Jàǹfààní Láti Inú Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọrun fún 1996—Apá 1
1 O ha ti ka ìtọ́ni tí ó wà nínú “Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọrun fún 1996” bí? O ha kíyè sí àwọn ìyípadà díẹ̀ bí? Láti January sí April, a óò gbé Iṣẹ́ Àyànfúnni No. 3 karí “Awọn Àkòrí Ọ̀rọ̀ Bibeli fún Ìjíròrò,” gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun, láti May títí dé December, a óò gbé e karí ìwé Ìmọ̀ tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ mú jáde. Iṣẹ́ Àyànfúnni No. 4 yóò jẹ́ lórí ìtàn gidi tí ó ṣẹlẹ̀ nínú Bibeli.
2 Àwọn Iṣẹ́ Àyànfúnni Akẹ́kọ̀ọ́: Arábìnrin ni a ń yan Iṣẹ́ Àyànfúnni No. 3 fún. Nígbà tí a bá gbé e karí “Awọn Àkòrí Ọ̀rọ̀ Bibeli fún Ìjíròrò,” gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun, ọ̀nà ìgbékalẹ̀ rẹ̀ gbọ́dọ̀ ní ìjẹ́rìí ẹnu-ọ̀nà dé ẹnu-ọ̀nà tàbí ti àìjẹ́-bí-àṣà nínú. Nígbà tí a bá gbé e karí ìwé Ìmọ̀, a gbọ́dọ̀ gbé e kalẹ̀ lọ́nà ìpadàbẹ̀wò tàbí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé. Èyí yẹ kí ó ṣàǹfààní, níwọ̀n bí a óò ti lo ìwé Ìmọ̀ dáadáa nínú dídarí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé.
3 Àwọn arábìnrin méjèèjì lè jókòó, bí ìgbékalẹ̀ náà bá jẹ́ lọ́nà ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé. Bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ náà nípa ṣíṣe ìnasẹ̀ kúkúrú, kí o sì béèrè ìbéèrè tí a tẹ̀ jáde. Ipa onílé náà ní láti jẹ́ gidi. A lè ṣí àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ tí a tọ́ka sí, kí a sì kà wọ́n, bí àkókò bá ṣe yọ̀ọ̀da sí. Arábìnrin náà gbọ́dọ̀ lo ọnà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ nípa lílo àwọn ìbéèrè láti jẹ́ kí onílé sọ ti ọkàn rẹ̀ jáde àti nípa fífèrò wérò lórí àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ tí a lò.
4 Kí ni ó yẹ kí a ṣe bí àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ tí a tọ́ka sí nínú iṣẹ́ náà bá pọ̀ ju èyí tí a lè jíròrò láàárín ìṣẹ́jú márùn-ún lọ? Yan àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ ṣíṣe kókó tí ó tẹnu mọ́ àwọn kókó pàtàkì. Bí ó bá jẹ́ àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ díẹ̀ péré ni ó wà nínú rẹ̀, a lè jíròrò àwọn kókó pàtàkì inú ẹ̀kọ́ náà ní kíkún sí i. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, a lè ka ìpínrọ̀ kan tàbí gbólóhùn ọ̀rọ̀ kan láti inú ìwé náà, kí a sì jíròrò rẹ̀ pẹ̀lú onílé.
5 Akéde tí iṣẹ́ àyànfúnni rẹ̀ kárí ìpínrọ̀ tí ó kẹ́yìn orí náà lè ṣàtúnyẹ̀wò àpótí tí a pe àkọlé rẹ̀ ní “Dán Ìmọ̀ Rẹ Wò,” tí ó wà ní òpin orí kọ̀ọ̀kan ìwé Ìmọ̀, ní ṣókí. A tún lè jíròrò àwọn àpótí ìsọfúnni, tí ó wà láàárín àwọn ìpínrọ̀ tí a yàn fúnni, bí àkókò bá ti yọ̀ọ̀da sí. Bí àpótí ìsọfúnni kan bá wà láàárín iṣẹ́ àyànfúnni méjì, arábìnrin tí ń bójú tó iṣẹ́ àyànfúnni àkọ́kọ́ lè bójú tó o. A lè sọ̀rọ̀ lórí àwọn àwòrán inú ìwé náà, nígbàkugbà tí wọ́n bá bá àwọn àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ tí a ń jíròrò mu.
6 A gbọ́dọ̀ jẹ́ kí Iṣẹ́ Àyànfúnni No. 4 lárinrin, kí ó sì gbéṣẹ́. Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, yóò dá lórí ìtàn gidi tí ó ṣẹlẹ̀ nínú Bibeli. Fi tìṣọ́ratìṣọ́ra kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí àwọn ìtẹ̀jáde Society míràn ní í sọ nípa ibi tí a yàn fúnni náà. Gbé ọ̀rọ̀ náà kalẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀, kí o sì yan àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ ṣíṣe kókó tí yóò ran àwùjọ lọ́wọ́ láti pọkàn pọ̀ sórí ẹṣin ọ̀rọ̀ náà àti sórí ẹ̀kọ́ èyíkéyìí tí a lè rí kọ́.
7 Bí a bá lo gbogbo àǹfààní ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí ilé ẹ̀kọ́ náà pèsè, yóò ṣeé ṣe fún wa láti “wàásù ọ̀rọ̀ naa” dáradára sí i, ní ọ̀nà tí ń fi “ọgbọ́n-ọnà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́” àtàtà hàn.—2 Tim. 4:2.