ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 2/00 ojú ìwé 7
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Tuntun fún Àpéjọ Àkànṣe

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Tuntun fún Àpéjọ Àkànṣe
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Tuntun fún Àpéjọ Àkànṣe
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Tuntun fún Àpéjọ Àkànṣe
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Tuntun fún Àpéjọ Àyíká
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àkànṣe Tuntun
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
km 2/00 ojú ìwé 7

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Tuntun fún Àpéjọ Àkànṣe

Ẹṣin ọ̀rọ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ àkànṣe tí yóò bẹ̀rẹ̀ ní oṣù March ọdún 2000 ni: “Wíwá Inú Àwọn Ohun Ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run.” (1 Kọ́r. 2:10) Kí ni àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye tí a óò kọ́?

Ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń ṣàfẹ́rí ìmọ̀ ni ìmọ̀ tí wọ́n rí kó jọ kì í sọ ìrònú wọn dọ̀tun. Àmọ́ Bíbélì máa ń fún wa lókun, gẹ́gẹ́ bí a ó ti gbọ́ ọ nínú ọ̀rọ̀ alábòójútó àyíká, tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ “Wíwá Inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ń Mú Ìtura Wá.” Olùbánisọ̀rọ̀ tí a rán wá yóò sọ̀rọ̀ nípa bí wíwá ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run ṣe tan mọ́ wíwàásù ìhìn rere náà nígbà tó bá ń jíròrò ìbéèrè náà, “Ojú Wo Lo Fi Ń Wo Ìwàásù Ìjọba Náà?”

Báwo làwọn òbí ṣe lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti máa ṣèwádìí jinlẹ̀jinlẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? A ó pèsè àwọn ìmọ̀ràn tó mọ́yán lórí nínú ọ̀rọ̀ náà, “Gbin Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Sínú Àwọn Ọmọ Rẹ.” Àwọn ọ̀dọ́ Kristẹni yóò máa rí àpẹẹrẹ rere tẹ̀lé bí wọ́n bá ń kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn tó dàgbà dénú nípa tẹ̀mí nínú ìjọ. A óò mú àwọn àpẹẹrẹ kan wá nípa ipa rere tí èyí ti ní lórí wọn nínú ọ̀rọ̀ náà, “Àwọn Ọ̀dọ́ Tí Ń Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Àwọn Àgbà.”

Èé ṣe tó fi yẹ ká máa fi taratara wá àwọn ìṣúra tẹ̀mí tó fara sin ní àkókò yìí? Ìdí ni pé Ẹni tí ń ṣí àṣírí payá ni Jèhófà jẹ́. Olùbánisọ̀rọ̀ tí a rán wá yóò ṣàlàyé ohun tí Jèhófà ṣí payá láyé àtijọ́ àti lóde òní nínú ọ̀rọ̀ náà, “Jèhófà Ń Ṣí Àwọn Ohun Ìjìnlẹ̀ Payá Ní Ṣísẹ̀-N-Tẹ̀lé.” Èyí yóò jẹ́ ká túbọ̀ túnra mú, láti máa bá a nìṣó ní wíwá inú “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run.”

Bẹ̀rẹ̀ sí wéwèé báyìí nípa bóo ṣe máa wà níbẹ̀. Kí àwọn tó bá fẹ́ fàmì ìyàsímímọ́ wọn hàn fún Jèhófà nípasẹ̀ ìbatisí tètè fi tó alábòójútó olùṣalága létí. Ohun táa bá gbọ́ yóò jẹ́ kí ìfẹ́ àtọkànwá wa túbọ̀ lágbára sí i láti kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jinlẹ̀jinlẹ̀. Nítorí náà, máà jẹ́ kí wọ́n fi àkànṣe ọjọ́ ìtọ́ni tẹ̀mí yìí pìtàn fún ẹ o!

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́