Máa Fi Ìwà Dídára Lọ́pọ̀lọpọ̀, Tó Ń Fògo fún Ọlọ́run Hàn
1 Ibikíbi tí a bá wà, ìwà wa, ìwọṣọ wa, àti ìmúra wa máa ń jẹ́rìí nípa wa àti nípa Ọlọ́run tí a ń sìn. Èyí máa ń hàn gbangba ní pàtàkì ní àpéjọ ńlá tí àwọn èèyàn Ọlọ́run máa ń ṣe, níbi tí ọ̀pọ̀ èèyàn ti máa ń rí wa. Nígbà tí a bá jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ, ó máa ń fògo fún orúkọ Jèhófà. (1 Pét. 2:12) Ṣùgbọ́n, ìwà tí kò dára tàbí ìgbésẹ̀ aláìnírònú tí àwọn díẹ̀ péré bá gbé lè mú ẹ̀gàn bá orúkọ Ọlọ́run àti àwọn èèyàn rẹ̀. (Oníw. 9:18b) Níní in lọ́kàn pé ìwà wa ni àwọn ará ìta ń wò láti fi díwọ̀n ètò àjọ wa àti Ọlọ́run tí a ń sìn gbọ́dọ̀ mú kí a máa fẹ̀rí ọkàn “ṣe ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run.”—1 Kọ́r. 10:31.
2 Ìwà Àwòfiṣàpẹẹrẹ ní Ibi Tí Ẹ Bá Dé Sí: Nínú àwọn ọ̀ràn tó pọ̀ jù lọ, ṣíṣe nǹkan létòlétò, ìwà rere, àti wíwà ní mímọ́ tónítóní àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń wú àwọn onílé lórí. Nígbà tí bàbá onílé kan ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìdílé Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n dé sí ilé rẹ̀, ó wí pé: “Ọmọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn ọmọ tó dára jù lọ tí mo tíì rí rí! Ṣe ni wọ́n múra fún wọn bí ọmọlúwàbí; òye yé wọn, wọ́n ń bọ̀wọ̀ fúnni, ìwà wọn sì dára; wọn kò sì fa ìṣòro kankan bó ti wù kó mọ. Ó yẹ kí wọ́n yìn yín nítorí àwọn èwe yín. A gbádùn bí àwọn ọmọ yín ṣe wá síbí.” Àwọn ọ̀rọ̀ báyìí ń wá ṣáá ni nítorí pé àwọn tó ń lájọṣe pẹ̀lú wa lè rí ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ tó wà láàárín àwọn èèyàn Jèhófà.
3 Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ọ̀rọ̀ tí àwọn onílé kan sọ fi hàn pé àwọn kan tí kò bìkítà nípa bí wọ́n ṣe ń hùwà tàbí tí wọ́n lo ilé tí wọ́n dé sí ní ìlòkulò ṣì jẹ́ ìṣòro. Èyí ń fa wàhálà, ó sì ń fa àríwísí tí kò yẹ kó wáyé. Àwọn onílé kan ṣàròyé pé àwọn ọmọ kéékèèké àti àwọn ọ̀dọ́langba máa ń pariwo, pé wọ́n sì ya ewèlè níwọ̀n bí àwọn òbí wọn kò ti bójú tó wọn.
4 Nínú àwọn ọ̀ràn kan, àwọn alápèéjọpọ̀ dé sí òtẹ́ẹ̀lì. Ọ̀pọ̀ òtẹ́ẹ̀lì wọ̀nyí ló ní ìlànà tí wọ́n retí pé kí àwọn àlejò tẹ̀ lé. Àwọn ará kan kò tẹ̀ lé ìlànà wọ̀nyí, ńṣe ni wọ́n ń pariwo tàbí tí wọ́n se oúnjẹ ní yàrá wọn. Àwọn alábòójútó òtẹ́ẹ̀lì sọ fún wa pé wọ́n sábà máa ń lo òtẹ́ẹ̀lì àwọn nílòkulò nípa síse oúnjẹ níbi tí kò yẹ. Kì í ṣe pé wọ́n ba yàrá jẹ́ ní ti gidi nìkan ni, ṣùgbọ́n òórùn tí kì í lọ bọ̀rọ̀ tún mú kó ṣòro láti gba àwọn ẹlòmíràn sínú àwọn yàrá náà fún ọ̀pọ̀ ọjọ́ tàbí ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀ lẹ́yìn náà. Bí wọn kò bá sọ ní pàtó pé àwọ́n fàyè gba síse oúnjẹ nínú yàrá, a kò gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀.
5 A gbọ́dọ̀ sapá gidigidi láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ pẹ̀lú àwọn onílé àti àwọn tó ní òtẹ́ẹ̀lì. Dájúdájú, a kò fẹ́ mú kí àwọn ẹlòmíràn ní èrò tí kò dára nípa àwọn èèyàn Jèhófà. Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, a gbọ́dọ̀ máa hùwà àìlábòsí nígbà gbogbo. A kò gbọ́dọ̀ mọ̀ọ́mọ̀ mú àwọn nǹkan tó jẹ́ ti àwọn ẹlòmíràn láìgba àṣẹ níbi tí a dé sí, nítorí pé olè jíjà ni ìyẹn jẹ́; bẹ́ẹ̀ ni a kò gbọ́dọ̀ parọ́ nígbà tí a bá ń sọ àwọn ohun tó bá bà jẹ́ níbi tí a dé sí.
6 Ìwà Ìmẹ̀yẹ ní Àpéjọpọ̀: Irú ibi yòówù kí a lò, a gbọ́dọ̀ wo ibẹ̀ bíi Gbọ̀ngàn Ìjọba ńlá lákòókò àpéjọpọ̀. Wíwọṣọ àti mímúra lọ́nà yíyẹ gbọ́dọ̀ hàn gbangba bíi ti ìgbà tí a bá ń lọ sí àwọn ìpàdé ìjọ wa. Nígbà tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọpọ̀ bá ń lọ lọ́wọ́ àti nígbà tó bá parí, àwọn arákùnrin àti arábìnrin gbọ́dọ̀ yẹra fún wíwọ aṣọ tí kò wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì tàbí tó jẹ́ ti aláṣà ìgbàlódé, tó ń fi ẹ̀mí ayé hàn, tó sì ń jẹ́ kó ṣòro láti dá wa mọ̀ pé a yàtọ̀ lọ́nà gbígbámúṣé. Kí àwọn arábìnrin kíyè sára, kí wọ́n rí i pé irú síkẹ́ẹ̀tì àti aṣọ tí wọ́n wọ̀ wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, kí àwọn aṣọ náà sì gùn níwọ̀ntúnwọ̀nsì lọ́nà tó bójú mu. (1 Tím. 2:9, 10) Bóyá a ń lọ sí àpéjọpọ̀ ni o, a wà ní ibi tí a dé sí ni o, a ń jẹun ní ilé àrójẹ ni o, tàbí a ń rajà ní ilé ìtajà ni o, a gbọ́dọ̀ máa fi hàn nígbà gbogbo pé òjíṣẹ́ Ọlọ́run ni wá, kí a má ṣe ohunkóhun tó lè fa ìkọ̀sẹ̀.—2 Kọ́r. 6:3.
7 Batisí yóò wáyé ní òwúrọ̀ ọjọ́ Saturday ní àpéjọpọ̀ náà. Ilé Ìṣọ́nà, April 15, 1995, ojú ìwé 30 ṣàpèjúwe bó ṣe yẹ ká ṣe nígbà ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn. Ó sọ pé a “níláti fi ọwọ́ pàtàkì tí ó yẹ mú ìbatisí. Kì í ṣe àkókò fún ariwo gèè, fún pípe àpèjẹ, tàbí fún ẹ̀rín aláriwo. Ṣùgbọ́n kì í tún ṣe àkókò amúnifajúro tàbí abaninínújẹ́.” Kò ní bójú mu rárá pé kí àwọn tó fẹ́ ṣe batisí wọ aṣọ ìwẹ̀ tí ó fò tàbí tí ń fi ara hàn, ì báà jẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin. Nítorí náà, gbogbo wa gbọ́dọ̀ fi ìjẹ́pàtàkì àti ayọ̀ ìbatisí Kristẹni hàn.
8 Pétérù rán wa létí nípa ‘irú ènìyàn tó yẹ kí á jẹ́ nínú ìṣe ìwà mímọ́ àti àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run.’ (2 Pét. 3:11) Ǹjẹ́ kí ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa ní Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Olùṣe Ohun Tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Wí” ran àwọn aláìlábòsí ọkàn tó ń wò wá lọ́wọ́ láti mọ Ọlọ́run wa atóbilọ́lá, ẹni tí gbogbo ìyìn àti ògo yẹ, kí wọ́n sì jọ́sìn rẹ̀.—1 Kọ́r. 14:24, 25.