Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ji! Sept. 8
“Àwọn àgbà retí pé káwọn èwe máa láyọ̀ nítorí pé ó hàn gbangba pé ìgbésí ayé wọn kò mú àníyàn lọ́wọ́. Ó dájú pé àníyàn táwọn àgbà máa ń ní kì í bá wọn. Ṣùgbọ́n, láwọn ọdún lọ́ọ́lọ́ọ́, àwọn èwe tó túbọ̀ ń pọ̀ sí i ló ń ní ìsoríkọ́. Ǹjẹ́ o mọ ohun tó fà á? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé díẹ̀ lára àwọn ohun tó ń fà á, àti bí a ṣe lè ṣèrànwọ́ fún àwọn ọ̀dọ́langba tó ń ní ìsoríkọ́. [O lè ka 1 Tẹsalóníkà 5:14.]”
Ilé Ìṣọ́ Sept. 15
“Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé inú gbogbo ìsìn la ti lè rí àwọn tó fẹ́ràn òtítọ́. Síbẹ̀, ní gbogbo gbòò, ìsìn máa ń pín àwọn èèyàn níyà ni. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe láti mú àwọn olóòótọ́ ọkàn ṣọ̀kan? [Lẹ́yìn tí ẹni náà bá fèsì, ka Sefanáyà 3:9.] Ìwé ìròyìn yìí sọ nípa bí ìmọ̀ Ọlọ́run tòótọ́ náà ṣe ń mú àwọn èèyàn níbi gbogbo ṣọ̀kan.”
Ilé Ìṣọ́ Oct. 1
“Ìwọ́ pẹ̀lú á gbà pé àwọn èèyàn kò fi bẹ́ẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ mọ́. Ṣùgbọ́n, kí ló fà èyí? [Lẹ́yìn tí ẹni náà bá fèsì, ka Hébérù 11:1.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé ohun tí ìgbàgbọ́ tòótọ́ jẹ́ gan-an, àti ìyàtọ̀ tí ń bẹ nínú pé kí èèyàn ní ìgbàgbọ́ àti kéèyàn má ní in.”
Ji! Oct. 8
“Ọ̀pọ̀ jù lọ lára wa ló máa ń rò pé ìgbà gbogbo loúnjẹ á máa wà. Ṣùgbọ́n ominú ti ń kọ àwọn èèyàn báyìí pé ó ṣeé ṣe kí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣàkóbá fún ọ̀nà tí a ń gbà rí oúnjẹ. Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé díẹ̀ lára ohun tó ń kọ àwọn èèyàn lóminú yìí àti ìrètí tí ó tinú Bíbélì wá pé ojútùú gidi wà sí ìṣòro ọ̀hún.”