‘Kí A Dán Wọn Wò Ní Ti Bí Wọ́n Ti Yẹ Sí’—Lọ́nà Wo?
1 Bí àwọn èèyàn ṣe ń pọ̀ sí i nínú ètò Jèhófà, à ń fẹ́ àwọn arákùnrin tí ó tóótun láti sìn gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́. Ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin tí a kò tíì yàn, títí kan àwọn ọ̀dọ́langba ń fẹ́ láti sìn nínú ìjọ. Báa bá fún wọn ní iṣẹ́ sí i, wọ́n máa ń nímọ̀lára pé àwọn wúlò, inú wọn sì máa ń dùn pé àwọn ṣàṣeyọrí. Ìtẹ̀síwájú wọn yóò sinmi lórí ‘dídán wọn wò ní ti bí wọ́n ti yẹ sí.’ (1 Tím. 3:10) Báwo la ṣe lè ṣe èyí?
2 Ojúṣe Àwọn Alàgbà: Gẹ́gẹ́ bí apá kan fífi ohun tí Ìwé Mímọ́ là sílẹ̀ díwọ̀n arákùnrin kan lórí ìpìlẹ̀ àwọn ohun tó ń múni tóótun láti jẹ́ ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, tó wà ní 1 Tímótì 3:8-13, àwọn alàgbà yóò dán arákùnrin kan wò láti mọ bó ṣe lè bójú tó ẹrù iṣẹ́ sí. Wọ́n lè yàn án pé kó máa ṣèrànwọ́ nínú àwọn iṣẹ́ tó ní í ṣe pẹ̀lú bíbójútó ìwé ìròyìn àti ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́, bíbójútó maikirofóònù, títún Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣe, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn alàgbà yóò kíyè sí ẹ̀mí tó fi gba àwọn iṣẹ́ tí wọ́n yàn fún un àti bó ṣe ń bójú tó wọn. Wọ́n a wò ó bóyá ó ní ànímọ́ tó fi hàn pé á jẹ́ ẹni tó ṣeé gbára lé, pé ó máa ń dé lákòókò, pé ó jẹ́ aláápọn, pé ó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, pé ó ní ẹ̀mí ìmúratán láti ṣe nǹkan, àti pé ó jẹ́ ẹni tó máa ń wà lálàáfíà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. (Fílí. 2:20) Ǹjẹ́ bó ṣe ń múra àti bó ṣe ń wọṣọ jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ? Ǹjẹ́ ó mọṣẹ́ rẹ̀ níṣẹ́? Wọ́n gbọ́dọ̀ rí “àwọn iṣẹ́ rẹ̀ . . . láti inú ìwà rẹ̀ tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ pẹ̀lú ìwà tútù tí ó jẹ́ ti ọgbọ́n.” (Ják. 3:13) Ǹjẹ́ ó ń sapá ní ti gidi láti ṣèrànwọ́ nínú ìjọ? Ǹjẹ́ ó ń pa àṣẹ Jésù mọ́ láti ‘máa sọ àwọn ènìyàn di ọmọ ẹ̀yìn,’ nípa fífi ìtara kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá?—Mát. 28:19; wo Ilé-ìṣọ́nà, September 1, 1990, ojú ìwé 18 sí 28.
3 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì kò dá ọjọ́ orí kan téèyàn gbọ́dọ̀ dé ká tó lè yàn án gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, ó sọ̀rọ̀ irú àwọn arákùnrin bẹ́ẹ̀ pé wọ́n jẹ́ “àwọn ọkùnrin tí ń ṣe ìránṣẹ́.” Yóò ṣòro ká retí pé kí wọ́n jẹ́ ẹni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di ọ̀dọ́langba tàbí tó wà ní ìdajì àwọn ọdún ọ̀dọ́langba, pàápàá bí a ṣe mẹ́nu kàn án pé ó ṣeé ṣe kí wọ́n ní ìyàwó àti àwọn ọmọ. (1 Tím. 3:12, 13) Irú àwọn ọkùnrin bẹ́ẹ̀ kò ní máa fàyè gba “àwọn ìfẹ́-ọkàn tí ó máa ń bá ìgbà èwe rìn,” ṣùgbọ́n wọ́n gbọ́dọ̀ máa hùwà lọ́nà ọgbọ́n, kí wọ́n sì ní ìdúró rere àti ẹ̀rí ọkàn mímọ́ níwájú Ọlọ́run àti ènìyàn.—2 Tím. 2:22.
4 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ànímọ́ táa dá mọ́ni ṣe pàtàkì, ìṣarasíhùwà ẹni àti irú ẹ̀mí tẹ́ni náà ní ló ṣe pàtàkì jù. Ǹjẹ́ arákùnrin kan wà tó fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ fẹ́ láti yin Ọlọ́run, tó sì fẹ́ láti sìn nítorí àwọn ará? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, Jèhófà yóò bù kún ìsapá rẹ̀ láti tẹ̀ síwájú nínú ìjọ.