Ẹ Máa Bá Aládùúgbò Yín Sọ Òtítọ́
1 Ọ̀kan lára òfin méjì tí ó tóbi jù lọ ni pé: “Iwọ gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.” (Matt. 22:39) Irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ yóò sún wa láti ṣàjọpín ohun tí ó dára jù lọ tí a ní—òtítọ́ tí a rí nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun—pẹ̀lú aládùúgbò wa. Níwọ̀n bí ìwé ìròyìn Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí! ti ń ké àtótó arére ìhìn iṣẹ́ òtítọ́ Bibeli, pínpín àwọn ìwé ìròyìn wọ̀nyí kiri ní oṣù May jẹ́ ọ̀nà kan fún wa láti ‘sọ òtítọ́ pẹlu aládùúgbò wa.’—Efe. 4:25.
2 O ní láti máa gbé “Jí!” April 22 jáde lákànṣe títí tí èyí tí o ní lọ́wọ́ yóò fi tán. O lè bẹ̀rẹ̀ ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ nípa bíbéèèrè pé:
◼ “Kí ni o rò nípa ayé kan láìsí ogun? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Ǹjẹ́ o mọ̀ pé àwọn ìsìn ayé ń gbé ogun àti ìpànìyàn lárugẹ ní ti gidi? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Ní ìyàtọ̀ pátápátá, kíyè sí ohun tí Bibeli sọ pé àwọn tí ń sin Ọlọrun ní tòótọ́ yóò máa ṣe.” Ka Isaiah 2:2-4 láti òkè ojú ìwé 4 ìwé ìròyìn náà, lẹ́yìn náà ní ojú ìwé 10, ka ìpinrọ̀ àkọ́kọ́ lábẹ́ ìsọ̀rí orí ọ̀rọ̀ náà, “Kíké sí Àwọn Olùfẹ́ Àlàáfíà.” Lẹ́yìn náà, béèrè pé: “Ǹjẹ́ o mọ bí Ọlọrun yóò ṣe ṣe ìyẹn? Ìdáhùn náà wà nínú ìwé ìròyìn yìí, ẹ̀dà tìrẹ sì nìyí láti kà. Ó wà fún ọrẹ ₦20 péré.”
3 Nígbà tí o bá ń fi “Ilé-Ìṣọ́nà” May 15 lọni, gbìyànjú láti tọ́ka sí ìṣẹ̀lẹ̀ lọ́ọ́lọ́ọ́ kan tí ó jáde nínú ìròyìn, tí ó mú kí àwọn ènìyàn máa nímọ̀lára àìláàbò, kí o wá béèrè lẹ́yìn náà pé:
◼ “Kí ni o rò pé ó ń béèrè fún kí á tó lè nímọ̀lára ààbò tòótọ́ nínú ayé yìí? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Kí a sọ tòótọ́, ǹjẹ́ ó bọ́gbọ́n mu láti gbẹ́kẹ̀ lé ènìyàn láti yanjú àwọn ìṣòro tí ń dojú kọ ìran ènìyàn? [Jẹ́ kí ó fèsì; lẹ́yìn náà ka Orin Dafidi 146:3.] Onipsalmu náà tún fún wa ní ìdí tí ó fi yẹ kí a jẹ́ olùfojúsọ́nà-fún-rere nípa ọjọ́ ọ̀la. [Ka Orin Dafidi 146:5, 6.] Ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yìí, ‘Ààbò Tòótọ́, Nísinsìnyí àti Títí Láé,’ ṣàlàyé ìdí tí a fi lè gbẹ́kẹ̀ lé Jehofa Ọlọrun láti mú àwọn ìpò tí ó sàn wá sí ilẹ̀ ayé.” Fi ọ̀wọ́ àwọn ìwé ìròyìn kan sílẹ̀ fún un, kí o sì ṣètò láti padà wá láti jíròrò bí ó ṣe lè ṣeé ṣe láti gbádùn ìgbésí ayé aláàbò nísinsìnyí.
4 Nítorí ìdágunlá tí ó gbòde kan kárí ayé nípa ìsìn, bóyá àwọn ènìyàn yóò nífẹ̀ẹ́ sí àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó wà nínú “Jí!” April 8, 1996. O lè nasẹ̀ ìwé ìròyìn náà ní sísọ pé:
◼ “Ọ̀pọ̀ ènìyàn lónìí ti pa ìsin wọn tì tàbí wọn kò fi ìtara ìsìn hàn mọ́. Kí ni o rò pé ó fà á?” [Jẹ́ kí ó fèsì, kí o sì gbóríyìn fún un.] O lè máa bá ọ̀rọ̀ rẹ nìṣó ní sísọ pé: “Nítorí ìwa àgàbàgebè àwọn aṣáájú ìsìn, ọ̀pọ̀ ènìyàn ni ọ̀kan wọ́n ti ṣí kúró nínú ìsìn àjọṣepọ̀. Ṣùgbọ́n, ìwọ ha rò pé ìsìn já mọ́ nǹkan kan bí?” [Jẹ́ kí ó fèsì.] Fi àwòrán ìwájú ìwé ìròyìn náà han onílé, kí o sì ka àkọlé rẹ̀, “Ìsìn Ha Já Mọ́ Nǹkan Kan Mọ́ Bí?” Pe àfiyèsi sí àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ méjì àkọ́kọ́ inú ìwé ìròyìn náà, kí o sì ka ọ̀rọ̀ tí a fàyọ ní ojú ìwé 9, lábẹ kókó ọ̀rọ̀ náà, “Òpin Ìsìn Ha Ti Sún Mọ́lé Bí?” Tọ́ka sí Isaiah 11:9, ẹsẹ ìwé mímọ́ tí a ti fa ọ̀rọ̀ náà yọ. Lẹ́yìn náà, fi ìwé ìròyìn náà lọ̀ ọ́, kí o sì wí pé: “Nígbà ìbẹ̀wò mi tí ń bọ̀, èmi yóò fẹ̀ láti bá ọ jíròrò nípa bí a ṣe lè rí ìsìn tí Ọlọrun tẹ́wọ́ gbà.”
5 Bí ó bá jẹ́ pé ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tí kò gùn ni o nífẹ̀ẹ́ sí, o lè gbìyànjú èyí:
◼ “Ọ̀pọ̀ rò pé èyí tí ó pọ̀ jù lọ lára àwọn ìwé ìròyìn gbígbajúmọ̀, tí ó wà lónìí, ló ń gbé òwò elérè àjẹjù, ìbálòpọ̀ takọtabo, tàbí ìwà ipá jáde ju bí ó ṣe yẹ lọ. [Fi Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí! hàn án.] À ń pín àwọn ìwé ìròyìn gbígbámúṣé wọ̀nyí tí a gbé karí Bibeli, káàkiri. Wọ́n ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ gan-an, wọ́n sì ń kọ́ni láti jọ́sìn Ọlọrun, àti láti nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò wa, kí a sì máa hu ìwà rere. Bí o bá nífẹ̀ẹ́ sí irú ìwé kíkà báyìí, mo mọ̀ pé ìwọ yóò gbádùn ohun tí ó wà nínú àwọn ìtẹ̀jáde wọ̀nyí.”
6 Bí a bá jẹ́ onítara nínú bíba àwọn aládùúgbò wa sọ òtítọ́, ó lè ṣeé ṣe fún wa láti mú ayọ̀ rẹpẹtẹ wá fún ọ̀pọ̀ ènìyàn.—Ìṣe 8:4, 8.