Fífi Ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí Lọni
1 December jẹ́ oṣù àtàtà tí a lè fi ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí lọni. Àwọn aláfẹnujẹ́ Kristian máa ń ronú nípa Jesu ní oṣù yìí ju ìgbàkígbà lọ láàárín ọdún. Ó yẹ kí gbogbo wa lo àǹfààní tí oṣù yìí ṣí sílẹ̀ fún wa láti fi ìwé dáradára yìí, tí ó kún fún àwòrán nípa Jesu Kristi, lọni ní gbogbo ìgbà tí àǹfààní bá ṣí sílẹ̀. Ohun tí a nílò lè má ju ìgbékalẹ̀ rírọrùn kan láti ru ọkàn-ìfẹ́ sókè nínú ìwé náà.
2 Lẹ́yìn kíkí onílé, o lè sọ ohun kan bí èyí:
◼ “Ayé ti mú àwọn ènìyàn ńlá tí ìtàn kò lè gbàgbé jáde. A ń díwọ̀n àwọn ènìyàn ńlá nípa ohun tí wọ́n fi sílẹ̀ láti gbèrú lẹ́yìn wọn, tí ó ń bá a lọ lẹ́yìn ikú wọn. Nínú èrò tìrẹ, ta ni ọkùnrin títóbi lọ́lá jù lọ tí ó tíì gbé ayé rí? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Nígbà kan rí, ọba kan sọ nípa Jesu Kristi pé: ‘Wò ó! Ọkùnrin naa!’ (Joh. 19:5) Nígbà ayé rẹ̀, a mọ̀ ọ́n sí ọkùnrin títóbi lọ́lá jù lọ tí ó tíì gbé ayé rí. Ṣùgbọ́n, ní àkókò wa yìí ńkọ́? A ha ṣì mọ̀ ọ́n sí ọkùnrin títóbi lọ́lá jù lọ tí ó tíì gbé ayé rí bí?” Ṣí ìwé náà sí ìbẹ̀rẹ̀, kí o sì ka ìpínrọ̀ 2 àti 3. Ṣàlàyé pé, àwọn òpìtàn àti àwọn ọba ńlá jẹ́rìí sí i pé, Jesu ni ọkùnrin títóbi lọ́lá jù lọ tí ó tíì gbé ayé rí. Kí onílé náà baà lè kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa ìdí tí Jesu fi jẹ́ irú ènìyàn ńlá bẹ́ẹ̀, fi ìwé náà lọ̀ ọ́ fún iye owó tí a ń fi síta. Ṣètò láti padà wá fún ìjíròrò síwájú sí i.
3 Lẹ́yìn sísọ ẹni tí o jẹ́, o lè sọ pé:
◼ “Ọ̀pọ̀ ènìyàn ní ń ronú nípa Jesu Kristi. A mọrírì rẹ̀, a sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ fún oore rẹ̀. Kí ni èrò rẹ—ká ní Jesu Kristi ni olùṣàkóso ayé yìí, kò ha ní jẹ́ ibi tí ó sunwọ̀n láti gbé bí? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Yóò ha ṣeé ṣe láé fún Jesu Kristi láti ṣàkóso wa ní tààràtà bí? [Ka Isaiah 9:6, 7.] A sọ tẹ́lẹ̀ pé Jesu Kristi ni ẹni tí yóò mú àlàáfíà tòótọ́, tí ó wà pẹ́ títí, wá fún aráyé. Ìwé yìí, Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí, yóò mú un dá ọ lójú pé àkóso Jesu yóò sọ ilẹ̀ ayé di ibi rírẹwà kan láìpẹ́.” Tọ́ka sí orí 132, kí o sì fi ìwé náà lọ̀ ọ́ ní iye tí a ń fi síta.
4 O lè yàn láti lo ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ yìí:
◼ “A fẹ́ mọ èrò àwọn aládùúgbò wa lórí ọ̀ràn yìí: Àwọn ọ̀nà ha wà tí a lè gbà sún mọ́ Kristi bí? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Ó pọn dandan láti ní ìmọ̀ kíkún rẹ́rẹ́ nípa àwọn ẹlòmíràn, láti lè bá wọn ṣọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́. Ohun tí ó ń béèrè lọ́wọ́ wa láti sún mọ́ Jesu Kristi tímọ́tímọ́ kò kéré sí èyí. A ní láti mọ irú ènìyàn tí ó jẹ́, àwọn ìgbòkègbodò rẹ̀ ojoojúmọ́, ìyà tí ó jẹ ẹ́, ìmọ̀lára rẹ̀, àti gbogbo apá iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀ nípa Jesu Kristi pọn dandan bí a óò bá jèrè ìyè àìnípẹ̀kun. [Ka Johannu 17:3.] Ìwé yìí, Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí, jẹ́ àkópọ̀ ìròyìn kíkún rẹ́rẹ́ nípa Jesu, tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti jèrè irú ìmọ̀ pípéye bẹ́ẹ̀ nípa rẹ̀.” Fi ìwé náà lọ̀ ọ́ ní iye tí a ń fi síta, kí o sì ṣètò gúnmọ́ fún ìpadàbẹ̀wò.
5 O lè lo ọ̀nà ìgbàyọsíni tààràtà láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, pẹ̀lú ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ kúkúrú yìí:
◼ “A ń fi ìwé tí a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli yìí han àwọn aládùúgbò wa. Ó dá lórí Jesu Kristi. O ha ti rí i rí bí? [Jẹ́ kí ó fèsì.] N óò fẹ́ láti lo ìṣẹ́jú díẹ̀, láti fi bí o ṣe lè lò ó pẹ̀lú Bibeli rẹ hàn ọ́.” Ṣí i sí orí 59, kí o sì jíròrò ìpínrọ̀ 1 sí 4. Fi ìwé náà lọ̀ ọ́.
6 Bí a bá múra sílẹ̀ dáradára, yóò ṣeé ṣe fún wa láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti mú ìmọrírì wọn fún Jehofa àti Ọmọkùnrin rẹ̀, Jesu Kristi, jinlẹ̀ sí i. Lo gbogbo àǹfààní tí o ní láti fi ìwé Ọkunrin Titobilọla lọni, ní oṣù December tí a wà nínú rẹ̀ yìí.