ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 6/98 ojú ìwé 8
  • Jíjẹ́rìí fún “Gbogbo Onírúurú Ènìyàn”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jíjẹ́rìí fún “Gbogbo Onírúurú Ènìyàn”
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìmọ̀ Láti Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Ń Dáhùn Ọ̀pọ̀ Ìbéèrè
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Dámọ̀ràn fún Lílò Lóde Ẹ̀rí
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • “Èyí Túmọ̀ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun”
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Àwọn Ìnasẹ̀ Ọ̀rọ̀ Tí A Dábàá fún Lílò Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Pápá
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
km 6/98 ojú ìwé 8

Jíjẹ́rìí fún “Gbogbo Onírúurú Ènìyàn”

1 Nígbà tí a bá bá àwọn ènìyàn tí ó ní onírúurú ipò àtilẹ̀wá ní ti àṣà àti ẹ̀sìn pàdé, a ń rántí pé ìfẹ́ Jèhófà ni “pé kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (1 Tím. 2:4) Ní àfikún sí ọ̀pọ̀ ìwé àṣàrò kúkúrú àti àwọn ìwé pẹlẹbẹ tí a ṣe lákànṣe, a ní ìtẹ̀jáde méjì tí ó dára gan-an tí a lè lò nígbàkigbà láti ṣèrànwọ́ fún àwọn ènìyàn tí ìsìn wọn kò fi òtítọ́ nípa Ọlọ́run àti Kristi kọ́ wọn.

2 Ìwé náà, Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun lè ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ níbi gbogbo láti fi ohun tí wọ́n gbà gbọ́ wé ohun tí Bíbélì fi kọ́ni nípa Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, nípa títẹnumọ́ ìgbésí ayé Jésù Kristi, ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí lè ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti túbọ̀ di ojúlùmọ̀ pẹ̀lú Ọmọ Ọlọ́run, kí ó sì fà sún mọ́ ọn, gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ ènìyàn ti ṣe ní ọ̀rúndún kìíní. (Jòh. 12:32) Nígbàkigbà tí ó bá bá a mu, o lè gbìyànjú àbá tí ó tẹ̀ lé e yìí ní fífi àwọn ìwé wọ̀nyí lọni.

3 Bí o bá rò pé ó bójú mu láti fi ìwé “Ọkunrin Titobilọla Julọ” lọ ẹnì kan, o lè béèrè pé:

◼ “Kí ni ó máa ń wá sọ́kàn rẹ nígbà tí o bá ronú nípa Jésù Kristi? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Ọ̀pọ̀ òpìtàn gbà pé Jésù ni ọkùnrin títóbi lọ́lá jù lọ tí ó tíì gbé ayé rí. [Fa àpẹẹrẹ kan yọ láti inú ọ̀rọ̀ ìṣáájú nínú ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ.] Bíbélì fi hàn pé ìgbésí ayé Jésù jẹ́ àwòkọ́ṣe fún wa láti fara wé.” Ka 1 Pétérù 2:21 àti ìpínrọ̀ àkọ́kọ́ ní ojú ìwé tí ó kẹ́yìn nínú ọ̀rọ̀ ìṣáájú ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ. Bí onílé náà bá fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jésù, fi ìwé náà lọ̀ ọ́. Kí o tó lọ, ka Jòhánù 17:3, kí o sì béèrè pé, “Báwo ni a ṣe lè gba ìmọ̀ tí ń sinni lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun yìí sínú?” Ṣètò tí ó ṣe gúnmọ́ láti wá padà dáhùn.

4 Nígbà tí o bá padà wá láti ṣàlàyé bí a ṣe lè gba ìmọ̀ tí ń fúnni ní ìyè sínú, o lè sọ pé:

◼ “Mo ṣèlérí láti padà wá fi hàn ọ́ bí a ṣe lè gba ìmọ̀ tí ń sinni lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun sínú.” Fún un ní ìwé Ìmọ̀, nípa lílo àkòrí kìíní, fi bí a ṣe ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ hàn án.

5 Bí o bá fẹ́ láti fi ìwé “Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun” lọni, o lè sọ pé:

◼ “Bí onírúurú àwọn ẹ̀sìn ṣe wà lónìí, ìwọ ha ti ṣe kàyéfì rí nípa bí a ṣe lè mọ èyí tí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà bí?” Lẹ́yìn tí ó bá ti fèsì, ṣí ìwé Ìmọ̀ sí ojú ewé 46. Ka ìpínrọ̀ 6 àti 7, sì béèrè bóyá onílé náà gbà pé kì í ṣe gbogbo ẹ̀sìn ní “ń ṣe ìfẹ́ Baba [Jésù]” lónìí. Mẹ́nu kàn án pé ẹ̀sìn tòótọ́ lónìí ń kúnjú ìwọ̀n ohun tí a béèrè lókè yìí. Fi ìwé náà lọ̀ ọ́ ní iye tí a ń fi fúnni. Nígbà tí o bá ń lọ, o lè béèrè pé, “Báwo ni ó ṣe yẹ kí ẹ̀sìn tòótọ́ nípa lórí ìwà ẹni?” Ṣètò fún ìpadàbẹ̀wò láti dáhùn ìbéèrè náà.

6 Nígbà tí o bá padà wá láti ṣàlàyé bí ẹ̀sìn tòótọ́ ṣe ń nípa lórí ìgbésí ayé ẹni, o lè béèrè pé:

◼ “Báwo ni o ṣe rò pé ó yẹ kí ẹ̀sìn nípa lórí ìwà àwọn ènìyàn? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Kristi fún wa ní ohun tí ó yẹ kí a fi díwọ̀n ẹ̀sìn.” Ka Mátíù 7:17-20. Lẹ́yìn náà, sọ pé kí onílé náà ka ìpínrọ̀ 18 ní ojú ewé 50 àti 51. Bí àkókò bá wà, jíròrò ìpínrọ̀ 20 ní ojú ewé 51. Sọ pé ìwọ́ yóò padà wá láti máa bá ìjíròrò náà lọ.

7 Ohun tí a lè fi bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò: Ọ̀pọ̀ kókó tí a fi lè kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ wà nínú ìwé Ìmọ̀, èyí tí a lè lò gẹ́gẹ́ bí ohun tí a lè fi bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò nígbà tí a bá kọ́kọ́ ṣe ìkésíni tàbí nígbà ìpadàbẹ̀wò. O lè bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò nípa wíwulẹ̀ béèrè ìbéèrè kan tí ó bá a mu. Bí àpẹẹrẹ, ṣàkíyèsí ìbéèrè yìí, àwọn kókó ẹ̀kọ́ àti ojú ewé tí a ti jíròrò wọn:

“Ohun Tí Ó Wà Nínú Bibeli” (13)

“O Ha Lè Gbẹ́kẹ̀lé Bibeli Bí?” (15)

“Ọlọrun Tòótọ́ náà Ní Orúkọ Kan” (24)

“Ṣọ́ra fún Àwọn Ọgbọ́n-Ẹ̀wẹ́ Satani!” (59)

“Àwọn Apá-Ẹ̀ka Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn” (99)

“Àwọn Ohun Tí A Béèrè Fún Láti Súnmọ́ Ọlọrun” (152)

“Àwọn Ìgbésẹ̀ Tí Ń Sinni Lọ Sí Ìyè Títí Láé” (173)

8 O lè ṣí ojú ewé tí o yàn nínú ìwé Ìmọ̀ kí o sì ṣàlàyé kókó tí a ń jíròrò níbẹ̀. Lẹ́yìn náà, ṣètò fún ìpadàbẹ̀wò nípa bíbéèrè ìbéèrè kan tí ó jẹ mọ́ ọn tí a lè dáhùn láti inú yálà ìwé pẹlẹbẹ Béèrè tàbí nínú ìwé Ìmọ̀. Rí i dájú pé o ké sí onílé náà wá sí Ìpàdé fún Gbogbo Ènìyàn, kí o sì fún un ní ìwé ìléwọ́.

9 Gbogbo onírúurú ènìyàn aláìlábòsí-ọkàn ń wá òtítọ́ nípa Ọlọ́run àti Kristi kiri. A lè ràn wọ́n lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìjẹ́rìí wa. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a máa bá a lọ láti máa ‘ṣiṣẹ́ kára, kí a sì máa tiraka, nítorí tí a ti gbé ìrètí wa lé Ọlọ́run alààyè, ẹni tí ó jẹ́ Olùgbàlà gbogbo onírúurú ènìyàn.’—1 Tím. 4:10.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́