ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 10/15 ojú ìwé 12-15
  • Máa Lọ Síhà Ìmọ́lẹ̀ Náà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Máa Lọ Síhà Ìmọ́lẹ̀ Náà
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Má Ṣe Jẹ́ Kí ‘Ọkọ̀ Ìgbàgbọ́ Rẹ Rì’
  • Nítòsí Ilẹ̀ Ìlérí
  • Àwọn Ohun Tó Máa Mú Ká Wà Lójúfò
  • Ṣọ́ra fún Ayédèrú Ìmọ́lẹ̀
  • Awọn Wo ni Wọn Ń Tẹle Ìmọ́lẹ̀ Ayé?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ẹ Tẹle Ìmólẹ̀ Ayé Naa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Awọn Olùtan Ìmọ́lẹ̀—Fun Ète Wo?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ìmọ́lẹ̀ Ọlọ́run Ń lé Òkùnkùn Dà Nù!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 10/15 ojú ìwé 12-15

Máa Lọ Síhà Ìmọ́lẹ̀ Náà

Ọ̀PỌ̀ ẹ̀mí ni ìmọ́lẹ̀ tó ń tọ́ ọkọ̀ òkun sọ́nà tó máa ń wà lórí ilé ìmọ́lẹ̀ létí òkun ti gbà là. Tí arìnrìn-àjò tó ti rẹ̀ tẹnutẹnu bá rí iná náà lọ́ọ̀ọ́kán, á mọ̀ pé ńṣe ló ń ki àwọn nílọ̀ pé àpáta tàbí òkìtì yanrìn wà níbẹ̀. Àmọ́ ìmọ́lẹ̀ yẹn máa ń ṣe nǹkan míì. Ó tún ń jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé wọ́n ti sún mọ́ èbúté. Lọ́nà tó jọ ìyẹn, àwọn Kristẹni lóde òní ń sún mọ́ òpin ìrìn àjò gígùn kan. Inú ayé tó ṣókùnkùn yìí tó sì lè ba àjọṣe ẹni pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́ sì ni wọ́n ti ń rin ìrìn àjò náà. Bíbélì sọ pé ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn, ìyẹn àwọn ọmọ aráyé tí wọ́n jìnnà sí Ọlọ́run, dà bí “òkun tí a ń bì síwá bì sẹ́yìn, nígbà tí kò lè rọ̀ wọ̀ọ̀, èyí tí omi rẹ̀ ń sọ èpò òkun àti ẹrẹ̀ sókè.” (Aísáyà 57:20) Irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ ló yí àwọn èèyàn Ọlọ́run ká. Síbẹ̀, àwọn èèyàn Ọlọ́run ní ìrètí tó dájú pé àwọn á rí ìgbàlà, èyí tó dà bí ìmọ́lẹ̀ tí kì í ṣini lọ́nà. (Míkà 7:8) Jèhófà àti Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ti mú kí “ìmọ́lẹ̀ . . . kọ mànà fún olódodo, àti ayọ̀ yíyọ̀ àní fún àwọn adúróṣánṣán ní ọkàn-àyà.”—Sáàmù 97:11.a

Àmọ́, àwọn Kristẹni kan ti jẹ́ kí àwọn ohun tó ń pín ọkàn níyà nínú ayé yìí tan àwọn kúrò níbi ìmọ́lẹ̀ Jèhófà, èyí tó mú kí ọkọ̀ ìgbàgbọ́ wọn rì. Ohun tó mú kí ọkọ̀ ìgbàgbọ́ wọn rì yìí la lè fi wé àwọn àpáta tó fara sin, irú bí ìfẹ́ ọrọ̀, ìṣekúṣe tàbí ìpẹ̀yìndà pàápàá. Bẹ́ẹ̀ ni, “ọkọ̀ ìgbàgbọ́” àwọn kan ti “rì” lóde òní bíi tàwọn Kristẹni kan ní ọ̀rúndún kìíní. (1 Tímótì 1:19; 2 Pétérù 2:13-15, 20-22) Ayé tuntun dà bí èbúté tá à ń lọ gúnlẹ̀ sí. Níwọ̀n bó sì ti sún mọ́lé gan-an báyìí, ẹ ẹ̀ rí i pé ohun ìbànújẹ́ ló máa jẹ́ téèyàn bá lọ pàdánù ojú rere Jèhófà!

Má Ṣe Jẹ́ Kí ‘Ọkọ̀ Ìgbàgbọ́ Rẹ Rì’

Láyé àtijọ́, ọkọ̀ òkun kan lè ti la agbami òkun kọjá kó sì wá rì nígbà tó kù díẹ̀ kó dé èbúté. Ìgbà tó sábà máa ń léwu jù ni ìgbà tí ọkọ̀ òkun bá ń sún mọ́ èbúté. Bákan náà, ìgbà tó léwu jù lọ fún ọ̀pọ̀ èèyàn ni “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ètò àwọn nǹkan tá a wà yìí. Bó ṣe rí gan-an ni Bíbélì sọ ọ́, pé àwọn ọjọ́ ìkẹyìn “nira láti bá lò,” pàápàá jù lọ fún àwa Kristẹni tá a ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run.—2 Tímótì 3:1-5.

Kí nìdí tí àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí fi le koko tó bẹ́ẹ̀? Ṣó o rí i, Sátánì mọ̀ pé “àkókò kúkúrú” ló ṣẹ́ kù fóun láti fi gbógun ti àwọn èèyàn Ọlọ́run. Ìdí nìyẹn tó fi túbọ̀ ń sapá kíkankíkan láti lè ri ọkọ̀ ìgbàgbọ́ wa. (Ìṣípayá 12:12, 17) Àmọ́ a lẹ́ni tó ń ràn wá lọ́wọ́ tó sì ń tọ́ wa sọ́nà. Jèhófà ń bá a nìṣó láti jẹ́ ibi ààbò, fáwọn tó ń tẹ̀ lé ìtọ́ni rẹ̀. (2 Sámúẹ́lì 22:31) Ó jẹ́ ká mọ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ kan nígbà láéláé, èyí tó jẹ́ ká mọ ọgbọ́n àrékérekè tí Sátánì máa ń lò. Ẹ jẹ́ ká wo méjì lára àpẹẹrẹ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tó kù díẹ̀ kí wọ́n dé Ilẹ̀ Ìlérí.—1 Kọ́ríńtì 10:11; 2 Kọ́ríńtì 2:11.

Nítòsí Ilẹ̀ Ìlérí

Mósè ló kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní Íjíbítì. Kò sì pẹ́ tí wọ́n fi dé ààlà Ilẹ̀ Ìlérí lápá gúúsù. Mósè wá rán ọkùnrin méjìlá pé kí wọ́n lọ ṣamí Ilẹ̀ náà. Mẹ́wàá lára àwọn amí náà ò nígbàgbọ́, ìròyìn tí ò dáa ni wọ́n mú bọ̀. Wọ́n ní apá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò ní lè ká àwọn ará Kénáánì nítorí pé wọ́n “tóbi lọ́nà àrà ọ̀tọ̀” wọ́n sì ní ẹgbẹ́ ọmọ ogun tó lágbára ju tàwọn lọ. Ipa wo ni ìròyìn búburú yìí ní lórí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì? Àkọsílẹ̀ náà sọ fún wa pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kùn sí Mósè àti Áárónì, wọ́n ní: “Èé . . . ṣe tí Jèhófà fi ń mú wa bọ̀ ní ilẹ̀ yìí láti tipa idà ṣubú? Àwọn aya wa àti àwọn ọmọ wa kéékèèké yóò di ohun tí a piyẹ́. . . . Ẹ jẹ́ kí a yan olórí sípò, kí a sì padà sí Íjíbítì!”—Númérì 13:1, 2, 28-32; 14:1-4.

Ẹ gbọ́ ná, ṣé kì í ṣe àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yìí kan náà ló fojú ara wọn rí bí Jèhófà ṣe fi ìyọnu mẹ́wàá àti iṣẹ́ ìyanu ńlá tó ṣe ní Òkun Pupa han orílẹ̀-èdè Íjíbítì alágbára tó ń ṣàkóso ayé nígbà yẹn léèmọ̀ ni? Kẹ́ sì máa wò ó o, díẹ̀ ló kù kí wọ́n dé Ilẹ̀ Ìlérí. Ẹnu pé kí wọ́n kàn máa lọ síbẹ̀ ni bí ìgbà ti ọkọ̀ òkun bá ń lọ síbi ìmọ́lẹ̀ tó ń jẹ́ kó mọ èbúté tó máa gúnlẹ̀ sí. Síbẹ̀, wọ́n rò pé Jèhófà ò lágbára láti ṣẹ́gun àwọn ìlú tó wà ní Kénáánì tó jẹ́ pé ńṣe ni kálukú wọn ń dájọba ara rẹ̀ ṣe. Kò sí àní-àní pé ìjákulẹ̀ gbáà ni ìwà àìnígbàgbọ́ wọn yìí jẹ́ fún Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ náà ló sì jẹ́ fún àwọn amí tó nígboyà náà, ìyẹn Jóṣúà àti Kálébù tí wọ́n nígbàgbọ́ pé bí i “oúnjẹ” ni Kénáánì “jẹ́ fún” Ísírẹ́lì. Jóṣúà àti Kálébù mọ báwọn ará Kénáánì ṣe jẹ́ gan-an, torí wọ́n fúnra wọn rìn la Kénáánì kọjá. Nígbà tó wá di pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ̀nyẹn ò lè wọ Ilẹ̀ Ìlérí mọ́, Jóṣúà àti Kálébù ṣì ní láti máa bá wọn rìn káàkiri nínú aginjù fún ọ̀pọ̀ ọdún, àmọ́ àwọn ò kú sínú aginjù ní tiwọn. Àwọn tí kò nígbàgbọ́ ló kú. Kódà, Jóṣúà àti Kálébù ló ṣáájú ìran tó dé lẹ́yìn àwọn tó kú yẹn la aginjù kọjá tí wọ́n sì kó wọn lọ sí Ilẹ̀ Ìlérí. (Númérì 14:9, 30) Àmọ́ nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì dé ìtòsí Ilẹ̀ Ìlérí ní ẹlẹ́ẹ̀kejì yìí, wọ́n tún rí ìdánwò míì. Kí ni wọ́n máa wá ṣe?

Bálákì ọba Móábù ní kí wòlíì èké kan tó ń jẹ́ Báláámù bá òun gégùn-ún fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Àmọ́ Jèhófà ò jẹ́ kí Báláámù lè gbé wọn ṣépè, ńṣe ló mú kó súre fún wọn. (Númérì 22:1-7; 24:10) Kàkà kí Báláámù kiwọ́ ọmọ rẹ bọṣọ nítorí ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn, ńṣe ló tún ronú nǹkan míì tóun lè fi ṣàkóbá fáwọn èèyàn Ọlọ́run kí wọ́n má bàa dé ilẹ̀ náà. Ọgbọ́n wo ló ta? Ọgbọ́n tó dá ni pé kí wọ́n tan àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti ṣèṣekúṣe kí wọ́n sì bọ òrìṣà tí wọ́n ń pè ní Báálì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ jù lọ ọmọ Ísírẹ́lì ni ọgbọ́nkọ́gbọ́n yẹn ò mú, síbẹ̀, ó mú ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélógún [24, 000] lára wọn. Àwọn yẹn bá àwọn obìnrin Móábù ṣèṣekúṣe wọ́n sì bọ òrìṣà Báálì ti Péórù.—Númérì 25:1-9.

Kẹ́ ẹ sì máa wò ó o, ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ̀nyẹn ti fojú ara wọn rí bí Jèhófà ṣe mú wọn la “aginjù ńlá àti amúnikún-fún-ẹ̀rù yẹn kọjá” láìséwu. (Diutarónómì 1:19) Síbẹ̀, nígbà tó kù díẹ̀ kí wọ́n dé Ilẹ̀ Ìlérí, ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélógún [24, 000] lára wọn jẹ́ kí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara borí wọn, Jèhófà sì pa wọ́n. Ìkìlọ̀ lèyí jẹ́ fáwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run lónìí bá a ṣe ń sún mọ́ ogún tó ju Ilẹ̀ Ìlérí lọ fíìfíì!

Bí Sátánì ṣe ń sa ipá àsàkẹ́yìn láti mú kọ́wọ́ àwa ìránṣẹ́ Jèhófà òde òní má tẹ èrè tí Jèhófà fẹ́ fún wa, kò lọ́gbọ́n míì tó ń lò yàtọ̀ sáwọn tó ti lò tẹ́ lẹ̀. Sátánì máa ń lo ìhalẹ̀mọ́ni, inúnibíni tàbí ìfiniṣẹ̀sín láti lè mú ká ṣiyèméjì, èyí sì mú ká rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà àkọ́kọ́ tí wọ́n dé ìtòsí Ilẹ̀ Ìlérí. Àwọn Kristẹni kan sì ti jẹ́ kírú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ gbé wọn ṣubú. (Mátíù 13:20, 21) Nǹkan míì tí Sátánì máa ń lò tó sì máa ń jẹ́ ẹ lọ́wọ́ ni sísọni di oníwà ìbàjẹ́. Nígbà míì, àwọn kan tí wọ́n yọ́ wọnú ìjọ máa ń kó èèràn ìwà ìbàjẹ́ ran àwọn tí òtítọ́ ò jinlẹ̀ nínú wọn tí wọn ò sì rìn nínú ìmọ́lẹ̀ Ọlọ́run bó ṣe yẹ.—Júúdà 8, 12-16.

Àmọ́ àwọn tí àjọṣe àárín àwọn àti Ọlọ́run jinlẹ̀ tí wọ́n sì ń kíyè sára mọ̀ pé bí ayé ṣe ń rì sínú ìwà ìbàjẹ́ sí i yìí jẹ́ ẹ̀rí tó fi hàn gbangba pé Sátánì ń sa gbogbo ipá rẹ̀ kó lè rí àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run mú. Sátánì mọ̀ pé láìpẹ́ sígbà tá a wà yìí, ọwọ́ òun ò ní lè tẹ̀ wá mọ́. Nítorí náà, àkókò yìí gan-an ló yẹ ká máa kíyè sára ká lè mọ àwọn ọgbọ́n tí Sátánì ń lò láti fi ba àjọṣe àárín àwa àti Ọlọ́run jẹ́.

Àwọn Ohun Tó Máa Mú Ká Wà Lójúfò

Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé Ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run jẹ́ “fìtílà tí ń tàn ní ibi tí ó ṣókùnkùn,” nítorí pé ó máa ń jẹ́ káwa Kristẹni rí ohun tí Jèhófà ń ṣe láti mú àwọn ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ ká sì lóye rẹ̀. (2 Pétérù 1:19-21) Àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí wọ́n sì jẹ́ kó máa tọ́ àwọn sọ́nà rí i pé Jèhófà yóò mú kí ipa ọ̀nà àwọn tọ́. (Òwe 3:5, 6) Ìrètí tí irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ tí wọ́n moore ní mú kí wọ́n máa “fi ìdùnnú ké jáde nítorí ipò rere ọkàn-àyà.” Àmọ́ àwọn tí kò mọ Jèhófà tàbí tí wọ́n fi ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀ ń ní “ìrora ọkàn-àyà” àti “ìrẹ̀wẹ̀sì tí ó bùáyà.” (Aísáyà 65:13, 14) Nítorí náà, tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì dáadáa tá a sì ń fi ohun tá à ń kọ́ sílò, a óò lè pọkàn pọ̀ sórí ìrètí tó dájú tí Ọlọ́run fún wa dípò ká máa wo adùn ayé yìí tó jẹ́ pé díẹ̀ ló kù kó kọjá lọ.

Àdúrà gbígbà lohun pàtàkì míì tó lè mú ká wà lójúfò kí ohunkóhun má bàa ba àjọṣe àwa àti Ọlọ́run jẹ́. Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa òpin ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí, ó ní: “Ẹ máa wà lójúfò, nígbà náà, ní rírawọ́ ẹ̀bẹ̀ ní gbogbo ìgbà, kí ẹ lè kẹ́sẹ járí ní yíyèbọ́ nínú gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí a ti yàn tẹ́lẹ̀ láti ṣẹlẹ̀, àti ní dídúró níwájú Ọmọ ènìyàn.” (Lúùkù 21:34-36) Kíyè sí i pé Jésù lo ọ̀rọ̀ náà, ‘ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀,’ èyí tó jẹ́ àdúrà téèyàn fi taratara gbà. Jésù mọ̀ pé ó ṣeé ṣe kí ìyè àìnípẹ̀kun bọ́ mọ́ọ̀yàn lọ́wọ́ lákòókò tó ṣe kókó yìí. Ǹjẹ́ àdúrà rẹ máa ń fi hàn pé ó wù ẹ́ gan-an láti wà lójúfò kí ohunkóhun má bàa ba àjọṣe àárín ìwọ àti Ọlọ́run jẹ́?

Ẹ má ṣe jẹ́ ká gbàgbé pé ó lẹ̀ jẹ́ pé ìgbà tó kù díẹ̀ ká dé èbúté tá a ti máa gba ogún wa yìí ló máa ṣòro jù nínú ìrìn àjò wa. Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì gan-an ká wà lójúfò ká a má bàa dẹni tí kò rí ìmọ́lẹ̀ tó máa tọ́ wa sọ́nà la ayé yìí já sí ìyè àìnípẹ̀kun.

Ṣọ́ra fún Ayédèrú Ìmọ́lẹ̀

Láyé ìgbà táwọn èèyàn sábà máa ń fi ọkọ̀ òkun onígbòkun rìnrìn àjò, àwọn èèyànkéèyàn máa ń ṣe nǹkan kan tó jẹ́ ewu fún àwọn awakọ̀ òkun, alẹ́ tí kò sì sí òṣùpá ni wọ́n máa ń ṣe é, torí wọ́n mọ̀ pé àwọn awakọ̀ ò ní lè rí èbúté dáadáa. Àwọn èèyànkéèyàn náà lè gbé iná sí etíkun tó léwu láti tan àwọn awakọ̀ lọ síbi tí kò dára. Ọkọ̀ àwọn tí ẹ̀tàn náà bá mú lè rì, àwọn èèyànkéèyàn náà á sì jí wọ́n lẹ́rù kó, ẹ̀mí sì tún lè ṣòfò.

Ọgbọ́n tí Sátánì náà máa ń dá nìyẹn. Ó máa ń ṣe bí “áńgẹ́lì ìmọ́lẹ̀,” láti lè já àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run gbà mọ́ wa lọ́wọ́. Èṣù lè lo àwọn “èké àpọ́sítélì” àtàwọn apẹ̀yìndà tí wọ́n ń pera wọn ní “òjíṣẹ́ òdodo” láti tan àwọn tí kò fura jẹ. (2 Kọ́ríńtì 11:13-15) Àmọ́ bí ayédèrú iná ò ṣe ní tan awakọ̀ òkun tó nírìírí dáadáa àtàwọn tó ń bá a ṣiṣẹ́ jẹ tí wọ́n bá kíyè sára, bẹ́ẹ̀ ni àwọn tó ń tan ẹ̀kọ́ èké àti ọgbọ́n ayé yìí tó lè pani lára kálẹ̀ ò ṣe ní lè tan àwa Kristẹni jẹ tó bá jẹ́ pé a “tipasẹ̀ lílò kọ́ agbára ìwòye [wa] láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.”—Hébérù 5:14; Ìṣípayá 2:2.

Àwọn awakọ̀ òkun máa ń ní àkọsílẹ̀ àwọn ilé ìmọ́lẹ̀ tó ń tọ́ ọkọ̀ òkun sọ́nà tí wọ́n máa rí nígbà ìrìn àjò wọn. Àkọsílẹ̀ náà sọ ohun tí wọ́n máa fi dá ilé ìmọ́lẹ̀ kọ̀ọ̀kan mọ̀, to fi mọ́ iná rẹ̀ tó yàtọ̀ sí tàwọn tó kù. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia sọ pé: “Táwọn awakọ̀ òkun bá rí ilé ìmọ́lẹ̀ kan, wọ́n máa ń kíyè sí àwọn ohun tí ilé ìmọ́lẹ̀ náà fi yàtọ̀ sáwọn tó kù wọ́n á sì yẹ àkọsílẹ̀ wò kí wọ́n lè mọ ilé ìmọ́lẹ̀ tó jẹ́ gan-an. Wọ́n á wá tipa bẹ́ẹ̀ mọ ibi tí wọ́n wà.” Bẹ́ẹ̀ ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe máa ń ran àwọn tó mọyì òtítọ́ lọ́wọ́ láti dá ìsìn tòótọ́ mọ̀, àtàwọn tó ń ṣe é, pàápàá láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí tí Jèhófà tí gbé ìsìn tòótọ́ lékè ìsìn èké. (Aísáyà 2:2, 3; Málákì 3:18) Ìwé Aísáyà 60:2, 3 sọ ìyàtọ̀ gédégédé tó wà láàárín ìsìn tòótọ́ àti ìsìn èké, ó ní: “Òkùnkùn pàápàá yóò bo ilẹ̀ ayé, ìṣúdùdù nínípọn yóò sì bo àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè; ṣùgbọ́n Jèhófà yóò tàn sára rẹ, a ó sì rí ògo rẹ̀ lára rẹ. Dájúdájú, àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì lọ sínú ìmọ́lẹ̀ rẹ, àwọn ọba yóò sì lọ sínú ìtànyòò tí ó wá láti inú ìtànjáde rẹ.”

Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ìmọ́lẹ̀ Jèhófà ló ń tọ́ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn látinú gbogbo orílẹ̀-èdè sọ́nà, ọkọ̀ ìgbàgbọ́ wọn ò ní rì léyìí tó ku díẹ̀ kí wọ́n dé èbúté yìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n á la àkókò tó ṣẹ́ kù fún ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí já, wọ́n á sì gúnlẹ̀ sínú ayé tuntun alálàáfíà tí ewu kankan ò ti ní wu wọ́n mọ́.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ìwé Mímọ́ lo “ìmọ́lẹ̀” lọ́nà àpẹẹrẹ láwọn ọ̀nà mélòó kan. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé Ọlọ́run jẹ́ ìmọ́lẹ̀. (Sáàmù 104:1, 2; 1 Jòhánù 1:5) Ìwé Mímọ́ fi àwọn nǹkan tá a mọ̀ nípa Ọlọ́run àtàwọn ohun tó fẹ́ ṣe tá a rí nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ wé ìmọ́lẹ̀. (Aísáyà 2:3-5; 2 Kọ́ríńtì 4:6) Ìmọ́lẹ̀ ni Jésù jẹ́ nígbà tó ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. (Jòhánù 8:12; 9:5; 12:35) Jésù sì pàṣẹ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ wọn máa tàn.—Mátíù 5:14, 16.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Àwa Kristẹni ń kíyè sára bí àwọn awakọ̀ òkun kí ayédèrú iná má bàa tàn wá jẹ

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́