Nasẹ̀ Ìwé Walaaye Titilae Lọ́nà Gbígbéṣẹ́
1 Jésù dáńgájíá nínú bí ó ṣe ń nasẹ̀ ọ̀rọ̀. Ó mọ ohun tí ó yẹ kí òun sọ láti ru ọkàn-ìfẹ́ sókè. Ní ìgbà kan, ó bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú obìnrin ará Samáríà kan nípa wíwulẹ̀ sọ fún obìnrin náà pé kí ó fún òun ní omi mu. Èyí gba àfiyèsí obìnrin náà lọ́gán nítorí pé “àwọn Júù kì í ní ìbálò kankan pẹ̀lú àwọn ará Samáríà.” Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ìjíròrò tí ó tẹ̀ lé e ran obìnrin náà àti ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn lọ́wọ́ láti di onígbàgbọ́. (Jòh. 4:7-9, 41) A lè kẹ́kọ̀ọ́ láti inú àpẹẹrẹ rẹ̀.
2 Nígbà tí o bá ń múra bí ìwọ yóò ṣe fi ìwé Walaaye Titilae lọni, bi ara rẹ léèrè pé, ‘Kí ni ó jẹ́ àníyàn àwọn ènìyàn gan-an ní ìpínlẹ̀ wa? Kí ni yóò fa ọ̀dọ́langba, àgbàlagbà, ọkọ, tàbí aya lọ́kàn mọ́ra?’ O lè múra ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tí ó ju ẹyọ kan lọ kí o sì wéwèé láti lo èyí tí ó bá dà bí pé ó ba ipò mu jù lọ.
3 Níwọ̀n bí bíburú tí ìgbésí ayé ìdílé ń burú sí i ti ń kọ ọ̀pọ̀ lóminú, o lè sọ pé:
■ “Pákáǹleke ojoojúmọ́ nínú ìgbésí ayé ń han àwọn ìdílé léèmọ̀ gidigidi lónìí. Ibo ni wọ́n ti lè rí ìrànwọ́? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Bíbélì lè ràn wá lọ́wọ́ ní ti gidi. [Ka 2 Tímótì 3:16, 17.] Ìwé Mímọ́ pèsè ìtọ́sọ́nà ṣíṣàǹfààní tí ó lè ran ìdílé lọ́wọ́ láti là á já. Ṣàkíyèsí ohun tí ó wà ní ìpínrọ̀ 3 ní ojú ìwé 238 nínú ìtẹ̀jáde yìí, Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye.” Ka ìpínrọ̀ 3, kí o sì fi lọ̀ ọ́.
4 Ọ̀pọ̀ ń kọminú nípa ìṣòro ìwà ọ̀daràn tí ń gbilẹ̀. O lè lo ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tí ó tẹ̀ lé e yìí:
■ “A ń bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ nípa ọ̀ràn ààbò ẹnì kọ̀ọ̀kan. Ọ̀pọ̀ ìwà ọ̀daràn ni ó yí wa ká, ó sì ń ní ipa lórí ìgbésí ayé wa. Kí ni o rò pé ó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ kí èmi àti ìwọ tó lè ní ààbò lójú pópó ní alẹ́?” O lè ka Sáàmù 37:10, 11 kí o sì tọ́ka sí àwọn ìbùkún tí Ìjọba Ọlọ́run yóò mú wá, kí o lo ojú ìwé 156 sí 158 nínú ìwé Walaaye Titilae.
5 Bí o bá fẹ́ ìyọsíni tí ó túbọ̀ rọrùn, o lè sọ pé:
■ “A ń fún àwọn aládùúgbò wa níṣìírí láti ṣàyẹ̀wò ọjọ́ ọ̀la kíkọyọyọ tí Bíbélì nawọ́ rẹ̀ sí wa. [Ka Ìṣípayá 21:3, 4.] Èyí ha dùn mọ́ ọ bí? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Orí 19 nínú ìtẹ̀jáde yìí ṣàlàyé àwọn ìbùkún mìíràn tí aráyé onígbọràn yóò gbádùn lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run.” Bí ó bá fi ọkàn-ìfẹ́ hàn, fi ìwé Walaaye Titilae lọ̀ ọ́.
6 Mímúra ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ gbígbéṣẹ́ sílẹ̀ lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti dé ọ̀dọ̀ àwọn tí ebi òdodo ń pa.—Mát. 5:6.