Wá Àwọn Tí Ó Ní Ìtẹ̀sí Ọkàn Títọ́ Rí
1 Ọ̀kan lára ète tí a fi ń ṣiṣẹ́ ìwàásù jẹ́ láti wá àwọn tí ó “ní ìtẹ̀sí ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun” rí. (Ìṣe 13:48) Ìpínkiri ìwé ìròyìn Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí! ti jẹ́ ọ̀nà títayọ lọ́la kan láti ṣàṣeparí èyí, bí ó ti jẹ́ pé àwọn ìwé ìròyìn wa ń mú kí àwọn ènìyàn mọ̀ nípa ìrètí Ìjọba náà. A óò gbé àsansílẹ̀-owó fún Ilé-Ìṣọ́nà jáde lákànṣe ní April. Níbi tí a kò bá ti gba àsansílẹ̀-owó, a lè fi ẹ̀dà ìwé ìròyìn lọni. A retí pé, níbi tí a bá ti fi ìfẹ́ hàn, a lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli tuntun nínú ìwé náà, Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Àwọn àbá díẹ̀ nìyí tí ó lè wúlò fún ọ:
2 Nígbà tí o bá ń lo “Ile-Ìṣọ́nà,” April 1, o lè gbé “Ẹ Yin Ọba Ayérayé!,” jáde lákànṣe, èyí tí ó kó àfiyèsí jọ sórí ọ̀rọ̀ àwíyé fún gbogbo ènìyàn ti àpéjọpọ̀ àgbègbè wa tí ó kọjá, kí o sì sọ pé:
◼ “Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn tí a bá sọ̀rọ̀ ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọrun. Kò rọrùn fún àwọn mìíràn láti gbà gbọ́ nínú rẹ̀. Kí ni èrò rẹ̀? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Àwọn ẹ̀rí tí a lè fojú rí wà yí wa ká tí ń fi hàn pé Ọlọrun kan gbọ́dọ̀ wà. [Ka Orin Dafidi 104:24.] Nígbà tí a bá rí ẹ̀rọ ayàwòrán kan tàbí ẹ̀rọ kọ̀m̀pútà kan, a máa ń mọ̀ tìrọ̀rùntìrọ̀rùn pé oníṣẹ́-ọnà kan tí ó lóye ni ó ṣe é. Yóò ha bọ́gbọ́n mu láti sọ pé àwọn ohun tí ó túbọ̀ díjú lọ́pọ̀lọpọ̀, irú bí ilẹ̀ ayé àti àwa ẹ̀dá ènìyàn, pilẹ̀ṣẹ̀ lọ́nà èèṣì bí?” Lo ìpínrọ̀ kan nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà láti fi ìdí yíyè kooro fún gbígbàgbọ́ nínú Ọlọrun hàn. Lẹ́yìn náà, fi àsansílẹ̀-owó lọ̀ ọ́.
3 “Ilé-Ìṣọ́nà,” April 15 gbé ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà “Ìdí Tí Ìsìn Tòótọ́ Fi Ń Rí Ìbùkún Ọlọrun Gbà,” jáde lákànṣe. O lè béèrè pé:
◼ “Pẹ̀lú ọgọ́rọ̀ọ̀rún ìsìn tí ń bẹ ní ayé, o ha ronú pé Ọlọrun lè tẹ́wọ́ gba gbogbo wọn bí? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Jesu sọ tẹ́lẹ̀ pé, láìka ìjẹ́wọ́sọ àwọn ènìyàn onísìn sí, a kì yóò tẹ́wọ́ gba àwọn tí kò ṣe ìfẹ́ Ọlọrun. [Ka Matteu 7:21-23.] Ó ṣe pàtàkì pé kí á dá ìsìn tòótọ́ tí Jesu fi kọ́ni mọ̀ yàtọ̀.” Ṣí i sí ìsọ̀rí náà “Èso Wo Ni Ìsìn Tòótọ́ Gbọ́dọ̀ Mú Jáde?” tí ó bẹ̀rẹ̀ ní ojú ìwé 16, kí o sì jíròrò àpẹẹrẹ kan láti ṣàkàwé kókó náà. Lẹ́yìn náà fí àsansílẹ̀-owó lọ̀ ọ́.
4 Nígbà tí o bá ń gbé lájorí àkòrí inú “Jí!,” April 22, “Nígbà Tí Ogun Kì Yóò Sí Mọ́” jáde lákànṣe, o lè ronú sísọ pé:
◼ “Ní ọ̀rúndún yìí, ọgọ́rọ̀ọ̀rún ogun ti ṣẹlẹ̀, tí ó ní ogun àgbáyé méjì nínú. Síbẹ̀, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo àwọn aṣáájú ayé ni ń sọ pé àwọn ń fẹ́ àlàáfíà. Gbogbo àwọn tí mo mọ̀ ń sọ ohun kan náà. Bí gbogbo ènìyàn bá ń fẹ́ àlàáfíà, èé ṣe tí ọwọ́ wọn kò fi lè tẹ̀ ẹ́? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Kí ni o ronú pé a nílò láti lè rí àlàáfíà tòótọ́ lórí ilẹ̀ ayé?” Lẹ́yìn tí onílé bá ti fèsì, ṣí i sí ojú ìwé 8 àti 9, kí o sì ka ẹsẹ ìwé mímọ́ bí Orin Dafidi 46:8, 9. Ní lílo àwọn àwòràn àti àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ tí a tọ́ka sí, fi bí Ìjọba Ọlọrun yóò ṣe mú àlàáfíà kárí ayé tí yóò wà pẹ́ títí wá hàn. Ní ibi tí o dé yìí, fi àsansílẹ̀-owó fún Ilé-Ìṣọ́nà lọ̀ ọ́. Ṣùgbọ́n bí kò bá gba àsansílẹ̀-owó náà, o lè fi ẹ̀dà ìwé ìròyìn lọ̀ ọ́, o sì lè ṣètò láti padà wá.
5 Bí o bá bá ọ̀pọ̀ pàdé tí wọ́n sọ pé ọwọ́ àwọ́n dí, o lè gbìyànjú èyí:
◼ “A nífẹ̀ẹ́ nínú ṣíṣèrànwọ́ fún àwọn ènìyàn tí ń gbé ìgbésí ayé tí ó kún fún iṣẹ́ pẹrẹwu, tí wọ́n sì ní ìwọ̀nba àkókò díẹ̀ láti ronú lórí apá ìhà tẹ̀mí nínú ìgbésí ayé. A pète àwọn ìwé ìròyìn wa, Ilé-Ìsọ́nà àti Jí!, láti pèsè àwọn ìsọfúnni tí ó ṣe ṣókí nípa àwọn ọ̀ràn pàtàkì tí ó kan ìwọ àti ìdílé rẹ. Èmi yóò fẹ́ láti fi àwọn ẹ̀dà wọ̀nyí sílẹ̀ fún ọ láti kà wọ́n.”
6 Jẹ́ aláápọn nínú wíwá àwọn tí ó ní ìtẹ̀sí ọkan títọ́ rí. Dájúdájú, wọn yóò jàǹfààní nínú kíka Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí!, tí ń mú “ìhìn rere ohun rere wá.”—Isa. 52:7.