ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 9/02 ojú ìwé 8
  • Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
  • Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
  • Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
km 9/02 ojú ìwé 8

Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn

Ilé Ìṣọ́ Sept. 15

“Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn gbà gbọ́ pé ‘àwọn ẹni mímọ́’ ní agbára tó ṣàrà ọ̀tọ̀, àti pé kò sóhun tó burú láti máa gbàdúrà nípasẹ̀ wọn. Kí lo rò? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Kíyè sí ohun tí Jésù Kristi sọ. [Ka Jòhánù 14:6.] Ọ̀rọ̀ Bíbélì yìí máa ń mú kí àwọn kan ṣe kàyéfì bóyá ó tọ́ láti gbàdúrà nípasẹ̀ ‘àwọn ẹni mímọ́.’ Ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ yìí jíròrò kókó pàtàkì náà.”

Ilé Ìṣọ́ Oct. 1

“Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń ṣe kàyéfì bóyá àwọn wàhálà tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́tùn-ún lósì máa dópin láé—irú bí ogun, ìwà ọ̀daràn, àti ìpániláyà. Kí lèrò tìẹ? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Bíbélì fún wa ní ìdánilójú yìí tí ń tuni nínú. [Ka Sáàmù 37:10, 11.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé ìdí tí Ọlọ́run kò ṣe tíì fòpin sí ìwà ibi àti ìjìyà tó máa ń fà fún àwọn èèyàn.”

Jí! Oct. 8

“Ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ni ìwà láabi àwọn apániláyà ń bà lẹ́rù, torí wọ́n tún lè lo àwọn ohun ìjà oníkòkòrò àrùn. Ǹjẹ́ o rò pé àwọn ìjọba èèyàn lè mú ìpániláyà kúrò lórí ilẹ̀ ayé? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Bíbélì jẹ́ ká mọ ohun tí Ọlọ́run pinnu láti ṣe. [Ka Ìsíkíẹ́lì 34:28.] Ìwé ìròyìn Jí! yìí jíròrò díẹ̀ lára àwọn ohun tó so mọ́ irú àjálù tí wọ́n lè fà.”

“Lónìí, ó dà bíi pé iye àwọn ìdílé olóbìí kan ti wá pọ̀ gan-an lọ́nà tó kàmàmà. Bíbélì fi hàn pé àánú wọn ń ṣe Ẹlẹ́dàá wa. [Ka Sáàmù 146:9.] Ìtẹ̀jáde Jí! yìí ṣàlàyé bí àwọn ìlànà Bíbélì ṣe lè ran àwọn òbí tó ń dá tọ́mọ lọ́wọ́ láti ṣe àṣeyọrí nínú títọ́ ọmọ wọn.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́