ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 5/1 ojú ìwé 27-31
  • Ẹ Jẹ́ Olóòótọ́ Sí Kristi Ọba

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ Jẹ́ Olóòótọ́ Sí Kristi Ọba
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọba Táwọn Ànímọ́ Rẹ̀ Mú Ká Jẹ́ Olóòótọ́ Sí I
  • Bá A Ṣe Lè Di Ara Àwọn Tí Kristi Máa Ṣàkóso Lé Lórí
  • Àwọn Tí Kristi Máa Ṣàkóso Lé Lórí Ń Pa Òfin Rẹ̀ Mọ́
  • Wọ́n Kojú Ìdánwò Ìgbàgbọ́
  • Èrè Ayérayé Fáwọn Tó Jólóòótọ́ sí Kristi
  • “Ìwọ Nìkan Ni Adúróṣinṣin”
    Sún Mọ́ Jèhófà
  • Kíyè Sí Àwọn Adúróṣinṣin!
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Kíkojú Ìpènijà Ìdúróṣinṣin
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Fífi Ìdúróṣinṣin Sìn Pẹ̀lú Ètò Àjọ Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 5/1 ojú ìwé 27-31

Ẹ Jẹ́ Olóòótọ́ Sí Kristi Ọba

“A sì fún un ní agbára ìṣàkóso àti iyì àti ìjọba, pé kí gbogbo àwọn ènìyàn, àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè àti àwọn èdè máa sin àní òun.”—DÁNÍẸ́LÌ 7:14.

1, 2. Báwo la ṣe mọ̀ pé Kristi kò tíì gba Ìjọba náà lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ lọ́dún 33 Sànmánì Kristẹni?

ALÁKÒÓSO wo ló lè kú nítorí àwọn tó ń ṣàkóso lé lórí síbẹ̀ kó tún wà láàyè kó sì tún máa ṣàkóso bí ọba? Ọba wo ló tíì gbé ayé rí, táwọn tó ń ṣàkóso lé lórí nígbẹ̀ẹ́kẹ̀lé nínú rẹ̀ tí wọ́n sì jólóòótọ́ sí i, lẹ́yìn náà tó tún wá ń ṣàkóso látọ̀run? Ẹnì kan ṣoṣo tó lè ṣe ohun tá a wí yìí àti ọ̀pọ̀ nǹkan míì ni Jésù Kristi. (Lúùkù 1:32, 33) Ní ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, lẹ́yìn tí Kristi ti kú, tó jíǹde, tó sì gòkè re ọ̀run, Ọlọ́run “fi í ṣe orí lórí ohun gbogbo fún ìjọ.” (Éfésù 1:20-22; Ìṣe 2:32-36) Kristi wá tipa bẹ́ẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso, àmọ́ ìṣàkóso náà ò tíì karí ayé nígbà yẹn. Àwọn tó kọ́kọ́ ń ṣàkóso lé lórí ni àwọn Kristẹni tá a fi ẹ̀mí yàn, tí wọ́n para pọ̀ jẹ́ Ísírẹ́lì tẹ̀mí, ìyẹn “Ísírẹ́lì Ọlọ́run.”—Gálátíà 6:16; Kólósè 1:13.

2 Ní nǹkan bí ọgbọ̀n ọdún lẹ́yìn Pẹ́ńtíkọ́sì ti ọdún 33 Sànmánì Kristẹni yẹn, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mú un dáni lójú pé Kristi kò tíì gba Ìjọba náà lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́, àmọ́ ó wà “ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run, láti ìgbà náà lọ, ó ń dúró títí a ó fi fi àwọn ọ̀tá rẹ̀ ṣe àpótí ìtìsẹ̀ fún ẹsẹ̀ rẹ̀.” (Hébérù 10:12, 13) Lẹ́yìn ìgbà yẹn, nígbà tó kù díẹ̀ kí ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni parí, àpọ́sítélì Jòhánù tó ti darúgbó nígbà náà rí ìran kan nínú èyí tí Jèhófà, Ọba Aláṣẹ Ọ̀run òun Ayé ti gbé Kristi Jésù gorí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba ọ̀run tí Ọlọ́run ṣẹ̀ṣẹ̀ fìdí rẹ̀ múlẹ̀. (Ìṣípayá 11:15; 12:1-5) Tá a bá wo ohun tó ti ń ṣẹlẹ̀ bọ̀ títí di àkókò tiwa yìí, a lè rí ẹ̀rí tó dájú pé Kristi ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí Mèsáyà Ọba ní ọ̀run látọdún 1914.a

3. (a) Ìròyìn tuntun wo ni ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ní nínú látọdún 1914? (b) Àwọn ìbéèrè wo la lè bi ara wa?

3 Dájúdájú, látọdún 1914 ni ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tún ti wá ní ìròyìn tuntun kan nínú tó ń mọ́kàn yọ̀. Kristi ti ń ṣàkóso lọ́run gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọ́run ó sì ń darí ìgbòkègbodò àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, àmọ́ ‘láàárín àwọn ọ̀tá rẹ̀’ ló ti ń ṣàkóso. (Sáàmù 110:1, 2; Mátíù 24:14; Ìṣípayá 12:7-12) Ìyẹn nìkan kọ́ o, jákèjádò ayé làwọn olóòótọ́ tó ń ṣàkóso lé lórí ti ń fìtara ṣègbọràn sí àṣẹ rẹ̀ nípa lílọ́wọ́ nínú iṣẹ́ kíkọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, èyí tí kò tíì sírú rẹ̀ rí nínú ìtàn ọmọ aráyé. (Dáníẹ́lì 7:13, 14; Mátíù 28:18) Àwọn Kristẹni tá a fi ẹ̀mí yàn, ìyẹn “àwọn ọmọ ìjọba,” ló ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí “ikọ̀ tí ń dípò fún Kristi.” “Àwọn àgùntàn mìíràn” fún Kristi, tí wọ́n jẹ́ agbo kan tó túbọ̀ ń gbèrú sì ń kọ́wọ́ tì wọ́n lẹ́yìn. Àwọn wọ̀nyí ló ń ṣojú fún Ìjọba Ọlọ́run. (Mátíù 13:38; 2 Kọ́ríńtì 5:20; Jòhánù 10:16) Síbẹ̀ náà, ó yẹ ká ṣàyẹ̀wò ara wa bóyá àwa bí ẹnì kan mọyì àṣẹ Kristi. Ṣé a jẹ́ olóòótọ́ sí i lójú méjèèjì? Ọ̀nà wo la lè gbà jẹ́ olóòótọ́ sí Ọba tó ń ṣàkóso lọ́run? Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ jíròrò àwọn ìdí tó fi yẹ ká jólóòótọ́ sí Kristi.

Ọba Táwọn Ànímọ́ Rẹ̀ Mú Ká Jẹ́ Olóòótọ́ Sí I

4. Kí ni Jésù gbé ṣe gẹ́gẹ́ bí Ọba Lọ́la lákòókò iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé?

4 Nítorí pé a mọrírì àwọn ohun tí Kristi ṣe àtàwọn ànímọ́ rẹ̀ títayọ ló mú ká jẹ́ olóòótọ́ sí i. (1 Pétérù 1:8) Nígbà tí Jésù wà láyé, tí kò tíì di Ọba, ó fi díẹ̀ hàn lára ohun tó máa ṣe nígbà tó bá tó àkókò lójú Ọlọ́run láti sọ ọ́ di Ọba tó ń ṣàkóso lórí gbogbo ayé. Ó bọ́ àwọn tí ebi ń pa. Ó mú àwọn aláìsàn lára dá, ó la ojú afọ́jú, ó wo àwọn aláàbọ̀ ara sàn, ó ṣí etí adití, ó sì mú káwọn odi sọ̀rọ̀. Kódà, ó jí àwọn bíi mélòó kan tó kú dìde. (Mátíù 15:30, 31; Lúùkù 7:11-16; Jòhánù 6:5-13) Láfikún sí i, níní ìmọ̀ nípa ìgbésí ayé Jésù lórí ilẹ̀ ayé ń mú kó ṣeé ṣe fún wa láti mọ àwọn ànímọ́ rẹ̀ tó mú kó kúnjú ìwọ̀n láti jẹ́ Alákòóso lọ́jọ́ iwájú. Ìfẹ́ ló gbawájú jù lọ nínú àwọn ànímọ́ náà, èyí tó ń mú kó lo ara rẹ̀ fáwọn èèyàn. (Máàkù 1:40-45) Lórí kókó yìí, a gbọ́ pé alákòóso kan tó ń jẹ́ Napoléon Bonaparte sọ pé: “Alexander, Caesar, Charlemagne, àti èmi fúnra mi tẹ àwọn ilẹ̀ ọba dó, àmọ́ orí kí la gbé gbogbo àṣeyọrí tá a ṣe kà? Orí agbára ni. Jésù Kristi nìkan ló dá ìjọba rẹ̀ sílẹ̀ lórí ìfẹ́, títí dòní olónìí ni àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn sì múra tán láti kú fún un.”

5. Kí nìdí táwọn ànímọ́ Jésù fi fa àwọn èèyàn mọ́ra gan-an?

5 Nítorí pé Jésù jẹ́ onínú tútù àti ẹni rírẹlẹ̀, ẹ̀kọ́ rẹ̀ tó ń gbéni ró àti jíjẹ́ tó jẹ́ onínúure mú ìtura bá àwọn tí pákáǹleke àti ìnira ìgbésí ayé kó ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn bá. (Mátíù 11:28-30) Ọkàn àwọn ọmọdé máa ń balẹ̀ nígbà tí wọ́n bá wà lọ́dọ̀ rẹ̀. Ojú ẹsẹ̀ làwọn olóye èèyàn tí wọ́n jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ di ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. (Mátíù 4:18-22; Máàkù 10:13-16) Bí Jésù ṣe máa ń gba tẹni rò tó sì tún ní ọ̀wọ̀ mú kí ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin tó bẹ̀rù Ọlọ́run jẹ́ olóòótọ́ sí i. Kódà àwọn mélòó kan lára wọn yọ̀ǹda àkókò wọn, okun wọn àti ohun ìní wọn láti bójú tó Jésù bó ṣe ń bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lọ lórí ilẹ̀ ayé.—Lúùkù 8:1-3.

6. Nígbà tí Lásárù kú, báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé nǹkan máa ń dun òun lọ́kàn gan-an?

6 Kristi fi bí nǹkan ṣe máa ń dùn ún lọ́kàn tó hàn nígbà tí Lásárù ọ̀rẹ́ rẹ̀ ọ̀wọ́n kú. Bó ṣe ń wo Màríà àti Màtá tí wọ́n ń sunkún kíkorò ká a lára gan-an, débi pé kò lè mú ìbànújẹ́ náà mọ́ra mọ́, ó sì “bẹ̀rẹ̀ sí da omijé.” Ó “dààmú,” èyí tó túmọ̀ sí pé ìrora ọkàn àti ìbànújẹ́ tí Màríà àti Màtá ní bà á lọ́kàn jẹ́ gan-an, bẹ́ẹ̀ ó mọ̀ pé òun máa tó jí Lásárù dìde. Lẹ́yìn náà, ìfẹ́ àti ìyọ́nú tí Jésù ní wá mú kó lo àṣẹ tí Ọlọ́run gbé lé e lọ́wọ́, ó sì jí Lásárù dìde.—Jòhánù 11:11-15, 33-35, 38-44.

7. Kí nìdí tí Jésù fi yẹ lẹ́ni tá a ní láti jẹ́ olóòótọ́ sí? (Tún wo àpótí tó wà ní ojú ìwé 31.)

7 Bí Jésù ṣe nífẹ̀ẹ́ ohun tó tọ́, tó sì kórìíra àgàbàgebè àti ìwà ibi jọni lójú gan-an. Ìgbà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló fìgboyà lé àwọn oníṣòwò tí wọ́n jẹ́ oníwọra kúrò nínú tẹ́ńpìlì. (Mátíù 21:12, 13; Jòhánù 2:14-17) Yàtọ̀ síyẹn, nígbà tó ṣì jẹ́ èèyàn lórí ilẹ̀ ayé, onírúurú ìpọ́njú ló dojú kọ, ìyẹn sì jẹ́ kó mọ̀ nípa pákáǹleke àtàwọn ìṣòro tó ń bá ọmọ aráyé fínra. (Hébérù 5:7-9) Kódà, Jésù mọ bó ṣe máa ń rí lára nígbà tí wọ́n bá kórìíra ẹni tí wọ́n sì ń gbé ẹ̀bi fún aláre. (Jòhánù 5:15-18; 11:53, 54; 18:38–19:16) Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ó fìgboyà yọ̀ǹda ara rẹ̀ láti kú ikú oró kó lè mú ìfẹ́ Bàbá rẹ̀ ṣẹ kó sì fún àwọn tó máa ṣàkóso lé lórí ní ìyè àìnípẹ̀kun. (Jòhánù 3:16) Ǹjẹ́ irú àwọn ànímọ́ tí Kristi ní yìí kò yẹ kó sún ọ láti máa jólóòótọ́ sí i láìjáwọ́? (Hébérù 13:8; Ìṣípayá 5:6-10) Àmọ́ kí lèèyàn gbọ́dọ̀ ṣe kó tó lè di ara àwọn tí Kristi Ọba ń ṣàkóso lé lórí?

Bá A Ṣe Lè Di Ara Àwọn Tí Kristi Máa Ṣàkóso Lé Lórí

8. Kí là ń béèrè lọ́wọ́ àwọn tó fẹ́ wà lára àwọn tí Kristi máa ṣàkóso lé lórí?

8 Ronú nípa ìfiwéra yìí: Kéèyàn tó lè di ọmọ orílẹ̀-èdè mìíràn, onítọ̀hún gbọ́dọ̀ ṣe àwọn ohun kan. Wọ́n lè sọ pé àwọn tó fẹ́ di ọmọ orílẹ̀-èdè tuntun náà gbọ́dọ̀ jẹ́ ọmọlúàbí èèyàn, kí wọ́n sì jẹ́ ẹni tí ara rẹ̀ le dé ìwọ̀n àyè kan. Bákan náà, àwọn tó fẹ́ di ara àwọn tí Kristi máa ṣàkóso lé lórí gbọ́dọ̀ ní ìwà tó dára gan-an, kí wọ́n sì dúró sán-ún nípa tẹ̀mí.—1 Kọ́ríńtì 6:9-11; Gálátíà 5:19-23.

9. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a jólóòótọ́ sí Kristi?

9 Jésù Kristi tún fẹ́ káwọn tóun máa ṣàkóso lé lórí jẹ́ olóòótọ́ sí òun àti sí Ìjọba òun. Wọ́n ń fi irú ìṣòtítọ́ bẹ́ẹ̀ hàn nípa gbígbé ìgbésí ayé wọn níbàámu pẹ̀lú ohun tó fi kọ́ni nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí Ọba Lọ́la. Bí àpẹẹrẹ, ìfẹ́ Ọlọ́run àtàwọn ohun tó jẹ mọ́ Ìjọba rẹ̀ ló jẹ wọ́n lógún ju ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì lọ. (Mátíù 6:31-34) Wọ́n tún ń sa gbogbo ipá wọn láti ní àwọn ànímọ́ tí Kristi ní, kódà nígbà tí wọ́n bá wà nínú ipò tó le gan-an. (1 Pétérù 2:21-23) Síwájú sí i, àwọn tí Kristi ń darí máa ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ nípa ṣíṣe ohun tó dára sáwọn ẹlòmíì.—Mátíù 7:12; Jòhánù 13:3-17.

10. Báwo la ṣe lè fi ìṣòtítọ́ sí Kristi hàn nínú (a) ìdílé àti (b) nínú ìjọ?

10 Àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tún ń fi hàn pé àwọn jẹ́ olóòótọ́ sí i nípa fífi àwọn ànímọ́ Kristi hàn nínú ìdílé wọn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ọkọ máa ń fi ìṣòtítọ́ wọn sí Ọba wọn ọ̀run hàn nípa fífara wé Kristi nínú ọ̀nà tí wọ́n ń gbà bá àwọn aya àtàwọn ọmọ wọn lò. (Éfésù 5:25, 28-30; 6:4; 1 Pétérù 3:7) Àwọn aya sì ń fi ìṣòtítọ́ sí Kristi hàn nípa ìwà mímọ́ wọn àti nípa níní “ẹ̀mí ìṣejẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ àti ti ìwà tútù.” (1 Pétérù 3:1-4; Éfésù 5:22-24) Bákan náà, àwọn ọmọ ń fi hàn pé àwọn jẹ́ olóòótọ́ sí Kristi nígbà tí wọ́n bá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ jíjẹ́ tó jẹ́ onígbọràn. Nígbà tí Jésù wà lọ́mọdé, ó ṣègbọràn sí àwọn òbí rẹ̀, bí wọ́n tilẹ̀ jẹ́ aláìpé. (Lúùkù 2:51, 52; Éfésù 6:1) Àwọn tí Kristi máa ṣàkóso lé lórí ń fi ìṣòtítọ́ sapá láti fara wé e nípa bí wọ́n ṣe ń ‘fi ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì hàn, tí wọ́n ń ní ìfẹ́ni ará,’ tí wọ́n sì ń fi “ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn.” Wọ́n ń gbìyànjú láti dà bíi Kristi nípa jíjẹ́ ‘onírẹ̀lẹ̀ ní èrò inú, wọn kì í sì í fi ìṣeniléṣe san ìṣeniléṣe tàbí ìkẹ́gàn san ìkẹ́gàn.’—1 Pétérù 3:8, 9; 1 Kọ́ríńtì 11:1.

Àwọn Tí Kristi Máa Ṣàkóso Lé Lórí Ń Pa Òfin Rẹ̀ Mọ́

11. Òfin wo làwọn tí Kristi máa ṣàkóso lé lórí ń tẹ̀ lé?

11 Gẹ́gẹ́ bí ẹni tó fẹ́ di ọmọ orílẹ̀-èdè kan ṣe máa pa òfin orílẹ̀-èdè tuntun náà mọ́, bẹ́ẹ̀ náà làwọn tí Kristi máa ṣàkóso lé lórí ṣe ní láti pa “òfin Kristi” mọ́ nípa gbígbé ìgbésí ayé wọn lọ́nà tó bá ohun tí Jésù fi kọ́ni àtohun tó pa láṣẹ mu. (Gálátíà 6:2) Ní pàtàkì, wọ́n ń fi ìṣòtítọ́ tẹ̀ lé “ọba òfin” náà, ìyẹn ìfẹ́. (Jákọ́bù 2:8) Kí làwọn òfin wọ̀nyí ní nínú?

12, 13. Báwo la ṣe ń fi ìṣòtítọ́ tẹ̀ lé “òfin Kristi”?

12 Aláìpé làwọn Kristẹni o, wọ́n sì lè ṣàṣìṣe. (Róòmù 3:23) Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi gbọ́dọ̀ máa ní “ìfẹ́ni ará tí kò ní àgàbàgebè” nínú, kí wọ́n lè máa “nífẹ̀ẹ́ ara [wọn] lẹ́nì kìíní-kejì lọ́nà gbígbóná janjan láti inú ọkàn-àyà wá.” (1 Pétérù 1:22) “Bí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí fún ẹjọ́ lòdì sí ẹlòmíràn,” àwọn Kristẹni máa ń fi ìṣòtítọ́ tẹ̀ lé òfin Kristi nípa ‘bíbá a lọ ní fífaradà á fún ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì, wọ́n sì máa ń dárí ji ara wọn fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì.’ Ṣíṣègbọràn sí òfin yìí ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti máa gbójú fo ìkùdíẹ̀-káàtó ara wọn, wọ́n sì máa ń kíyè sí àwọn ànímọ́ rere tẹ́nì kọ̀ọ̀kan wọ́n ní tó lè mú kí wọ́n túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ara wọn. Ǹjẹ́ inú rẹ ò dùn pé o wà lára àwọn tí ìṣòtítọ́ wọn sí Ọba wa onífẹ̀ẹ́ ń mú kí wọ́n fi ìfẹ́ tó jẹ́ “ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé” wọ ara wọn láṣọ?—Kólósè 3:13, 14.

13 Síwájú sí i, Jésù ṣàlàyé pé ìfẹ́ tí òun fi àpẹẹrẹ rẹ̀ lélẹ̀ kọjá ìfẹ́ táwọn èèyàn sábà máa ń ní fún ọmọnìkejì wọn. (Jòhánù 13:34, 35) Tá a bá ń nífẹ̀ẹ́ kìkì àwọn tó nífẹ̀ẹ́ wa, a ò ṣe “ohun ara ọ̀tọ̀” kankan. Ìyẹn sì fi hàn pé ìfẹ́ wa kò pé ó sì lábùkù lọ́nà kan. Jésù rọ̀ wá pé ká fara wé Bàbá òun nípa níní ìfẹ́ tí a gbé karí ìlànà, ká tiẹ̀ tún nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá wa tó kórìíra wa tí wọ́n sì ń ṣe inúnibíni sí wa pẹ̀lú. (Mátíù 5:46-48) Ìfẹ́ yìí tún ń mú káwọn tí Kristi ń darí máa fi ìṣòtítọ́ bá iṣẹ́ pàtàkì tó gbé lé wọn lọ́wọ́ lọ láìjáwọ́. Iṣẹ́ wo nìyẹn?

Wọ́n Kojú Ìdánwò Ìgbàgbọ́

14. Kí nìdí tí iṣẹ́ ìwàásù náà fi ṣe pàtàkì gan-an?

14 Àwọn tó máa wà lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run ní iṣẹ́ bàǹtàbanta kan láti ṣe báyìí, ìyẹn ni iṣẹ́ “jíjẹ́rìí kúnnákúnná nípa ìjọba Ọlọ́run.” (Ìṣe 28:23) Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì gan-an nítorí pé Ìjọba Mèsáyà ni yóò fi hàn pé Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti máa ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ. (1 Kọ́ríńtì 15:24-28) Tá a bá ń wàásù ìhìn rere, àwọn olùgbọ́ wa á láǹfààní láti di ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. Ìyẹn nìkan kọ́ o, ohun táwọn èèyàn bá ṣe nípa ìhìn rere tí wọ́n gbọ́ ni Kristi Ọba fi máa dá olúkúlùkù wọn lẹ́jọ́. (Mátíù 24:14; 2 Tẹsalóníkà 1:6-10) Nítorí náà, ọ̀nà tó ṣe pàtàkì jù lọ tá a lè gbà fi hàn pé a jẹ́ olóòótọ́ sí Kristi ni pé ká ṣègbọràn sí àṣẹ tó pa fún wa pé ká sọ nípa Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn.—Mátíù 28:18-20.

15. Kí nìdí tí Èṣù fi ń dán ìṣòtítọ́ àwọn Kristẹni wò?

15 Láìsí àní-àní, a mọ̀ pé gbogbo ọ̀nà ni Sátánì ń gbà láti dènà iṣẹ́ ìwàásù náà, àti pé àwọn alákòóso èèyàn ò gbà pé Kristi ni Ọlọ́run gbé àṣẹ lé lọ́wọ́. (Sáàmù 2:1-3, 6-8) Abájọ tí Jésù fi kìlọ̀ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹrú kò tóbi ju ọ̀gá rẹ̀ lọ. Bí wọ́n bá ti ṣe inúnibíni sí mi, wọn yóò ṣe inúnibíni sí yín pẹ̀lú.” (Jòhánù 15:20) Ìdí nìyẹn táwọn ọmọlẹ́yìn Kristi fi bá ara wọn nínú jíja ogun tẹ̀mí tó ń dán ìṣòtítọ́ wọn wò.—2 Kọ́ríńtì 10:3-5; Éfésù 6:10-12.

16. Báwo làwọn ọmọ abẹ́ Ìjọba náà ṣe máa ń san ‘ohun tó jẹ́ ti Ọlọ́run padà fún Ọlọ́run’?

16 Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run ń jẹ́ olóòótọ́ nìṣó sí Ọba wọn tí kò ṣeé fojú rí láìsí pé wọ́n ń ṣàfojúdi sáwọn aláṣẹ ìjọba èèyàn. (Títù 3:1, 2) Jésù sọ pé: “Ẹ san àwọn ohun ti Késárì padà fún Késárì, ṣùgbọ́n àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.” (Máàkù 12:13-17) Ìdí nìyẹn táwọn tí Kristi ń darí fi máa ń ṣègbọràn sáwọn òfin ìjọba tí kò bá ta ko àwọn òfin Ọlọ́run. (Róòmù 13:1-7) Àmọ́ ṣá o, nígbà tí ilé ẹjọ́ gíga àwọn Júù ṣe ohun tó lòdì sí òfin Ọlọ́run, tí wọ́n sọ pé káwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù dáwọ́ iṣẹ́ ìwàásù wọn dúró, wọ́n sọ fún àwọn aláṣẹ náà tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ àmọ́ láìṣojo pé àwọn ní láti “ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.”—Ìṣe 1:8; 5:27-32.

17. Kí nìdí tó fi yẹ ká nígboyà tá a bá ń kojú àdánwò ìgbàgbọ́?

17 Ká sòótọ́, ó gba ìgboyà gidi káwọn tí Kristi ń darí tó lè jólóòótọ́ sí Ọba wọn nígbà táwọn èèyàn bá ń ṣenúnibíni sí wọn. Síbẹ̀, Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni yín nígbà tí àwọn ènìyàn bá gàn yín, tí wọ́n sì ṣe inúnibíni sí yín, tí wọ́n sì fi irọ́ pípa sọ gbogbo onírúurú ohun burúkú sí yín nítorí mi. Ẹ yọ̀, kí ẹ sì fò sókè fún ìdùnnú, níwọ̀n bí èrè yín ti pọ̀ ní ọ̀run.” (Mátíù 5:11, 12) Àwọn tó jẹ́ ọmọlẹ́yìn Kristi ní ìjímìjí fi hàn pé òótọ́ pọ́ńbélé lọ̀rọ̀ yẹn. Kódà nígbà táwọn aláṣẹ nà wọ́n nítorí pé wọn ò jáwọ́ nínú wíwàásù nípa Ìjọba náà, ńṣe ni wọ́n ń yọ̀ “nítorí a ti kà wọ́n yẹ fún títàbùkù sí nítorí orúkọ rẹ̀. Ní ojoojúmọ́ nínú tẹ́ńpìlì àti láti ilé dé ilé ni wọ́n sì ń bá a lọ láìdábọ̀ ní kíkọ́ni àti pípolongo ìhìn rere nípa Kristi náà, Jésù.” (Ìṣe 5:41, 42) A yìn yín lọ́pọ̀lọpọ̀ bí ẹ ṣe ń fi irú ìdúróṣinṣin yìí hàn nígbà tẹ́ ẹ bá ń fara da ìyà tàbí àìsàn, nígbà tí ọ̀fọ̀ bá ṣẹ̀ yín, tàbí tí ẹ̀ ń kojú àtakò.—Róòmù 5:3-5; Hébérù 13:6.

18. Kí lọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fún Pọ́ńtíù Pílátù fi hàn?

18 Nígbà tí Jésù ṣì jẹ́ Ọba Lọ́la, ó ṣàlàyé fún Gómìnà Róòmù nì, Pọ́ńtíù Pílátù pé: “Ìjọba mi kì í ṣe apá kan ayé yìí. Bí ìjọba mi bá jẹ́ apá kan ayé yìí, àwọn ẹmẹ̀wà mi ì bá ti jà kí a má bàa fà mí lé àwọn Júù lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí, ìjọba mi kì í ṣe láti orísun yìí.” (Jòhánù 18:36) Nítorí ìdí èyí, àwọn ọmọ abẹ́ Ìjọba ọ̀run kì í gbé ohun ìjà láti bá ẹnikẹ́ni jà bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í lọ́wọ́ nínú rògbòdìyàn èyíkéyìí tó bá ṣẹlẹ̀. Nítorí pé wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sí “Ọmọ Aládé Àlàáfíà,” wọn kì í dá sí àwọn àlámọ̀rí ayé tó pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ yìí rárá.—Aísáyà 2:2-4; 9:6, 7.

Èrè Ayérayé Fáwọn Tó Jólóòótọ́ sí Kristi

19. Kí nìdí tó fi yẹ kí ọkàn àwọn tó jólóòótọ́ sí Kristi balẹ̀ bí wọ́n ti ń retí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú?

19 Ọkàn àwọn tó jólóòótọ́ sí Kristi, “Ọba àwọn ọba,” balẹ̀ gan-an bí wọ́n ti ń retí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Wọ́n ń hára gàgà láti rí i bí Jésù á ṣe máa ti ọ̀run jọba lé ayé lórí lọ́nà kíkàmàmà láìpẹ́. (Ìṣípayá 19:11–20:3; Mátíù 24:30) Àwọn yòókù lára àwọn olóòótọ́ “ọmọ ìjọba náà” tá a fi ẹ̀mí yàn ń wọ̀nà fún ogún wọn ṣíṣeyebíye, ìyẹn bíbá Kristi jọba lókè ọ̀run. (Mátíù 13:38; Lúùkù 12:32) “Àwọn àgùntàn mìíràn” tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sí Kristi sì ń fi gbogbo ara retí rírí ìtẹ́wọ́gbà Ọba wọn nígbà tó bá polongo pé: “Ẹ wá, ẹ̀yin tí Baba mi ti bù kún, ẹ jogún [Párádísè orí ilẹ̀ ayé tó jẹ́ apákan] ìjọba tí a ti pèsè sílẹ̀ fún yín láti ìgbà pípilẹ̀ ayé.” (Jòhánù 10:16; Mátíù 25:34) Nítorí ìdí èyí, a rọ gbogbo àwọn tó jẹ ọmọ abẹ́ Ìjọba náà láti pinnu pé àwọn á máa jólóòótọ́ sí Kristi Ọba wọn títí lọ.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo ìwé Reasoning From the Scriptures, lábẹ́ àkọlé tó sọ pé: “Kí nìdí táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi sọ pé ọdún 1914 la fìdí Ìjọba Ọlọ́run múlẹ̀?” (èdè Gẹ̀ẹ́sì) ojú ìwé 95 sí 97. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.

Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?

• Kí nìdí tí Kristi fi yẹ lẹ́ni tá a ní láti jẹ́ olóòótọ́ sí?

• Ọ̀nà wo làwọn tí Kristi máa ṣàkóso lé lórí gbà ń fi ìṣòtítọ́ wọn hàn sí i?

• Kí nìdí tá a fi fẹ́ jẹ́ olóòótọ́ sí Kristi Ọba?

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 31]

ÀWỌN ÀNÍMỌ́ TÍTAYỌ MÌÍRÀN TÍ KRISTI TÚN NÍ

Àìṣègbè—Jòhánù 4:7-30.

Ìyọ́nú—Mátíù 9:35-38; 12:18-21; Máàkù 6:30-34.

Ìfẹ́ tó ń mú kó ló ara rẹ̀ fáwọn èèyàn—Jòhánù 13:1; 15:12-15.

Ìṣòtítọ́—Mátíù 4:1-11; 28:20; Máàkù 11:15-18.

Ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò—Máàkù 7:32-35; Lúùkù 7:11-15; Hébérù 4:15, 16.

Ìgbatẹnirò—Mátíù 15:21-28.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Tá a bá ń fìfẹ́ hàn sí ara wa, “òfin Kristi” là ń tẹ̀ lé yẹn

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Ǹjẹ́ àwọn ànímọ́ Kristi ń mú kó o jólóòótọ́ sí i láìjáwọ́?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́