Ẹ̀kọ́ Bíbélì Ń Mú Kí Ìgbàgbọ́ Lágbára
“ÀǸFÀÀNÍ ńláǹlà ló jẹ́ láti fi odindi oṣù márùn-ún kọ́ nípa èrò Ẹlẹ́dàá wa àti láti mọ bá a ṣe le máa wo àwọn nǹkan lọ́nà tó ń gbà wò wọ́n!” Èyí lohun tẹ́ni tó ṣojú kíláàsì kejìlélọ́gọ́fà [122] ti ilé ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead sọ lọ́jọ́ ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege wọn. Ọjọ́ mánigbàgbé ni ọjọ́ kẹwàá oṣù March, ọdún 2007 jẹ́ fáwọn mẹ́rìndínlọ́gọ́ta tí wọ́n fẹ́ lọ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ míṣọ́nnárì ní orílẹ̀-èdè mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n tá a yàn wọ́n sí.
Lẹ́yìn tí Arákùnrin Theodore Jaracz tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti kí ẹgbẹ̀rún mẹ́fà, igba ó lé márùn-ún èèyàn [6,205] káàbọ̀ tọ̀yàyàtọ̀yàyà, ó sọ pé: “Ó dá wa lójú pé wíwá tẹ́ ẹ wá síbi ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege yìí yóò jẹ́ kí àjọṣe àárín ẹ̀yin àti Ọlọ́run túbọ̀ dára sí i yóò sì mú kí ìgbàgbọ́ yín túbọ̀ lágbára sí i.” Ó wá dárúkọ àwọn mẹ́rin tó máa sọ̀rọ̀ tí wọ́n sì máa fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní ìṣírí àti ìmọ̀ràn tó dá lórí Bíbélì, èyí tó bọ́ sásìkò, tí yóò sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì wọn.
Ọ̀rọ̀ Ìṣírí Láti Ran Àwọn Mìíràn Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Nígbàgbọ́
Arákùnrin Leon Weaver tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, sọ̀rọ̀ lórí ẹṣin ọ̀rọ̀ tó sọ pé “Ẹ Máa Ṣe Ohun Tó Dára.” Ó rán àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà létí pé tá a bá pín in dọ́gba-dọ́gba, ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ti lo ọdún mẹ́tàlá nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún, tí wọ́n ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó ń mú kí ìgbàgbọ́ lágbára. Ó wá sọ pé: “Iṣẹ́ tó dára ni nítorí pé ó ń gba ẹ̀mí àwọn èèyàn là, àti pé èyí tó ṣe pàtàkì jù ni pé ó ń gbé Jèhófà, Bàbá wa ọ̀run ga.” Arákùnrin Weaver tún fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà níṣìírí láti máa bá a lọ láti máa ‘fúnrúgbìn lọ́nà tẹ̀mí’ kí wọ́n má sì ṣe “juwọ́ sílẹ̀ ní ṣíṣe ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀.”—Gálátíà 6:8, 9.
Arákùnrin David Splane tó jẹ́ ará Ìgbìmọ̀ Olùdarí sọ àwọn ọ̀rọ̀ ìṣílétí tó máa wúlò fún wọn gan-an. Ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni “Ẹ Rí I Dájú Pé Ìwà Yin Dára Gan-an.” Arákùnrin Splane gba àwọn míṣọ́nnárì tuntun yìí níyànjú pé kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ wọn lọ́nà tó dára gan-an, ó sì sọ àwọn nǹkan tó yẹ kí wọ́n máa ṣe, ó ní: “Ẹ máa ní èrò to dára. Ẹ má ṣe kù gììrì sọ pé irú ẹni báyìí lẹnì kán jẹ́. Ẹ jẹ́ ọlọ́yàyà. Ẹ má máa ṣàríwísí àwọn èèyàn. Ẹ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ kẹ́ ẹ sì máa bọ̀wọ̀ fáwọn ará níbi tẹ́ ẹ bá wà.” Ó tún fi kún un pé: “Bí ẹ bá ti ń sọ̀kalẹ̀ nínú ọkọ̀ òfuurufú ni kẹ́ ẹ ti máa fìwà tó dára hàn, Jèhófà á sì bù kún ẹsẹ yin tó dára rèǹtèrente bẹ́ ẹ ti ń mú ‘ìhìn rere ohun tí ó dára jù’ wá fáwọn èèyàn.”—Aísáyà 52:7.
Ẹṣin ọ̀rọ̀ tí Arákùnrin Lawrence Bowen tó jẹ́ olùkọ́ nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì gbé ọ̀rọ̀ rẹ̀ kà ni “Ogún Kan Tó Dájú.” Arákùnrin Bowen rán àwọn akẹ́kọ̀ọ́ létí pé orí ìgbàgbọ́ tó dájú nínú ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Jèhófà la gbé Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì kà nígbà tí wọ́n dá a sílẹ̀ nígbà Ogun Àgbáyé Kejì. (Hébérù 11:1; Ìṣípayá 17:8) Látìgbà yẹn ni ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì ti ń fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láǹfààní láti mú kí ìgbàgbọ́ wọn túbọ̀ lágbára sí i. Ìgbàgbọ́ tó lágbára yìí ló ń mú káwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ yege níbẹ̀ lọ máa fi tọkàntara kéde òtítọ́ fáwọn èèyàn.
Arákùnrin Mark Noumair tóun náà jẹ́ olùkọ́ nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì sọ̀rọ̀ lórí ẹṣin ọ̀rọ̀ kan tó fani mọ́ra tó pè ní “Ẹ Mú Mi Rántí Ẹnì Kan.” Ó tọ́ka sí àpẹẹrẹ wòlíì Èlíṣà tó ní ìgbàgbọ́ àti ìgboyà lẹ́nu iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé e lọ́wọ́. Arákùnrin Noumair gbé ọ̀rọ̀ rẹ̀ ka 1 Àwọn Ọba 19:21, ó sọ pé: “Èlíṣà múra tán láti yí ọ̀nà tó ń gbà gbé ìgbésí ayé rẹ̀ padà, ó fi àwọn ohun tó nífẹ̀ẹ́ sí sípò kejì, ó sì fi ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Jèhófà ṣíwájú.” Ó gbóríyìn fáwọn akẹ́kọ̀ọ́yege náà pé wọ́n ti ṣe irú ohun tí Èlíṣà ṣe yẹn, ó sì gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n máa bá a lọ láti máa ṣe bẹ́ẹ̀ níbi tí wọ́n ń lọ.
Ìgbàgbọ́ Ń Mú Kéèyàn Lè Sọ̀rọ̀ Fàlàlà
Báwọn míṣọ́nnárì tuntun ti ń mú kí ìgbàgbọ́ wọn lágbára nígbà tí wọ́n wà nílé ẹ̀kọ́, ni wọ́n tún ń lo àwọn òpin ọ̀sẹ̀ láti wàásù ìhìn rere fáwọn èèyàn. Èyí mú kí wọ́n lè sọ àwọn ohun dáadáa tó ṣẹlẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù náà, wọ́n sì ṣàṣefihàn wọn nínú ọ̀rọ̀ tí Arákùnrin Wallace Liverance, tóun náà jẹ́ olùkọ́ nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì sọ. Ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó pè ní “A Lo Ìgbàgbọ́, Nítorí Náà A Sọ̀rọ̀” jẹ́ ká rántí ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó wà nínú 2 Kọ́ríńtì 4:13.
Àwọn tí wọ́n tún sọ̀rọ̀ lẹ́yìn èyí ní Arákùnrin Daniel Barnes àti Charles Woody tí wọ́n jẹ́ ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì. Wọ́n fọ̀rọ̀ wá àwọn tó jẹ́ míṣọ́nnárì tẹ́lẹ̀ rí lẹ́nu wò àtàwọn tó ń ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì lọ́wọ́lọ́wọ́. Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò yìí fi hàn pé Jèhófà ń bójú tó àwọn tó ń sìn ín tọkàntọkàn, ó sì ń bù kún wọn. (Òwe 10:22; 1 Pétérù 5:7) Míṣọ́nnárì kan sọ pé: “Látinú ẹ̀kọ́ tí èmi àti ìyàwó mi gbà nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì, a ti rí i dájú pé Jèhófà ń bójú tó wa. Èyí mú kí ìgbàgbọ́ wa lágbára sí i. Ìgbàgbọ́ ṣe pàtàkì nítorí pé gbogbo ìránṣẹ́ Ọlọ́run, títí kan àwọn míṣọ́nnárì, ló mọ̀ pé a máa rí àdánwò àti ìṣòro, a ó sì máa ṣàníyàn.”
Máa Kọ́ni Ní Ẹ̀kọ́ Bíbélì Tó Ń Mú Kí Ìgbàgbọ́ Lágbára Sí I
Ọ̀nà tó dára gan-an ni Arákùnrin Samuel Herd tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí gbà mú ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege náà wá sí ìparí. Ẹṣin ọ̀rọ̀ tó fi bá àwùjọ náà sọ̀rọ̀ ni “Ẹ Máa Mú Ìgbàgbọ́ Àwọn Ará Lágbára Sí I.” Kí nìdí tẹ́yin akẹ́kọ̀ọ́ fi gbà ẹ̀kọ́ yìí? Arákùnrin Herd sọ pé: “Ìdí tẹ́ ẹ fi gbà á ni ká lè kọ́ yín bẹ́ ẹ ṣe lè fi ahọ́n yín yin Jèhófà, bẹ́ ẹ ṣe lè kọ́ni ní òtítọ́ níbi tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn yín sí àti bẹ́ ẹ ṣe lè mú kí ìgbàgbọ́ ọmọnìkejì yín lágbára sí i.” Síbẹ̀, ó rán àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà létí pé ahọ́n tún lè sọ àwọn ohun tí kò lè ṣeni láǹfààní. (Òwe 18:21; Jákọ́bù 3:8-10) Ó gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà níyànjú láti máa lo ahọ́n wọn lọ́nà tí Jésù gbà lo ahọ́n rẹ̀. Nígbà kan táwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù gbọ́rọ̀ rẹ̀ tán, wọ́n fèsì pé: “Ọkàn-àyà wa kò ha ń jó fòfò bí ó ti . . . ń ṣí Ìwé Mímọ́ payá fún wa lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́?” (Lúùkù 24:32) Arákùnrin Herd wá sọ pé: “Bí ọ̀rọ̀ yin bá dára, yóò fún àwọn arákùnrin àti arábìnrin yín níṣìírí níbi tá a yàn yín sí.”
Lẹ́yìn ìyẹn làwọn akẹ́kọ̀ọ́yege gba ìwé ẹ̀rí dípúlọ́mà wọn. Lẹ́yìn náà wọ́n ka lẹ́tà ìmọrírì tí kíláàsì náà kọ. Lẹ́tà náà sọ pé: “A óò rí i dájú pé a lo gbogbo ohun tá a ti kọ́ nílé ẹ̀kọ́ yìí lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì wa. Bá a ti múra tán láti lọ sáwọn ibi tó jìnnà lórí ilẹ̀ ayé, àdúrà wa ni pé kí ìsapá wa mú ọ̀pọ̀ ìyìn bá Jèhófà Ọlọ́run, Olùkọ́ni wa Atóbilọ́lá.” Àwọn tó wà ní ìjókòó pàtẹ́wọ́ tó rinlẹ̀ gan-an. Ká sòótọ́, ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege náà ti mú kí ìgbàgbọ́ àwọn tó wá síbẹ̀ túbọ̀ lágbára sí i.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 17]
“Bí ọ̀rọ̀ yin bá dára, yóò fún àwọn arákùnrin àti arábìnrin yín níṣìírí níbi tá a yàn yín sí”
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 15]
ÌSỌFÚNNI NÍPA KÍLÁÀSÌ
Iye orílẹ̀-èdè táwọn akẹ́kọ̀ọ́ ti wá: 9
Iye orílẹ̀-èdè tá a yàn wọ́n sí: 26
Iye àwọn akẹ́kọ̀ọ́: 56
Ìpíndọ́gba ọjọ́ orí wọn: 33.4
Ìpíndọ́gba ọdún tí wọ́n ti lò nínú òtítọ́: 16.8
Ìpíndọ́gba ọdún tí wọ́n ti lò nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún: 13
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Kíláàsì Kejìlélọ́gọ́fà Tó Kẹ́kọ̀ọ́ Yege Nílé Ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead
Nínú ìlà àwọn orúkọ tí ń bẹ nísàlẹ̀ yìí, nọ́ńbà kọ̀ọ̀kan jẹ́ láti iwájú lọ sẹ́yìn, a sì to orúkọ láti ọwọ́ òsì sí ọwọ́ ọ̀tún lórí ìlà kọ̀ọ̀kan.
(1) Howitt, R.; Smith, P.; Martinez, A.; Pozzobon, S.; Kitamura, Y.; Laud, C. (2) Fiedler, I.; Beasley, K.; Matkovich, C.; Bell, D.; Lippincott, W. (3) Sites, W.; Andersen, A.; Toevs, L.; Fusano, G.; Rodríguez, C.; Yoo, J. (4) Sobomehin, M.; Thomas, L.; Gasson, S.; Dauba, V.; Bertaud, A.; Winn, C.; Dobrowolski, M. (5) Yoo, J.; Dauba, J.; Mixer, H.; Newton, M.; Rodríguez, F.; Mixer, N. (6) Laud, M.; Lippincott, K.; Martinez, R.; Haub, A.; Schamp, R.; Pozzobon, L.; Toevs, S. (7) Howitt, S.; Kitamura, U.; Newton, D.; Haub, J.; Sites, J.; Thomas, D. (8) Sobomehin, L.; Matkovich, J.; Fusano, B.; Winn, J.; Schamp, J.; Andersen, D.; Dobrowolski, J. (9) Fiedler, P.; Bell, E.; Beasley, B.; Smith, B.; Bertaud, P.; Gasson, M.