Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ile Iṣọ Sept. 15
“Kí lèrò ẹ nípa ohun tí ẹsẹ Bíbélì yìí sọ. [Ka Diutarónómì 32:4.] Ǹjẹ́ kò máa ṣe ẹ́ ní kàyéfì pé bó bá jẹ́ pé òótọ́ ni Ọlọ́run jẹ́ alágbára gbogbo, tí kì í fi igbá kan bọ̀kan nínú, kí ló dé tí ìyà àti ìwà ibi fi pọ̀ tó báyìí lórí ilẹ̀ ayé? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé ìdí tí Ọlọ́run ò fi tíì wá nǹkan ṣe sí ìwà ibi títí di àkókò yìí.”
Ile Iṣọ Oct. 1
“Ǹjẹ́ o ti ṣe nǹkan kan rí tó o wá rò ó nínú ara ẹ pé, ‘Ǹ bá má ṣe ohun tí mo ṣe yìí o!’? [Jẹ́ kó fèsì.] Gbọ́ ohun tí ẹsẹ Bíbélì yìí sọ nípa ìdí tá a fi máa ń kábàámọ̀ àwọn nǹkan kan lẹ́yìn tá a bá ti ṣe é tán. [Ka Jeremáyà 10:23.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé bí ìmọ̀ràn wíwúlò tó wà nínú Bíbélì ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó dáa.”
Jí! July–Sept.
“Àwa èèyàn yàtọ̀ sáwọn ẹranko tó jẹ́ pé ọgbọ́n àdámọ́ni ló ń darí wọn, torí pé fúnra tiwa là ń yan ìlànà tá a máa tẹ̀ lé. Ibo lo rò pé a ti lè rí ìtọ́sọ́nà tó ṣeé gbára lé. [Jẹ́ kó fèsì. Kó o wá ka Sáàmù 119:105.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé bí ìmọ̀ràn tó wà nínú Bíbélì ṣe wúlò láìmọye ọ̀nà ju ìmọ̀ràn èyíkéyìí lọ.”
“Màá fẹ́ kó o gbọ́ ẹsẹ Bíbélì tí mo fẹ́ kà yìí. [Ka 1 Tímótì 6:10.] Ṣéwọ náà gbà pé báwọn tó wà nínú ìdílé kì í bá walé ayé máyà, pákáǹleke á dín kù, ọkàn gbogbo wọn á balẹ̀, àti pé àtúbọ̀tán tí ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ ò ní kàn wọ́n? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí mẹ́nu ba àwọn àbá tó ti ran àwọn kan lọ́wọ́ láti dín ọrọ̀ tí wọ́n ń kó jọ kù, ó sì tún sọ nípa bí ètò tó mọ́gbọ́n dání tí wọ́n ṣe ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́.” Fi àpótí tó wà lójú ewé 29 hàn án.