ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 9/01 ojú ìwé 3
  • Ìgbà Àpéjọpọ̀ Jẹ́ Àkókò Ayọ̀!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìgbà Àpéjọpọ̀ Jẹ́ Àkókò Ayọ̀!
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jèhófà Ń kó Àwọn Èèyàn Rẹ̀ Aláyọ̀ Jọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Tí Ọlọ́run Fẹ́” ti 1998
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
  • Ǹjẹ́ O Mọrírì Àwọn Ohun Ọlọ́wọ̀?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
  • Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run” ti 1999
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
km 9/01 ojú ìwé 3

Ìgbà Àpéjọpọ̀ Jẹ́ Àkókò Ayọ̀!

1 Àkókò àpéjọpọ̀ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ àkókò ayọ̀ ńláǹlà. Fún ohun tó ti ju ọgọ́rùn-ún ọdún lọ, àwọn àpéjọpọ̀ wọ̀nyí ti fi kún ìbísí tó ti ń wáyé nínú ètò àjọ yìí. Láti ibi kékeré táa ti bẹ̀rẹ̀, a ti rí ìbùkún ńláǹlà látọ̀dọ̀ Jèhófà lórí iṣẹ́ wa. Lóde òní, ní àpéjọpọ̀ tí a kọ́kọ́ ṣe ní Chicago, Illinois, ní ọdún 1893, àádọ́rin nínú ọ̀tàlélọ́ọ̀ọ́dúnrún [360] èèyàn tó pésẹ̀ síbẹ̀ ló ṣe ìrìbọmi láti fi hàn pé àwọn ti ya ara àwọn sí mímọ́ fún Jèhófà. Jákèjádò ayé, iye àwọn tó wá sí ọ̀wọ́ Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Olùṣe Ohun Tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Wí” táa ṣe lọ́dún tó kọjá jẹ́ mílíọ̀nù mẹ́sàn-án, ẹgbẹ̀rún lọ́nà irínwó ó lè mẹ́rìnléláàádọ́ta, àti ẹyọ márùnléláàádọ́ta [9,454,055], tí àwọn ẹgbẹ̀rún lọ́nà mọ́kàndínláàádóje àti ọ̀ọ́dúnrún ó lé mẹ́tàdínláàádọ́rin [129,367] sì ṣe ìrìbọmi. Èyí mà táyọ̀ o!

2 Láti ìgbà tí a ti kọ Bíbélì ni pípéjọ àwọn èèyàn Ọlọ́run ti jẹ́ ọ̀nà títayọ tí Jèhófà ń gbà fúnni ní ìtọ́ni. Nígbà ayé Ẹ́sírà àti Nehemáyà, àwọn èèyàn tẹ́tí sí kíka Òfin náà “láti àfẹ̀mọ́jú títí di ọjọ́kanrí.” (Neh. 8:2, 3) Nítorí pé àwọn èèyàn tó wà níbẹ̀ túbọ̀ lóye Òfin náà sí i, wọ́n ní ‘ayọ̀ ńláǹlà.’ (Neh. 8:8, 12) Àwa náà yọ̀ pé àwọn àpéjọpọ̀ máa ń jẹ́ ká láǹfààní láti gbọ́ ìtọ́ni tó dára ká sì jẹ oúnjẹ tẹ̀mí “ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu” látọ̀dọ̀ Jèhófà nípasẹ̀ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye.” (Mát. 24:45) Níwọ̀n bí Jésù ti sọ pé èèyàn gbọ́dọ̀ wà láàyè nípasẹ̀ “gbogbo àsọjáde tí ń jáde wá láti ẹnu Jèhófà,” àwọn àpéjọpọ̀ ṣe kókó fún ìlera wa nípa tẹ̀mí.—Mát. 4:4.

3 Ẹ Jẹ́ Ká Ṣe Gbogbo Ohun Táa Bá Lè Ṣe Láti Wà Níbẹ̀: Kí gbogbo wa fi wíwà ní Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Olùkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” ti ọdún yìí láti ìbẹ̀rẹ̀ dópin ṣe ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ń lépa. Kí á wéwèé láti tètè dé ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan kí a sì wà níbẹ̀ títí tí a óò fi dara pọ̀ láti sọ pé “Àmín!” sí àdúrà ìparí. Láti ṣe èyí, ó lè gba pé ká yí ìtòlẹ́sẹẹsẹ wa padà. Gbígba àyè níbi iṣẹ́ wa láti lọ sí àpéjọpọ̀ yìí lè ṣòro díẹ̀. Ó yẹ ká pinnu pé a ní láti wà níbẹ̀, kò yẹ ká ronú pé tó bá ṣeé ṣe ni. Bí a bá nílò ilé tí a óò dé sí àti/tàbí ohun ìrìnnà, kí á tètè ṣètò ìyẹn. Gbogbo ohun táa bá lè ṣe láti wà níbẹ̀ ló yẹ ká ṣe!

4 Kì í ṣe owó ni àwọn ìbùkún táwọn èèyàn Jèhófà ń rí nínú lílọ sí àpéjọpọ̀. Wo àpẹẹrẹ àwọn kan tí wọ́n pinnu láti lọ sí Àpéjọpọ̀ Àgbáyé Ìfẹ́ Àtọ̀runwá ti Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́dún 1958 ní Ìlú New York. Arákùnrin kan pa iṣẹ́ kọ́lékọ́lé tó ń ṣe tì fún ọ̀sẹ̀ méjì kí ó lè yọ̀ǹda ara rẹ̀ láti ṣèrànwọ́ kí ó sì lọ sí àpéjọ náà. Arákùnrin kan ní erékùṣù Virgin Islands ta ilẹ̀ hẹ́kítà méjì kí gbogbo ìdílé rẹ tí wọ́n jẹ́ mẹ́fà lápapọ̀ lè lọ. Tọkọtaya kan tí wọn ò dàgbà púpọ̀ ta ọkọ̀ ojú omi wọn tí ń lo ẹ̀rọ kí àwọn àtàwọn ọmọ wọn mẹ́ta tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ oṣù méjì sí ọdún méje lè lọ sí àpéjọpọ̀ náà. Àwọn arákùnrin mẹ́ta kan láti California tí wọ́n jẹ́ ìbátan ni wọ́n sọ fún níbi iṣẹ́ pé bí wọ́n bá fi lè pa ibi iṣẹ́ jẹ, kò ní sí iṣẹ́ fún wọn mọ́ nígbà tí wọ́n bá padà dé. Ṣùgbọ́n, ìyẹn kò dá wọn dúró pé kí wọ́n má lọ sí àpéjọpọ̀ mánigbàgbé yẹn.

5 Jèhófà Máa Ń Bù Kún Ìsapá Aláápọn Wa: Jèhófà máa ń rí ìsapá táwọn èèyàn rẹ̀ bá ṣe, ó sì máa ń bù kún un. (Héb. 6:10) Bí àpẹẹrẹ, ní Àpéjọpọ̀ Ìbísí Ìjọba Ọlọ́run lọ́dún 1950, àwọn tó pésẹ̀ síbẹ̀ gbọ́ àsọyé mánigbàgbé tí a pe àkọlé rẹ̀ ní “Ètò Àwọn Nǹkan Tuntun.” Arákùnrin Frederick Franz ru ìfẹ́ àwọn èèyàn sókè nípa bíbéèrè pé: “Ǹjẹ́ àwa táa wá sí àpéjọpọ̀ àgbáyé yìí yóò láyọ̀ láti mọ̀ pé níhìn-ín, lálẹ́ yìí, àwọn kan wà láàárín wa tí wọ́n fojú sọ́nà láti jẹ́ olórí nínú ilẹ̀ ayé tuntun?” Àádọ́ta ọdún ti kọjá o, ṣùgbọ́n a ṣì ń yọ̀ nítorí òye tó ṣe yékéyéké nípa Sáàmù 45:16 yìí.

6 Lẹ́yìn lílọ sí àpéjọpọ̀ àgbègbè ọdún tó kọjá, olórí ìdílé kan tó mọrírì kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin ará, ẹ ò lè mọ bí àpéjọpọ̀ yìí ṣe jẹ́ agbẹ̀mílà tó. Ọ̀rọ̀ iṣẹ́ ló mú kí ìdílé mi kó lọ sí ìlú ńlá, ṣùgbọ́n ohun tó wá ṣẹlẹ̀ ni pé ipò tẹ̀mí wa ò fi bẹ́ẹ̀ lọ déédéé mọ́. . . . A ò tún náání àwọn ojúṣe wa gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni mọ́. Kódà, a ṣíwọ́ lílọ sí àwọn ìpàdé bẹ́ẹ̀ la ò sì kópa nínú iṣẹ́ ìsìn mọ́. . . . Àpéjọpọ̀ yìí ló mú wa bọ̀ sípò, bẹ́ẹ̀ la tún dẹni tó ń wéwèé àwọn nǹkan tẹ̀mí táa fẹ́ láti lépa, a sì ń ṣètò láti rí i pé ọwọ́ wa tẹ̀ wọ́n.”

7 Jèhófà ń fún wa ní oúnjẹ tẹ̀mí táa nílò. Ó máa ń tẹ́ tábìlì ọ̀pọ̀ yanturu oúnjẹ ní àwọn àpéjọpọ̀ wa. Ó yẹ kí ìmọrírì táa ní fún ohun tó ń pèsè yìí mú ká sọ ohun tí Kọ̀nílíù sọ nígbà tí àpọ́sítélì Pétérù ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sọ pé: “Lọ́tẹ̀ yìí, gbogbo wa wà níwájú Ọlọ́run láti gbọ́ gbogbo ohun tí Jèhófà ti pàṣẹ pé kí o sọ.” (Ìṣe 10:33) Ẹ jẹ́ ká pinnu láti “wà níwájú Ọlọ́run” ní gbogbo àkókò ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Olùkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” ti ọdún yí kí a sì yọ̀!

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́