“Kí Ohun Gbogbo Máa Ṣẹlẹ̀ fún Ìgbéniró”
1 Nínú bí a ṣe ń hùwà sí àwọn ará wa, a gbọ́dọ̀ máa ṣe ohun rere láti gbé wọn ró. Èyí túmọ̀ sí pé a gbọ́dọ̀ máa jẹ́ kí dídáàbò bo ire wọn nípa tẹ̀mí jẹ wá lógún. Bí a bá ń ṣe iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ kan, tó jẹ́ pé a ń ta nǹkan kan tàbí tí a ń ṣe irú iṣẹ́ kan fún àwọn èèyàn, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kí a má bàa ṣe ohunkóhun tí yóò mú àwọn ará wa kọsẹ̀.—2 Kọ́r. 6:3; Fílí. 1:9, l0.
2 Àwọn kan ti lọ́wọ́ nínú onírúurú okòwò tó léwu, tí wọ́n á sì máa wá bí àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn yóò ṣe di oníbàárà àwọn. Àwọn àjọ kan tí wọ́n ń bá tajà máa ń fún àwọn tí ó jẹ́ aṣojú wọn níṣìírí pé kí wọ́n máa fojú oníbàárà wo gbogbo èèyàn, títí kan àwọn tí wọ́n jọ ń ṣe ẹ̀sìn kan náà. Àwọn ará kan ti ṣètò àpéjọ ńlá fún àwọn Ẹlẹ́rìí kí wọ́n lè fún wọn níṣìírí láti lọ́wọ́ nínú okòwò kan. Àwọn mìíràn máa ń gbé okòwò wọn lárugẹ nípa fífi àwọn àpilẹ̀kọ, àwọn ìwé pẹlẹbẹ, tàbí kásẹ́ẹ̀tì àti fídíò ránṣẹ́ sí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn, tí kì í sì í ṣe pé àwọn yẹn ló béèrè fún un. Ṣe ó yẹ kí Kristẹni kan máa lo àjọṣe tó ní lọ́nà ti ìṣàkóso Ọlọ́run láti fi máa tú àwọn arákùnrin rẹ̀ nípa tẹ̀mí jẹ? Rárá o!—1 Kọ́r. 10:23, 24, 31-33.
3 Àwọn Ará Gbọ́dọ̀ Ṣọ́ra: Èyí kò túmọ̀ sí pé àwọn Kristẹni kò lè bá ara wọn ṣòwò. Ọ̀ràn ara ẹni nìyẹn. Ṣùgbọ́n, àwọn kan máa ń bẹ̀rẹ̀ okòwò tó kún fún ojúkòkòrò, wọ́n sì máa ń sún àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn láti wá bá wọn dòwò pọ̀ tàbí láti kówó lé irú okòwò bẹ́ẹ̀. Ọ̀pọ̀ lára irú okòwò bẹ́ẹ̀ ló máa ń forí ṣánpọ́n, wọ́n sì máa ń mú kí àwọn tó lọ́wọ́ nínú wọn pàdánù owó ribiribi. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ nítorí kí àwọn tó lọ́wọ́ nínú okòwò náà lè rí èrè jẹ ní kíákíá ni ó jẹ́ kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, ẹni tó ṣètò rẹ̀ kò gbọ́dọ̀ ronú pé òun kò lẹ́bi rárá bí okòwò náà bá forí ṣánpọ́n. Kí ó kọ́kọ́ fara balẹ̀ ronú ná nípa bí ipò àwọn ará yẹn yóò ṣe rí nípa ti ara àti nípa ti ẹ̀mí bí okòwò náà kò bá yọrí sí rere. Ní pàtàkì, àwọn tó di ipò ẹrù iṣẹ́ mú lábẹ́ ìṣàkóso Ọlọ́run gbọ́dọ̀ ṣọ́ra nípa àwọn iṣẹ́ ajé tí wọ́n ń ṣe nítorí pé àwọn mìíràn lè máa bọ̀wọ̀ fún wọn, wọ́n á sì gbẹ́kẹ̀ lé wọn gidigidi. Kò ní dáa kí wọ́n ṣi ìgbẹ́kẹ̀lé yẹn lò. Arákùnrin kan lè pàdánù àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn mímọ́ bí àwọn ẹlòmíràn kò bá bọ̀wọ̀ fún un mọ́.
4 Kí a fi ṣe góńgó wa pé “kí ohun gbogbo máa ṣẹlẹ̀ fún ìgbéniró.” (1 Kọ́r. 14:26) A gbọ́dọ̀ yẹra fún ṣíṣe ohunkóhun tó lè dá okòwò sílẹ̀ nínú ìjọ, a kò sì gbọ́dọ̀ gbé irú ohun bẹ́ẹ̀ lárugẹ. Irú àwọn nǹkan báyẹn kò ní ohunkóhun í ṣe pẹ̀lú ìdí tí Ìwé Mímọ́ fi sọ pé kí a máa pé jọ.—Héb. 10:24, 25.