ́ káyé ẹni lójú.

Bíbélì fi níní ìmọ̀ Ọlọ́run wé oúnjẹ jíjẹ. Jésù sọ pé: “Ènìyàn kì yóò wà láàyè nípasẹ̀ oúnjẹ nìkan ṣoṣo, bí kò ṣe nípasẹ̀ gbogbo àsọjáde tí ń jáde wá láti ẹnu Jèhófà.” (Mátíù 4:4; Hébérù 5:12-14) Bí jíjẹ oúnjẹ aṣaralóore lójoojúmọ́ ṣe ṣe pàtàkì fún wa ká lè máa wà láàyè nìṣó, bẹ́ẹ̀ ni kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé ṣe ṣe pàtàkì tá a bá fẹ́ ní ìyè ayérayé tí Ọlọ́run ṣèlérí.

A máa ń fẹ́ láti jẹun nítorí pé Ọlọ́run ti dá wa lọ́nà tí a óò fi máa gbádùn oúnjẹ jíjẹ àti nítorí pé ó níṣẹ́ tí oúnjẹ ń ṣe lára wa. Àmọ́ o, ohun pàtàkì kan tún wà tí Ọlọ́run dá mọ́ wa tá a gbọ́dọ̀ ṣe nǹkan kan nípa rẹ̀ tá a bá fẹ́ láyọ̀. Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.” (Mátíù 5:3) Ó ṣeé ṣe fún wa láti láyọ̀ nítorí pé ohun tó ń jẹ wá lọ́kàn nípa tẹ̀mí lè tẹ̀ wá lọ́wọ́ tá a bá ní òye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

Lóòótọ́, kò rọrùn fáwọn kan láti lóye Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, ó lè pọn dandan kẹ́nì kan ràn ọ́ lọ́wọ́ kó o tó lè lóye àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó ń sọ nípa àwọn àṣà tó ṣàjèjì tàbí àwọn ẹsẹ tó lo èdè ìṣàpẹẹrẹ. Bákan náà, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ kan tún wà nínú Bíbélì tí wọ́n fi èdè àpèjúwe kọ tó sì jẹ́ pé àyàfi téèyàn bá ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ mìíràn tó ní í ṣe pẹ̀lú kókó yẹn nìkan lèèyàn fi lè lóye wọn. (Dáníẹ́lì 7:1-7; Ìṣípayá 13:1, 2) Síbẹ̀, o lè lóye Bíbélì. Kí nìdí tó fi yẹ kó o gbà bẹ́ẹ̀?

Ohun Kan Tó Lè Fún Gbogbo Èèyàn Láyọ̀

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì. Inú rẹ̀ ni Ọlọ́run ti sọ ohun tó fẹ́ ká ṣe. Ṣé o rò pé Ọlọ́run á fún wa ní ìwé kan tá ò ní lè lóye ohun tó wà nínú rẹ̀ tàbí tó jẹ́ kìkì àwọn ọ̀mọ̀wé nìkan ló máa lè lóye rẹ̀? Rárá o, Jèhófà kò jẹ́ ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀. Kristi Jésù sọ pé: “Baba wo ní ń bẹ láàárín yín tí ó jẹ́ pé, bí ọmọ rẹ̀ bá béèrè ẹja, bóyá tí yóò fi ejò lé e lọ́wọ́ dípò ẹja? Tàbí bí ó bá tún béèrè ẹyin, tí yóò fi àkekèé lé e lọ́wọ́? Nígbà náà, bí ẹ̀yin, tí ẹ tilẹ̀ jẹ́ ẹni burúkú, bá mọ bí ẹ ṣe ń fi ẹ̀bùn rere fún àwọn ọmọ yín, mélòómélòó ni Baba tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀!” (Lúùkù 11:11-13) Nítorí náà, jẹ́ kó dá ọ lójú pé o lè lóye ohun tó wà nínú Bíbélì. Bó o bá bẹ Ọlọ́run tọkàntọkàn pé kó ràn ọ́ lọ́wọ́, yóò ṣe ọ̀nà tí wàá fi lè lóye Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Kódà, àwọn ọmọdé pàápàá lè lóye àwọn ohun téèyàn kọ́kọ́ máa ń kọ́ nínú Bíbélì!—2 Tímótì 3:15.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ní láti sapá ká tó lè lóye Bíbélì, síbẹ̀ òye Bíbélì tá a bá ní lè fún wa lókun ó sì tún lè fún wa níṣìírí. Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó fara han méjì lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ó sì bá wọn sọ̀rọ̀ nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Bíbélì. Àkọsílẹ̀ Lúùkù sọ pé: “Bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Mósè àti gbogbo àwọn Wòlíì, ó túmọ̀ àwọn nǹkan tí ó jẹmọ́ ara rẹ̀ nínú gbogbo Ìwé Mímọ́ fún wọn.” Kí ni àbájáde rẹ̀? Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn, báwọn ọmọlẹ́yìn náà ti ń ronú lórí ohun tí wọ́n gbọ́, wọ́n sọ fún ara wọn pé: “Ọkàn-àyà wa kò ha ń jó fòfò bí ó ti ń bá wa sọ̀rọ̀ ní ojú ọ̀nà, bí ó ti ń ṣí Ìwé Mímọ́ payá fún wa lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́?” (Lúùkù 24:13-32) Òye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run táwọn ọmọ ẹ̀yìn méjì wọ̀nyí ní fún wọn láyọ̀. Ìdí ni pé ó jẹ́ kí ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run lágbára sí i, ó sì fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ pé ọjọ́ ọ̀la yóò dára.

Lílóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kì í ṣe ohun tó nira rárá. Kàkà bẹ́ẹ̀ ohun tó ń gbádùn mọ́ni tó sì ń ṣàǹfààní fúnni ló jẹ́. Ńṣe ló dà bí ìgbà téèyàn ń jẹ oúnjẹ aṣaralóore tó sì ń gbádùn oúnjẹ náà. Kí lo wá yẹ kó o ṣe láti ní irú òye bẹ́ẹ̀? Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí yóò jẹ́ kó o mọ bó o ṣe lè gbádùn níní “ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an.”—Òwe 2:1-5.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Bíi bàbá kan tó nífẹ̀ẹ́ ọmọ rẹ̀ ni Jèhófà ṣe máa ń fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ ká lè lóye Bíbélì

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́