KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | O LÈ LÓYE BÍBÉLÌ
Ohun Tó Máa Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́ Láti Lóye Bíbélì
Ká sọ pé o lọ sí orílẹ̀-èdè míì fún ìgbà àkọ́kọ́. O wá rí i pé gbogbo nǹkan ní ilẹ̀ yẹn ló yàtọ̀ sí tìẹ, bí owó tí wọ́n ń ná, àwọn èèyàn tó ń gbé níbẹ̀, àṣà wọn, àti oúnjẹ wọn. Kò sí àní-àní pé gbogbo nǹkan á tojú sú ẹ.
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé bó ṣe máa rí nìyẹn nígbà àkọ́kọ́ tó o ka Bíbélì. Ó máa dà bíi pé o pa dà sáyé àtijọ́, tí gbogbo nǹkan ti ṣàjèjì sí ẹ. Níbẹ̀, wàá rí àwọn èèyàn tí wọ́n ń pè ní àwọn Filísínì, wàá tún rí àwọn àṣà wọn tó máa yà ẹ́ lẹ́nu bíi ‘gbígbọn ẹ̀wù ya,’ àti oúnjẹ tí wọ́n ń pè ní mánà tàbí ẹyọ owó tí wọ́n mọ̀ sí dírákímà. (Ẹ́kísódù 16:31; Jóṣúà 13:2; 2 Sámúẹ́lì 3:31; Lúùkù 15:9) Ó ṣeé ṣe káwọn nǹkan tó o kà máà yé ẹ. Àmọ́, bíi ti ẹni tó lọ sí ilẹ̀ òkèèrè, ṣé inú rẹ kò ní dùn tó o bá rí ẹni tó máa ṣàlàyé àwọn nǹkan wọ̀nyí fún ẹ?
OHUN TÓ RAN ÀWỌN ÈÈYÀN LỌ́WỌ́ LÁTI LÓYE BÍBÉLÌ LÁYÉ ÀTIJỌ́
Láti ìgbà tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ kíkọ Bíbélì ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrìndínlógún Ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni wọ́n ti ń kọ́ àwọn èèyàn bí wọ́n ṣe máa lóye ohun tó wà nínú rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Mósè tó jẹ́ aṣáájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń ‘ṣe àlàyé’ àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀.—Diutarónómì 1:5.
Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún lẹ́yìn ìgbà yẹn, àwọn ọ̀mọ̀wé Bíbélì ṣì ń kọ́ àwọn èèyàn ní ohun tó wà nínú Bíbélì. Ní ọdún 455 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ọ̀pọ̀ àwọn Júù, títí kan àwọn ọmọdé ló kóra jọ pọ̀ sí ojúde ìlú ní Jerúsálẹ́mù. Àwọn ọ̀mọ̀wé Bíbélì tó wà níbẹ̀ ń ‘ka [ìwé mímọ́ náà] sókè.’ Kò tán síbẹ̀ o. ‘Wọ́n tún ń mú kí ìwé kíkà náà yéni.’—Nehemáyà 8:1-8.
Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] ọdún lẹ́yìn èyí, Jésù Kristi náà ṣe irú iṣé ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀. Kódà, olùkọ́ ni àwọn èèyàn mọ Jésù sí. (Jòhánù 13:13) Ó máa ń kọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn pa pọ̀, nígbà míì ó tún máa ń kọ́ wọn ní ọ̀kọ̀ọ̀kan. Ó tiẹ̀ nígbà kan tó bá ogunlọ́gọ̀ èèyàn sọ̀rọ̀, nígbà tó ń ṣe Ìwàásù Lórí Òkè. Lẹ́yìn ìwàásù náà, “háà ń ṣe ogunlọ́gọ̀ sí ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀.” (Mátíù 5:1, 2; 7:28) Nígbà ìrúwé lọ́dún 33 Sànmánì Kristẹni, Jésù ń bá àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ méjì sọ̀rọ̀ bí wọ́n ṣe ń rìn lọ lójú ọ̀nà tó lọ sí abúlé kan ní ìtòsí Jerúsálẹ́mù, ó “ń ṣí Ìwé Mímọ́ payá fún wọn lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́,” tàbí ṣàlàyé lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́ fún wọn.—Lúùkù 24:13-15, 27, 32.
Àwọn ọmọ ẹ̀yin Jésù náà máa ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ìgbà kan wà tí òṣìṣẹ́ láàfin kan láti ilẹ̀ Etiópíà ń ka apá kan nínú Ìwé Mímọ́. Ọ̀kan lára ọmọ ẹ̀yin Jésù tó ń jẹ́ Fílípì sún mọ́ ọn, ó sì bi í pé: “Ní ti gidi, ìwọ ha mọ ohun tí o ń kà bí?” Ará Etiópíà náà dáhùn pé: “Ní ti tòótọ́, báwo ni mo ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀, láìjẹ́ pé ẹnì kan fi mí mọ̀nà?” Fílípì wá ṣàlàyé ohun tí ibi tó kà túmọ̀ sí fún un.—Ìṣe 8:27-35.
ÌRÀNLỌ́WỌ́ TÓ WÀ LÓNÌÍ
Bíi tàwọn tó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láyé àtijọ́, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní igba ó lé mọ́kàndínlógójì ilẹ̀ [239] kárí ayé lónìí. (Mátíù 28:19, 20) Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, à ń ran ọ̀pọ̀ èèyàn tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́sàn lọ́wọ́ láti lóye Bíbélì. Púpọ̀ lára àwọn wọ̀nyí ni kì í ṣe Kristẹni. Ọ̀fẹ́ ni ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí, o sì lè ṣe é ní ilé rẹ tàbí ibi tó bá rọ̀ ẹ́ lọ́rùn. Àwọn kan máa ń gbádùn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọn lórí fóònù tàbí kí wọ́n ṣe é lórí íńtánẹ́ẹ̀tì.
Jọ̀wọ́ kàn sí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó o bá rí, kó lè ṣàlàyé bó o ṣe lè jàǹfààní nínú ẹ̀kọ́ yìí. Wàá rí i pé Bíbélì kì í ṣe ìwé tó ṣòro lóye, kàkà bẹ́ẹ̀, ó “ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́, fún bíbániwí nínú òdodo,” kí o lè tóótun pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo.—2 Tímótì 3:16, 17.