Dídarí Àwọn Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tí Ń Tẹ̀ Síwájú
1 Kí ni nọ́ọ̀sì kan ní Tanzania, èwe kan ní Ajẹntínà, àti ìyá kan ní Latvia fi jọra? Ìwé 1997 Yearbook (ojú ìwé 8, 46, àti 56) ròyìn pé àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ní ìtẹ̀síwájú yíyára kánkán nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí a ń bá wọn ṣe nínú ilé, ọpẹ́lọpẹ́ ìmúratán tí wọ́n ní láti kẹ́kọ̀ọ́ ju ẹ̀ẹ̀kan lọ lọ́sẹ̀ nínú ìwé Ìmọ̀. A ti dámọ̀ràn rẹ̀ pé nígbàkigbà tí ó bá ṣeé ṣe, kí àwọn akéde sakun láti jíròrò orí kan nínú ìwé náà ní àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan. Ṣùgbọ́n, àwọn kan rí i pé ó ṣòro láti ṣe bẹ́ẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé púpọ̀ sinmi lórí àyíká ipò àti agbára ìkẹ́kọ̀ọ́ akẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan, àwọn olùkọ́ tí wọ́n ní ìrírí ti ṣàṣeyọrí nípa lílo àwọn àbá tí ó tẹ̀ lé e yìí.
2 Gẹ́gẹ́ bí a ti jíròrò nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti June 1996, ó ṣe pàtàkì pé kí o kọ́ akẹ́kọ̀ọ́ rẹ láti múra sílẹ̀ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Ní ìbẹ̀rẹ̀ gan-an, yóò dára láti ṣàlàyé bí a ṣe ń ṣe èyí, kí o sì ṣàṣefihàn rẹ̀. Fi ẹ̀dà ìwé Ìmọ̀ tìrẹ tí o fi ń kẹ́kọ̀ọ́ hàn wọ́n. Ẹ múra ẹ̀kọ́ kìíní pa pọ̀. Ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ láti wá àwọn ọ̀rọ̀ tàbí àpólà ọ̀rọ̀ tí ó jẹ́ kókó pàtàkì, tí ó dáhùn àwọn ìbéèrè tí a tẹ̀ ní tààràtà, kí o sì fàlà sídìí wọn lẹ́yìn náà, tàbí kí o kùn wọ́n. Àwọn akéde kan tilẹ̀ ti fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọn ní kálámù tàbí pẹ́ńsùlù láti lò. Fún wọn níṣìírí láti ṣàyẹ̀wò gbogbo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ bí wọ́n ti ń múra fún ìkẹ́kọ̀ọ́. Nípa ṣíṣe èyí, ìwọ yóò tún máa dá wọn lẹ́kọ̀ọ́ láti múra sílẹ̀ fún pípésẹ̀ sí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ àti Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́.—Lúùk. 6:40.
3 Olùkọ́ dáradára kan yóò mú kí akẹ́kọ̀ọ́ sọ tẹnu rẹ̀, kì yóò sì fúnra rẹ̀ sọ ọ̀rọ̀ tí ó pọ̀ jù. Ó máa ń yẹra fún yíyagbóyajù lórí àwọn kókó tí kò ṣe pàtàkì. Kì yóò fi bẹ́ẹ̀ mú àwọn àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ míràn tí kò bá a mu wọnú ọ̀rọ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, yóò tẹnu mọ́ àwọn kókó pàtàkì nínú ẹ̀kọ́ náà. Àwọn kan ti pèsè àfikún ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè. Síwájú sí i, àwọn olùfìfẹ́hàn yóò rí àfikún kúlẹ̀kúlẹ̀ ìsọfúnni gbà nípa lílọ sí àwọn ìpàdé ìjọ.
4 Ó lè má pọn dandan láti ṣàyẹ̀wò gbogbo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a tọ́ka sí nínú ẹ̀kọ́ náà. O lè ṣàlàyé àwọn kókó pàtàkì kan láti inú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a ṣàyọlò wọn nínú ìpínrọ̀ náà. Nígbà àtúnyẹ̀wò, tẹnu mọ́ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ pàtàkì tí ẹ jíròrò, kí o sì fún akẹ́kọ̀ọ́ níṣìírí láti fi èyí sọ́kàn.
5 Báwo Ni Ó Ṣe Yẹ Kí Àkókò Ìkẹ́kọ̀ọ́ Kọ̀ọ̀kan Pẹ́ Tó?: Kò pọn dandan pé kí a fi ìkẹ́kọ̀ọ́ náà mọ sí wákàtí kan. Àwọn onílé kan máa ń ráyè, wọ́n sì lè fẹ́ láti túbọ̀ lo àkókò gígùn sí i láti kẹ́kọ̀ọ́. Akẹ́kọ̀ọ́ náà sì lè fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ ju ẹ̀ẹ̀kan lọ lọ́sẹ̀. Èyí yóò ṣàǹfààní fún àwọn tí ó bá lè ṣe bẹ́ẹ̀.
6 Gẹ́gẹ́ bí Aísáyà 60:8 ti ṣàgbéyọ rẹ̀, lónìí, ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn olùyin Jèhófà, tí wọ́n jẹ́ ẹni tuntun “ń fò bí àwọ̀ sánmà, àti bí àwọn ẹyẹlé sí ojúlé wọn” sínú ìjọ àwọn ènìyàn rẹ̀. Ẹ jẹ́ kí gbogbo wa ṣe ipa tiwa ní bíbá Jèhófà ṣiṣẹ́ pẹ́kípẹ́kí bí òun ti ń mú kí ìkójọ àwọn ẹni bí àgùntàn yára kánkán.—Aísá. 60:22.