Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ile Iṣọ Sept. 15
Mẹ́nu ba ìròyìn kan tó wà lẹ́nu àwọn èèyàn ládùúgbò yín. Kó o wá bi onítọ̀hún pé: “Ṣó o rò pé ohun tí ẹsẹ Bíbélì yìí sọ nípa àkókò tá à ń gbé yìí bá ohun tó ń ṣẹlẹ̀ mu? [Ka 2 Tímótì 3:1, kó o sì jẹ́ kó fèsì.] Àpilẹ̀kọ yìí ṣàgbéyẹ̀wò ẹ̀rí tó wà pé àkókò òpin là ń gbé, ó sì sọ ohun tá a gbọ́dọ̀ ṣe.”
Ile Iṣọ Oct. 1
“Àwọn onímọ̀ nípa ohun alààyè ń gbìyànjú láti mú kí àrùn kásẹ̀ nílẹ̀ kí ẹ̀mí wa bàa lè gùn. Ṣó o rò pó máa ṣeé ṣe pé kéèyàn máà kù láéláé? [Jẹ́ kó fèsì.] Kíyè sí ohun tó ń mú kó máa wù wá láti pẹ́ láyé. [Ka Oníwàásù 3:11.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé ìdí tí Ọlọ́run fi dá ohun tó ń mú kó máa wù wá láti wàláàyè títí láé mọ́ wa.”
Jí! July-Sept.
Bó o bá bá ọ̀dọ́ kan pàdé, o lè sọ fún un pé: “Ǹjẹ́ o tiẹ̀ ti sọ fáwọn òbí ẹ rí pé kí wọ́n ṣàlàyé bí ọ̀ràn àbójútó ilé ṣe rí fún ẹ? [Jẹ́ kó fèsì.] Ohun tó dáa ni pé kó o bi wọ́n, ìyẹn bó o bá fẹ́ kí ọkàn ẹ balẹ̀ pé o ò ní kó sí gbèsè. [Ka Òwe 1:5.] Àpilẹ̀kọ tó wà lójú ewé 13 ìwé ìròyìn yìí fi hàn látinú Bíbélì bá a ṣe lè máa ṣọ́wó ná.”
“Lẹ́yìn táwọn kan bá ka ẹsẹ Bíbélì bí èyí, [Ka Mátíù 3:16, 17.] wọ́n máa ń rò pé ẹnì kan ni ẹ̀mí mímọ́. Ṣé ohun tíwọ náà ń rò nìyẹn? [Jẹ́ kó fèsì.] Àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 30 nínú ìwé ìròyìn yìí tẹnu mọ́ ìdí mẹ́ta tó mú kó ṣe kedere pé Bíbélì ò fi kọ́ni pé ẹ̀mí mímọ́ jẹ́ ẹnì kan.”