OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
Báwo lo ṣe lè kọ́ àwọn ọmọ rẹ láti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run?
Fi àpẹẹrẹ àwọn ohun tí Ọlọ́run dá kọ́ àwọn ọmọ rẹ nípa Ọlọ́run kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ rẹ̀
Táwọn ọmọ rẹ bá mọ̀ pé lóòótọ́ ni Ọlọ́run wà, tó sì fẹ́ràn wọn, wọ́n á nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Àmọ́, wọ́n gbọ́dọ̀ mọ Ọlọ́run kí wọ́n tó lè nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. (1 Jòhánù 4:8) Bí àpẹẹrẹ, wọ́n gbọ́dọ̀ lóye àwọn ìbéèrè bíi, kí ló dé tí Ọlọ́run fi dá àwa èèyàn? Kí nìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìyà? Kí ni Ọlọ́run máa ṣe fún wa lọ́jọ́ iwájú?—Ka Fílípì 1:9.
Kó o tó lè ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, ìwọ alára gbọ́dọ̀ jẹ́ kí wọ́n rí i pé o nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. Tí wọ́n bá rí bó o ṣe nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tó, èyí á sún àwọn náà láti nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.—Ka Diutarónómì 6:5-7; Òwe 22:6.
Báwo lo ṣe lẹ̀ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ wọ àwọn ọmọ rẹ lọ́kàn?
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lágbára. (Hébérù 4:12) Torí náà, kọ́ àwọn ọmọ rẹ ní àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì tó wà nínú Bíbélì. Kí ohun tí Jésù sọ lè wọ àwọn èèyàn lọ́kàn, ó máa ń lo ìbéèrè, ó tún máa ń fetí sílẹ̀ sí ohun tí wọ́n bá sọ, á sì ṣàlàyé Ìwé Mímọ́ fún wọn lẹ́sẹẹsẹ. Ìwọ náà lè fara wé ọ̀nà tí Jésù gbà ń kọ́ni kí ọ̀rọ̀ rẹ lè wọ àwọn ọmọ rẹ lọ́kàn.—Ka Lúùkù 24:15-19, 27, 32.
Bákan náà, àwọn ìtàn inú Bíbélì máa ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti mọ Ọlọ́run kí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Wàá rí àwọn ìwé tó dá ló rí ìtàn Bíbélì lórí ìkànnì www.jw.org/yo.—Ka 2 Tímótì 3:16.